ORÍ KẸTA
“Kí o Sì Sọ Ọ̀rọ̀ Yìí Fún Wọn”
1. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù àti Jeremáyà gbà jọra? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà nínú iṣẹ́ ìwàásù wa?
JÉSÙ KRISTI ni àpẹẹrẹ tó ta yọ tá à ń tẹ̀ lé bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere. Ẹ sì wá wò ó o, nígbà táwọn èèyàn kan ní ọ̀rúndún kìíní kíyè sí Jésù, ńṣe ni wọ́n rò pé wòlíì Jeremáyà ni. (Mát. 16:13, 14) Bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ pé kí Jésù wàásù náà ló ṣe pàṣẹ pé kí Jeremáyà lọ wàásù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan Ọlọ́run sọ fún Jeremáyà pé: “Kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà . . . wí.’” (Jer. 13:12, 13; Jòh. 12:49) Àwọn ànímọ́ tí Jeremáyà lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ àtèyí tí Jésù lò sì jọra wọn.
2. Báwo ni ohun tó yẹ káwọn èèyàn ṣe lónìí ṣe jọ ohun tó yẹ káwọn Júù ṣe nígbà ayé Jeremáyà?
2 Lóòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí kan lè sọ pé: ‘Iṣẹ́ ìwàásù wa yàtọ̀ sí ti Jeremáyà. Orílẹ̀-èdè tó ti yara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni Jeremáyà ń jíṣẹ́ Ọlọ́run fún, nígbà tó jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn táwa ń wàásù fún ni kò mọ Jèhófà.’ Òótọ́ ni. Àmọ́ nígbà ayé Jeremáyà lọ́hùn-ún, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ti di “aláìgbọ́n” tí wọ́n sì ti fi Ọlọ́run tòótọ́ sílẹ̀. (Ka Jeremáyà 5:20-22.) Èyí gba pé kí wọ́n yí pa dà, kí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Bákan náà ló ṣe yẹ káwọn èèyàn mọ Jèhófà lónìí, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì máa sìn ín lọ́nà tó tọ́, yálà wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn tàbí wọn kì í ṣe Kristẹni. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà, káwa náà máa sin Ọlọ́run tòótọ́, ká sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.
‘JÈHÓFÀ FỌWỌ́ KAN ẸNU MI’
3. Kí ni Ọlọ́run ṣe fún Jeremáyà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì, ipa wo sì ni èyí ní lórí rẹ̀?
3 Rántí pé nígbà tí Jeremáyà di wòlíì, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí: “Ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí èmi yóò rán ọ lọ ni kí o lọ; ohun gbogbo tí mo bá sì pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ. Má fòyà nítorí ojú wọn, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè,’ ni àsọjáde Jèhófà.” (Jer. 1:7, 8) Ọlọ́run sì ṣe ohun kan tí Jeremáyà kò rò tẹ́lẹ̀. Jeremáyà sọ pé: “Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú kí ó kan ẹnu mi. Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún mi pé: ‘Kíyè sí i, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ. Wò ó, mo ti fàṣẹ yàn ọ́ lónìí.’” (Jer. 1:9, 10) Látìgbà yẹn ni Jeremáyà ti mọ̀ pé òun ti di agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run Olódùmarè.a Ọlọ́run sì ti Jeremáyà lẹ́yìn gan-an débi pé ìtara rẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i.—Aísá. 6:5-8.
4. Sọ àpẹẹrẹ àwọn onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó o mọ̀.
4 Lónìí, Jèhófà kì í fọwọ́ ara rẹ̀ kan èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe ṣe fún Jeremáyà níhìn-ín. Síbẹ̀, ó ń jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ mú kó máa wù wọ́n láti wàásù ìhìn rere. Púpọ̀ nínú wọn sì ní ìtara gan-an. Àpẹẹrẹ kan ni ti Maruja tó ń gbé nílẹ̀ Sípéènì. Ó lé ní ogójì ọdún tó ti rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀. Èyí mú kó ṣòro fún un láti máa wàásù láti ilé dé ilé. Nítorí náà, ó wá àwọn ọ̀nà mìíràn táá fi lè máa ṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀nà kan ni pé ó máa ń kọ lẹ́tà. Maruja máa ń sọ ohun tó fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ fún ọmọbìnrin rẹ̀. Ọmọ yìí á wá kọ wọ́n sínú lẹ́tà. Ní oṣù kan tí Maruja àti ọmọbìnrin rẹ̀ tó ń bá a kọ lẹ́tà yìí ṣe iṣẹ́ ìwàásù lákànṣe, wọ́n fi lẹ́tà tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [150] ránṣẹ́ sáwọn èèyàn, wọ́n sì fi àṣàrò kúkúrú sínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ìsapá wọn yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbé lábúlé kan tó wà nítòsí wọn láti gbọ́ ìhìn rere. Maruja sọ fún ọmọ rẹ̀ pé: “Tí ọ̀kan nínú àwọn lẹ́tà wa bá bọ́ sọ́wọ́ ẹni tó lọ́kàn tó dáa, Jèhófà á jẹ́ kó yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Alàgbà kan ní ìjọ tí Maruja wà sọ pé: “Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí irú àwọn arábìnrin bíi Maruja, tó máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́.”
