ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jr orí 15 ojú ìwé 182-192
  • “Èmi Kò Lè Dákẹ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Èmi Kò Lè Dákẹ́”
  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÁA WÀÁSÙ NÌṢÓ BÁWỌN ÈÈYÀN Ò TIẸ̀ FẸ́ GBỌ́
  • ÀWỌN ALÁTAKÒ Ò LÈ DÁ IṢẸ́ ỌLỌ́RUN DÚRÓ
  • “MÁ FÒYÀ”
  • Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN TÍ JEREMÁYÀ KỌ SÍLẸ̀ FÚN Ọ
  • “Kí O sì Sọ Ọ̀rọ̀ Yìí Fún Wọn”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Àwọn Wo Ló Yẹ Kó O Yàn Lọ́rẹ̀ẹ́?
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Ọkàn tí Àárẹ̀ Mú Ni Èmi Yóò Tẹ́ Lọ́rùn ní Kíkún”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi sí Ẹnu Rẹ”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
Àwọn Míì
Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
jr orí 15 ojú ìwé 182-192

Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún

“Èmi Kò Lè Dákẹ́”

1. Kí nìdí tí Jeremáyà àtàwọn wòlíì Jèhófà yòókù kò fi dákẹ́?

LÁTI ọdún 647 ṣáájú Sànmánì Kristẹni làwọn aráàlú Jerúsálẹ́mù ti ń gbọ́ tí wòlíì Jeremáyà ń kéde lemọ́lemọ́ láàárín ìgboro àti láwọn gbàgede ìlú wọn pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.” Jeremáyà ò sì yéé kéde ọ̀rọ̀ yìí sétí wọn. Kódà nígbà tí ìlú yẹn pa run ní ogójì ọdún lẹ́yìn náà, ó tún sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí kan náà. (Jer. 2:4; 42:15) Ọlọ́run Olódùmarè ń rán àwọn wòlíì sáwọn Júù láti rí i pé wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú òun kí wọ́n lè ronú pìwà dà. Bá a sì ṣe sọ níṣàájú nínú ìwé yìí, ti Jeremáyà ṣàrà ọ̀tọ̀ láàárín gbogbo àwọn wòlíì tí Ọlọ́run gbẹnu wọn sọ̀rọ̀. Nígbà tí Ọlọ́run yan Jeremáyà ṣe wòlíì, ohun tó sọ fún un ni pé: “Dìde, kí o sì bá wọn sọ ohun gbogbo tí èmi fúnra mi yóò pa láṣẹ fún ọ. Má ṣe jẹ́ kí ìpayà èyíkéyìí bá ọ.” (Jer. 1:17) Iṣẹ́ tó gba akitiyan gan-an ni. Onírúurú ìyà àti ìdààmú ló bá Jeremáyà nídìí iṣẹ́ yẹn, àmọ́ ó sọ ohun pàtàkì kan tó mú kó ṣe iṣẹ́ rẹ̀ parí láìfi gbogbo ìṣòro yẹn pè. Ó ní: “Ọkàn-àyà mi ń ru gùdù nínú mi. Èmi kò lè dákẹ́.”—Jer. 4:19.

2, 3. (a) Báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà?

2 Ọ̀nà tí Jeremáyà gbà ṣe iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yòókù lẹ́yìn rẹ̀. (Ják. 5:10) Bí àpẹẹrẹ, láìpẹ́ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn aláṣẹ àwọn Júù mú àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́. Wàá kúkú ti ka èsì tí wọ́n fún àwọn aláṣẹ yẹn. Wọ́n ní: “Àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:19, 20) Làwọn aláṣẹ náà bá halẹ̀ mọ́ Pétérù àti Jòhánù pé táwọn bá tún gbá wọn mú pẹ́nrẹ́n, wọ́n á jẹ palaba ìyà, wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀. Ìwọ náà mọ ohun táwọn méjèèjì ṣe lẹ́yìn náà. Ká sòótọ́, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn kò lè dákẹ́ ìwàásù o, wọn ò sì dákẹ́ rárá.

