Irin Iṣẹ́ Tuntun Láti Ran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Mọ Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Ń béèrè
“RÍRỌRÙN tí ìgbékalẹ̀ rẹ̀ rọrùn, tí ó ṣe tààràtà, tí ó sì jẹ́ ti onínúure yóò ṣàṣeyọrí ju bí a ti fojú sọ́nà lọ. A ṣàlàyé àwọn kókó ẹ̀kọ́ náà lọ́nà tí kò díjú, tí ó sì gbádùn mọ́ni tí ó fi jẹ́ pé, a óò sún ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, tí ń ṣèwákiri láti wí pé, ‘Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.’” (Kọ́ríńtì Kíní 14:25) Ohun tí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Thailand sọ nìyẹn nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Watch Tower Society ni ó mú un jáde ní àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ní 1996 sí 1997.
A pète ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32, aláwọ̀ mèremère yìí fún ìjíròrò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kárí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọrùn ó sì ṣe ṣókí, ní ṣíṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa lọ́nà tí ó ṣe kedere. Kò yẹ kí ó ṣòro fún àwọn òǹkàwé láti lóye rẹ̀. Báwo ni o ṣe lè fi ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Lo àwọn ìbéèrè. Àwọn ìbéèrè wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan, ìwọ yóò rí nọ́ńbà ìpínrọ̀ tí ìdáhùn wà nínú àkámọ́. A lè lo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìrànwọ́ fún ìnasẹ̀ ẹ̀kọ́ àti fún àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí a ń ṣe nínú ilé, ó lè béèrè àwọn ìbéèrè náà lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ láti lè gbọ́ ìlóhùnsí rẹ̀. Dípò ṣíṣàtúnṣe ìdáhùn èyíkéyìí tí kò bá tọ̀nà lọ́gán, o lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó. Ní òpin ẹ̀kọ́ náà, o lè pa dà sórí àwọn ìbéèrè náà láti mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ náà ti lè dáhùn wọn nísinsìnyí lọ́nà tí ó bá Bíbélì mu.
Yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wò. Nínú ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fi ti ọ̀rọ̀ lẹ́yìn tẹ̀ lé àwọn gbólóhùn kúkúrú nípa òtítọ́ Bíbélì. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ṣe ni a tọ́ka sí púpọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, tí a kò ṣàyọlò wọn, ó ṣe pàtàkì pé kí a fún akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí láti yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí wò nínú Bíbélì tirẹ̀. Ó ní láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì ṣàṣàrò lórí rẹ̀, kí ó tó lè fi sí ìlò nínú ìgbésí ayé.—Jọ́ṣúà 1:8.
Ṣàlàyé àwọn àwòrán. A fi oríṣiríṣi fọ́tò àti àwòrán ṣàlàyé nínú ìwé pẹlẹbẹ náà—iṣẹ́ ọnà rẹ̀ lápapọ̀ lé ní 50. Kì í ṣe nítorí kí o lè wò ó lásán ni a ṣe pèsè ìwọ̀nyí ṣùgbọ́n láti túbọ̀ jẹ́ ìrànwọ́ fún ẹ̀kọ́. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀kọ́ méjì tí ó gbẹ̀yìn (tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ojú ìwé kan, tí méjèèjì dojú kọra) ní àkọlé náà, “Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọrun” àti “Ìpinnu Rẹ Láti Sin Ọlọrun.” Fọ́tò tí ó gba ojú ìwé méjì náà fi ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí ẹnì kan náà hàn, ó fi í hàn bí ó ti ń wàásù láìjẹ́bí àṣà, bí ó ti ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ilé dé ilé, bí ó ti ń ya ara rẹ̀ sí mímọ́, àti bí ó ti ṣe batisí ní paríparí rẹ̀. Nípa dídarí àfiyèsí akẹ́kọ̀ọ́ sí àwọn àwòrán wọ̀nyí, o ń ràn án lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìgbésẹ̀ tí a ń béèrè fún láti lè ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run.
Bí ẹnì kan tí ń fi ìfẹ́ hàn kò bá lè kàwé dáradára ńkọ́ tàbí tí kò lè kàwé rárá? Society ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ìwé pẹlẹbẹ yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àwọn èdè mélòó kan lórí kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí. Kásẹ́ẹ̀tì náà ní ọ̀rọ̀ ìwé pẹlẹbẹ náà nínú títí kan ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. A gbà á sílẹ̀ lọ́nà yí: A ka ìbéèrè àkọ́kọ́, ìpínrọ̀ (tàbí àwọn ìpínrọ̀) tí ó dáhùn rẹ̀ tẹ̀ lé e, pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Lẹ́yìn náà, a ka ìbéèrè tí ó kàn, ọ̀rọ̀ àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó dáhùn rẹ̀ tẹ̀ lé e, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Akẹ́kọ̀ọ́ lè tẹ́tí sí ohùn tí a gbà sílẹ̀ náà bí ó ti ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀. A tún lè lo kásẹ́ẹ̀tì náà nígbà tí a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́.
Àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà hára gàgà láti lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wọn. Fún àpẹẹrẹ, kìkì ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ìwé pẹlẹbẹ náà, àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì (àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún) láti United States fún tọkọtaya ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ti máa ń kàn sí tẹ́lẹ̀. Nígbà tí tọkọtaya náà wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ inú ìwé náà, ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Àṣà Tí Ọlọrun Kórìíra” gba àfiyèsí wọn. Ọ̀dọ́bìnrin náà wí pé: “Ìgbà gbogbo ni mo ti máa ń ronú pé Ọlọ́run kò lè kórìíra láé—ìfẹ́ nìkan ni ó lè ní. Èyí ni mo máa kọ́kọ́ kà.” Nígbà tí àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì náà pa dà ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, ọ̀dọ́bìnrin náà wí pé: “Mo ń ka ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà. Ó ṣòro gan-an láti ṣe gbogbo ohun tí ó yẹ kí a ṣe. Inú Jèhófà kò dùn sí wa—a kò tí ì ṣe ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n a ti ṣe ìpinnu. A ti ṣètò láti ṣègbéyàwó ní Friday tí ń bọ̀.” Bí wọ́n ti gbá àwọn tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà náà mọ́ra, wọ́n fi kún un pé: “A tọrọ àforíjì fún ṣíṣàìṣèkẹ́kọ̀ọ́ tí a máa ń ṣe, ṣùgbọ́n ìtura ńlá ni èyí jẹ́ fún wa.”
Ní gbogbo ọ̀nà, lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Béèrè. Irin iṣẹ́ àtàtà ni ó jẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Báwo ni ìwọ yóò ṣe lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà?