Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Lóṣù August ọdún 2012, iye aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó ròyìn jẹ́ 34,383. A ò tíì ní iye aṣáájú-ọ̀nà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí lórílẹ̀-èdè yìí. Èyí fi 1,144 ju iye aṣáájú-ọ̀nà tó ròyìn lọ́dún 2011 lọ. Inú wa tún dùn pé iye ìwé tá a fi sóde àti iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tún pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa fi 62,441 ju ti oṣù August, ọdún 2011 lọ. A dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń bù kún ìsapá wa! Ẹ jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ rere wa nìṣò. Ká jẹ́ kí ọwọ́ wa túbọ̀ máa “dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà.”—Ìṣe 18:5.