ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 11/15 ojú ìwé 20-25
  • Ẹ Wá Jèhófà, Olùṣàyẹ̀wò Ọkàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Wá Jèhófà, Olùṣàyẹ̀wò Ọkàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Yẹ Ísírẹ́lì Wò
  • Ísírẹ́lì—Orílẹ̀-Èdè Tó Bàjẹ́ Bàlùmọ̀
  • Àwọn Ayẹyẹ Ti Òde Òní
  • “Nífẹ̀ẹ́ Ohun Rere”
  • Jèhófà Ní Kí Wọ́n Jíhìn
  • Aásìkí Ńbẹ Bí Ìyàn Tilẹ̀ Ń Mú Nípa Tẹ̀mí
  • Fi Ìgboyà Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Ámósì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ìdájọ́ Jèhófà Yóò Dé Sórí Àwọn Ẹni Ibi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóẹ́lì àti Ìwé Ámósì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 11/15 ojú ìwé 20-25

Ẹ Wá Jèhófà, Olùṣàyẹ̀wò Ọkàn

“Wá mi, kí o sì máa wà láàyè nìṣó.”—ÁMÓSÌ 5:4.

1, 2. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Jèhófà “ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́”?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN sọ fún wòlíì Sámúẹ́lì pé: “Ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Báwo ni Jèhófà ṣe “ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́”?

2 Ìwé Mímọ́ sábà máa ń lo ọkàn-àyà láti fi ṣàpẹẹrẹ ohun tí ẹnì kan jẹ́ ní ti gidi, ìyẹn àwọn ohun tó ń wù ú, àwọn ohun tó ń rò, bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára rẹ̀, àtàwọn ohun tó fẹ́ràn. Nítorí náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ń wo ọkàn, ìyẹn túmọ̀ sí pé ohun tẹ́nì kan jẹ́ ní ti gidi ló máa ń wò, kì í ṣe ìrísí ẹni náà.

Ọlọ́run Yẹ Ísírẹ́lì Wò

3, 4. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ámósì 6:4-6 wí, báwo ni ipò nǹkan ṣe rí nínú ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì?

3 Nígbà tí Olùṣàyẹ̀wò ọkàn kíyè sí ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì ní ọjọ́ Ámósì, kí ló rí? Ámósì 6:4-6 sọ nípa àwọn ọkùnrin tó ‘ń dùbúlẹ̀ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú tí a fi eyín erin ṣe, tí wọ́n ń nà gbalaja sórí àga ìnàyìn wọn.’ Wọ́n “ń jẹ àwọn àgbò láti inú agbo ẹran àti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù láti inú àwọn àbọ́sanra ọmọ màlúù.” Irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ti “hùmọ̀ ohun èlò orin fún ara wọn” wọ́n sì “ń mu láti inú àwokòtò wáìnì.”

4 Téèyàn bá kọ́kọ́ wò ó, ó lè dà bí ẹni pé wọ́n ń gbádùn. Ńṣe ni fàájì ń ṣàn, àwọn ọlọ́rọ̀ ń gbádùn oúnjẹ àtohun mímu tó dáa jù lọ, wọ́n sì ń fi àwọn ohun èlò orin tó dára jù lọ jayé orí wọn nínú ilé wọn olówó iyebíye. Wọ́n tún ní àwọn “àga ìrọ̀gbọ̀kú tí a fi eyín erin ṣe.” Ní Samáríà, olú ìlú ìjọba Ísírẹ́lì, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eyín erin tí wọ́n fi iṣẹ́ ọnà dárà sí lára. (1 Àwọn Ọba 10:22) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n fi àwọn kan dárà sí ohun ọ̀ṣọ́ ilé lára tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kan àwọn mìíràn mọ́ igi tí wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́ sára ògiri.

