Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 1
Orin 38 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 7 ìpínrọ̀ 7 sí 13 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Lúùkù 7-9 (10 min.)
No. 1: Lúùkù 7:18-35 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Orílẹ̀-Èdè Tuntun Wo Ni Jèhófà Yàn ní Pẹ́ńtíkọ́sì, Kí sì Nìdí?—Gál. 6:16; 1 Pét. 2:9 (5 min.)
No. 3: Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Kọ Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀ Pátápátá?—td 13D (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù April. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ April, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! March–April 2013. Bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Ǹjẹ́ O Ti Gbìyànjú Ẹ̀ Wò? Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn àbá tó jáde nínú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Fi Ìgboyà Wàásù Níbi Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé” (km 3/12), “Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run” (km 7/12) àti “Ǹjẹ́ O Lè Kópa Nínú Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́?” (km 10/12). Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà sílò àti àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí.
Orin 75 àti Àdúrà