ORÍ KARÙN-ÚN
Àwọn Wo Ló Yẹ Kó o Yàn Lọ́rẹ̀ẹ́?
1, 2. (a) Kí làwa Kristẹni máa ń bá pàdé lọ́dọ̀ àwọn tí nǹkan jọ ń dà wá pọ̀? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ irú àwọn èèyàn tí Jeremáyà yàn lọ́rẹ̀ẹ́?
KÍ LO máa ṣe táwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn aládùúgbò tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ wà níléèwé bá ní kó o wá bá àwọn ṣọdún? Tí ọ̀gá rẹ níbi iṣẹ́ bá ní kó o purọ́ tàbí kó o ṣe ohun kan tí kò bófin mu ńkọ́? Ká ní ìjọba pè ọ́ pé kó o wá dìbò tàbí kó o wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ológun tàbí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ńkọ́? Àfàìmọ̀ ni ẹ̀rí ọkàn rẹ ò ní sọ pé kó o má ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan tá a sọ yìí, wọn ì báà tiẹ̀ torí ìyẹn bínú sí ọ tàbí kí wọ́n ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.
2 A máa rí i nínú ibí yìí pé àìmọye ìgbà ni Jeremáyà bá irú ipò bẹ́ẹ̀ pàdé. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára irú àwọn èèyàn tí Jeremáyà bá pàdé bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, wàá rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ níbẹ̀. Àwọn míì lára wọn gbìyànjú láti mú kí Jeremáyà jáwọ́ nínú iṣẹ́ Ọlọrun. Lóòótọ́, ó di dandan kí nǹkan da irú àwọn bẹ́ẹ̀ àti Jeremáyà pọ̀, àmọ́ kò fi wọ́n ṣọ̀rẹ́ rárá. Ṣùgbọ́n tó o bá kíyè sí irú àwọn èèyàn tí Jeremáyà fi ṣọ̀rẹ́, ìyẹn àwọn tí wọ́n tì í lẹ́yìn, tí wọ́n sì ń fún un níṣìírí kó lè máa bá iṣẹ́ Ọlọ́run lọ, wàá jàǹfààní púpọ̀ gan-an. Ká sòótọ́, ẹ̀kọ́ gidi la máa rí kọ́ lára Jeremáyà nípa irú àwọn èèyàn tó yàn lọ́rẹ̀ẹ́.
IRÚ ÀWỌN WO LÒ Ń BÁ ṢỌ̀RẸ́?
3. Kí ni Sedekáyà ń fẹ́ gbọ́ látọ̀dọ̀ Jeremáyà, kí sì ni Jeremáyà ṣe?
3 Àìmọye ìgbà ni Sedekáyà Ọba lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jeremáyà ṣáájú kí Jerúsálẹ́mù tó pa run. Kí nìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ńṣe ló ń fẹ́ láti gbọ́ èsì táá fi í lọ́kàn balẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú ìjọba rẹ̀. Ó fẹ́ kí Jeremáyà sọ fóun pé Ọlọ́run máa kó Júdà yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Sedekáyà rán àwọn ońṣẹ́ kí wọ́n lọ bẹ Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nítorí wa, nítorí pé Nebukadirésárì ọba Bábílónì ń bá wa jagun. Bóyá Jèhófà yóò ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀, kí [Nebukadirésárì] lè fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wa.” (Jer. 21:2) Sedekáyà ò fẹ́ tẹ̀ lé ohun tí Ọlọ́run sọ, pé kó juwọ́ sílẹ̀ fáwọn ará Bábílónì. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé Sedekáyà dà bí “aláìsàn tí kò fẹ́ lo oògùn tí dókítà ní kó lò, síbẹ̀ tó ń pàrà ọ̀dọ̀ dókítà ṣáá kí dókítà lè sọ fún un pé ara rẹ̀ máa yá.” Kí ni Jeremáyà wá ṣe? Ì bá kàn sọ ohun tí Sedekáyà fẹ́ gbọ́ fún un láti lè fi gbayì. Kí wá nìdí tí kò fi yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà kó sọ ohun tí ọba yìí fẹ́ gbọ́ láti fi wá ìrọ̀rùn fún ara rẹ̀? Jeremáyà kò yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà nítorí ohun tí Jèhófà ní kó máa kéde ni pé Jerúsálẹ́mù máa pa run.—Ka Jeremáyà 32:1-5.