5. (a) Kí ni kò jẹ́ kí Jeremáyà dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró nígbà táwọn èèyàn ò kọbi ara sí ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Báwo lo ṣe lè máa fi ìtara bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ lọ?
5 Nígbà ayé Jeremáyà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ni kò “ní inú dídùn sí” ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ Jeremáyà wá dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró nítorí pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn kò kọbi ara sí ohun tó ń sọ? Rárá o! Jeremáyà sọ pé: “Mo . . . ti kún fún ìhónú Jèhófà. Àárẹ̀ mú mi láti mú un mọ́ra.” (Jer. 6:10, 11) Báwo lo ṣe lè ní ìtara bíi ti Jeremáyà? Ọ̀nà kan ni pé kó o máa ronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tó o ní láti máa ṣojú fún Ọlọ́run tòótọ́. O mọ̀ pé àwọn olókìkí inú ayé yìí ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run tòótọ́. Sì tún wo bí àwọn aṣáájú ìsìn ṣe ń ṣi àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ tó o tí ń wàásù lọ́nà bíi tàwọn wòlíì ìgbà ayé Jeremáyà. (Ka Jeremáyà 2:8, 26, 27.) Àmọ́, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí o ń polongo jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí Ọlọ́run gbà ń ṣojú rere sí aráyé. (Ìdárò 3:31, 32) Tó o bá ń ronú lórí kókó yìí, ìtara tó o fi ń polongo ìhìn rere, tó o sì fi ń ran àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́wọ́ á túbọ̀ máa pọ̀ sí i.
6. Àwọn ìṣòro tó le wo ni Jeremáyà bá pàdé?
6 Nígbà míì kì í rọrùn láti fi ìtara wàásù lóde ẹ̀rí. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Jeremáyà náà bá ìṣòro tó le pàdé bó ṣe ń sin Jèhófà, títí kan àwọn wòlíì èké. O lè rí àpẹẹrẹ kan nínú Jeremáyà orí kejìdínlọ́gbọ̀n. Ọ̀pọ̀ èèyàn kò kọbi ara sí iṣẹ́ tí Jeremáyà ń jẹ́, débi pé nígbà míì ó máa ń ṣe é bíi pé ó dá wà lóun nìkan. (Jer. 6:16, 17; 15:17) Ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn ọ̀tá láwọn máa pa á, àmọ́ kò jẹ́ kí ìyẹn dẹ́rù ba òun.—Jer. 26:11.
Kí nìdí tó o fi lè gbára lé Jèhófà pé á jẹ́ kó o lè borí àwọn ìṣòro tó o bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
“O TI TÀN MÍ, JÈHÓFÀ”
7, 8. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà fi ọgbọ́n ‘tan’ Jeremáyà?
7 Láàárín ìgbà kan tí wọ́n ń fi Jeremáyà ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń bú u lójoojúmọ́, ó sọ bó ṣe rí lára rẹ̀ fún Ọlọ́run. Àmọ́, ọ̀nà wo lo rò pé Jèhófà gbà ‘tan’ wòlíì rẹ̀ olóòótọ́ yìí, bí Jeremáyà 20:7, 8 ṣe sọ?—Kà á.
