Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Ìwé Tuntun Tá A Ṣe Láti Máa Fi Darí Àwọn Èèyàn Sínú Ètò Ọlọ́run
1. Sọ ìdí mẹ́ta tá a fi ṣe ìwé tuntun yìí.
1 Ǹjẹ́ o ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? Ìdí tá a fi ṣe ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí ni pé (1) kí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè mọ irú èèyàn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, (2) kí wọ́n lè mọ̀ nípa iṣẹ́ wa, kí wọ́n sì lè (3) mọ bí ètò Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́. Àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé tuntun yìí kò ju ojú ìwé kọ̀ọ̀kan lọ torí kó lè rọrùn láti máa jíròrò rẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́.
2. Sọ àwọn ohun tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà.
2 Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Náà: Apá mẹ́ta ni ìwé náà pín sí. Apá kọ̀ọ̀kan ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ìwé náà dá lé. Ẹ̀kọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ló wà nínú ìwé náà, ìbéèrè sì ni àkòrí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀kọ́ náà. Àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ lábẹ́ àkòrí kọ̀ọ̀kan ló dáhùn àwọn ìbéèrè náà. Oríṣiríṣi àwòrán tá a yà ní ohun tó lé ní àádọ́ta [50] orílẹ̀-èdè tún wà nínú ìwé náà. Èyí á jẹ́ káwọn èèyàn lè mọ bí iṣẹ́ wa ṣe gbilẹ̀ kárí ayé tó. Àpótí kan wà nínú àwọn kan lára àwọn ẹ̀kọ́ náà tá a pè ní “Ṣe Ìwádìí Sí I.” Àwọn ohun tá a lè dábàá pé kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ló wà níbẹ̀.
3. Báwo la ṣe lè lo ìwé tuntun yìí?
3 Bá A Ṣe Lè Lò Ó: Kọ́kọ́ fi ìbéèrè tá a fi ṣe àkòrí ẹ̀kọ́ náà han ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bí ẹ ṣe ń ka ohun tó wà níbẹ̀, tẹnu mọ́ àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ. Tẹ́ ẹ bá sì ka ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan tán, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ ojú ìwé náà. Ẹ lè kọ́kọ́ ka gbogbo ìpínrọ̀ náà látòkèdélẹ̀ kẹ́ ẹ tó jíròrò rẹ̀ tàbí kẹ́ ẹ kà á ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Ẹ fúnra yín pinnu èyí tẹ́ ẹ máa kà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ síbẹ̀. Ẹ má ṣe gbàgbé láti jíròrò àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀ àti àpótí tá a pè ní “Ṣe Ìwádìí Sí I.” Ó dáa kẹ́ ẹ máa ka àwọn ẹ̀kọ́ náà ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé. Àmọ́ ẹ lè yàn láti jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà nífẹ̀ẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ẹ kò ní pẹ́ lọ sí àpéjọ, ẹ lè fo ẹ̀kọ́ kọkànlá.
4. Kí nìdí tí inú rẹ fi dùn pé a gbé ìwé tuntun yìí jáde?
4 Tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe là ń jẹ́ kó mọ Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run. Àmọ́, ó tún yẹ ká jẹ́ kó mọ ètò Ọlọ́run. (Òwe 6:20) Inú wa dùn gan-an pé a ní ìwé tuntun yìí tó jẹ́ kó rọrùn fún wa láti fi àwọn èèyàn mọ ètò Ọlọ́run!