5. Kí nìdí tínú Ọlọ́run ò fi dùn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Ámósì?

5 Ṣé báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń gbé nínú ilé tó dáa, tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ aládùn, tí wọ́n ń mu wáìnì tó dáa, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sórin aládùn ni inú Jèhófà Ọlọ́run ò dùn sí? Rárá o! Ṣebí òun náà ló pèsè gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn aráyé. (1 Tímótì 6:17) Ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí ni bí ọkàn àwọn èèyàn náà ṣe rí, ohun àìdáa tí wọ́n ń rò lọ́kàn, ìwà ìgbéraga tí wọ́n ń hù sí Ọlọ́run, àti bí wọn ò ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiwọn.

6. Báwo ni ipò tẹ̀mí Ísírẹ́lì ṣe rí nígbà ayé Ámósì?

6 Àwọn tí ‘wọ́n ń nà gbalaja sórí àga ìnàyìn wọn, tí wọ́n ń jẹ àwọn àgbò láti inú agbo ẹran, tí wọ́n ń mu wáìnì, tí wọ́n sì ń hùmọ̀ ohun èlò orin fún ara wọn’ yìí máa kàgbákò. Wọ́n bi àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn pé: “Ẹ ha ń mú ọjọ́ tí ó kún fún ìyọnu àjálù kúrò lọ́kàn yín?” Ńṣe ló yẹ kí ipò tí Ísírẹ́lì wà bà wọ́n lọ́kàn jẹ́, àmọ́ wọn ò “ṣàìsàn nítorí àjálù ibi Jósẹ́fù.” (Ámósì 6:3-6) Láìfi bí nǹkan ṣe rọ̀ ṣọ̀mù fún orílẹ̀-èdè náà pè, Ọlọ́run rí i pé àjálù tẹ̀mí dé bá Jósẹ́fù, ìyẹn Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ń bá ohun tí wọ́n ǹ ṣe lójoojúmọ́ lọ láìbìkítà nípa nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Ìwà tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn òde òní sì ń hù náà nìyẹn. Wọ́n lè gbà pé lóòótọ́ là ń gbé lákòókò tí nǹkan ò rọgbọ, àmọ́ níwọ̀n bí wọn ò bá ti níṣòro, wọn ò fẹ́ mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn míì, ọ̀ràn tẹ̀mí ò sì jẹ nǹkankan lójú wọn.

Ísírẹ́lì—Orílẹ̀-Èdè Tó Bàjẹ́ Bàlùmọ̀

7. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ táwọn èèyàn Ísírẹ́lì ò bá kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run?

7 Ìwé Ámósì ṣàpèjúwe orílẹ̀-èdè kan tó láásìkí, àmọ́ tó bàjẹ́ tó sì bàlùmọ̀. Bí àwọn èèyàn náà ò bá gba ìkìlọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì tún inú wọn rò, Jèhófà ò ní dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn mọ́. Àwọn ará Ásíríà á dé, wọ́n á lé wọn dìde lórí àwọn àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn tí wọ́n fi eyín erin ṣe, wọ́n á sì fipá kó wọn lọ sígbèkùn. Wọn ò ní lè gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́!

8. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dẹni tó bàjẹ́ bàlùmọ̀ nípa tẹ̀mí?

8 Kí ló gbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dénú ipò burúkú yìí? Gbogbo ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 997 ṣáájú Sànmánì Tiwa, nígbà tí Sólómọ́nì Ọba kú tí Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì jọba, tí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì wá yapa lára ẹ̀yà Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì. Ọba tó kọ́kọ́ jẹ lórí ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì ni Jèróbóámù Kìíní tí í ṣe “ọmọkùnrin Nébátì.” (1 Àwọn Ọba 11:26) Jèróbóámù Kìíní mú káwọn tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀ gbà pé ó ti nira jù láti máa fẹsẹ̀ rìn lọ sí Jerúsálẹ́mù láti sin Jèhófà. Kì í ṣe pé ire àwọn èèyàn náà ló jẹ ẹ́ lógún o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tó máa gbà tẹ́ ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀ lọ́rùn ló ń wá. (1 Àwọn Ọba 12:26) Ẹ̀rù ń ba Jèróbóámù pé bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ tìrítìrí lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àwọn àjọ̀dún ọdọọdún tí wọ́n fi ń bọlá fún Jèhófà, bópẹ́ bóyá ọkàn wọn á padà fà mọ́ ìjọba Júdà. Kí èyí má bàá ṣẹlẹ̀, Jèróbóámù gbé ère ọmọ màlúù oníwúrà méjì kalẹ̀, ọ̀kan ní Dánì èkejì ní Bẹ́tẹ́lì. Bí ìjọsìn ọmọ màlúù ṣe di ìsìn tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń ṣe nìyẹn.—2 Kíróníkà 11:13-15.

