MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
A ṣe ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? ká lè jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú akẹ́kọ́ọ̀ ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ̀ọ̀kan.a Ẹ̀kọ́ 1 sí 4 máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ irú èèyàn tá a jẹ́, ẹ̀kọ́ 5 sí 14 máa jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan tí à ń ṣe, ẹ̀kọ́ 15 sí 28 sì máa ṣàlàyé ohun tí ètò wa ń gbéṣe fún wọn. Ó máa dáa ká jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ yìí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àyàfi tó bá gba pé ká jíròrò apá kan ní kíá. Ojú ìwé kan ni ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan wà, a sì lè lo ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá láti jíròrò ẹ̀kọ́ kan.
Pe àfíyèsí akẹ́kọ́ọ̀ sí ìbéèrè àkọ́kọ́ tó jẹ́ àkórí ẹ̀kọ́ náà
Ẹ jọ ka ẹ̀kọ́ náà papọ̀, ẹ lè kà á látòkè-délẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, ẹ sì lè ṣàlàyé ìpínrọ̀ kan kí ẹ tó ka ìpínrọ̀ tó tẹ̀lé e
Ẹ jọ jíròrò ohun tí ẹ kà. Béèrè àwọn ìbẹ́èrè tó wà nísàlẹ̀ ìwé, kí ẹ sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀. Àwa la máa pinnu èyí tá a máa kà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí, tá a sì máa ṣàlàyé. Sọ bí àwọn ìsọ̀rí tí wọ́n kọ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀ ṣe dáhùn ìbéèrè tó jẹ́ àkórí ẹ̀kọ́ náà
Tí àpótí “Ṣe Ìwádìí Sí I” bá wà nínú ẹ̀kọ́ náà, ẹ jọ́ kà á, kó o sì gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó tẹ̀lé àbá tó wà níbẹ̀
a A ti ṣe àwọn àtúnṣe díẹ̀ sí ẹ̀dà ìwé yìí tó wà lórí ìkànnì.