4. Kí ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò tó bá dọ̀rọ̀ àwọn tá a máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́ níbi iṣẹ́ tàbí níbòmíì?
4 Ọ̀rọ̀ tìrẹ náà jọ ti Jeremáyà láwọn ọ̀nà kan. Ó dájú pé ìwọ náà máa láwọn èèyàn tí nǹkan jọ máa ń dà yín pọ̀, bóyá ẹ jọ jẹ́ aládùúgbò, ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ẹ jọ wà níléèwé. Ṣùgbọ́n ṣé wàá wá jẹ́ kí àjọṣe yín jùyẹn lọ, kó o wá sọ wọ́n dọ̀rẹ́, bí wọ́n bá tiẹ̀ ti jẹ́ kó o mọ̀ pé àwọn ò fẹ́ máa gbọ́ nípa ìlànà Ọlọ́run, àwọn ò sì fẹ́ máa tẹ̀ lé e? Ṣó o rí i, Jeremáyà ò lè yẹra fún Sedekáyà pátápátá torí pé ọba ṣì ni, kódà bó ṣe kọ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò pọn dandan pé kó fara mọ́ èrò òdì tí ọba yẹn ní tàbí pé kó máa wá ojú rere rẹ̀. Lóòótọ́, ká ní ó ṣe ohun tí Sedekáyà fẹ́ ni, ọba yìí ì bá fún un lẹ́bùn rẹpẹtẹ àtàwọn àǹfààní míì. Àmọ́, kò jẹ́ kí ọba yẹn fi ohunkóhun fa ojú òun mọ́ra. Ìdí sì ni pé Jeremáyà kò ṣe tán láti yí ohun tí Jèhófà ní kó ṣe pa dà. Ó yẹ kí àpẹẹrẹ Jeremáyà mú kí kálukú wa ṣàyẹ̀wò àwọn tá à ń bá ṣọ̀rẹ́ bóyá wọ́n jẹ́ àwọn tó ń fún wa níṣìírí láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Kò sí bí nǹkan ò ṣe ní da ìwọ àtàwọn tí kò sin Ọlọ́run pọ̀, yálà níbi iṣẹ́, níléèwé tàbí ládùúgbò. (1 Kọ́r. 5:9, 10) Ṣùgbọ́n, mọ̀ dájú pé kò sí bó o ṣe lè firú àwọn bẹ́ẹ̀ ṣọ̀rẹ́ tí kò ní ṣàkóbá fún àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run.
ǸJẸ́ Ó YẸ KÁ MÁA BÁ ÀWỌN TÍ KÒ KA ÌLÀNÀ JÈHÓFÀ SÍ ṢỌ̀RẸ́?
5, 6. Kí làwọn kan ṣe kí wọ́n lè pa Jeremáyà lẹ́nu mọ́?
5 Sedekáyà nìkan kọ́ ló gbìyànjú láti dá Jeremáyà lọ́wọ́ kọ́. Àlùfáà kan tó ń jẹ́ Páṣúrì “lu” Jeremáyà, bóyá nípa sísọ pé kí wọ́n nà án ní ẹgba mọ́kàndínlógójì. (Jer. 20:2; Diu. 25:3) Báwọn ọmọ aládé Júdà kan ṣe tún na Jeremáyà náà nìyẹn, kí wọ́n tó fi í sínú “ilé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.” Inú yàrá abẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n há a mọ́ yìí burú débi pé lẹ́yìn tó lo ọjọ́ mélòó kan níbẹ̀, ó ní tí wọ́n bá fi òun sílẹ̀ níbẹ̀, òun lè kú. (Ka Jeremáyà 37:3, 15, 16.) Nígbà tí wọ́n wá tú Jeremáyà sílẹ̀ fúngbà díẹ̀, àwọn ọmọ aládé yòókù rọ Sedekáyà pé kó pa á dà nù. Lójú tiwọn, ṣe ni Jeremáyà ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun Júdà. Ni wọ́n bá jù ú sínú ìkùdu tó kún fún ẹrẹ̀, kó lè kú síbẹ̀. (Jer. 38:1-4) Wàá ti kà á pé àwọn kan ló fa Jeremáyà yọ tí kò fi kú ikú ẹ̀sín yẹn. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí bí àwọn tó yẹ kó máa bẹ̀rù Ọlọ́run ṣe dẹni tí kò fẹ́ gbọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí wòlíì Ọlọ́run ń sọ, tí wọ́n sì gbìyànjú láti pa á.