9, 10. (a) Àwọn àjọyọ̀ ìsìn wo ni Ọba Jèróbóámù Kìíní ṣètò rẹ̀? (b) Ojú wo ni Ọlọ́run fi wo àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Ísírẹ́lì nígbà ayé Ọba Jèróbóámù Kejì?

9 Jèróbóámù fẹ́ sọ ìsìn tuntun yìí di èyí tó dára lójú gbogbo èèyàn. Ó ṣètò oríṣiríṣi àjọyọ̀ irú èyí tí wọn ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù. A kà á nínú 1 Àwọn Ọba 12:32 pé: “Jèróbóámù sì ń bá a lọ láti ṣe àjọyọ̀ ní oṣù kẹjọ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, gẹ́gẹ́ bí àjọyọ̀ tí ó wà ní Júdà, kí ó lè rú àwọn ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì.”

10 Jèhófà ò tẹ́wọ́ gba irú àwọn àjọyọ̀ ìsìn èké bẹ́ẹ̀. Ó tipasẹ̀ Ámósì fi èyí hàn kedere ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, nígbà ìjọba Jèróbóámù Kejì, tó di ọba ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì ní nǹkan bíi ọdún 844 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (Ámósì 1:1) Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú Ámósì 5:21-24, Ọlọ́run sọ pé: “Mo kórìíra, mo kọ àwọn àjọyọ̀ yín, èmi kì yóò sì gbádùn òórùn àwọn àpéjọ ọ̀wọ̀ yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi odindi àwọn ọrẹ ẹbọ sísun rúbọ sí mi, àní èmi kì yóò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn yín, èmi kì yóò sì wo àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ ti ẹran àbọ́pa yín. Mú yánpọnyánrin àwọn orin rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi; kí n má sì gbọ́ ìró orin atunilára àwọn ohun èlò ìkọrin rẹ olókùn tín-ín-rín. Sì jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo tú jáde gan-an gẹ́gẹ́ bí omi, àti òdodo bí ọ̀gbàrá tí ń ṣàn nígbà gbogbo.”

Àwọn Ayẹyẹ Ti Òde Òní

11, 12. Àwọn ọ̀nà wo ni ìjọsìn Ísírẹ́lì ìgbàanì fi jọ ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

11 Ní kedere, Jèhófà ṣàyẹ̀wò ọkàn àwọn tó ń lọ́wọ́ nínú àwọn àjọyọ̀ Ísírẹ́lì, kò sì tẹ́wọ́ gba ayẹyẹ àti ọrẹ ẹbọ wọn. Bákan náà lónìí, Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba àwọn ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà bíi Kérésìmesì àti Ọdún Àjíǹde tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe. Àwọn olùjọsìn Jèhófà gbà pé kò sí bí òdodo àti ìwà àìlófin ṣe lè jọ ní àjọṣe, bẹ́ẹ̀ ni àjọṣe kankan ò sì lè wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.—2 Kọ́ríńtì 6:14-16.

