ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jr orí 7 ojú ìwé 81-91
  • “Ọkàn tí Àárẹ̀ Mú Ni Èmi Yóò Tẹ́ Lọ́rùn ní Kíkún”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ọkàn tí Àárẹ̀ Mú Ni Èmi Yóò Tẹ́ Lọ́rùn ní Kíkún”
  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ KÓ ÌRẸ̀WẸ̀SÌ BÁNI
  • MÚ ÌTURA BÁ ỌKÀN TÍ ÀÁRẸ̀ MÚ
  • “Èmi Kò Lè Dákẹ́”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Àwọn Wo Ló Yẹ Kó O Yàn Lọ́rẹ̀ẹ́?
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi sí Ẹnu Rẹ”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Jèhófà Rán Jeremáyà Pé Kó Lọ Wàásù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
jr orí 7 ojú ìwé 81-91

Orí Keje

“Ọkàn Tí Àárẹ̀ Mú Ni Èmi Yóò Tẹ́ Lọ́rùn Ní Kíkún”

1. Èwo nínú àwọn ìbùkún ayé tuntun lò ń wọ̀nà fún ní pàtàkì?

TÓ O bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ayé tuntun,” ó ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ máa lọ sáwọn ìbùkún tó ṣeé fojú rí tí Bíbélì sọ pé a máa rí gbà ní Párádísè. Bóyá irú bí ìlera pípé, ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ aṣaralóore, àwọn ẹranko tí kò ní pani lára àti bí olúkúlùkù ṣe máa ní ilé tirẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó o tiẹ̀ lè tọ́ka sáwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyẹn. Àmọ́ ṣá o, má gbàgbé ìbùkún pàtàkì yìí, ìyẹn ni pé, àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run máa túbọ̀ dára sí i, kò sì ní sí ohunkóhun tó máa fa ìdààmú ọkàn fúnni. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo ìdùnnú yòókù kò ní tọ́jọ́.

2, 3. Àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo la máa rí nínú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ?

2 Nígbà tí Ọlọ́run ní kí Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn Júù máa pa dà wá láti ìgbèkùn Bábílónì, Ọlọ́run dìídì pàfiyèsí sí bí nǹkan ṣe máa rí lára wọn nígbà yẹn. Ó ní: “Ìwọ yóò ṣì fi ìlù tanboríìnì rẹ ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, ìwọ yóò sì jáde lọ nínú ijó àwọn tí ń rẹ́rìn-ín.” (Ka Jeremáyà 30:18, 19; 31:4, 12-14.) Ọlọ́run sì tún wá ṣe ìlérí míì tó ṣeé ṣe kó wú ọ lórí, ó ní: “Ọkàn tí àárẹ̀ mú ni èmi yóò tẹ́ lọ́rùn ní kíkún, olúkúlùkù ọkàn tí ó sì ń láálàṣí ni èmi yóò kún.”—Jer. 31:25.

3 Ìgbà yẹn á mà lárinrin o! Àní sẹ́, Jèhófà sọ pé òun máa tẹ́ ẹni tó ti rẹ̀, tí ìrẹ̀wẹ̀sì sì ti bá, lọ́rùn ní kíkún. Ọlọ́run sì ṣe bẹ́ẹ̀, torí ó máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ jẹ́ kí ọkàn àwa náà balẹ̀ pé Ọlọ́run máa tẹ́ wa lọ́rùn. Wọ́n tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa rí ìṣírí gbà nísinsìnyí, ká sì nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Bákàn náà, wọ́n jẹ́ ká rí bá a ṣe lè máa gba àwọn tí àárẹ̀ mú níyànjú, tí agbára wọn á fi dọ̀tun.

4. Kí ló jẹ́ ká lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára Jeremáyà?

4 Ìlérí yẹn lohun pàtàkì tó ń tu Jeremáyà nínú, ó sì lè máa tu àwa náà nínú. Kí nìdí? Rántí kókó kan tá a mẹ́nu kàn nínú Orí Kìíní ìwé yìí, pé bíi ti Èlíjà náà ni Jeremáyà ṣe jẹ́ èèyàn ẹlẹ́ran ara “tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.” (Ják. 5:17) Tiẹ̀ ronú ná nípa ìdí mélòó kan tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi lè bá Jeremáyà tàbí ìdí tí ìdààmú ọkàn fi lè bá a nígbà míì pàápàá. Bó o ṣe ń rò ó, máa fojú inú wo bó ṣe máa rí lára rẹ ká sọ pé ìwọ ni àwọn nǹkan náà ṣẹlẹ̀ sí, kó o sì wo ìdí tí wọ́n fi lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ.—Róòmù 15:4.