6 Àwọn aláṣẹ nìkan kọ́ lọ̀tá Jeremáyà. Nígbà kan, àwọn ọmọ ìlú Jeremáyà, ìyẹn àwọn ará Ánátótì, sọ pé àwọn máa pa á tí kò bá yéé sọ àsọtẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ àwọn sì la tún lè pè ní aládùúgbò rẹ̀ o. (Jer. 11:21) Bínú wọn ò ṣe dùn sọ́rọ̀ tí wọ́n ń gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, wọ́n láwọn máa pa á bí kò bá gbẹ́nu rẹ̀ dákẹ́. Àmọ́, ṣe ni Jeremáyà fi Jèhófà ṣọ̀rẹ́ dípò àwọn ọmọ ìlú rẹ̀. Àwọn míì ò tiẹ̀ fi àtakò tiwọn sí Jeremáyà mọ lọ́rọ̀ ẹnu. Nígbà kan, Jeremáyà ṣe àjàgà ó sì gbé e sọ́rùn láti fi rọ àwọn Júù pé kí wọ́n gbà láti sìnrú fún ọba Bábílónì kí wọ́n lè máa wà láàyè, àmọ́ ṣe ni Hananáyà gba àjàgà onígi náà lọ́rùn Jeremáyà, tó sì ṣẹ́ ẹ. Lẹ́yìn ìyẹn, wòlíì èké yìí sọ pé ohun tí Jèhófà sọ ni pé: “Èmi yóò ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.” Ọdún yẹn gan-an ni ikú pa Hananáyà, wàá sì rántí pé ọ̀rọ̀ Jeremáyà wòlíì ló ṣẹ. (Jer. 28:1-11, 17) Lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù pa run bí Jeremáyà ṣe sọ, Jóhánánì àtàwọn olórí ọmọ ogun yòókù kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run pé kí wọ́n má ṣe kúrò nílẹ̀ Júdà. Wọ́n sọ fún Jeremáyà pé: “Èké ni ìwọ ń sọ. Ọlọ́run wa kò rán ọ, pé, ‘Má ṣe wọ Íjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀.’” Àní wọ́n tiẹ̀ tún tàpá sí Jèhófà jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n fipá mú Jeremáyà àti Bárúkù tẹ̀ lé wọn lọ sí Íjíbítì.—Jer. 42:1-43:7.
Àárín irú àwọn èèyàn wo ló di dandan kí Jeremáyà wà nígbà ayé rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jeremáyà?
7. Ohun pàtàkì tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà wo ló yẹ kó o máa ronú lé?
7 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jeremáyà fi gbé láàárín àwọn alátakò àtàwọn tí kò ka ìlànà Jèhófà sí. Ìwọ ronú nípa nǹkan tí ì bá ṣe ná. Ó lè wá àwáwí kó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tí kò ka Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí kẹ́gbẹ́. Àárín wọn ló kúkú ń gbé, àwọn ló sì ń rí ní gbogbo ìgbà. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo ni ipò tìẹ náà ṣe rí? Nǹkan lè máa da ìwọ náà pọ̀ pẹ̀lú àwọn tíwà wọn jọ tàwọn èèyàn ìgbà ayé Jeremáyà. Ǹjẹ́ ó yẹ kó o bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́, yálà wọ́n ń ṣe bí èèyàn dáadáa tàbí wọ́n ń ṣàtakò lójú méjèèjì sí ìwọ àti Ọlọ́run tó ò ń sìn? Ṣó máa bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa bá àwọn tí kò fọwọ́ pàtàkì mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ṣe wọléwọ̀de? Ká sọ pé Jeremáyà ló wà nírú ipò tó o wà, ǹjẹ́ yóò fi àwọn tó ń gbé ìgbé ayé tí kò bá ìlànà Bíbélì mu tàbí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn ṣọ̀rẹ́? (2 Kíró. 19:2) Gbangba gbàǹgbà ni Ọlọ́run jẹ́ kí Jeremáyà mọ̀ pé ìgbẹ̀yìn ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ará ayé dípò Ọlọ́run kì í dáa. (Ka Jeremáyà 17:5, 6.) Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí mú ọ ronú jinlẹ̀ nípa irú àwọn tó ò ń bá ṣọ̀rẹ́?
