Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
Ìwé Tuntun Tá A Lè Máa Fi Ṣe Ìpadàbẹ̀wò àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
1. Ìwé tuntun wo la mú jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!” tá a lè máa fi ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Nígbà tá a ṣe àpéjọ àgbègbè “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!” inú wa dùn láti gba ìwé tuntun kan tá a lè máa fi ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Orúkọ ìwé náà ni Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Òun la fi rọ́pò ìwé Béèrè. Àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé tuntun yìí ṣe ṣókí-ṣókí. Èyí á mú kó rọrùn gan-an láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìdúró. Àmọ́ ìwé tuntun yìí yàtọ̀ sí ìwé Béèrè. Ìwé Béèrè sọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì kí Kristẹni mọ̀, ó sì lè ṣòro fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti fara mọ́ ọn. Àmọ́ ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì ni ìwé tuntun yìí dá lé.—Ìṣe 15:35.
2. Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé Ìròyìn Ayọ̀?
2 Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé Ìròyìn Ayọ̀? Àwọn ará wa káàkiri ayé ti ń béèrè fún ìwé kan tó máa rọrùn táwọn èèyàn sì máa nífẹ̀ẹ́ sí. Kí wọ́n lè máa fi ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ fún àwọn èèyàn, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, tó jẹ́ olórí ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn tí kì í fẹ́ kàwé tó pọ̀ máa ń fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a bá fi ìwé pẹlẹbẹ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún rọrùn láti túmọ̀ ìwé pẹlẹbẹ sí èdè tó pọ̀.
3. Kí ni ìwé pẹlẹbẹ yìí fi yàtọ̀ sí àwọn ìwé míì tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Bá A Ṣe Ṣe Ìwé Náà: Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ la ṣe lọ́nà tí àwọn tó ń kà á fi lè lóye rẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. Àmọ́, ìwé tuntun yìí yàtọ̀. A ṣe é lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwa la máa fi kọ́ onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé náà, ohun tó máa dáa jù ni pé ká jọ jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú rẹ̀. Àwọn ìpínrọ̀ rẹ̀ kò gùn rárá, torí náà, a lè jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn lẹ́nu ọ̀nà tàbí lẹ́nu iṣẹ́ ajé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára láti bẹ̀rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ kìíní, a lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àkòrí èyíkéyìí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà.
4. Báwo la ṣe lè fi ìwé náà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì ní tààràtà?
4 Inú àwọn ìpínrọ̀ la ti sábà máa ń rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Àmọ́, inú Bíbélì ni ìdáhùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé tuntun yìí wà. Inú Bíbélì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ dípò látinú àwọn ìwé wa. Torí náà, a kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe àyọkà àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìwé yìí. Inú Bíbélì la retí pé kẹ́ ẹ ti máa kà á jáde. Èyí máa jẹ́ kí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rí i pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ ti wá.—Aísá. 54:13.
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a fẹ́ lọ ṣe sílẹ̀ dáadáa?
5 Gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà kọ́ la ṣàlàyé síbẹ̀. Ìdí ni pé a ṣe ìwé náà lọ́nà tí yóò fi mú kí ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè máa béèrè ìbéèrè. Kí ẹni tó ń kọ́ ọ sì lè lo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a fẹ́ lọ ṣe sílẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra o, ká má ṣe sọ̀rọ̀ jù! Òótọ́ ni pé ó máa ń wù wá láti ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Àmọ́ àṣeyọrí ńlá la máa ṣe tá a bá jẹ́ kí ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe yé e sí. Tá a bá fọgbọ́n bi í ní ìbéèrè, a lè ràn án lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ kó lè lóye ẹsẹ Bíbélì tá a bá kà.—Ìṣe 17:2.
6. Báwo la ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ yìí (a) tá a bá fẹ́ wàásù fáwọn tó ń ṣiyè méjì nípa Ọlọ́run àti Bíbélì? (b) tá a bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé? (d) láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tààràtà? (e) nígbà ìpadàbẹ̀wò?
6 Ìgbàkugbà la lè fún àwọn èèyàn ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀ bá a ṣe máa ń fún wọn láwọn ìtẹ̀jáde míì tá a fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà tí kì í bá ṣe ìwé náà là ń lò lóṣù yẹn. Ọ̀pọ̀ akéde máa fẹ́ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tààràtà lẹ́nu ọ̀nà àwọn èèyàn. Bá a sì ṣe sọ ní àpéjọ àgbègbè, tó o bá lo ìwé náà nígbà ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ó “máa jẹ́ kó o dìídì gbádùn ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò dọ́ba!”—Wo àwọn àpótí tó wà lójú ìwé 5 sí 7.