5. Kí lohun tó ṣeé ṣe kó kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Jeremáyà?

5 Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ìlú Jeremáyà wà lára àwọn ohun tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Ìlú rẹ̀ Ánátótì ló dàgbà sí, ìyẹn ìlú àwọn ọmọ Léfì, tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí àríwá ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù. Àwọn ojúlùmọ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sì máa wà nílùú Ánátótì yìí. Jésù sọ pé wòlíì kì í ní ọlá ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ohun tó sì ti ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà nìyẹn. (Jòh. 4:44) Kò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn ará Ánátótì ìlú rẹ̀, wọn ò sì fẹ́ rí i sójú rárá. Kódà, tiwọn le débi pé, nígbà kan, Ọlọ́run pàápàá sọ pé ‘àwọn ènìyàn Ánátótì ń wá ọkàn’ Jeremáyà. Wọ́n lérí sí i pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, kí o má bàa kú ní ọwọ́ wa.” Àbẹ́ ò rí nǹkan! Kírú ọ̀rọ̀ burúkú báyìí máa jáde lẹ́nu àwọn ará àdúgbò bóyá àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, àwọn tó yẹ kó tì í lẹ́yìn!—Jer. 1:1; 11:21.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 83

6. Táwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn míì bá ń ta kò ọ́, báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ Jeremáyà àti “àwọn ènìyàn Ánátótì” ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?

6 Táwọn aládùúgbò rẹ, àwọn ọmọ iléèwé rẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ pàápàá bá gbógun tì ọ́, fi ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ Jeremáyà tu ara rẹ nínú. Nígbà ayé Jeremáyà, Ọlọ́run sọ pé òun yóò ‘yí àfiyèsí òun sí’ àwọn ará Ánátótì tó ń gbógun ti wòlíì òun. (Ka Jeremáyà 11:22, 23.) Ohun tí Ọlọ́run fi dá Jeremáyà lójú yìí jẹ́ kó lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì èyíkéyìí tí àtakò àwọn èèyàn rẹ̀ lè fà bá a. Ó mọ̀ dájú pé “ìyọnu àjálù [máa] wá sórí àwọn ènìyàn Ánátótì” nígbà tí Ọlọ́run bá yí àfiyèsí rẹ̀ sí wọn. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà ń wo gbogbo bí ọ̀ràn tìrẹ ṣe ń lọ àti pé gbogbo àwọn alátakò pátá ló máa yí àfiyèsí rẹ̀ sí. (Sm. 11:4; 66:7) Tó o bá “dúró nínú” àwọn ohun tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì, tó o sì ń ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn lè jẹ́ kí àwọn míì lára àwọn alátakò rẹ yí pa dà kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ àjálù tó ń bọ̀.—1 Tím. 4:16.

Nínú ìwé Jeremáyà, kí ló fi hàn pé Ọlọ́run ò fojú kékeré wo bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn rẹ̀, ìrànlọ́wọ́ wo lèyí sì ṣe fún wòlíì Jeremáyà?

ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ KÓ ÌRẸ̀WẸ̀SÌ BÁNI

7, 8. Kí ni wọ́n fojú Jeremáyà rí, ipa wo ni nǹkan wọ̀nyẹn sì ní lórí rẹ̀?

7 Jeremáyà tún bá àwọn nǹkan míì pàdé yàtọ̀ sí báwọn ará ìlú rẹ̀ ṣe lérí sí i. Ọ̀kan ni ti àlùfáà náà Páṣúrì ní Jerúsálẹ́mù, tí ẹnu rẹ̀ tólẹ̀ gan-an.a Nígbà tí Páṣúrì àlùfáà gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run látẹnu Jeremáyà, ńṣe ló “lu Jeremáyà wòlíì, [tó] sì fi í sínú àbà.” (Jer. 20:1, 2) Kì í ṣe bíi ká kàn fọ́ni létí nibí yìí ń wí o. Àwọn kan gbà pé ó tó ogójì ẹgba tí Páṣúrì ní kí wọ́n na Jeremáyà. (Diu. 25:3) Bí ìyà yẹn ṣe ń jẹ Jeremáyà lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn máa fi í ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n máa bú u, kí wọ́n tiẹ̀ tutọ́ sí i lára. Kò mọ síbẹ̀ o. Páṣúrì ní kí wọ́n fi Jeremáyà sínú “àbà” mọ́jú. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí wọ́n lò níhìn-ín fi hàn pé, ó ní láti jẹ́ pé wọ́n mú kí ara rẹ̀ ká kò síbẹ̀. Àwọn ìkà èèyàn yẹn há Jeremáyà mọ́ inú igi àbà, wọ́n mú kó jẹ̀rora ńlá mọ́jú.