8 Ó dájú pé Jèhófà kò fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tàbí ètekéte tan Jeremáyà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fọgbọ́n ‘tan’ wòlíì rẹ̀ yìí ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ṣé ẹ rí i, Jeremáyà gbà pé àtakò tí òun ń dojú kọ ti pọ̀ jù fóun, pé ẹ̀mí òun ò gbé iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fòun mọ́. Ṣùgbọ́n ó ṣiṣẹ́ yẹn parí o, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn Olódùmarè. Jèhófà fi ọgbọ́n tó ju ti Jeremáyà lọ mú un ṣe ohun tó ti rò pé òun ò lágbaja rẹ̀. Nígbà tó rò pé agbára òun ti pin, pé ẹ̀mí òun ò gbé e mọ́, Jèhófà fi ọgbọ́n yí i lérò pa dà bí ẹni pé ńṣe ló tàn án ṣe iṣẹ́ náà. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run lo agbára tirẹ̀ láti mú kí wòlíì náà ṣe ohun tó ti rò pé òun ò lè ṣe. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lójú ìdágunlá, ẹ̀tanú àti àtakò tó le koko, Jeremáyà ń bá a lọ láti wàásù.
9. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ inú Jeremáyà 20:11 fi lè mú ká ní ìgboyà?
9 Jèhófà wà pẹ̀lú Jeremáyà gẹ́gẹ́ bí “alágbára ńlá tó ń jáni láyà,” ó sì ń tì í lẹ́yìn. (Jer. 20:11) Ọlọ́run lè fún ìwọ náà nígboyà tí wàá fi máa lo ìtara nínú ìjọsìn tòótọ́, kó o sì máa bá a lọ láìfi ìṣòro tó le koko pè.
10. Kí lo ti pinnu láti ṣe tó o bá dojú kọ àtakò?
10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kí kókó yẹn ṣe kedere nígbà tó ń gba àwọn Kristẹni tó dojú kọ àtakò níyànjú. Ó kọ̀wé pé: “Kìkì pé kí ẹ máa hùwà lọ́nà tí ó yẹ ìhìn rere nípa Kristi . . . kí n lè máa gbọ́ . . . pé ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere, tí àwọn tí ó kọjú ìjà sí yín kò sì kó jìnnìjìnnì bá yín lọ́nàkọnà.” (Fílí. 1:27, 28) Bíi ti Jeremáyà àtàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, á dára kí ìwọ náà gbára lé Ọlọ́run Olódùmarè bó o ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Bí àwọn kan bá ń fi ọ́ ṣẹ̀sín tàbí wọ́n ń ta kò ọ́, rántí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, yóò sì fún ọ lágbára. Ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún Jeremáyà àti fún ọ̀pọ̀ àwọn ará wa, nítorí náà jẹ́ kó dá ọ lójú pé yóò fún ìwọ náà lágbára. Máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i, kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pé yóò gbọ́ àdúrà rẹ. Ìwọ náà lè rí i pé Ọlọ́run “tàn” ọ́ ní ti pé ó lo agbára rẹ̀ láti fún ọ ní ìgboyà tó o fi ń borí àtakò dípò tí wàá fi máa bẹ̀rù. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run lè mú kí ìwọ náà ṣe ju ohun tó o rò pé agbára rẹ gbé lọ.—Ka Ìṣe 4:29-31.
11, 12. (a) Àwọn ìyípadà wo lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí? (b) Àwọn ibo nìwọ náà ti lè máa rí àwọn èèyàn wàásù fún bí èyí tá a rí nínú àwòrán ojú ìwé 39?
11 Ohun tá a kà nípa bí wòlíì Jeremáyà ṣe ṣe iṣẹ́ rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà ká lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tá à ń ṣe. Lẹ́yìn tó ti lé ní ogún ọdún tí Jeremáyà ti jẹ́ wòlíì Jèhófà, ó sọ pé: “Mo . . . ń bá yín sọ̀rọ̀ ṣáá, mo ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀.” (Jer. 25:3) Jeremáyà kì í pẹ́ kó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, ṣe ló máa ń jí ní kùtùkùtù láti bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀? Ní ọ̀pọ̀ ìjọ, àwọn akéde kan máa ń jí jáde ní ìdájí láti lọ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láwọn ibùdókọ̀ àti ní ojú irin. Láwọn abúlé pàápàá, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí máa ń jáde láàárọ̀ kùtù láti lọ bá àwọn àgbẹ̀ àtàwọn míì tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ronú àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà lo ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nípa bí wòlíì Jeremáyà ṣe ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀? O ò ṣe máa tètè gbéra nílé kó o lè máa bá àwọn ará bẹ̀rẹ̀ ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lásìkò tí ìjọ fi sí.
