Ìdájọ́ Jèhófà Yóò Dé Sórí Àwọn Ẹni Ibi
“Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ.”—ÁMÓSÌ 4:12.
1, 2. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò fòpin sí ìwà ibi?
ǸJẸ́ Jèhófà tiẹ̀ máa fòpin sí ìwà ibi àti ìnira to wà lórí ilẹ̀ ayé yìí? Ìbéèrè yẹn ṣe pàtàkì gan-an ní ọ̀rúndún tá a wà yìí. Ó dà bí ẹni pé ibikíbi tá a bá yíjú sí la ti ń rí ẹ̀rí ìwà tó burú jáì táwọn èèyàn ń hù sí ọmọnìkejì wọn. Ńṣe ló ń ṣe wá bíi pé kí ayé tí kò ti ní sí ìwà ipá, ìpániláyà, àti ìwà ìbàjẹ́ ti dé!
2 Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni pé a lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò fòpin sí ìwà ibi. Àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní jẹ́ ká mọ̀ dájú pé yóò fìyà jẹ àwọn ẹni ibi. Olódodo àti onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Sáàmù 33:5 sọ fún wa pé: “Òun jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.” Sáàmù mìíràn sọ pé: “Ọkàn [Jèhófà] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Dájúdájú, Jèhófà, Ọlọ́run alágbára gbogbo, tó nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo kò ní gbà kí àwọn ohun tóun kórìíra máa wà bẹ́ẹ̀ lọ títí.
3. Kí la óò túbọ̀ mọ̀ sí i bá a ṣe ń gbé àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì yẹ̀ wò?
3 Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí mìíràn tó jẹ́ ká ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò fòpin sí ìwà ibi. Àkọsílẹ̀ nípa bó ṣe bá àwọn èèyàn lò láyé àtijọ́ mú èyí dá wa lójú hán-únhán-ún. Àwọn àpẹẹrẹ tó gbàfiyèsí nípa bí Jèhófà ṣe máa ń fìyà jẹ àwọn ẹni ibi wà nínú ìwé Ámósì. Àyẹ̀wò síwájú sí i tá a fẹ́ ṣe nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì yóò jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run. Ìkíní, ìdájọ́ náà máa ń tọ́ sáwọn èèyàn tó máa ń dé bá. Èkejì, ìdájọ́ náà ò ṣeé sá fún. Ẹ̀kẹta, ẹni tó bá ṣẹ́ nìkan ni ìdájọ́ náà máa ń dé bá, nítorí pé Jèhófà máa ń dá àwọn ẹni ibi lẹ́jọ́, àmọ́ ó máa ń ṣàánú àwọn tó ronú pìwà dà àtàwọn tó lọ́kàn tó dáa.—Róòmù 9:17-26.
Ìdájọ́ Ọlọ́run Máa Ń Tọ́ Sáwọn Tó Máa Ń Dé Bá
4. Ibo ni Jèhófà rán Ámósì lọ, kí sì nìdí tó fi rán an lọ?
4 Wọ́n ti pín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí ìjọba méjì nígbà ayé Ámósì. Ọ̀kan ni ẹ̀yà méjì ìjọba Júdà tó wà níhà gúúsù. Èkejì sì ni ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì tó wà níhà àríwá. Jèhófà ní kí Ámósì ṣe iṣẹ́ wòlíì, ó ní kó fi Júdà, ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, kó kọjá lọ sí Ísírẹ́lì. Ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti ní kí Ámósì lọ kéde ìdájọ́ òun.
5. Àwọn orílẹ̀-èdè wo ni Ámósì kọ́kọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn, kí sì nìdí kan tí ìdájọ́ gbígbóná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fi tọ́ sí wọn?
5 Kì í ṣe ìkéde ìdájọ́ Jèhófà lórí ìjọba àríwá Ísírẹ́lì oníwàkiwà ni Ámósì fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Dípò ìyẹn, ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ ni ìpolongo ìdájọ́ Ọlọ́run tó máa dé bá àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́fà tó wà nítòsí Ísírẹ́lì. Àwọn orílẹ̀-èdè náà ni Síríà, Filísíà, Tírè, Édómù, Ámónì, àti Móábù. Ǹjẹ́ ìdájọ́ gbígbóná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tọ́ sáwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn? Ó tọ́ sí wọn mọ̀nà! Ìdí kan ni pé ọ̀tá paraku ni wọ́n jẹ́ sí àwọn èèyàn Jèhófà.
6. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa mú kí Síríà, Filísíà, àti Tírè ko àgbákò?
6 Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dẹ́bi fún àwọn ará Síríà ‘nítorí pípa tí wọ́n pa Gílíádì bí ọkà.’ (Ámósì 1:3) Àwọn ará Síríà gba ìpínlẹ̀ mọ́ Gílíádì lọ́wọ́, ìyẹn àgbègbè Ísírẹ́lì níhà ìlà oòrùn Odó Jọ́dánì, wọ́n sì ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run tó ń gbé níbẹ̀ léṣe gan-an. Filísíà àti Tírè ńkọ́? Àwọn Filísínì jẹ̀bi kíkó tí wọ́n kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn, tàbí àwọn òǹdè, tí wọ́n sì tà wọ́n fáwọn ará Édómù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tiẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Tírè tó ń ṣe òwò ẹrú. (Ámósì 1:6, 9) Etí wo ló ń báni gbọ́ ọ pé a ta àwọn èèyàn Ọlọ́run sóko ẹrú! Abájọ tí Jèhófà fi máa mú kí Síríà, Filísíà, àti Tírè ko àgbákò.
7. Báwo ni Édómù, Ámónì, Móábù ṣe jẹ́ sí Ísírẹ́lì, àmọ́ irú ìwà wo ni wọ́n hù sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
7 Ibi tí Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ wa náà ni Édómù, Ámónì, àti Móábù ti ṣẹ̀ wá. Ìbátan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì làwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Àwọn ọmọ Édómù ṣẹ̀ wá látinú ìlà ìdílé Ábúráhámù nípasẹ̀ Ísọ̀ tí òun àti Jákọ́bù jọ jẹ́ ìbejì. Torí náà, ká kúkú sọ pé arákùnrin Ísírẹ́lì ni wọ́n. Àwọn ọmọ Ámónì àti Móábù ṣẹ̀ wá látinú ìlà ìdílé Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù. Àmọ́ ṣá o, ǹjẹ́ Édómù, Ámónì àti Móábù fìfẹ́ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ìbátan wọn lò? Rárá o! Édómù ò ṣàánú wọn rárá, ńṣe ló fi idà pa àwọn “arákùnrin rẹ̀,” àwọn ọmọ Ámónì náà sì hùwà ìkà gan-an sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn. (Ámósì 1:11, 13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ámósì ò sọ ní tààràtà bí Móábù ṣe hùwà sáwọn èèyàn Ọlọ́run, ọjọ́ ti pẹ́ táwọn ọmọ Móábù ti lòdì sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n jọ jẹ́ ìbátan kan yìí á jẹ dẹndẹ ìyà. Pípa ni Jèhófà máa pa wọ́n run ráúráú.
Ìdájọ́ Ọlọ́run Kò Ṣeé Sá Fún
8. Kí nìdí tí ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà nítòsí Ísírẹ́lì ò fi ṣeé sá fún?
8 Láìsí àní-àní, ìdájọ́ gbígbóná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ámósì sọ̀rọ̀ nípa wọn níbẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Wọn ò sì lè sá fún ìdájọ́ náà. Nínú ìwé Ámósì orí kìíní, ẹsẹ ìkẹta títí dé orí kejì ẹsẹ kìíní, ẹ̀ẹ̀mẹfà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ pé: “Èmi kì yóò yí i padà.” Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò ṣàìdá àwọn orílẹ̀-èdè yẹn lẹ́jọ́. Ìtàn fi hàn lóòótọ́ pé, nígbà tó ṣe, àwọn orílẹ̀-èdè náà kàgbákò níkọ̀ọ̀kan. Àní, ó kéré tán, a ò tiẹ̀ gbúròó mẹ́rin lára àwọn orílẹ̀-èdè náà mọ́, ìyẹn Filísíà, Móábù, Ámónì àti Édómù!