8. Sọ àpẹẹrẹ onírúurú ipò táwọn Kristẹni tó wà lágbègbè rẹ lè bá pàdé.
8 Àwọn Kristẹni kan ronú pé nǹkan á túbọ̀ ṣẹnuure fáwọn nídìí iṣẹ́ tàbí òwò àwọn táwọn bá ń kó àwọn èèyàn ayé tó jẹ́ oníbàárà wọn lẹ́nu jọ. Àmọ́ ṣé èyí kò ní jẹ́ kírú Kristẹni bẹ́ẹ̀ máa bá àwọn tó lè kéèràn ràn án kẹ́gbẹ́ tàbí kó kó o sínú ewu bíi, gbígbọ́ ọ̀rọ̀ rírùn tàbí mímutí àmujù? Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ Kristẹni tó wà nípò láti ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ fi máa ń dìídì yẹra fún un láti lè yàgò fún ẹgbẹ́ búburú, kódà tó bá tiẹ̀ máa yọrí sí pé wọ́n á pàdánù èrè ńlá tàbí ìgbéga lọ́dọ̀ èèyàn ayé. Bákan náà, ọ̀gá èèyàn níbi iṣẹ́ tàbí àwọn téèyàn jọ ń ṣiṣẹ́ lè ṣàìrí ohun tó burú nínú rírẹ́ àwọn oníbàárà wọn jẹ. Àmọ́ àwa Kristẹni tòótọ́ kì í jẹ́ kí àwọn tó wà láyìíká wa kó èèràn ràn wá. Ní tòdodo, kì í rọrùn nígbà míì láti ṣèpinnu tó yẹ lórí irú àwọn ọ̀ràn báwọ̀nyí. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé a nírú àpẹẹrẹ bíi ti Jeremáyà tá a lè tẹ̀ lé, torí ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ló ń ṣe nígbà gbogbo, èyí tó ń jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mọ́. Ìyẹn jẹ́ kó ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù.
9. Ewu wo ló wà nínú kéèyàn fẹ́ láti jẹ́ ẹni tó gbajúmọ̀ láyé?
9 Bó ṣe jẹ́ pé ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ nìkan ni Jeremáyà ń sọ tó sì ń ṣe, ṣe làwọn ará Júdà èèyàn rẹ̀ ń fi ṣẹlẹ́yà. (Jer. 18:18) Síbẹ̀, kò torí ìyẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi tàwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ tó jẹ́ pé wọ́n ń tọ “ipa ọ̀nà gbígbajúmọ̀.” Ṣe ló dá yàtọ̀ sí wọn pátápátá. (Jer. 8:5, 6) Kódà, láwọn ìgbà míì, ó máa ń tẹ́ Jeremáyà lọ́rùn pé ‘kó dá jókòó ní òun nìkan.’ Ìyẹn tẹ́ ẹ lọ́rùn ju kó máa bá àwọn tó lè kéèràn ràn án jókòó pa pọ̀, èyí táá jẹ́ ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. (Ka Jeremáyà 9:4, 5; 15:17.) Ìwọ wá ńkọ́? Lóde òní, ìwà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run ni ìwà tó gbajúmọ̀ láàárín àwọn èèyàn ayé, àní bó ṣe rí nígbà ayé Jeremáyà. Tipẹ́tipẹ́ sì làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń ṣọ́ra nípa irú àwọn èèyàn tí wọ́n ń bá ṣọ̀rẹ́. Kò wá túmọ̀ sí pé Jeremáyà ò lọ́rẹ̀ẹ́ o. Àwọn kan gbèjà rẹ̀, wọ́n sì tì í lẹ́yìn. Àwọn wo nìyẹn? Tó o bá mọ̀ wọ́n, wàá rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ lára wọn.