3 Ǹjẹ́ o rí bí ọ̀rọ̀ Pétérù àti ti Jòhánù tó wà nínú ìwé Ìṣe 4:20 ṣe fi hàn pé wọ́n ní ìtara bíi ti Jeremáyà? Níwọ̀n bí o ti jẹ́ òjíṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tọ́rọ̀ ò ṣeé fi falẹ̀ yìí, ó dájú pé ìwọ náà yóò ti pinnu látọkàn rẹ wá pé, ‘Èmi ò lè dákẹ́ rárá o!’ Jẹ́ ká wo bá a ṣe lè jẹ́ alákíkanjú bíi ti Jeremáyà tí kò dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, káwa náà máa wàásù ìhìn rere nìṣó láìfi ipò nǹkan tó túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé yìí pè.

MÁA WÀÁSÙ NÌṢÓ BÁWỌN ÈÈYÀN Ò TIẸ̀ FẸ́ GBỌ́

4. Ìhà wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn kọ sí gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì?

4 Ǹjẹ́ kò dá ọ lójú pé nínú gbogbo ìròyìn táwọn èèyàn ń gbọ́ láyé yìí, èyí tó sọ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun yóò mú ọjọ́ ọ̀la alárinrin wá lábẹ́ ìṣàkóso Ọmọ òun ló dáa jù? Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí máa ń sọ ohun tó dà bí èyí táwọn Júù ìgbàanì sọ fún Jeremáyà nígbà kan, pé: “Ní ti ọ̀rọ̀ tí o bá wa sọ ní orúkọ Jèhófà, àwa kì yóò fetí sí ọ.” (Jer. 29:19; 44:16) Irú ọ̀rọ̀ báyìí ni Jeremáyà sábà máa ń gbọ́ lẹ́nu wọn. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ṣe fẹ́ gbọ́ ìwàásù lónìí náà nìyẹn, wọ́n máa ń sọ fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé, “Mi ò ráyè o.” Báwọn èèyàn kì í ṣe fẹ́ máa gbọ́ ìwàásù yìí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, tíyẹn sì ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan ní ìjọ yín tàbí kó tiẹ̀ máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ìwọ alára, kí lẹ lè ṣe nípa rẹ̀?

5. (a) Irú ẹ̀mí wo ni Jeremáyà ní nígbà tó di pé àwọn èèyàn ò fẹ́ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé inú ewu gidi làwọn tó bá kọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere wà?

5 Wo irú ẹ̀mí tí Jeremáyà ní nígbà tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ará Júdà ò fẹ́ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń sọ fún wọn. Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì, Jèhófà jẹ́ kó rí ìran ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń bọ̀. (Ka Jeremáyà 4:23-26.) Jeremáyà wá rí i pé bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn wọ̀nyí ò bá ní pa run, wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí òun máa sọ, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lé e lórí. Irú ipò táwọn èèyàn wà lónìí náà nìyẹn, títí kan àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́” tí ìdájọ́ Ọlọ́run máa dé sórí ayé burúkú ìsinsìnyí, ó ní: “Yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:34-36) Látinú ọ̀rọ̀ Jésù yìí, o lè rí i pé inú ewu gidi làwọn tó bá kọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere wà.

ẸNI TÍ KÌ Í GBỌ́ ÌWÀÁSÙ LÈ DẸNI TÓ Ń GBỌ́

Obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ wàásù fún nílé rẹ̀ nílẹ̀ New Zealand lóun kì í gbọ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí òun fẹ́ gbọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé lọ́sẹ̀ yẹn, obìnrin náà lọ síbi ìsìnkú Ẹlẹ́rìí kan nítorí pé ọkọ rẹ̀ àti ọkọ arábìnrin tó kú náà jọ ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà. Obìnrin yìí ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ọkọ arábìnrin tó kú náà gan-an. Ó tún sọ pé àlàyé yékéyéké tí Ẹlẹ́rìí tó sọ̀rọ̀ ìsìnkú ṣe látinú Bíbélì nípa ìrètí àjíǹde bọ́gbọ́n mu gan-an ni.