9. Kí ló tọ́ sí àwọn olùgbé Júdà, kí sì nìdí tó fi tọ́ sí wọn?
9 Orílẹ̀-èdè keje ni àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì wá kàn báyìí, ìyẹn Júdà ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn olùgbọ́ Ámósì tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àríwá Ísírẹ́lì láti gbọ́ bó ṣe ń kéde ìdájọ́ lórí ìjọba Júdà. Kí nìdí tí ìdájọ́ gbígbóná fi tọ́ sáwọn olùgbé Júdà? Ámósì 2:4 sọ pé: “Ní tìtorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ òfin Jèhófà.” Jèhófà ò fojú kékeré wo irú ìwà ìmọ̀ọ́mọ̀ tàpá sí Òfin rẹ̀ yìí. Níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Ámósì 2:5, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi yóò sì rán iná sí Júdà dájúdájú, yóò sì jẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé Jerúsálẹ́mù run.”
10. Kí nìdí tí Júdà ò fi lè bọ́ lọ́wọ́ àgbákò?
10 Kó sọ́gbọ́n tí Júdà aláìṣòótọ́ fi lè mórí bọ́ nínú ègbé tó ń bọ̀ lórí rẹ̀ yìí. Lẹ́ẹ̀keje, Jèhófà sọ pé: “Èmi kì yóò yí i padà.” (Ámósì 2:4) Ìyà tí Ámósì sọ tẹ́lẹ̀ yìí dé sórí Júdà nígbà tí Bábílónì sọ ọ́ dahoro ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a tún rí i pé kò síbi táwọn ẹni ibi lè sá sí, ìdájọ́ Ọlọ́run máa dé sórí wọn ṣáá ni.
11-13. Orílẹ̀-èdè wo ni Ámósì kéde ìdájọ́ lé lórí, irú ìyà wo ni wọ́n sì fi ń jẹ àwọn èèyàn níbẹ̀?
11 Wòlíì Ámósì ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí orílẹ̀-èdè méje tán ni. Tí ẹnikẹ́ni bá sì rò pé Ámósì ti parí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nìyẹn, àṣìṣe gbáà lonítọ̀hún ṣe. Ámósì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mẹ́yẹ bọ̀ lápò ni! Iṣẹ́ tá a dìídì yàn fún Ámósì ni pé kó kéde ìdájọ́ mímúná sórí ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì tó wà níhà àríwá. Ìdájọ́ gbígbóná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì tọ́ sí Ísírẹ́lì lóòótọ́ nítorí ìwàkiwà rẹ̀ àti ipò bíburú jáì tó wà nípa tẹ̀mí.
12 Àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì tú àṣírí ìnilára tó gbòde kan ní ìjọba Ísírẹ́lì. Látàrí èyí, Ámósì 2:6, 7 kà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní tìtorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Ísírẹ́lì, àti ní tìtorí mẹ́rin, èmi kì yóò yí i padà, ní tìtorí títà tí wọ́n ta olódodo fún fàdákà lásán-làsàn, àti òtòṣì fún iye owó sálúbàtà ẹsẹ̀ méjèèjì. Wọ́n ń fi ìháragàgà ṣàfẹ́rí ekuru ilẹ̀ lórí àwọn ẹni rírẹlẹ̀; ọ̀nà àwọn ọlọ́kàn tútù ni wọ́n sì yí padà.’”
13 Wọ́n ń ta àwọn olódodo “fún fàdákà lásán-làsàn,” bóyá ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, lẹ́yìn táwọn onídàájọ́ bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fàdákà tán, wọ́n á wá fìyà jẹ àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Àwọn tá a jẹ ní gbèsè ń ta àwọn òtòṣì sóko ẹrú níye owó kan náà tí wọ́n ń ra “sálúbàtà ẹsẹ̀ méjèèjì,” bóyá láti fi san gbèsè tí ò tó nǹkan. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ‘ń mí hẹlẹhẹlẹ,’ tàbí pé wọ́n ń hára gàgà láti sọ “àwọn ẹni rírẹlẹ̀” di aláìníláárí débi pé àwọn òtòṣì wọ̀nyẹn á wá bẹ̀rẹ̀ sí í da erùpẹ̀ sórí ara wọn, láti fi hàn pé àwọn wà nínú ìpọ́njú, tàbí pé àwọn ń ṣọ̀fọ̀ tàbí pé àwọn ti di ẹni ẹ̀tẹ́. Ìwà ìbàjẹ́ gba gbogbo ìlú kan débi pé “àwọn ọlọ́kàn tútù” ò láǹfààní àtirí ìdájọ́ òdodo gbà.
14. Àwọn wo ni wọ́n ń fìyà jẹ nínú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì?
14 Kíyè sí àwọn tí wọ́n ń ṣe ṣúkaṣùka yìí. Àwọn olódodo, àwọn òtòṣì, àwọn ẹni rírẹlẹ̀, àtàwọn ọlọ́kàn tútù tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà ni. Májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá kàn án nípá fún wọn láti máa fi ìyọ́nú hàn sí àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àtàwọn aláìní. Ká ní wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ipò irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó wà lábẹ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì kì bá máà burú tó yẹn.
“Múra Sílẹ̀ Láti Pàdé Ọlọ́run Rẹ”
15, 16. (a) Kí nìdí tí wọ́n fi sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ”? (b) Báwo ni Ámósì 9:1, 2 ṣe fi hàn pé àwọn ẹni ibi kò lè sá fún ìdájọ́ Ọlọ́run? (d) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ní ọdún 740 ṣáájú Sànmánì Tiwa?
15 Ìṣekúṣe àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tó gbòde kan ní Ísírẹ́lì ló mú kí wòlíì Ámósì sọ fún orílẹ̀-èdè ọlọ̀tẹ̀ náà pé: “Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ.” (Ámósì 4:12) Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ò lè mórí bọ́ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí rẹ̀ nítorí pé Jèhófà kéde lẹ́ẹ̀kẹjọ pé: “Èmi kì yóò yí i padà.” (Ámósì 2:6) Ní ti àwọn ẹni ibi tí wọ́n lè fẹ́ sá pa mọ́, Ọlọ́run sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń sá lọ nínú wọn tí sísá rẹ̀ yóò kẹ́sẹ járí, kò sì sí ẹni tí ń sá àsálà nínú wọn tí yóò sá lọ gbé. Bí wọ́n bá walẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù, láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n; bí wọ́n bá sì gòkè lọ sí ọ̀run, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀ kalẹ̀.”—Ámósì 9:1, 2.
16 Àwọn ẹni ibi ò lè mórí bọ́ nínú ìdájọ́ Jèhófà nípa wíwalẹ̀ “lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù,” tó jẹ́ pé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ó túmọ̀ sí kéèyàn gbìyànjú láti sá pa mọ́ síbi tó jindò jù lọ láyé. Wọn ò sì lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run nípa gígòkè “lọ sí ọ̀run,” ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbìyànjú láti wá ibi ìsádi lórí àwọn òkè gíga fíofío. Ìkìlọ̀ Jèhófà ṣe kedere: Kò síbi ìsádi tí wọ́n lè wà tí ọwọ́ rẹ̀ kò ti ní tẹ̀ wọ́n. Ìlànà ìdájọ́ Ọlọ́run sì béèrè pé kí ìjọba Ísírẹ́lì jíhìn fún àwọn ìwà láabi tó ti hù. Àkókò náà sì dé ní tòótọ́. Ní ọdún 740 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ìyẹn ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn tí Ámósì sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun ìjọba Ísírẹ́lì.
Ẹni Tó Bá Ṣẹ̀ Ni Ìdájọ́ Ọlọ́run Máa Ń Dé Bá
17, 18. Kí ni Ámósì orí kẹsàn-án ṣí payá nípa àánú Ọlọ́run?
17 Àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì ti jẹ́ ká rí i pé ìdájọ́ Ọlọ́run máa ń tọ́ sáwọn èèyàn tó dé sórí wọn àti pé kò ṣeé sá fún. Àmọ́ ìwé Ámósì tún fi hàn pé ẹni tó bá ṣẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ Jèhófà máa ń dé bá. Ọlọ́run lè wá àwọn ẹni ibi kàn kò sì dá wọn lẹ́jọ́ níbikíbi tí wọ́n bá sá pa mọ́ sí. Ó sì tún lè wá àwọn tó ronú pìwà dà àtàwọn adúróṣinṣin kàn, ìyẹn àwọn tó fẹ́ fi àánú hàn sí. Kókó yìí ni orí tó kẹ́yìn nínú ìwé Ámósì gbé yọ lọ́nà tó fa kíki.