ÀWỌN WO NI JEREMÁYÀ BÁ ṢỌ̀RẸ́?
10, 11. (a) Kìkì irú àwọn èèyàn wo ni Jeremáyà máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́? (b) Àwọn wo ni ọ̀rẹ́ Jeremáyà, àwọn ìbéèrè wo la sì máa gbé yẹ̀ wò nípa wọn?
10 Àwọn wo ni Jeremáyà wá yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Ńṣe ni Jeremáyà ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn èèyàn burúkú, ẹlẹ́tàn, àwọn tí ń rẹ́ni jẹ, àwọn oníwà ipá, àwọn tí kò bìkítà àtàwọn oníṣekúṣe torí pé wọ́n kẹ̀yìn sí ìsìn tòótọ́, wọ́n ń bọ òrìṣà, èyí tó túmọ̀ sí pé wọ́n ń ṣe panṣágà nípa tẹ̀mí. Lemọ́lemọ́ ló ń bá wọn wí bí Jèhófà ṣe rán an. Ó rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Júù pé: “Kí olúkúlùkù jọ̀wọ́ yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí ẹ sì ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere.” (Jer. 18:11) Lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù wá pa run, Jeremáyà yin Ọlọ́run fún “àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ,” “àánú” àti “ìṣòtítọ” rẹ̀. (Ìdárò 3:22-24) Gbogbo èyí fi hàn pé kìkì àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́ ni Jeremáyà yàn lọ́rẹ̀ẹ́.—Ka Jeremáyà 17:7.
11 A ò ṣàìmọ̀ àwọn tí Jeremáyà yàn lọ́rẹ̀ẹ́ tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe nǹkan pọ̀. Àwọn díẹ̀ kan wà tí wọ́n ń tì í lẹ́yìn, àwọn bí Ebedi-mélékì, Bárúkù, Seráyà àtàwọn ọmọ Ṣáfánì. Irú èèyàn wo làwọn yìí jẹ́? Kí ló pa àwọn àti Jeremáyà pọ̀? Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà? Báwo ni wọ́n sì ṣe ti Jeremáyà lẹ́yìn kó lè máa bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ nìṣó? Ẹ jẹ́ ká wo ìdáhùn ìbéèrè wọ̀nyí ká sì máa ronú nípa bó ṣe kan àwa náà.
12. (a) Kí làwọn nǹkan tó pa Jeremáyà àti Bárúkù tá a rí lójú ìwé 58 pọ̀? (b) Ta ni Seráyà, kí la sì mọ̀ nípa rẹ̀?
12 Ó jọ pé Bárúkù ọmọ Neráyà ni ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ Jeremáyà tímọ́tímọ́ jù. Òun ni Jeremáyà pè jókòó pé kó wá tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà tó ti bá òun sọ, kó sì máa kọ ọ́ sílẹ̀. Òun ni Jeremáyà ní kó lọ ka ìwé tó kọ yẹn sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn, òun ló sì tún kà á sétígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ aládé Júdà. (Jer. 36:4-8, 14, 15) Bárúkù nígbàgbọ́, ó sì dá a lójú bíi ti Jeremáyà pé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ máa ṣẹ lóòótọ́. Àwọn méjèèjì ló jọ fojú winá gbogbo wàhálà inú ọdún méjìdínlógún tó gbẹ̀yìn ìjọba Júdà. Wọ́n tún jọ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run pa pọ̀ fúngbà pípẹ́. Àwọn méjèèjì ni wọ́n gbógun tì, tó sì di pé wọ́n ní láti sá pa mọ́ fáwọn ọ̀tá. Olúkúlùkù wọn ni Jèhófà sì sọ̀rọ̀ ìyànjú fún. Ó jọ pé inú ìdílé kan tó gbajúmọ̀ nídìí iṣẹ́ akọ̀wé nílẹ̀ Júdà ni Bárúkù ti wá. Ìwé Mímọ́ pe Bárúkù ní “akọ̀wé,” Seráyà arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ èèyàn pàtàkì kan nínú ìjọba Júdà. Nígbà tó yá, Seráyà yìí náà lọ bá Jeremáyà kéde àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà bíi ti Bárúkù. (Jer. 36:32; 51:59-64) Ìṣírí ńlá ló ní láti jẹ́ fún Jeremáyà báwọn ọmọ Neráyà méjèèjì yìí ṣe yọ̀ǹda ara wọn láti bá a ṣiṣẹ́ Ọlọ́run lákòókò tó le koko yẹn, á sì gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ró gan-an. Ìwọ náà lè rí ìṣírí gbà lọ́dọ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà pọ̀ tọkàntọkàn, wọ́n á sì gbé ìgbàgbọ́ tìrẹ náà ró.
Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú irú àwọn èèyàn tí Jeremáyà bá ṣọ̀rẹ́?
13. Bá a ṣe rí i nínú àwòrán tó wà lójú ìwé 63, báwo ni Ebedi-mélékì ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ àtàtà lòun jẹ́ sí Jeremáyà?
13 Ẹlòmíì tó tún ti Jeremáyà lẹ́yìn ni Ebedi-mélékì ará Etiópíà. Nígbà táwọn ọmọ aládé fìbínú sọ Jeremáyà sínú ìkùdu kan tí kò lómi kó lè kú síbẹ̀, ẹnì kan ṣoṣo tó láyà láti lọ gbà á sílẹ̀ ni Ebedi-mélékì ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yìí. Ìwẹ̀fà ni, ìyẹn òṣìṣẹ́ láàfin ọba. Ìta gbangba ló ti lọ bá Sedekáyà níbi tó jókòó sí ní Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì. Ó wá lo ìgboyà, ó bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí òun yọ Jeremáyà kúrò nínú ìkùdu tó kún fún ẹrẹ̀ náà. Ọgbọ̀n ọkùnrin ni Ebedi-mélékì mú dání láti lọ ṣe iṣẹ́ yẹn torí ó mọ̀ pé ó ṣeé ṣe káwọn ọ̀tá Jeremáyà wá dá òun dúró kóun má yọ Jeremáyà. (Jer. 38:7-13) A ò mọ bí Ebedi-mélékì àti Jeremáyà ṣe sún mọ́ra tó. Ṣùgbọ́n tá a bá wo ti pé àwọn méjèèjì jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, ó dájú pé ọ̀rẹ́ gidi ni wọ́n máa jẹ́. Ebedi-mélékì mọ̀ pé wòlíì Jèhófà ni Jeremáyà. Ó sọ pé “ohun búburú” làwọn ọmọ aládé yẹn ṣe, ó sì ṣe ohun tó tọ́ láìkọ ohun tíyẹn lè já sí fóun. Ká má purọ́, èèyàn dáadáa ni Ebedi-mélékì. Àní Jèhófà pàápàá fi dá a lójú pé: “Èmi yóò pèsè àsálà fún ọ [nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù] . . . nítorí pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi.” (Ka Jeremáyà 39:15-18.) Ohun tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ yìí mà dára o! Ǹjẹ́ irú ọ̀rẹ́ tí ìwọ náà ń fẹ́ kọ́ nìyẹn?