12 Àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tí ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń sin ọmọ màlúù fi jọra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan tó pera wọn ní Kristẹni gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìfẹ́ Ọlọ́run kọ́ làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ẹ̀sìn wọn. Ká ní pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni, wọn ì bá máà fara mọ́ ohunkóhun tó bá ti yàtọ̀ sí jíjọ́sìn Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” torí pé irú ìjọsìn tínú Ọlọ́run dùn sí nìyẹn. (Jòhánù 4:24) Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò “jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo tú jáde gan-an gẹ́gẹ́ bí omi, àti òdodo bí ọ̀gbàrá tí ń ṣàn nígbà gbogbo.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fọwọ́ rọ́ ìlànà tí Ọlọ́run là kalẹ̀ nípa ìwà tó yẹ ká máa hù tì sápá kan. Wọ́n ń fàyè gba ìwà àgbèrè àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tó burú jáì, débi pé wọ́n ń fọwọ́ sí ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin àtọkùnrin tàbí láàárín obìnrin àtobìnrin!

“Nífẹ̀ẹ́ Ohun Rere”

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ inú ìwé Ámósì 5:15?

13 Jèhófà sọ fún gbogbo àwọn tó fẹ́ jọ́sìn rẹ̀ ní ọ̀nà tó tẹ́wọ́ gbà pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (Ámósì 5:15) Ìfẹ́ àti ìkórìíra jẹ́ ànímọ́ alágbára tó ń fi irú ẹni tá a jẹ́ ní ti gidi hàn. Níwọ̀n bí ọkàn ti máa ń ṣe àdàkàdekè, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti dáàbò bò ó. (Òwe 4:23, Jeremáyà 17:9) Tá a bá gba èròkerò láyè nínú ọkàn wa, ó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ohun búburú ká sì wá kórìíra ohun rere. Tá a bá sì wá ṣe ìfẹ́ inú wa tá a sì dẹ́ṣẹ̀, bí ìtara wa nínú iṣẹ́ ìsìn tiẹ̀ wá ń jó fòfò, ìyẹn ò ní kí Ọlọ́run fojú rere wò wá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè “kórìíra ohun búburú, kí [a] sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.”

14, 15. (a) Àwọn wo ló wà lára àwọn tó ń ṣe rere ní Ísírẹ́lì, àmọ́ ìwà wo ni wọ́n ń hù sáwọn kan lára wọn? (b) Báwo la ṣe lè fún àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún níṣìírí lóde òní?

14 Kì í ṣe gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ló ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Hóséà àti Ámósì ‘nífẹ̀ẹ́ ohun rere’ wọ́n sì fi ìṣòtítọ́ sìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí wòlíì. Àwọn mìíràn jẹ́jẹ̀ẹ́, wọ́n di Násírì. Láàárín gbogbo àkókò tí wọ́n sì fi sìn gẹ́gẹ́ bí Násírì, wọ́n ò kì í mu àwọn ohun tó bá ti ara àjàrà wá, àgàgà wáìnì. (Númérì 6:1-4) Irú ojú wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù fi wo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí irú àwọn olùṣe ohun rere bẹ́ẹ̀ ní? Ìdáhùn tó yani lẹ́nu sí ìbéèrè yẹn jẹ́ ká mọ̀ bí orílẹ̀-èdè náà ṣe bàjẹ́ bàlùmọ̀ nípa tẹ̀mí tó. Ámósì 2:12 sọ pé: “Ẹ̀yin ń bá a nìṣó láti fún àwọn Násírì ní wáìnì mu, ẹ̀yin sì gbé àṣẹ kalẹ̀ fún àwọn wòlíì, pé: ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀.’”

15 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn rí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àwọn Násírì àtàwọn wòlíì, ó yẹ kójú tì wọ́n, kí wọ́n sì yíwà padà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọ́n á gbà kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn adúróṣinṣin wọ̀nyí, kí wọ́n má lè fi ògo fún Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ ká máa rọ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, tàbí àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì pé kí wọ́n fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, kí wọ́n padà wálé láti wá bímọ kí wọ́n sì wá máa ṣiṣẹ́ owó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa bá iṣẹ́ rere wọn nìṣó!