8 Ipa wo ni nǹkan wọ̀nyí ní lórí Jeremáyà? Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Mo di ohun ìfirẹ́rìn-ín láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Jer. 20:3-7) Ó tiẹ̀ wá sí i lọ́kàn pé kóun má gbẹnu sọ̀rọ̀ fún Ọlọ́run mọ́. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bó o ṣe mọ̀, Jeremáyà kò ṣe bẹ́ẹ̀, torí ara rẹ̀ kò gbà á láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ní kó kéde “dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun” rẹ̀, ó wá di dandan kó lọ máa jíṣẹ́ Jèhófà.—Ka Jeremáyà 20:8, 9.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 84, 85

9. Kí nìdí tó fi dára pé ká máa ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà?

9 Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà yìí lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà táwọn tá a mọ̀, ìyẹn àwọn ẹbí wa, aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tá a jọ wà níléèwé, bá ń fi wá ṣẹ̀sín. Kó má ṣe yà wá lẹ́nu pé nígbà míì, irú àtakò bẹ́ẹ̀ lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa díẹ̀. Ìrẹ̀wẹ̀sì sì tún lè bá wa tí wọ́n bá ń fìyà jẹ wá láwọn ọ̀nà míì nítorí ìjọsìn tòótọ́. Nǹkan wọ̀nyẹn nípa lórí Jeremáyà, ó sì lè nípa lórí àwa náà torí ẹ̀dá aláìpé, tó ń mọ ìyà lára bíi tiẹ̀ la jẹ́. Ṣùgbọ́n ká rántí pé Ọlọ́run ran Jeremáyà lọ́wọ́ tó tún fi dẹni tó ń fayọ̀ àti ìgboyà ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Jeremáyà borí ìrẹ̀wẹ̀sì tiẹ̀, nítorí náà, kò sídìí táwa náà ò fi ní lè borí tiwa.—2 Kọ́r. 4:16-18.

10. Kí ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa bí ọkàn Jeremáyà ṣe máa ń rí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

10 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọkàn Jeremáyà máa ń wúwo, ìyẹn ni pé á dédé rí i pé inú òun kò dùn rárá. Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí, bóyá tí inú rẹ ń dùn tẹ́lẹ̀ pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, àmọ́ tó o ṣàdédé rí i pé inú rẹ bà jẹ́ tí gbogbo nǹkan sì sú ọ? Ní ti Jeremáyà, wo ìgbà tínú rẹ̀ dùn nínú Jeremáyà 20:12, 13. (Kà á.) Èyí jẹ́ lẹ́yìn tó bọ́ nínú gbogbo ìyà tí Páṣúrì fi jẹ ẹ́, tínú rẹ̀ sì dùn pé òun dà bí ọ̀kan lára àwọn òtòṣì tí Ọlọ́run gbà “kúrò lọ́wọ́ àwọn aṣebi.” Bóyá ìgbà kan náà wà tínú rẹ náà ń dùn, tó sì ṣe ọ́ bíi pé kó o kọrin ayọ̀ sí Jèhófà lẹ́yìn tó kó ẹ yọ nínú ewu kan tàbí nígbà tí ohun ayọ̀ kan ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé rẹ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ. Ó sì dáa kínú èèyàn máa dùn bẹ́ẹ̀!—Ìṣe 16:25, 26.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 86

Ipa wo ni àtakò tàbí ìfiniṣẹlẹ́yà lè ní lórí wa?

