Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 23
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 23
Orin 109 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 14 ìpínrọ̀ 14 sí 19 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kọ́ríńtì 8-13 (10 min.)
No. 1: 2 Kọ́ríńtì 10:1-18 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Ó Tọ́ Láti Rú Òfin Ọlọ́run Torí Pé A Fẹ́ Gbẹ̀mí Là?—td 11B (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ìtumọ̀ Ohun Tó Wà Nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: “Màá Gba Ìwé Yín Tí Ìwọ Náà Bá Gba Ìwé Wa.” Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí wọ́n ti gbà fèsì nígbà tẹ́nì kan sọ bẹ́ẹ̀ fún wọn.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Kọjá? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọ yín ṣe ṣe sí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. Tẹnu mọ́ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe, kó o sì gbóríyìn fún àwọn ará. Mẹ́nu ba apá ibì kan tàbí méjì tó yẹ kí ìjọ yín ṣiṣẹ́ lé lórí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tá a wà yìí, kó o sì sọ àwọn ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti tẹ̀ síwájú.
15 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Ìṣe 16:19-40. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Orin 44 àti Àdúrà