16. Kí nìdí tí ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi dára nígbà ayé Mósè ju ti ìgbà ayé Ámósì lọ?

16 Nígbà ayé Ámósì, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ní ọrọ̀ gan-an, tí wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ, àmọ́ wọn “kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:13-21) Mánà nìkan làwọn baba ńlá wọn rí jẹ nínú aginjù fún odindi ogójì ọdún. Wọn ò rí akọ màlúù tá a bọ́ ní ibùjẹ ẹran fi se àsè tàbí kí wọ́n máa nà gbalaja sórí àga tá a fi eyín erin ṣe. Àmọ́, Mósè sọ bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe jẹ́ fún wọn pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ gbogbo. . . . Fún ogójì ọdún wọ̀nyí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ kò ṣaláìní ohun kan.” (Diutarónómì 2:7) Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà láginjù nílò gan-an ló máa ń tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Èyí tó wà ṣe pàtàkì jù ni pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn, ààbò rẹ̀ wà lórí wọn ó sì bù kún wọn!

17. Kí nìdí tí Jèhófà fi kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìjímìjí wá sí Ilẹ̀ Ìlérí?

17 Jèhófà rán àwọn tó gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Ámósì létí pé Òun lòun mú àwọn baba ńlá wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí, òun sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa gbogbo àwọn ọ̀tá wọn run kúrò lórí ilẹ̀ náà. (Ámósì 2:9, 10) Àmọ́ kí nìdí tí Ọlọ́run fi kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìjímìjí jáde nílẹ̀ Íjíbítì lọ sílẹ̀ ìlérí? Ṣé kí wọ́n lè máa gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ kí wọ́n sì kọ Ẹlẹ́dàá wọn sílẹ̀ ni? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà kó wọn jáde láti sọ wọ́n dòmìnira kí wọ́n lè máa jọ́sìn rẹ̀ kí wọ́n sì di mímọ́ nípa tẹ̀mí. Àmọ́, àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì ò kórìíra ohun búburú bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì fẹ́ràn ohun rere. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ère gbígbẹ́ ni wọ́n ń fògo fún, wọn ò fògo fún Jèhófà Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé ìwà wọn yìí tini lójú gan-an!

Jèhófà Ní Kí Wọ́n Jíhìn

18. Kí nìdí tí Jèhófà fi dá wa nídè nípa tẹ̀mí?

18 Ọlọ́run kò ní gbójú fo ìwà àìnítìjú táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù yìí dá. Ó sọ ohun tóun máa ṣe ní kedere pé: “Èmi yóò . . . béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ yín fún gbogbo ìṣìnà yín.” (Ámósì 3:2) Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ yìí mú ká ronú nípa ìdáǹdè tiwa fúnra wa kúrò nínú òǹdè Íjíbítì òde òní, ìyẹn ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Jèhófà ò dá wa nídè nítorí ká lè máa lépa àwọn ire tara wa. Dípò ìyẹn, Jèhófà dá wa nídè ká lè máa fi ògo fún un látọkànwá gẹ́gẹ́ bí ènìyàn olómìnira tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́. Olúkúlùkù wa ni yóò sì jíhìn nípa bá a ṣe ń lo òmìnira tí Ọlọ́run fún wa.—Róòmù 14:12.

19. Gẹ́gẹ́ bí Ámósì 4:4, 5 ti wí, kí ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ sí?

19 Ó bani nínú jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kò gba ìhìn alágbára tí Ámósì jẹ́ yìí. Nínú Ámósì 4:4, 5 wòlíì náà táṣìírí ipò tẹ̀mí wọn tó burú jáì, ó sọ pé: “Ẹ wá sí Bẹ́tẹ́lì, kí ẹ sì lọ́wọ́ nínú ìrélànàkọjá. Ẹ lọ́wọ́ nínú ìrélànàkọjá lemọ́lemọ́ ní Gílígálì, . . . nítorí bí ẹ ṣe fẹ́ nìyẹn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lérò tó dáa lọ́kàn. Wọn ò pa ọkàn wọn mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn dẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ohun búburú, wọ́n sì wá kórìíra ohun rere. Àwọn olóríkunkun èèyàn tí ń jọ́sìn ọmọ màlúù wọ̀nyẹn ò yíwà wọn padà. Jèhófà yóò ní kí wọ́n jíhìn, inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n sì máa kú sí!