11. Tí ọkàn wa bá ń wúwo nígbà míì, kí ló yẹ ká rántí nípa Jeremáyà?

11 Àmọ́ nítorí pé a jẹ́ aláìpé, nígbà míì, ọkàn wa náà lè wúwo bíi ti Jeremáyà. Lẹ́yìn tó fìdùnnú sọ pé “ẹ kọrin sí Jèhófà,” inú rẹ̀ tún dédé bà jẹ́, bóyá ó tiẹ̀ ń da omijé lójú pàápàá. (Ka Jeremáyà 20:14-16.) Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn rẹ̀ pọ̀ débi tó fi wò ó pé ì bá tiẹ̀ sàn tí wọn ò bá bí òun! Nínú ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ní irú ègún tó bá ìlú Sódómù àti Gòmórà ló máa bá ọkùnrin tó lọ ròyìn fáwọn èèyàn pé wọ́n bí òun. Àmọ́ ṣá o, ẹ jẹ́ ká ronú lórí kókó pàtàkì yìí: Ǹjẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn Jeremáyà ń bá a lọ títí ayé? Ṣé ńṣe ló sọ̀rètí nù pátápátá, pé bóun á ṣe máa bá a yí títí ayé nìyẹn? Rárá o. Ńṣe ló jọ pé ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì tó bá a yìí, ó sì borí rẹ̀ lóòótọ́. Ìwọ wo ohun tí ìwé Jeremáyà sọ tẹ̀ lé èyí. Páṣúrì kejì tó jẹ́ ọmọ aládé wá sọ́dọ̀ Jeremáyà pé Sedekáyà Ọba ní kóun wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ nípa àwọn ará Bábílónì tó sàga ti Jerúsálẹ́mù. Ni Jeremáyà bá tún gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀, tó fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà, tó sì sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìsàgatì náà. (Jer. 21:1-7) Ó hàn gbangba pé, ṣe ni Jeremáyà ń bá iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ lọ ní pẹrẹu!

12, 13. Tí ọkàn wa bá ń wúwo nígbà míì, kí la lè ṣe?

12 Lóde òní, ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì náà máa ń wúwo nígbà mìíràn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan kan ló fà á nínú àgọ́ ara wọn. Bóyá dókítà kan tó mọ̀ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dáadáa máa lè sọ ohun tó máa jẹ́ kí ìṣòro yẹn dín kù. (Lúùkù 5:31) Àmọ́, ní ti ọ̀pọ̀ jù lọ wa, àìsàn kọ́ ló ń jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa bá wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí kínú wa dédé máa dá dùn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ara ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá aláìpé ni. Ó lè jẹ́ àárẹ̀ ara tàbí ikú èèyàn ẹni ló fà á. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ẹ jẹ́ ká rántí pé ó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà náà, síbẹ̀ Ọlọ́run ò torí ìyẹn bínú sí i. Láti lè borí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, bóyá ńṣe la máa wáyè láti túbọ̀ máa sinmi dáadáa. Tàbí ká rí i pé a kọ́kọ́ ní sùúrù fún ara wa ná, ká lè ráyè túra ká déwọ̀n àyè kan lẹ́yìn ikú èèyàn wa dípò tá a ó fi dé ìbànújẹ́ mọ́ra. Àmọ́ ṣá o, ká rí i pé a ò pa àwọn ìpàdé ìjọ jẹ, ká sì máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn yòókù déédéé. Àwọn nǹkan pàtàkì yìí ni kò ní jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì lè borí wa, wọ́n á sì jẹ́ ká máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run.—Mát. 5:3; Róòmù 12:10-12.

13 Ì báà jẹ́ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ń bá ọ tàbí ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ déédéé, máa fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà tu ara rẹ nínú. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, àwọn ìgbà míì wà tí ìdààmú ọkàn bá Jeremáyà gan-an. Síbẹ̀, kò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú un kẹ̀yìn sí Ọlọ́run tó fẹ́ràn tó sì ń jọ́sìn tọkàntọkàn. Nígbà táwọn ọ̀tá rẹ̀ ń fi búburú san rere fún un, ńṣe ló ké pe Jèhófà, tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. (Jer. 18:19, 20, 23) Rí i dájú pé ìwọ náà ṣe bíi ti Jeremáyà.—Ìdárò 3:55-57.

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé nígbà míì ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá ọ tàbí gbogbo nǹkan ń sú ọ, báwo lo ṣe lè lo àwọn ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́ nínú ìwé Jeremáyà?

MÚ ÌTURA BÁ ỌKÀN TÍ ÀÁRẸ̀ MÚ

14. Ọ̀dọ̀ ta ni Jeremáyà ti rí ìṣírí gbà ní pàtàkì?

