Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. Kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. May àti June: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ẹ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Kí ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé.
◼ Ọjọ́ Tuesday, March 26, 2013 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Tó bá jẹ́ ọjọ́ Tuesday ni ìjọ yín máa ń ṣèpàdé, kí ẹ ṣe é ní ọjọ́ míì tí àyè máa wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yín lọ́sẹ̀ yẹn. Tó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé ẹ fagi lé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fi àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó bá kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì lóṣù yẹn. Kí àwọn ìjọ tó bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká lọ́sẹ̀ yẹn fi ìpàdé ọjọ́ Tuesday sí ojọ́ míì lọ́sẹ̀ náà.