7. Báwo lo ṣe lè fi ìwé náà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
7 Bó O Ṣe Lè Fi Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: O lè kọ́kọ́ ka ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí, tá a sì fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ náà àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fi lẹ́tà wínníwínní kọ. Fi ọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí onílé lè lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ kà sọ. Kẹ́ ẹ tó jíròrò ìbéèrè tó kàn, sọ pé kí onílé dáhùn ìbéèrè tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ, kó o lè mọ̀ bóyá ó ti lóye ohun tẹ́ ẹ kọ́. Ìbéèrè kan péré ló máa dáa kẹ́ ẹ kọ́kọ́ máa jíròrò lára àwọn ìbéèrè tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ. Tó bá wá yá, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í parí àkòrí kan nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
8. Báwo ló ṣe yẹ ká sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fẹ́ kà? Kí sì nìdí?
8 Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ “ka” sí ló dáhùn àwọn ìbéèrè tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ ní tààràtà. Tá a bá fẹ́ sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fẹ́ kà, kò ní dáa ká máa lo ọ̀rọ̀ bí, “Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé” tàbí “Gbọ́ asọtẹ́lẹ̀ tí Jeremáyà sọ.” Ó lè mú kí onílé rò pé ọ̀rọ̀ èèyàn lásán la kàn fẹ́ kà. Ó máa dáa ká sọ ọ̀rọ̀ bí, “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé” tàbí “Gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ.”
9. Ṣé gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú ìwé náà la gbọ́dọ̀ kà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́?
9 Ṣé gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí la gbọ́dọ̀ kà àbí àwọn tá a kọ́ “ka” sí nìkan? Bí ipò nǹkan bá ṣe rí ló máa pinnu. Ó nídìí pàtàkì tá a fi kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì náà síbẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ìsọfúnni tẹ́ ẹ lè jíròrò. Àmọ́, tá a bá rí i pé akẹ́kọ̀ọ́ ò ní àyè tó pọ̀ tó, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i tàbí tí kò lè kàwé dáadáa, a lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ “ka” sí nìkan.
10. Ìgbà wo la lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?
10 Ìgbà Tá A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni: Lẹ́yìn ìgbà mélòó kan tá a bá ti bá ẹnì kan jíròrò, tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sì ti fìdí múlẹ̀ dáadáa, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí ká ṣì máa tẹ̀ síwájú nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ títí tá a máa fi kà á tán. Àwọn akéde lè fòye mọ ìgbà tó máa dáa láti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé míì. Tá a bá yí ìwé tí à ń lò pa dà, ṣé ó pọn dandan ká mú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni látìbẹ̀rẹ̀? Kò pọn dandan. Àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yàtọ̀ síra. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa jàǹfààní gan-an tí a bá tún kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká lo ìwé pẹlẹbẹ yìí bó ṣe yẹ?
11 Nínú ayé tí ìròyìn ayọ̀ ti ṣọ̀wọ́n yìí, àǹfààní ńlá gbáà la ní láti máa polongo ìròyìn ayọ̀ tó dáa jù lọ! Ìyẹn ni pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso, ó sì máa tó sọ ayé yìí di tuntun níbi tí òdodo yóò máa gbé. (Mát. 24:14; 2 Pét. 3:13) Ó dá wa lójú pé ọ̀pọ̀ àwọn tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa máa gbà pé: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o, ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, ẹni tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́, ẹni tí ń sọ fún Síónì pé: ‘Ọlọ́run rẹ ti di ọba!’” (Aísá. 52:7) Ẹ jẹ́ ká máa fi ìwé tuntun yìí sọ ìròyìn ayọ̀ fún àwọn tí òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Táwọn Èèyàn Bá Ń Ṣiyè Méjì Nípa Ọlọ́run àti Bíbélì:
● Láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan, àwọn akéde ti rí i pé àwọn èèyàn kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa “Ọlọ́run” tàbí “Bíbélì.” Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ àwọn èèyàn lógún lágbègbè yẹn ló yẹ kí ọ̀rọ̀ tí a máa kọ́kọ́ bá wọn sọ dá lé. A lè sọ̀rọ̀ nípa ìdí táwọn èèyàn fi nílò ìjọba tó dáa, báwọn ìdílé ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ tó máa wúlò fún wọn àti ohun tá a lè máa retí lọ́jọ́ iwájú. A lè fún wọn ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lẹ́yìn tá a ti bá wọn sọ̀rọ̀ ní ẹ̀ẹ̀melòó kan, tá a sì ti jọ jíròrò nípa ohun tó mú ká gbà pé Ọlọ́run wà àti pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Tá A Bá Ń Wàásù Láti Ilé-Dé-Ilé:
● “Ìdí tá a fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ ni pé, a fẹ́ sọ fún ẹ nípa bó ṣe rọrùn gan-an láti mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé yìí sọ ibi tí ìdáhùn ìbéèrè yẹn wà nínú Bíbélì. [Fún onílé ní ìwé náà, kó o sì ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ kìíní àti Jeremáyà 29:11.] Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kà á nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo fẹ́ fún ẹ ní ìwé yìí. Tí mo bá pa dà wá, a máa jọ ka ìpínrọ̀ kejì ká lè jọ mọ ìdáhùn látinú Bíbélì sí ìbéèrè yìí, ‘Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn?’” Tó o bá kíyè sí pé onítọ̀hún ráyè dáadáa nígbà tó o kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀, ẹ lè jíròrò ìpínrọ̀ kejì àti ẹsẹ Bíbélì mẹ́ta tó wà níbẹ̀. Ṣètò bó o ṣe máa pa dà lọ jíròrò ìbéèrè kejì nínú ẹ̀kọ́ kìíní yẹn.