Obìnrin yìí sọ pé òun máa ń dá àwọn nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú àwọn tó ń ṣàìsàn tó máa yọrí sí ikú lẹ́kọ̀ọ́. Nítorí ibi ìsìnkú tó lọ yẹn, ó lóun tí ń sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ òun pé kí wọ́n lọ síbi ìsìnkú táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣe. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wá wàásù fún un pé òun máa ń sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ òun pé àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣàlàyé tó jóòótọ́ nípa ipò táwọn òkú wà, wọ́n sì ń jẹ́ káwọn èèyàn ní ojúlówó ìrètí nípa ọjọ́ ọ̀la. Ó wò ó pé àwọn nọ́ọ̀sì yẹn lè máa lo àwọn kókó méjèèjì yìí láti fi ṣèrànwọ́ fáwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú.

Ó ṣe kedere pé, tó bá tiẹ̀ ti pẹ́ táwọn kan kì í ti í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa, ìyẹn kò fi hàn pé Jèhófà ò lè ‘fún wọn ní ọkàn-àyà láti mọ òun.’ (Jer. 24:7) Nítorí náà, àwọn tí kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín ṣì lè dẹni tó ń gbọ́.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 184

6. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa wàásù fáwọn èèyàn nìṣó, títí kan àwọn ti ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù rẹ pàápàá?

6 Àmọ́ àwọn tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà tá à ń wàásù tí wọ́n sì kọbi ara sí i yóò gba èrè jaburata. Ìdí ni pé Ọlọ́run ti ṣọ̀nà tá a ó fi bọ́ lọ́wọ́ ìparun, ká sì wọnú ayé tuntun rẹ̀. Láwọn ọ̀nà kan, bó ṣe rí nígbà tí Jeremáyà ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run náà nìyẹn. Àwọn ará Júdà náà lè mórí bọ́ nínú ìparun tó ń bọ̀ wá bá wọn. (Ka Jeremáyà 26:2, 3.) Jeremáyà gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n “fetí sílẹ̀ kí olúkúlùkù wọn sì padà” wá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tòótọ́. A ò mọ iye àwọn tí ọ̀rọ̀ wòlíì náà mú kó ronú pìwà dà kí wọ́n sì yí pa dà. Àmọ́ àwọn kan yí pa dà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti yí pa dà lóde òní náà. Bá a ṣe ń bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà nìṣó, a sábà máa ń gbọ́ nípa bí àwọn kan tí kò fẹ́ máa gbọ́ ìwàásù wa tẹ́lẹ̀ ṣe yí pa dà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́. (Wo àpótí náà, “Ẹni Tí Kì Í Gbọ́ Ìwàásù Lè Dẹni Tó Ń Gbọ́,” lójú ìwé 184.) Ǹjẹ́ ìyẹn kì í ṣe ara ìdí tó fi yẹ ká tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tó ń gbẹ̀mí là yìí?

Kí nìdí tó o fi pinnu láti máa wàásù nìṣó, báwọn èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ?

ÀWỌN ALÁTAKÒ Ò LÈ DÁ IṢẸ́ ỌLỌ́RUN DÚRÓ

7. Báwo làwọn ọ̀tá ṣe gbìyànjú láti fòpin sí iṣẹ́ wòlíì tí Jeremáyà ń ṣe?

7 Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ni pé àwọn alátakò ń gbìyànjú léraléra láti pa á, àti láti fòpin sí iṣẹ́ wòlíì tó ń ṣe. Àwọn wòlíì èké ta kò ó ní gbangba. (Jer. 14:13-16) Bí Jeremáyà bá ń kọjá lọ nígboro Jerúsálẹ́mù, ṣe làwọn èèyàn máa ń bú u, tí wọ́n á sì máa fi ṣẹlẹ́yà. (Jer. 15:10) Àwọn kan lára àwọn ọ̀tá rẹ̀ tiẹ̀ gbèrò onírúurú ọ̀nà míì tí wọ́n á fi bà á lórúkọ jẹ́. (Jer. 18:18) Àwọn èèyàn míì ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ káàkiri láti fi ba Jeremáyà jẹ́ káwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń sọ má bàa gbọ́rọ̀ rẹ̀ mọ́. (Ìdárò 3:61, 62) Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ Jeremáyà panu mọ́? Rárá o. Ṣe ló ń bá a nìṣó láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ni kò jẹ́ kó panu mọ́?

8. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà bí àwọn alátakò rẹ̀ ṣe túbọ̀ ń fínná mọ́ ọn?

8 Nǹkan pàtàkì tí Jeremáyà fi ń borí gbogbo àtakò àwọn ọ̀tá yẹn ni ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Jèhófà. Gbàrà tí Jeremáyà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì ni Ọlọ́run ti fi yé e pé òun máa pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́ òun sì máa dáàbò bò ó. (Ka Jeremáyà 1:18, 19.) Jeremáyà gba ọ̀rọ̀ Jèhófà yìí gbọ́, Jèhófà ò sì já a kulẹ̀. Bí àwọn alátakò rẹ̀ ṣe ń fínná mọ́ ọn, tí wọ́n sì túbọ̀ ń fòró ẹ̀mí rẹ̀ ni àyà rẹ̀ ń le sí i, tí ìgboyà àti ẹ̀mí ìfaradà rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i. Jẹ́ ká wá wo bí ànímọ́ wọ̀nyẹn ṣe ràn án lọ́wọ́.

9, 10. Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà wo ló lè mú kí ìwọ náà ní ìgboyà?

9 Nígbà kan, àwọn àlùfáà àtàwọn wòlíì ọlọ̀tẹ̀ fa Jeremáyà lọ síwájú àwọn ọmọ aládé Júdà pé kí wọ́n pa á dà nù. Ǹjẹ́ èyí wá mú kí Jeremáyà bẹ̀rù kò sì lọ gbé jẹ́ẹ́? Ó tì o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni èsì tó fún wọn fọ́ gbogbo irọ́ àwọn apẹ̀yìndà náà yángá, tí wọn kò fi lè pa á.—Ka Jeremáyà 26:11-16; Lúùkù 21:12-15.

10 Rántí pé nígbà tí Páṣúrì tó jẹ́ kọmíṣọ́nà inú tẹ́ńpìlì gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ ńlá tí wòlíì Jeremáyà kéde, ó fi Jeremáyà sínú àbà. Ṣe ni Páṣúrì máa rò pé ìyẹn máa kọ́ Jeremáyà lọ́gbọ́n, á wá gbẹ́nu ẹ̀ dákẹ́. Nítorí náà, lọ́jọ́ kejì, Páṣúrì tú u sílẹ̀ kó máa lọ. Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ara á sì máa kan Jeremáyà nítorí ìrora rẹ̀ níbi tí wọ́n há a mọ́, síbẹ̀, ó kọjú sí Páṣúrì ó sì kéde ìdájọ́ Jèhófà lé e lórí. Tó fi hàn pé gbogbo bí wọ́n ṣe hàn án léèmọ̀ yẹn kò pa á lẹ́nu mọ́ rárá! (Jer. 20:1-6) Kí nìdí? Jeremáyà alára sọ fún wa pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú mi bí alágbára ńlá tí ń jáni láyà. Ìdí nìyẹn tí àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi yóò fi kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí.” (Jer. 20:11) Àní nígbà tí àwọn alátakò tí ojú wọn korò lágbárí dojú kọ Jeremáyà, jìnnìjìnnì ò bá a. Ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Jèhófà lágbára gan-an ni, ìwọ náà sì lè nírú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀.

11, 12. (a) Báwo ni Jeremáyà ṣe lo làákàyè nígbà tí Hananáyà ta kò ó? (b) Àǹfààní wo ló wà nínú kó o máa “kó ara [rẹ] ní ìjánu lábẹ́ ibi”?

11 Àmọ́ ṣá, ẹ má ṣe jẹ́ ká rò pé agbawèrèmẹ́sìn ni Jeremáyà o. Ó máa ń lo làákàyè táwọn alátakò bá dojú kọ ọ́. Ó máa ń mọ ìgbà tó yẹ kó fi wọ́n sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti Hananáyà. Wòlíì èké yẹn ta ko àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ní gbangba, Jeremáyà wá tọ́ ọ sọ́nà, ó sì sọ ohun téèyàn fi ń dá wòlíì tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Ni Hananáyà bá fipá gba àjàgà igi kan tí Jeremáyà gbé sí ọrùn tó fi ń ṣàpèjúwe bí àjàgà Bábílónì ṣe máa wà lọ́rùn àwọn èèyàn, ó sì ṣẹ́ ẹ. Kí ni Jeremáyà wá ṣe níwọ̀n bí kò ti mọ ohun tí Hananáyà máa tún fẹ́ ṣe lẹ́yìn ìyẹn? Bíbélì sọ pé: “Jeremáyà wòlíì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.” Ṣe ni Jeremáyà kúrò níbẹ̀ o. Nígbà tó yá, Jèhófà ní kó pa dà lọ bá Hananáyà, kó sì sọ ohun tí òun máa ṣe, ìyẹn ni pé Bábílónì yóò kó àwọn Júù nígbèkùn àti pé ikú yóò pa Hananáyà.—Jer. 28:1-17.

12 Àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí fi hàn kedere pé, bá a ṣe ń lo ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, a tún gbọ́dọ̀ máa lo làákàyè. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé nínú ilé kan, ẹnì kan kọ̀ láti gba àlàyé inú Bíbélì tá à ń ṣe, tó dà á sí ìbínú, bóyá tó tiẹ̀ fẹ́ sọ ọ́ dìjà, ńṣe ni ká rọra fibẹ̀ sílẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́, ká kọjá sí ilé míì. Kò sídìí láti máa bá ẹnikẹ́ni fa ọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run rárá o. Tá a bá “kó ara [wa] ní ìjánu lábẹ́ ibi,” ìyẹn lè jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ran onítọ̀hún lọ́wọ́ nígbà míì tó wọ̀.—Ka 2 Tímótì 2:23-25; Òwe 17:14.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 187

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere? Bá a ṣe ń lo ìgboyà, kí nìdí tó fi yẹ ká tún máa lo làákàyè?

“MÁ FÒYÀ”

13. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Jeremáyà pé: “Má fòyà,” kí sì nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa rẹ̀?

13 Ipò lílekoko tó gbòde kan ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni kan àwọn olùjọsìn tòótọ́ tó wà níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi sọ fún Jeremáyà pé: “Má fòyà.” (Jer. 1:8; Ìdárò 3:57) Jèhófà sì gbẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí kan náà fáwọn èèyàn Ọlọ́run yòókù. (Ka Jeremáyà 46:27.) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí? Lákòókò òpin tó léwu gan-an yìí, ẹ̀rù lè fẹ́ bà wá nígbà míì. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ a máa fetí sí Jèhófà tó ń tipa ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ fún àwa náà pé: “Má fòyà”? Níṣàájú, a ti ṣàlàyé nínú ìwé yìí nípa bí Ọlọ́run ṣe pa ẹ̀mí Jeremáyà mọ́ lákòókò tó bani lẹ́rù gan-an ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù. Ẹ jẹ́ ká ṣàtúnyẹ̀wò ṣókí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà náà ká lè rí ẹ̀kọ́ tó yẹ ká kọ́ níbẹ̀.

14, 15. (a) Inú ibi eléwu wo ni wọ́n ju Jeremáyà sí? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ pé òun máa dáàbò bo Jeremáyà ṣẹ?

14 Bí àwọn ará Bábílónì ṣe túbọ̀ sé ìlú Jerúsálẹ́mù mọ́ pinpin, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í han àwọn aráàlú léèmọ̀. Láìpẹ́, oúnjẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sì tán pátápátá. (Jer. 37:21) Pẹ̀lú gbogbo bí ìyàn náà ṣe mú tó, wọ́n tún wá ju Jeremáyà sínú ibi tó lè kú sí. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ aládé Júdà fúngun mọ́ Sedekáyà dọ̀bọ̀sìyẹsà ọba tó sì gbà pé kí wọ́n sọ Jeremáyà sínú ìkùdu jíjìn kan. Kò sómi nínú ìkùdu náà, ẹrẹ̀ ló kún ibẹ̀. Bí Jeremáyà ṣe ń rì sínú ẹrẹ̀ náà, á máa wò ó pé ikú rèé, pé àfi Ọlọ́run nìkan ló lè ṣọ̀nà àbáyọ fóun. Tó bá jẹ́ pé ìwọ ló wà nírú ipò yẹn, ǹjẹ́ ẹ̀rù ò ní bà ọ́?—Jer. 38:4-6.

