ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/13 ojú ìwé 8
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 3/13 ojú ìwé 8

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù April

“À ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n máa ka Bíbélì. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń rò pé ohun tó wà nínú Bíbélì kò lè yé àwọn. Ṣé ohun tí ìwọ náà rò nìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí ìwé yìí sọ.” Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ April 1 han onílé, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.

Ilé Ìṣọ́ April 1

“Kò sẹ́ni tí kò níṣòro láyé tá a wà yìí. Èyí ti mú kí nǹkan tojú sú àwọn kan tí wọ́n sì wá ń rò ó pé ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá kò ní ìtumọ̀ kankan. Kí lo rò pé kì í jẹ́ káwọn èèyàn láyọ̀ tó bí wọ́n ṣe ń fẹ́ láyé tá a wà yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ìṣòro wa láìpẹ́. [Ka Ìṣípayá 21:4.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run tó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú àti bá a ṣe lè ní ayọ̀ láyé tá a wà yìí.”

Jí! March–April

“Tọkọtaya máa láyọ̀ gan-an táwọn méjèèjì bá mọwọ́ ara wọn. Àmọ́ tí ìṣòro bá wà láàárín wọn, ó lè mú kí wọ́n máa bára wọn jiyàn. Ǹjẹ́ o rò pé ìmọ̀ràn inú Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́? [Ka Òwe 29:11. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Kì í rọrùn fún tọkọtaya tó ń bára wọn jiyàn láti gbé pọ̀ ní àlàáfíà. Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 4 nínú ìwé yìí ṣàlàyé ohun tí àwọn tọkọtaya lè ṣe láti yanjú ìṣòro wọn, tí wọn ò sì ní máa bára wọn jiyàn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́