12 Kódà lọ́pọ̀ ibi, ìgbà tí wọ́n bá wàásù láti ilé dé ilé lọ́wọ́ ọ̀sán tàbí nírọ̀lẹ́ ni wọ́n sábà máa ń rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀ jù. Àwọn akéde kan tilẹ̀ máa ń wàásù lọ́wọ́ alẹ́, wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilé epo, ilé oúnjẹ àtàwọn ibi iṣẹ́ míì tí kò sígbà tí wọn kì í ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ṣé ìwọ náà lè ṣètò àkókò rẹ kó o lè lọ máa wàásù lásìkò tó o lè bá àwọn èèyàn nílé tàbí láwọn ibòmíì tí wọ́n bá wà?
Kí nìdí tó fi dá ọ lójú pé Jèhófà ń tì ọ́ lẹ́yìn bó o ṣe ń wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀?
13, 14. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà nínú ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò? (b) Àpẹẹrẹ wo la rí níbí tó fi hàn pé ó yẹ ká máa pa àdéhùn tá a ṣe fún àwọn ìpadàbẹ̀wò wa mọ́?
13 Nígbà míì, Jèhófà máa ń pàṣẹ fún Jeremáyà pé kó lọ dúró lẹ́nu ibodè tẹ́ńpìlì tàbí ti Jerúsálẹ́mù kó sì kéde àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. (Jer. 7:2; 17:19, 20) Bí Jeremáyà ṣe ń kéde àwọn ọ̀rọ̀ yìí láwọn ẹnubodè, ìyẹn ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà látẹnu rẹ̀. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbabẹ̀ kọjá déédéé, títí kan àwọn èèyàn jàǹkàn jàǹkàn, àwọn oníṣòwò àti àwọn òǹtajà, ó ṣeé ṣe kí Jeremáyà bá àwọn kan sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà láti lè jẹ́ kí wọ́n lóye ohun tí wọ́n ti gbọ́ tẹ́lẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa nípa ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn?
14 Jeremáyà mọ̀ pé iṣẹ́ wòlíì tí Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́ lè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Nígbà kan tí kò ṣeé ṣe fún un láti jíṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán an sáwọn èèyàn nílé Jèhófà, ó rán Bárúkù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kó lọ jíṣẹ́ náà. (Ka Jeremáyà 36:5-8.) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà nínú ohun tó ṣe yìí? Tá a bá sọ fún onílé kan pé a ó pa dà wá, ṣé a máa ń pa dà lọ? Tá ò bá ní lè lọ sọ́dọ̀ ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, ǹjẹ́ a máa ń ṣètò pé kí ẹlòmíì bá wa lọ síbẹ̀? Jésù sọ pé: ‘Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni.’ (Mát. 5:37) Ó ṣe pàtàkì pé ká máa pa àdéhùn wa mọ́, nítorí Ọlọ́run tòótọ́, tó ń ṣe nǹkan létòlétò, là ń ṣojú fún.—1 Kọ́r. 14:33, 40.
Ṣé o ti ṣe ìyípadà nínú ìṣètò rẹ àti ọ̀nà tó o ń gbà wàásù, kí o lè túbọ̀ máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn wàásù fún?
15, 16. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn ará ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà láti lè túbọ̀ rí ọ̀pọ̀ èèyàn wàásù fún? (b) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú ohun tí Ẹlẹ́rìí kan ṣe nílẹ̀ Chile, èyí tó wà ní ojú ìwé 40?
15 Jeremáyà kọ lẹ́tà sí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì láti fi gbà wọ́n níyànjú nípa “ọ̀rọ̀ rere” tí Jèhófà sọ, pé òun máa mú wọn pa dà sí ilẹ̀ wọn. (Jer. 29:1-4, 10) Lónìí, àwa náà lè kọ lẹ́tà tàbí ká lo tẹlifóònù láti fi tan “ọ̀rọ̀ rere” nípa àwọn ohun tí Jèhófà máa tó ṣe kálẹ̀. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè lo àwọn ọ̀nà yẹn láti fi wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tàbí àwọn míì tó wà lọ́nà jíjìn tàbí àwọn tó jẹ́ pé kò rọrùn láti rí wọn bá sọ̀rọ̀?