20. Báwo lèèyàn ṣe lè ṣe ohun tí Ámósì 5:4 sọ?

20 Kò rọrùn fáwọn tó ń gbé ní Ísírẹ́lì láyé ìgbà yẹn láti jólóòótọ́ sí Jèhófà. Kò rọrùn fáwa Kristẹni tó wà lóde òní láti kọ àṣà tó lòde sílẹ̀, gbogbo wa la sì mọ̀yẹn dáadáa, àtọmọdé àtàgbà. Síbẹ̀, ìfẹ́ tí díẹ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà náà ní sí Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe múra tán láti ṣe ohun tó wù ú, sún wọn láti ṣe ìjọsìn tòótọ́. Àwọn ni Jèhófà sọ fún nínú Ámósì 5:4 pé: “Wá mi, kí o sì máa wà láàyè nìṣó.” Lóde òní, Ọlọ́run ń fi àánú hàn bákan náà sáwọn tó ronú pìwà dà tí wọ́n sì wá a nípa gbígba ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kì í ṣe ohun tó rọrùn láti ṣe, àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3.

Aásìkí Ńbẹ Bí Ìyàn Tilẹ̀ Ń Mú Nípa Tẹ̀mí

21. Ìyàn wo ló mú àwọn tí kò ṣe ìjọsìn tòótọ́?

21 Kí ló ń dúró de àwọn tí kò bá ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn? Ìyàn tá ò rírú ẹ̀ rí ló máa mú wọ́n, ìyẹn ìyàn nípa tẹ̀mí! “Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Ámósì 8:11) Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ráágó nínú irú ìyàn tẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, àwọn olóòótọ́ ọkàn tó wà láàárín wọn ń rí i pé àwọn èèyàn Ọlọ́run láásìkí nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ń wọ́ tìrítìrí sínú ètò àjọ Jèhófà. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín ipò tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà àti ipò táwọn Kristẹni tòótọ́ wà hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu, ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin.”—Aísáyà 65:13.

22. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yọ̀?

22 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ǹjẹ́ àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan mọrírì àwọn ìpèsè àti ìbùkún nípa tẹ̀mí tá a ní? Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ń tẹ̀ jáde, tá à ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àyíká, àti ti àgbègbè, ńṣe layọ̀ wa máa ń kún nítorí ipò rere ọkàn wa. Inú wa ń dùn nítorí pé a lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, títí kan àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì tó ní ìmísí Ọlọ́run.

23. Kí làwọn tó ń fi ògo fún Ọlọ́run ń gbádùn?

23 Àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì fẹ́ láti máa fi ògo fún un wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì. Láìka bí ipò àtijẹ-àtimu wa ṣe rí sí àti àdánwò èyíkéyìí tá a ti lè dojú kọ nínú ayé búburú yìí, Ọlọ́run ń bù kún àwa tá a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a sì ń jẹ oúnjẹ tó dára jù lọ nípa tẹ̀mí. (Òwe 10:22; Mátíù 24:45-47) Nígbà náà, Ọlọ́run, ẹni tó ń pèsè ohun gbogbo lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa ni gbogbo ògo yẹ o. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa báa nìṣó ní yíyìn ín látọkànwá títí láé. Ìyẹn yóò jẹ́ àǹfààní aláyọ̀ tá a ní tá a bá ń wá Jèhófà, Olùṣàyẹ̀wò ọkàn.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí ní Ísírẹ́lì nígbà ayé Ámósì?

• Ipò òde òní wo ló bá bí nǹkan ṣe rí ní ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì mu?

• Ìyàn wo ló wà báyìí bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn wo sì ni ìyàn náà ò mú?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ, àmọ́ wọn ò láásìkí nípa tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Fún àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ rere wọn lọ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Kò sí ìyàn tẹ̀mí láàárín àwọn èèyàn aláyọ̀ tó ń sin Jèhófà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́