Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 9
Orin 62 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 14 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kọ́ríńtì 10-16 (10 min.)
No. 1: 1 Kọ́ríńtì 14:7-25 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Ẹlẹ́ṣẹ̀ Ṣe Lè ‘Tu Jèhófà Lójú’?—2 Kíró. 33:12, 13; Aísá. 55:6, 7 (5 min.)
No. 3: Gbogbo Èèyàn Ni Bíbélì Wà Fún—td 8D (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe?—Apá Kìíní. Àsọyé tá a gbé ka ìpínrọ̀ 1 sí 9 nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? Gbóríyìn fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sapá láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́.
10 min: Àwọn Ìrírí Tá A Ní Nígbà Tá A Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀. Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó lárinrin tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n lo ìwé Ìròyìn Ayọ̀ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣe àṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè lo ìwé náà nígbà tá a bá ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó ti gba ìwé náà lọ́wọ́ wa tẹ́lẹ̀.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2013, ojú ìwé 7.
10 min: “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Ámósì.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 96 àti Àdúrà