14. Kí la mọ̀ nípa ìdílé Ṣáfánì àti àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti Jeremáyà?
14 Àwọn míì tó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ Jeremáyà ni àwọn ọmọ Ṣáfánì mẹ́ta àti ọmọ-ọmọ Ṣáfánì kan. Ìdílé èèyàn jàǹkàn jàǹkàn ni wọ́n ti wá, torí Ṣáfánì yìí jẹ́ akọ̀wé Jòsáyà Ọba láyé ìgbà kan. Nígbà táwọn ọ̀tá kọ́kọ́ fẹ́ pa wòlíì Jeremáyà, “ọwọ́ Áhíkámù ọmọkùnrin Ṣáfánì ni ó wà pẹ̀lú Jeremáyà, kí a má bàa fi í lé àwọn ènìyàn náà lọ́wọ.” (Jer. 26:24) Áhíkámú ní arákùnrin kan tó ń jẹ́ Gemaráyà. Nígbà tí Bárúkù ka ìdájọ́ Ọlọ́run sétígbọ̀ọ́ gbogbo èèyàn, Gemaráyà ọmọ Mikáyà gbọ́, ó sì sọ fún bàbá rẹ̀ àtàwọn ọmọ aládé míì. Bí ọkàn wọn ò sì ṣe balẹ̀ nípa ohun tí Jèhóákímù lè ṣe sí Jeremáyà àti Bárúkù, wọ́n ní káwọn méjèèjì lọ fara pa mọ́. Nígbà tí Jèhóákímù Ọba sì kọ ọ̀rọ̀ ìdájọ́ Ọlọ́run yẹn, Gemaráyà wà lára àwọn tó rọ ọba yìí pé kó má ṣe finá sun àkájọ ìwé náà. (Jer. 36:9-25) Jeremáyà tún fi lẹ́tà tó kọ àsọtẹ́lẹ̀ sí rán ọmọ Ṣáfánì míì, ìyẹn Élásà, sáwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. (Jer. 29:1-3) Èyí fi hàn pé odindi àwọn mẹ́ta nínú ọmọ Ṣáfánì àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ kan ló dúró ti Jeremáyà wòlíì Ọlọ́run gbágbáágbá. Ẹ ò rí i pé inú Jeremáyà máa dùn gan-an sí wọn! Ọ̀rẹ́ wọn tó wọ̀ yìí kì í ṣe tìtorí pé wọ́n jọ fẹ́ràn irú oúnjẹ kan náà, ohun mímu kan náà, eré ìdárayá tàbí ohun ìnàjú kan náà o. Ohun tó sọ wọ́n dọ̀rẹ́ ju ìyẹn lọ.
FI ỌGBỌ́N YAN ÀWỌN TÓ O MÁA BÁ ṢỌ̀RẸ́
15. Báwo ni Jeremáyà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú irú àwọn tó fi ṣọ̀rẹ́?
15 O lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú irú ọwọ́ tí Jeremáyà fi mú àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀, yálà èyí tó jéèyàn rere tàbí èyí tó jẹ́ni burúkú. Àní ọba, ọ̀pọ̀ ọmọ aládé, àwọn wòlíì èké àtàwọn ọ̀gágun fúngun mọ́ ọn pé kó yí iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán an sí wọn pa dà. Ṣùgbọ́n Jeremáyà kò yí i pa dà. Lóòótọ́ èyí mú káwọn èèyàn náà kórìíra rẹ̀, àmọ́ irú wọn kọ́ ni Jeremáyà fẹ́ bá ṣọ̀rẹ́. Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jù lọ látìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ wá. Táwọn kan bá tiẹ̀ torí pé Jeremáyà jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run rẹ̀ tí wọ́n sọ ọ́ dọ̀tá, ó fara mọ́ ọn. (Ka Ìdárò 3:52-59.) Àmọ́ ṣá, a ti rí i pé àwọn èèyàn míì náà kọ́wọ́ ti Jeremáyà nínú bó ṣe pinnu láti sin Jèhófà.
16, 17. (a) Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni ọ̀rẹ́ àtàtà lè ṣe fún ẹni tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà? (b) Orílẹ̀-èdè yòówù kó o máa gbé, ibo lo ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó dára jù?