14 Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò bí Jeremáyà ṣe rí ìṣírí gbà àti bóun náà ṣe fún àwọn “ọkàn tí àárẹ̀ mú” níṣìírí. (Jer. 31:25) Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni wòlíì Jeremáyà ti rí ìṣírí gbà ní pàtàkì. Wo bí ọ̀rọ̀ Jèhófà yìí ṣe máa gbé ọ ró tó ká ní ìwọ ló sọ fún pé: “Ní tèmi, kíyè sí i, lónìí, mo ti sọ ìwọ di ìlú ńlá olódi . . . Ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’” (Jer. 1:18, 19) Abájọ tí Jeremáyà fi lè sọ pé Jèhófà ni “okun mi àti ibi odi agbára mi, àti ibi ìsásí mi ní ọjọ́ wàhálà.”—Jer. 16:19.

15, 16. Báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà fún Jeremáyà níṣìírí ṣe jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fún àwọn èèyàn níṣìírí?

15 Ṣàkíyèsí pé Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ.” Ǹjẹ́ o rí ohun kan nínú ọ̀rọ̀ yẹn tó jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe tẹ́nì kan tó o mọ̀ bá nílò ìṣírí? Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn rí i pé ará kan nínú ìjọ tàbí ìbátan ẹni kan nílò ìṣírí, ọ̀tọ̀ sì ni pé kéèyàn ṣe ohun kan láti fi ṣèrànwọ́. Tẹ́nì kan bá nílò ìṣírí, lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa dáa jù ni pé kó o ṣe ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Jeremáyà, ìyẹn ni pé kó o wà pẹ̀lú onítọ̀hún. Tó o bá ti wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀, kó o wá sọ ọ̀rọ̀ tó máa tù ú nínú, àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ jù o. Ìwọ̀nba gbólóhùn mélòó kan tó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa lè gbé e ró táá sì tù ú nínú ló máa dáa jù. Kò pọn dandan pé kí ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in o. Ṣáà ti sọ ọ̀rọ̀ tó máa fi hàn pé o ṣaájò rẹ̀, pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ ọ́ lógún àti pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ràn án lọ́wọ́ gan-an.—Ka Òwe 25:11.

16 Jeremáyà ké pe Ọlọ́run pé: “Jèhófà, rántí mi kí o sì yí àfiyèsí rẹ sí mi.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́; ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi.” (Jer. 15:15, 16) Bákan náà, ó lè gba pé kí ìwọ náà fara balẹ̀ ṣaájò ẹni tó o fẹ́ gbé ró. Òótọ́ ni pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ò lè lágbára bí ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ṣùgbọ́n o lè fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún ọ̀rọ̀ tìrẹ. Ọ̀rọ̀ tó wá látinú Bíbélì tó o sọ látọkàn wá bẹ́ẹ̀ lè mú ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì náà láyọ̀.—Ka Jeremáyà 17:7, 8.

17. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jeremáyà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ Sedekáyà Ọba àti ọ̀gágun Jóhánánì?

17 Kíyè sí i pé Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn èèyàn níṣìírí lẹ́yìn tóun náà gba ìṣírí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Báwo ló ṣe fún àwọn èèyàn níṣìírí? Nígbà kan, Sedekáyà Ọba sọ fún Jeremáyà pé ẹ̀rù àwọn Júù tó lọ lẹ̀dí àpò pẹ̀lú àwọn ará Bábílónì ń ba òun. Wòlíì Jeremáyà wá sọ̀rọ̀ ìyànjú fún ọba náà, ó ní kó ṣègbọràn sí Jèhófà, kí nǹkan lè lọ dáadáa fún un. (Jer. 38:19, 20) Lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù, Jóhánánì tó jẹ́ ọ̀gágun àwọn Júù, ń gbèrò àtikó ìwọ̀nba àwọn Júù tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà lọ sí Íjíbítì. Ṣùgbọ́n ó kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ Jeremáyà wòlíì. Jeremáyà tẹ́tí gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Jóhánánì, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà. Nígbà tó yá, ó sọ èsì Jèhófà, ó sì sọ pé wọ́n á jàǹfààní tí wọ́n bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jèhófà pé kí wọ́n má ṣe kúrò ní ilẹ̀ náà. (Jer. 42:1-12) Kíyè sí i pé Jeremáyà tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ Sedekáyà Ọba àti ọ̀rọ̀ ọ̀gágun Jóhánánì dáadáa kó tó sọ̀rọ̀. Láti lè gbéni ró, ó ṣe pàtàkì pé ká máa kọ́kọ́ tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ẹni tó o fẹ́ gbé ró náà sọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀. Tẹ́tí gbọ́ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, àtohun tó ń bà á lẹ́rù, sì máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un bó bá ṣe yẹ. Ọlọ́run kò ní dìídì rán ọ níṣẹ́ sí ẹni tó nílò ìṣírí náà o, àmọ́ o lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì, tó dá lórí àwọn ìbùkún tá a máa rí gbà lọ́jọ́ ọ̀la, fún un.—Jer. 31:7-14.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 91

18, 19. Àpẹẹrẹ ọ̀nà tá a lè máa gbà fúnni níṣìírí wo la rí nínú ọ̀ràn tàwọn ọmọ Rékábù àti ti Ebedi-mélékì?

