ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yc ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 20-21
  • Jeremáyà Ń Bá A Lọ Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jeremáyà Ń Bá A Lọ Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Rán Jeremáyà Pé Kó Lọ Wàásù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • “Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi sí Ẹnu Rẹ”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Èmi Kò Lè Dákẹ́”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Kí O sì Sọ Ọ̀rọ̀ Yìí Fún Wọn”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
Àwọn Míì
Kọ́ Ọmọ Rẹ
yc ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 20-21

Ẹ̀kọ́ 9

Jeremáyà Ń Bá a Lọ Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà

Àwọn èèyàn tó ń bínú yí Jeremáyà ká

Kí nìdí tí àwọn èèyàn fi ń bínú sí Jeremáyà?

Wọ́n ń fa Jeremáyà jáde láti inú kòto jíjìn tó ní ẹrẹ̀

Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà

Nígbà míì, àwọn èèyàn lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n bínú sí wa tí a bá lọ sọ̀rọ̀ Jèhófà fún wọn. Èyí lè mú ká sọ pé a kò ní sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run mọ́. Ṣé ó ti ṣe ìwọ náà rí?— Bíbélì sọ fún wa nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ tí kò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà mọ́. Jeremáyà ni orúkọ ọkùnrin náà. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Jeremáyà kò tíì dàgbà púpọ̀ nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé, kó lọ kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n jáwọ́ nínú àwọn nǹkan búburú tí wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ yìí kò rọrùn fún Jeremáyà láti ṣe torí pé ẹ̀rù ń bà á. Ó wá sọ fún Jèhófà pé: ‘Èmi kò mọ ohun tí mo màá sọ. Ọmọdé lásán ni mí.’ Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún un pé: ‘Má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’

Bí Jeremáyà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nìyẹn pé, tí wọn kò bá yí ìwà pa dà, Ọlọ́run máa fìyà jẹ wọ́n. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn èèyàn ṣe ohun tí Jeremáyà sọ?— Rárá o. Ńṣe ni wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn míì tiẹ̀ bínú sí i, wọ́n sì tún fẹ́ pa á! Báwo lo ṣe rò pé gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ṣe rí lára Jeremáyà?— Ẹ̀rù bà á, ó sọ pé: ‘Èmi kò ní sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà mọ́.’ Àmọ́ ṣé Jeremáyà ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?— Rárá, kò sẹ bẹ́ẹ̀. O nífẹ̀ẹ́ Jèhófà débi pé kò tiẹ̀ lè dákẹ́ kó máà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́. Torí pé Jeremáyà kò jáwọ́, Jèhófà ń báa lọ láti máa dáàbò bò ó.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan àwọn ọkùnrin burúkú kan ju Jeremáyà sínú ihò ńlá kan tí ẹrọ̀fọ̀ kún inú rẹ̀. Wọn kò fún un ní oúnjẹ àti omi. Àwọn ọkùnrin yìí fẹ́ kí Jeremáyà kú síbẹ̀. Àmọ́ Jèhófà ràn án lọ́wọ́, ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn!

Kí lo kọ́ lára Jeremáyà?— Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù máa ń bà á nígbà míì, ó ń bá a lọ láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Tí ìwọ náà bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, àwọn èèyàn lè máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n bínú sí ẹ. Ojú lè máa tì ẹ́ tàbí kí ẹ̀rù máa bà ẹ́. Àmọ́ máa bá a lọ láti máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Nígbà gbogbo ni yóò máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, bó ṣe ran Jeremáyà lọ́wọ́.

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ

  • Jeremáyà 1:4-8; 20:7-9; 26:8-19, 24; 38:6-13

ÌBÉÈRÈ:

  • Kí ni Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé kó ṣe?

  • Kí nìdí tí Jeremáyà kò fi fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà mọ́?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jeremáyà lọ́wọ́?

  • Kí lo kọ́ lára Jeremáyà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́