16 Ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí Ebedi-mélékì ní nínú Jèhófà ló mú kó jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà fún Jeremáyà. Ọkùnrin yìí fi ìgboyà gbégbèésẹ̀ ní kíá mọ́sá, ó gba ẹ̀mí Jeremáyà là. Bárúkù fara balẹ̀ jókòó ti Jeremáyà gan-an, ó sì tún bá a jẹ́ iṣẹ́ tí Jèhófà rán an. Àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà nínú ìjọ Ọlọ́run lónìí náà lè dúró tì wá kí wọ́n sì gbé ìgbàgbọ́ wa ró bíi tàwọn ọ̀rẹ́ Jeremáyà yìí. Arábìnrin Cameron, tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé mọyì ipa rere tí aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Kara ní lórí rẹ̀ gan-an ni. Arábìnrin Cameron sọ pé, “Arábìnrin Kara fi àpẹẹrẹ rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ tó ń bá mi sọ gbà mí níyànjú láti fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé mi.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà àwọn arábìnrin méjèèjì jìn síra, Kara máa ń pe ọ̀rẹ́ rẹ̀ Cameron lórí tẹlifóònù, ó sì máa ń kọ̀wé sí i déédéé láti fi mọ bó ṣe ń ṣe dáadáa sí, kí wọ́n lè jọ fún ara wọn níṣìírí. Arábìnrin Cameron sọ pé: “Ó mọ bí nǹkan ṣe rí nínú ìdílé wa. Ó mọ gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti bó ṣe nira fún mi tó nígbà tí ẹ̀gbọ́n mi yìí dẹ́ṣẹ̀ tó sì fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Ó dúró tì mí gbágbáágbá ní gbogbo àsìkò yìí. Mi ò mọ ohun tí ǹ bá ṣe ká ní kì í ṣe ti ipa rere tó ní lórí mi àti ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣe fún mi. Alátìlẹyìn gidi ló jẹ́ fún mi o.”
17 Ìwọ náà lè láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà nínú ìjọ Kristẹni, yálà kẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́ tàbí kẹ́ ẹ dàgbà jura lọ. Ohun kan náà nìwọ àtàwọn ará nínú ìjọ gbà gbọ́, ìlànà Kristẹni kan náà lẹ jọ ń tẹ̀ lé, ẹ sì jọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni, tẹ́ ẹ tún jọ nírètí kan náà, bóyá ẹ sì ti jọ fojú winá irú ìṣòro kan náà pàápàá. Ẹ lè jọ máa jáde òde ẹ̀rí pa pọ̀. Wọ́n á dúró tì ọ́ nígbà ìṣòro rẹ, ìwọ náà á sì dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro tiwọn. Wọn yóò sì máa bá ọ yọ̀ nígbà tí nǹkan bá ń dùn fún ọ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Paríparí rẹ̀ sì tún ni pé ẹ lè jẹ́ ọ̀rẹ́ títí ayérayé.—Òwe 17:17; 18:24; 27:9.
18. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú irú àwọn èèyàn tí Jeremáyà bá ṣọ̀rẹ́?
18 Ó dájú pé a ó ti rí ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kọ́ látinú irú àwọn tí Jeremáyà yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Fi òótọ́ pọ́ńbélé yìí sọ́kàn: Kò sí bó o ṣe lè bá àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn lòdì sóhun tó wà nínú Bíbélì rìn tí o kò ní tẹ àwọn ìlànà Ọlọ́run tó o mọ̀ lójú. Bí Jeremáyà ṣe jẹ́ kí òótọ́ pọ́ńbélé yìí tọ́ òun sọ́nà nínú irú àwọn ọ̀rẹ́ tó yàn ló ṣe yẹ káwa náà jẹ́ kó máa tọ́ wa sọ́nà lóde òní. Jeremáyà rí i pé ìwà àti ìṣe rẹ̀ gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ kó bàa lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kó sì lè rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà. Ǹjẹ́ kì í ṣe bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ tìrẹ náà rí nìyẹn? Àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn bá ti Jeremáyà mu tí wọ́n sì ń kọ́wọ́ tì í lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run ni Jeremáyà ń bá rìn. Àní sẹ́, gbogbo Kristẹni olóòótọ́ lónìí ló lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jeremáyà nínú bó ṣe fi ọgbọ́n yan àwọn tó bá ṣọ̀rẹ́!—Òwe 13:20; 22:17.
Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà nígbà tó o bá ń yan àwọn tó o máa bá ṣọ̀rẹ́ àtàwọn tó ò ní bá ṣọ̀rẹ́?