ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/13 ojú ìwé 2
  • Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Irin Iṣẹ́ Tuntun Láti Ran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Mọ Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Ń béèrè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 9/13 ojú ìwé 2

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

1. Ìgbà wo la máa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? báwo ló sì ṣe máa ṣe wá láǹfààní?

1 Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ October 28 ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? la máa bẹ̀rẹ̀ sí í lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Àpéjọ Àgbègbè “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!” la ti mú ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí jáde, a sì ṣe é ká lè máa lò ó láti darí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú ètò Ọlọ́run. Nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé yìí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ètò Jèhófà tá a wà nínú rẹ̀, a ó sì mọ bá a ṣe lè lo ìwé tó gbéṣẹ́ yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa.—Sm. 48:13.

2. Báwo la ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ yìí nínú ìjọ?

2 Bí A Ṣe Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Rẹ̀: Ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbọ́dọ̀ ṣètò àkókò rẹ̀ dáadáa kó má bàa lo àkókò tó pọ̀ jù lórí ẹ̀kọ́ kan débi tó fi máa pa ẹ̀kọ́ míì lára. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀kọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n [28] tí ìwé náà ní, olùdarí á kọ́kọ́ ka ìbéèrè tá a fi ṣe àkòrí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Á wá sọ pé kí òǹkàwé ka ìpínrọ̀ tá a fi nasẹ̀ ẹ̀kọ́ yẹn. Lẹ́yìn èyí, olùdarí máa bi àwọn ará ní ìbéèrè tí òun fúnra rẹ̀ ṣètò fún ìpínrọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, ẹ ka àwọn ìpínrọ̀ tó wà lábẹ́ àwọn ìsọ̀rí tí a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ, kí ẹ sì jíròrò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Tẹ́ ẹ bá ti ka àwọn ìpínrọ̀ tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan tán, olùdarí máa ní káwọn ará sọ bí ìsọ̀rí náà ṣe dáhùn ìbéèrè tá a fi ṣe àkòrí ẹ̀kọ́ náà. Ìwé náà tún ní ọ̀pọ̀ àwòrán tẹ́ ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bí àkókò bá ṣe wà sí, ẹ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹnu mọ́ ohun tá à ń jíròrò. Kí olùdarí tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé e, ó máa fi àwọn ìbéèrè tó wà ní ìsàlẹ̀ ojú ìwé kọ̀ọ̀kan ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí. Tí àpótí tá a pè ní “Ṣe Ìwádìí Sí I” bá wà ní ẹ̀kọ́ kan, ó máa ní kí òǹkàwé kà á, lẹ́yìn náà, á wá ní kí àwọn ará sọ bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣe lè jàǹfààní tó bá tẹ̀ lé àbá tó wà níbẹ̀. Bí àkókò bá ṣe wà sí ní ìparí, olùdarí lè fi àkòrí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti gbé yẹ̀ wò ṣe ìbéèrè fún àtúnyẹ̀wò. Ẹ fi sọ́kàn pé kò pọn dandan pé kẹ́ ẹ tẹ̀ lé ìlànà yìí nígbà tẹ́ ẹ bá ń fi ìwé náà kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

3. Báwo la ṣe lè jàǹfààní kíkún látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ náà?

3 Tó o bá fẹ́ jàǹfààní ní kíkún, o gbọ́dọ̀ múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa. Rí i pé ìwọ náà dáhùn. Bí ìjíròrò náà bá ṣe ń lọ lọ́wọ́, máa ronú nípa ìdí tí ohun tí ẹ̀ ń jíròrò náà fi máa ṣe àwọn tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láǹfààní. Àdúrà wa ni pé kí ìwé pẹlẹbẹ tuntun tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ yìí mú ká lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ wa láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, káwọn náà lè ní ìrètí láti wà láàyè títí láé.—1 Jòh. 2:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́