15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara bíi tiwa ni Jeremáyà, ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún un pé òun ò ní fi í sílẹ̀ láé. (Ka Jeremáyà 15:20, 21.) Ǹjẹ́ Jèhófà sì jẹ́ kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ já sí asán? A mọ̀ dájú pé Jèhófà kò jẹ́ kó já sí asán. Ọlọ́run mú kí Ebedi-mélékì ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ìfẹ́ ọkàn àwọn ọmọ aládé, kó lọ gbàṣẹ lọ́dọ̀ ọba láti yọ Jeremáyà. Ó sì fà á yọ kúrò nínú ìkùdu ẹlẹ́rẹ̀ tó jìn náà níbi tí ì bá kú sí.—Jer. 38:7-13.

16. Inú àwọn ewu wo ni Jèhófà ti kó àwọn tó dúró ṣinṣin sí i yọ?

16 Kódà lẹ́yìn tí wọ́n fa Jeremáyà jáde tán, kò tíì bọ́ lọ́wọ́ ewu. Nítorí ohun tí Ebedi-mélékì sọ fún ọba nígbà tó lọ bẹ̀ ẹ́ láti fa Jeremáyà yọ ni pé: “[Yóò] kú sí ibi tí ó wà nítorí ìyàn náà. Nítorí kò sí búrẹ́dì mọ́ ní ìlú ńlá yìí.” (Jer. 38:9) Ìyàn tó wí yíì sì mú gan-an ní Jerúsálẹ́mù débi pé èèyàn bíi tiwọn ló kù táwọn ẹlòmíì ń jẹ. Àmọ́ Jèhófà ò fi Jeremáyà sílẹ̀ o, ó tún ṣọ̀nà tó fi gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Jeremáyà sì sọ fún Ebedi-mélékì pàápàá pé Jèhófà ní òun máa dáàbò bo òun pẹ̀lú dájúdájú. (Jer. 39:16-18) Jeremáyà ò gbàgbé ohun tí Ọlọ́run fi dá a lójú pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè.” (Jer. 1:8) Níwọ̀n bí Ọlọ́run Olódùmarè sì ti ń fìṣọ́ ṣọ́ àwọn adúróṣinṣin méjèèjì yìí, ọ̀tá tàbí ìyàn kankan ò lè pa wọ́n kú. Ẹ̀mí àwọn méjèèjì ò sì bá ìparun ìlú yẹn lọ. Kí ni kókó tá a wá fẹ́ fà yọ? Òun ni pé, Jèhófà lóun máa dáàbò bò wọ́n, ó sì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Jer. 40:1-4.

17. Kí nìdí tó fi yẹ kó o nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ òun?

17 Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí ń ṣẹ lójú méjèèjì báyìí, ó sì máa tó dé ògógóró rẹ̀. Láìpẹ́ sí àkókò yìí, “àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, àti lórí ilẹ̀ ayé làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè, láìmọ ọ̀nà àbájáde . . . nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Lúùkù 21:25, 26) Ńṣe ni ká ṣì máa wo ọ̀nà tí àwọn àmì wọ̀nyẹn máa gbà wáyé àti jìnnìjìnnì tí wọ́n máa fà bá ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, má ṣe mikàn nípa agbára Jèhófà láti gba àwa èèyàn rẹ̀ là, sì mọ̀ dájú pé ó ń wù ú láti gbà wá là. Àmọ́ ní tàwọn tí kò bá rí ojú rere rẹ̀, ojú wọn máa rí màbo. (Ka Jeremáyà 8:20; 14:9.) Àní tó bá tiẹ̀ dà bíi pé kò fẹ́ sọ́nà àbáyọ fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bí ìgbà tí Jeremáyà wà nínú ìsàlẹ̀ ìkùdu ẹlẹ́rẹ̀ tó ṣókùnkùn, Ọlọ́run lè kó wọn yọ! Ohun tí Ọlọ́run sọ fún Ebedi-mélékì ló máa ṣẹ sáwọn èèyàn rẹ̀ lára. Ó ní: “‘Láìkùnà, èmi yóò pèsè àsálà fún ọ, ìwọ kì yóò sì tipa idà ṣubú; dájúdájú, ìwọ yóò sì ni ọkàn rẹ bí ohun ìfiṣèjẹ, nítorí pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà.”—Jer. 39:18.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 190

Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN TÍ JEREMÁYÀ KỌ SÍLẸ̀ FÚN Ọ

18. (a) Àṣẹ Ọlọ́run wo ló yí ìgbésí ayé Jeremáyà pa dà? (b) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Jeremáyà nínú Jeremáyà 1:7?

18 Ọlọ́run sọ fún Jeremáyà pé: “Ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí èmi yóò rán ọ lọ ni kí o lọ; ohun gbogbo tí mo bá sì pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ.” (Jer. 1:7) Ìgbà tí Ọlọ́run ti pa àṣẹ yẹn fún Jeremáyà ni ìgbésí ayé rẹ̀ ti yí pa dà pátápátá. Látìgbà náà lọ, ohun tó ń jẹ ẹ́ lógún jù ni bó ṣe máa kéde “ọ̀rọ̀ Jèhófà.” Gbólóhùn yẹn sì ń hàn léraléra jálẹ̀ inú ìwé Jeremáyà. Ní orí tó gbẹ̀yìn ìwé náà, Jeremáyà sọ bí wọ́n ṣe pa Jerúsálẹ́mù run àti bí Sedekáyà, ọba tó jẹ gbẹ̀yìn níbẹ̀, ṣe dèrò ìgbèkùn. Jeremáyà ń bá a nìṣó láti kọ́ àwọn ará Júdà, ó sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà, títí ipò nǹkan fi jẹ́ kó hàn kedere pé iṣẹ́ rẹ̀ ti parí.

19, 20. (a) Kí nìdí tí iṣẹ́ Ọlọ́run tí Jeremáyà ṣe fi jẹ́ àpẹẹrẹ kan tó yẹ kó o tẹ̀ lé? (b) Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe tan mọ́ rírí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn? (d) Ipa wo ni àgbéyẹ̀wò ìwé Jeremáyà àti Ìdárò ti ní lórí rẹ?

19 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lónìí àti iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún Jeremáyà fi jọra. Bí Jeremáyà ṣe sin Ọlọ́run tòótọ́ lásìkò ìdájọ́ nìwọ náà ṣe ń sin Ọlọ́run lásìkò ìdájọ́. Òótọ́ ni pé àwọn ojúṣe míì wà tó lè máa gba àkókò àti agbára rẹ, síbẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kó o ṣe nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ńṣe lò ń fi iṣẹ́ yìí gbé orúkọ ńlá Ọlọ́run ga, o tún ń tipa iṣẹ́ yìí fi hàn pé o gbà pé Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, ló ní ẹ̀tọ́ àti àṣẹ tó ga jù. (Ka Ìdárò 5:19.) O sì tún ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gan-an bó o ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run tòótọ́ àtàwọn ohun tó ń fẹ́ kéèyàn ṣe láti lè rí ìyè.—Jer. 25:3-6.

20 Ohun tí Jeremáyà sọ nípa iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́ ni pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (Jer. 15:16) Irú ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn yìí kan náà ló wà fún gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ bá sún un láti máa gbẹnu sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ lónìí. Nítorí náà, ohun tó ti dára ni pé kó o máa kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà nìṣó bíi ti Jeremáyà.

Báwo ni àpẹẹrẹ Jeremáyà àti ti Ebedi-mélékì ṣe lè mú kí ìwọ náà jẹ́ onígboyà? Ànímọ́ Jeremáyà wo ni wàá fẹ́ máa lò bó o ṣe ń wàásù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́