18 Sedekáyà àti Jòhánánì kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àtàtà tí Jeremáyà fún wọn, bákan náà ó ṣeé ṣe káwọn míì lónìí má tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tìẹ náà. Má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. A ṣáà rí àwọn èèyàn kan tó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jeremáyà fún wọn, ó ṣeé ṣe káwọn kan tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tìẹ náà. Wo ọ̀rọ̀ tàwọn ọmọ Rékábù, tó jẹ́ ìran ọmọ Kénì, tí àwọn àtàwọn Júù jọ wà pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Lára àṣẹ tí Jèhónádábù baba ńlá wọn pa fún wọn ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ mu wáìnì torí àtìpó ni wọ́n. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé lákòókò tí àwọn ará Bábílónì ń bá àwọn ará Júdà jà, Jeremáyà mú àwọn ọmọ Rékábù wá sínú iyàrá ìjẹun tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Ó gbé wáìnì kalẹ̀ níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe rán an, ó ní kí wọ́n fi gbádùn ara wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rékábù kò ya aláìgbọràn bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n bọ̀wọ̀ fún àṣẹ baba ńlá wọn, wọn kò jẹ́ mu wáìnì náà. (Jer. 35:3-10) Ni Jeremáyà bá yìn wọ́n bí Jèhófà ṣe rán an, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la wọn. (Ka Jeremáyà 35:14, 17-19.) Àpẹẹrẹ tó o lè máa tẹ̀ lé nìyẹn nígbà tó o bá fẹ́ fúnni níṣìírí. Ìyẹn ni pé kó o máa gbóríyìn fáwọn èèyàn tọkàntọkàn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.

19 Ohun tí Jeremáyà ṣe náà nìyẹn fún Ebedi-mélékì ará Etiópíà, tí ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Sedekáyà Ọba. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ aládé Júdà sọ Jeremáyà sínú ìkùdu ẹlẹ́rẹ̀, kó lè kú síbẹ̀. Ebedi-mélékì wá lọ bẹ Sedekáyà Ọba pé kó jẹ́ kóun fa wòlíì náà yọ, ó sì gbà bẹ́ẹ̀. Ni Ebedi-mélékì ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yìí bá fa Jeremáyà yọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá Jeremáyà lè wá fipá dá òun dúró. (Jer. 38:7-13) Níwọ̀n bí ohun tí Ebedi-mélékì ṣe yìí ti lè sọ ọ́ dọ̀tá àwọn ọmọ aládé Júdà, ẹ̀rù lè máa bà á nípa ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Ṣùgbọ́n Jeremáyà ò dákẹ́ kó máa wo Ebedi-mélékì níran, pé á borí ìbẹ̀rù rẹ̀ tó bá yá. Ńṣe ló sọ̀rọ̀ ìṣírí fún Ebedi-mélékì, tó sì sọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run máa ṣe fún un lọ́jọ́ iwájú.—Jer. 39:15-18.

20. Kí ló yẹ ká máa ṣe fún àwọn ará wa tàgbà tèwe?

20 Bá a ṣe ka ìwé Jeremáyà yìí, ó dájú pé a ti rí àpẹẹrẹ àtàtà nípa bí àwa náà ṣe lè ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará ní Tẹsalóníkà láti ṣe. Ó ní: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró lẹ́nì kìíní-kejì . . . Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú yín.”—1 Tẹs. 5:11, 28.

Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni wàá fẹ́ lò nínú èyí tó o kọ́ lára Jeremáyà nígbà tó o bá ń gbìyànjú láti gbé ọkàn tí àárẹ̀ mú ró?

a Páṣúrì míì tún wà nígbà ìjọba Sedekáyà o. Àmọ́ ọmọ aládé nìyẹn ní tiẹ̀, òun ló sì ní kí ọba jẹ́ káwọn pa Jeremáyà.—Jer. 38:1-5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́