Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Ámósì
1. Kí nìdí tí àpẹẹrẹ Ámósì fi lè fún wa níṣìírí?
1 Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé o kò kúnjú ìwọ̀n láti wàásù torí pé o kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé, o kì í sì í ṣẹni pàtàkì láwùjọ? Bó bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, àpẹẹrẹ Ámósì lè jẹ́ kó o ní ìgboyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn ni Ámósì, tó sì máa ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ láwọn àkókò kan lọ́dún, síbẹ̀ Jèhófà lò ó láti kéde iṣẹ́ pàtàkì kan. (Ámósì 1:1; 7:14, 15) Bákan náà, lóde òní Jèhófà máa ń lo àwọn ẹni rírẹlẹ̀. (1 Kọ́r. 1:27-29) Àwọn ẹ̀kọ́ míì wo la tún lè kọ́ lára wòlíì Ámósì tó máa ṣe wá láǹfààní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù tí wọ́n bá ta kò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
2 Má Ṣe Bẹ̀rù Tí Wọ́n Bá Ta Kò Ọ́: Àlùfáà kan wà tó ń jẹ́ Amasááyà, ère ọmọ màlúù ló máa ń jọ́sìn, ara ẹ̀ya mẹ́wàá Ísírẹ́lì ti àríwá ló sì ti wá. Nígbà tí àlùfáà yìí gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì, inú bí i. Ṣe ló dà bíi pé ó ń sọ fún Ámósì pé: ‘Máa lọ sílé ẹ! Fi wá sílẹ̀! A ní ẹ̀sìn tiwa!’ (Ámósì 7:12, 13) Amasááyà tún wá purọ́ mọ́ wòlíì Ámósì nígbà tó ń rọ Jèróbóámù Ọba láti ka iṣẹ́ wòlíì náà léèwọ̀. (Ámósì 7:7-11) Síbẹ̀, Ámósì kò bẹ̀rù. Lónìí, àwọn olórí ẹ̀sìn kan máa ń lo àwọn aláṣẹ láti ṣe inúnibíni sí àwọn èèyàn Jèhófà. Àmọ́, Jèhófà ti fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé kò sí ìpalára táwọn ọ̀tá lè ṣe fún wa tó kọjá àtúnṣe.—Aísá. 54:17.
3. Ìhìn alápá méjì wo là ń kéde lónìí?
3 Kéde Ìdájọ́ Ọlọ́run àti Àwọn Ìbùkún Ọjọ́ Iwájú: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ámósì kéde ìdájọ́ Ọlọ́run sórí àwọn ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, ohun tó fi kádìí ìwé Bíbélì tí wọ́n forúkọ rẹ̀ pè ni Ìlérí tí Jèhófà ṣe pé Òun máa dá àwọn èèyàn náà pa dà sí ilẹ̀ wọn, òun sì máa bù kún wọn jìgbìnnì. (Ámósì 9:13-15) Àwa náà ń sọ fáwọn èèyàn pé “ọjọ́ ìdájọ́” Ọlọ́run ń bọ̀, àmọ́ apá kan “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run tá a gbọ́dọ̀ kéde nìyẹn jẹ́. (2 Pét. 3:7; Mát. 24:14) Lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa àwọn ẹni burúkú run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ayé máa di Párádísè.—Sm. 37:34.
4. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé a lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́?
4 Bá a ṣe ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ta kò wá. Àmọ́, tí a kò bá juwọ́ sílẹ̀, èyí ló máa fi hàn pé a ṣì dúró lórí ìpinnu wa pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà àti pé ìfẹ́ rẹ̀ lá ó máa ṣe títí ayé. (Jòh. 15:19) Bó ti wù kí ó rí, ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa tì wá lẹ́yìn ká lè máa ṣe ohun tó fẹ́, bí ó ti ṣe fún Ámósì.—2 Kọ́r. 3:5.