16 Lónìí, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wòlíì Jeremáyà tó ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí. Ó ṣẹlẹ̀ pé Ẹlẹ́rìí kan nílẹ̀ Chile lọ bá obìnrin kan bó ṣe ń jáde bọ̀ láti ibùdókọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ kan. Inú obìnrin náà dùn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì, ó sì gbà pé kí wọ́n máa wá bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé. Àmọ́, Ẹlẹ́rìí yìí kò kọ àdírẹ́sì rẹ̀ sílẹ̀. Nígbà tó wá rántí pé ó yẹ kóun ran obìnrin tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ mọ̀ sí i, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà. Lọ́jọ́ kejì, ó pa dà síbi tó ti bá obìnrin náà pàdé lákòókò kan náà. Ó sì tún rí obìnrin yẹn níbẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, ó rí i dájú pé òun kọ àdírẹ́sì rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wá a lọ sílé lẹ́yìn náà láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A mọ̀ pé láìpẹ́, ìdájọ́ Ọlọ́run máa tó dé sórí ayé Sátánì, ṣùgbọ́n ìrètí wà fún àwọn tó bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere náà. (Ka Ìdárò 3:31-33.) Níwọ̀n bí a ti mọ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa rí i pé à ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù kúnnákúnná ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.
Ṣé o máa ń sa gbogbo ipá rẹ láti pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó o rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?
“BÓYÁ WỌN YÓÒ FETÍ SÍLẸ̀ KÍ OLÚKÚLÙKÙ WỌN SÌ PADÀ”
17. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ?
17 Jèhófà ò fẹ́ káwọn èèyàn pàdánù ẹ̀mí wọn. Láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sí àkókò ìparun Jerúsálẹ́mù ló ti gbẹnu Jeremáyà sọ ìrètí táwọn tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ní. A kà á pé: “Èmi yóò sì gbé ojú mi lé wọn lọ́nà rere, dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ yìí. Èmi yóò sì gbé wọn ró, èmi kì yóò sì ya wọ́n lulẹ̀; èmi yóò sì gbìn wọ́n èmi kì yóò sì fà wọ́n tu.” Jeremáyà wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ìrètí sì wà fún ọjọ́ ọ̀la [yín].” (Jer. 24:6; 26:3; 31:17) Irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn èèyàn lòun náà fi wò wọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ẹ̀mí àwọn èèyàn jẹ ẹ́ lógún. Ó rọ̀ wọ́n bí Jèhófà ṣe sọ, ó ní: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí padà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí ẹ sì ṣe ìbálò yín ní rere.” (Jer. 35:15) Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ronú àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà fi hàn pé ire àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ jẹ ọ́ lógún?
18, 19. (a) Irú ọwọ́ wo ni kò yẹ ká fi mú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tá à ń ṣe? (b) Irú ojú wo ni Jeremáyà fi wo iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀, èyí tó yẹ káwa náà fi wo tiwa?
18 Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jeremáyà ní sáwọn èèyàn Júdà kò dín kù. Àní nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù, àánú wọn ń ṣe é. (Ka Ìdárò 2:11.) Lóòótọ́ àwọn Júù yìí ló fọwọ́ ara wọn fa ìparun tó dé bá wọn, àmọ́ Jeremáyà kò yọ̀ wọ́n, kó ní, ‘Ṣe bí mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló kédàárò nítorí ohun tó dé bá wọn. Lónìí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wa di èyí tá à ń fara ṣe láìfọkàn ṣe. A ní láti rí i dájú pé ìdí tá a fi ń sa gbogbo ipá wa láti wàásù jẹ́ nítorí pé a fẹ́ràn Ọlọ́run wa ọba aláàánú àtàwọn èèyàn tó dá ní àwòrán ara rẹ̀.
Ṣé o máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé ire wọn jẹ ọ́ lógún?
19 Kò sí àǹfààní tàbí ipò èyíkéyìí láyé tó ga tó pé kéèyàn jẹ́ aṣojú Ọlọ́run tòótọ́ tó ń wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn èèyàn. Bọ́rọ̀ yìí ṣe rí lára Jeremáyà náà nìyẹn tó fi sọ pé: “A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́; ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà.” (Jer. 15:16) Bá a ti ń wàásù ìhìn rere, àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lè dẹni tó mọ Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wọn, kí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀. Èyí á lè ṣeé ṣe tí a bá ń fi ìtara àti ìfẹ́ ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa bíi ti Jeremáyà.
Àwọn ọ̀nà mìíràn wo lo tún lè gbà ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ iwájú láti mú kí “ọ̀rọ̀ rere” Jèhófà gbilẹ̀, bíi ti Jeremáyà?
a Jèhófà sábà máa ń mú kí áńgẹ́lì wá ṣojú fún òun bíi pé òun gan-an ló ń sọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣe níhìn-ín.—Oníd. 13:15, 22; Gál. 3:19.