● “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ gbàdúrà, pàápàá nígbà tí wọ́n bá níṣòro. Ṣé ìwọ náà máa ń gbàdúrà? [Jẹ́ kó fèsì.] Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́, àbí kì í gbọ́ àwọn àdúrà kan? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo ní ìwé kan tó máa jẹ́ kó o mọ bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. [Fún onílé ní ìwé náà, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ 12 àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ “ka” sí.] Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run máa ń fẹ́ láti gbọ́ àdúrà wa. Àmọ́ ó yẹ ká mọ Ọlọ́run dáadáa ká tó lè jàǹfààní tó wà nínú àdúrà gbígbà. [Ṣí ìwé náà sí ẹ̀kọ́ kejì, kó o sì fi àwọn ìsọ̀rí tó wà níbẹ̀ hàn án.] Mo fẹ́ fún ẹ ní ìwé yìí, tí mo bá sì pa dà wá nígbà míì, a máa wá dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn látinú Bíbélì.”
● “Ibi tọ́rọ̀ ayé yìí ń lọ ti tojú sú àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o rò pé nǹkan ṣì lè dáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu pé ìròyìn ayọ̀ tó lè fún wa ní ìrètí wà nínú Bíbélì. Wo díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí Bíbélì dáhùn lójú ìwé yìí.” Fún onílé ní ìwé náà, kó o sì ní kó yan èyí tó bá wù ú nínú àwọn ìbéèrè tó wà ní ẹ̀yìn ìwé náà. Ṣí ìwé náà sí àkòrí tí onílé bá mú, kó o sì fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Ṣètò bó o ṣe máa pa dà lọ jíròrò ìbéèrè tó kàn lábẹ́ àkòrí yẹn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọ̀ Wọ́n Ní Tààràtà:
● “Mo fẹ́ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn ọ́. Àkòrí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] wà nínú ìwé yìí tó sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn nínú Bíbélì sí àwọn ìbéèrè pàtàkì kan. [Fi iwájú àti ẹ̀yìn ìwé náà han onílé.] Ǹjẹ́ o máa ń fẹ́ lóye ohun tí Bíbélì sọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé yìí kò le rárá, jẹ́ kí n fi bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ hàn ọ́. [Ẹ jọ jíròrò ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ lábẹ́ ìbéèrè kẹta ní ẹ̀kọ́ kẹta, kẹ́ ẹ sì ka Ìṣípayá 21:4, 5. Tí àyè bá sì wà, ẹ jíròrò ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ “ka” sí.] Mo fẹ́ fún ẹ ní ìwé yìí. O ò ṣe jẹ́ ká tún jọ fi ìwé yìí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà míì? Tó o bá nífẹ̀ẹ́ sí i, a lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ. Tí mo bá pa dà wá nígbà míì, a lè jọ jíròrò ẹ̀kọ́ kìíní. Ojú ìwé kan péré ni, kò gùn rárá.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Fi Lọ̀ Wọ́n Nígbà Ìpadàbẹ̀wò:
● Tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, a lè sọ pé: “Inú mi dùn láti tún rí ẹ. Mo bá ẹ mú ìwé kan wá tó máa sọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì fún wa látinú Bíbélì. [Fún onílé ní ìwé náà, kó o sì ní kó wo ẹ̀yìn rẹ̀.] Èwo nínú àwọn àkòrí yìí ló wù ọ́ jù? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà kó o ṣí ìwé náà sí àkòrí tó bá yàn.] Jẹ́ ká jọ wo bí ìwé yìí ṣe fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè tó o mú yẹn.” Fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han onílé. Kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì, àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ “ka” sí. Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn! Fún onílé ní ìwé náà, kó o sì sọ ìgbà tó o máa pa dà wá fún un. Tẹ́ ẹ bá ti jíròrò àkòrí náà tán, ẹ lè jíròrò àkòrí míì tí onílé bá yàn tàbí kẹ́ ẹ lọ bẹ̀rẹ̀ ní àkòrí àkọ́kọ́.