18 Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ámósì orí kẹsàn-án, ẹsẹ ìkẹjọ, Jèhófà sọ pé: “Èmi kì yóò pa ilé Jékọ́bù rẹ́ ráúráú.” Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ ìkẹtàlá sí kẹẹ̀ẹ́dógún sọ, Jèhófà ṣèlérí pé òun á “kó òǹdè” àwọn ènìyàn òun “jọ padà.” A ó sì ṣojú àánú sí wọn, wọn yóò sì ní ààbò àti aásìkí. Jèhófà ṣèlérí pé, “atulẹ̀ yóò sì lé olùkórè bá ní ti tòótọ́.” Fojú inú wo irú ipò yẹn, ìkórè yóò pọ̀ yanturu débi pé káwọn èèyàn náà tó parí ìkórè kan, àkókò ìtúlẹ̀ àti fífúnrúgbìn mìíràn á tún ti dé!
19. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà?
19 A lè sọ pé àwọn tó ṣẹ̀ nìkan ló jìyà nígbà tí ìdájọ́ Jèhófà dé sórí àwọn ẹni ibi ní Júdà àti Ísírẹ́lì nítorí pé ó ṣàánú àwọn tó ronú pìwà dà àtàwọn tó lọ́kàn tó dáa. Ámósì orí kẹsàn-án sọ nípa ìlérí ìmúbọ̀sípò, èyí sì ní ìmúṣẹ nígbà tí àwọn àṣẹ́kù tó ronú pìwà dà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà padà wálé láti ìgbèkùn àwọn ará Bábílónì ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Nígbà tí wọ́n padà dé ìlú ìbílẹ̀ wọn, wọ́n mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Wọ́n tún àwọn ilé wọn kọ́, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà àti ọgbà ọ̀gbìn láìsí ewu kankan tó wu wọ́n.
Ìdájọ́ Gbígbóná Látọ̀dọ̀ Jèhófà Yóò Dé!
20. Kí ni ìjíròrò wa nípa àwọn ìdájọ́ tí Ámósì kéde rẹ̀ mú dá wa lójú?
20 Ó yẹ kí ohun tá a jíròrò nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tí Ámósì kéde rẹ̀ yìí mú un dá wa lójú pé Jèhófà yóò fòpin sí ìwà ibi ní ọjọ́ wa. Kí nìdí tá a fi ní láti gba ọ̀rọ̀ yìí gbọ́? Èkíní, àwọn àpẹẹrẹ nípa bí Ọlọ́run ṣe fìyà jẹ àwọn ẹni ibi jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣe ní ọjọ́ tiwa. Èkejì, ìdájọ́ Ọlọ́run tó ṣẹ sórí ìjọba Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò mú ìparun wá sórí ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù tó jẹ́ apá pàtàkì jù lọ nínú “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé.—Ìṣípayá 18:2.
21. Kí nìdí tí ìdájọ́ gbígbóná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fi tọ́ sí ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù?
21 Kò sí iyèméjì kankan nípa bóyá ìdájọ́ gbígbóná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tọ́ sí ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ètò ẹ̀sìn wọn ẹlẹ́gbin àti ìwàkiwà inú ìsìn wọn jẹ́ ká mọ̀ pé ìdájọ́ tọ́ sí i. Ìdájọ́ Jèhófà tọ́ sí ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù àti ìyókù ayé Sátánì. Kò sì sọ́nà àbáyọ fún wọn, nítorí pé nígbà tí àkókò bá tó láti mú ìdájọ́ náà ṣẹ, àwọn ọ̀rọ̀ Ámósì orí kẹsàn-án ẹsẹ ìkíní yóò ní ìmúṣẹ, ibẹ̀ sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń sá lọ nínú wọn tí sísá rẹ̀ yóò kẹ́sẹ járí, kò sì sí ẹni tí ń sá àsálà nínú wọn tí yóò sá lọ gbé.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ibikíbi táwọn ẹni ibi ì báà sá pa mọ́ sí, Jèhófà yóò rí wọn.
22. Àwọn kókó wo nípa ìdájọ́ Ọlọ́run ni 2 Tẹsalóníkà 1:6-8 mú ṣe kedere?
22 Ìdájọ́ Ọlọ́run máa ń tọ́ sáwọn tó máa ń dé bá, kò ṣeé sá fún, ẹni tó bá sì ṣẹ̀ ló máa ń dé bá. A lè rí èyí nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé: “Ó jẹ́ òdodo níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti san ìpọ́njú padà fún àwọn tí ń pọ́n yín lójú, ṣùgbọ́n, fún ẹ̀yin tí ń ní ìpọ́njú, ìtura pa pọ̀ pẹ̀lú wa nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:6-8) “Ó jẹ́ òdodo níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” láti san ẹ̀san fún àwọn tí ìdájọ́ gbígbóná rẹ̀ tọ́ sí nítorí bí wọ́n ṣe ń pọ́n àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ lójú. Ìdájọ́ yẹn ò ní ṣeé sá fún nítorí pé àwọn ẹni ibi kò ní lè la ‘ìṣípayá Jésù pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò’ já. Ó tún láwọn tí ìdájọ́ Ọlọ́run máa dé bá, nítorí pé Jésù yóò mú ẹ̀san “wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” Ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọ́run yóò sì jẹ́ nǹkan ìtùnú fáwọn èèyàn Ọlọ́run tó rí ìpọ́njú.
Ìrètí Tó Wà Fáwọn Adúróṣinṣin
23. Ìrètí àti ìtùnú wo la lè rí nínú ìwé Ámósì?
23 Àwọn ìsọfúnni tó ń fún àwọn tó lọ́kàn tó dáa ní ìrètí àti ìtùnú tún wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Ámósì ti wí, Jèhófà ò pa àwọn ènìyàn rẹ̀ ìgbàanì run tán ráúráú. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà tó wà nígbèkùn jọ, ó dá wọn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ó dáàbò bò wọ́n ó sì fún wọn ní ọ̀pọ̀ aásìkí. Báwo lèyí ṣe kan ìgbà tiwa yìí? Ó mú un dá wa lójú pé nígbà tí ìdájọ́ Ọlọ́run bá máa dé, Jèhófà yóò wá àwọn ẹni ibi kàn níbikíbi tí wọn ì báà sá pa mọ́ sí, yóò sì wá àwọn tí àánú rẹ̀ tọ́ sí kàn níbikíbi tí wọ́n bá wà lórí ilẹ̀ ayé.
24. Àwọn ìbùkún wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń rí lóde òní?
24 Lákòókò tá a fi ń dúró kí ìdájọ́ Jèhófà dé bá àwọn ẹni ibi, kí ni àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ń gbádùn? Láìsí àní-àní, Jèhófà ń fi aásìkí yàbùgà-yabuga nípa tẹ̀mí jíǹkí wa! À ń gbádùn ìjọsìn tí kò ní irọ́ àti èrú tó tinú ẹ̀kọ́ èké Kirisẹ́ńdọ̀mù wá. Jèhófà tún ń fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu. Àmọ́, ká má ṣe gbàgbé pé iṣẹ́ bàǹtà-banta ló ń bá àwọn ìbùkún yanturu tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà yìí rìn. Ọlọ́run fẹ́ ká kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ìdájọ́ tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ náà. A fẹ́ láti sa gbogbo ipá wa láti wá àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” rí. (Ìṣe 13:48) Láìsí àní-àní, a fẹ́ ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn tá a bá lè ràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní aásìkí tẹ̀mí tá à ń gbádùn nísinsìnyí. A sì fẹ́ kí wọ́n yè bọ́ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn ẹni ibi. Àmọ́ ṣá o, ká tó lè gbádùn àwọn ìbùkún wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ ní ọkàn tó tọ́. Àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì tẹnu mọ́ kókó yìí pẹ̀lú, a óò sì rí i nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì ṣe fi hàn pé ìdájọ́ mímúná látọ̀dọ̀ Jèhófà tọ́ sí àwọn tó máa ń dé bá?
• Àwọn ẹ̀rí wo ni Ámósì fún wa tó fi hàn pé ìdájọ́ Ọlọ́run kò ṣeé sá fún?
• Báwo ni ìwé Ámósì ṣe fi hàn pé ẹni tó bá ṣẹ ni ìdájọ́ Ọlọ́run máa ń dé bá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ìjọba Ísírẹ́lì kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì àti Júdà padà wálé láti ìgbèkùn àwọn ará Bábílónì