Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 16
Orin 21 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 14 ìpínrọ̀ 8 sí 13 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kọ́ríńtì 1-7 (10 min.)
No. 1: 2 Kọ́ríńtì 1:15–2:11 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára Rú Òfin Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀—td 11A (5 min.)
No. 3: Kí La Lè Ṣe Láti Sá Di Orúkọ Jèhófà?—Sef. 3:12 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe?—Apá Kejì. Àsọyé tá a gbé ka ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe?, ìpínrọ̀ 10 sí ìparí ìwé náà. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún nígbà tó wà ní ọ̀dọ́. Kí ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn ìbùkún wo ló sì ti rí?
10 min: Nígbà Tó O Bá Ń Dá Wàásù. Ìjíròrò. (1) Kí la lè ṣe ká lè máa láyọ̀ nígbà tá a bá ń dá wàásù? (2) Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún tá a bá máa dá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò? (3) Tí kò bá sẹ́ni tó máa ń jáde láwọn ọjọ́ tá a máa ń jáde òde ẹ̀rí, báwo la ṣe lè fáwọn míì nínú ìjọ níṣìírí ká lè jọ máa jáde? (4) Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn dìídì máa dá wàásù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbàkigbà àti níbikíbi tá a bá ti rí i pé kò léwu láti ṣe bẹ́ẹ̀?
10 min: “Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, sọ àwọn ohun tó wà nínú ìwé náà, títí kan àwọn àwòrán tó wà nínú rẹ̀.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2013, ojú ìwé 3.
Orin 107 àti Àdúrà