Ran Àwọn Aláìnírìírí Lọ́wọ́ Láti Lóye
1 Nípasẹ̀ iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, a ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn ni ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn. (Mát. 28:19, 20) Ìsapá ribiribi láti ṣe ìyẹn ni Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó ju mílíọ̀nù márùn-ún ń ṣe kárí ayé. A kì í díwọ̀n àṣeyọrí nípasẹ̀ wákàtí tí a lò, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi sóde, tàbí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a bẹ̀rẹ̀. Ọwọ́ wa ń tẹ ète ìlépa wa nígbà tí àwọn ènìyàn bá lóye ohun tí wọ́n kọ́, tí wọ́n sì gbégbèésẹ̀ lórí rẹ̀.
2 Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ní ‘mímú kí àwọn aláìní ìrírí lóye’ nínú. (Orin Dá. 119:130, NW) A máa ń wú àwọn ènìyàn lórí, a sì máa ń ta wọ́n jí kìkì nígbà tí ‘òye bá yé wọn.’ (Mát. 15:10) Bí iṣẹ́ wa ti ń gbòòrò, tí ó sì ń pọ̀ sí i, a ń rí àìní náà síwájú sí i láti sọ̀rọ̀, kí a sì kọ́ni lọ́nà rírọrùn. Ìdí nìyẹn tí Society ṣe tẹ ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, jáde. Ó ní ẹ̀kọ́ kíkún rẹ́rẹ́ tí ó kárí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì nínú. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kúrú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò díjú, ìtọ́ni rẹ̀ sì rọrùn láti yéni, tí ó mú kí ìwé pẹlẹbẹ náà wu ọ̀pọ̀ ènìyàn.
3 A óò gbé ìwé pẹlẹbẹ yìí jáde lákànṣe pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn nínú oṣù April àti May. A dámọ̀ràn pé nígbà tí o bá ń wéwèé ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí o ṣètò láti fi àsansílẹ̀ owó àti ìwé pẹlẹbẹ náà lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ déédéé. Mú ìwé pẹlẹbẹ náà tọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fi ìmúratán gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ lọ. Rántí pé ó lè wúlò ní pàtàkì láti kọ́ àwọn ọmọdé, àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè àjèjì, àti àwọn tí kò lè kàwé dáradára lẹ́kọ̀ọ́.
4 Lo Ìyọsíni Rírọrùn: Nígbà tí o bá ń ṣàgbékalẹ̀ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, tọ́ka sí ojú ìwé 2, níbi tí ó ti ṣàlàyé pé, “a pète ìwé yìí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Tọ́ka sí ìpínrọ̀ 3 ní ojú ìwé 3 láti fi ìdí tí ẹni náà fi ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn. Ru ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ sókè nípasẹ̀ díẹ̀ nínú àwọn àkòrí ẹ̀kọ́ tí ń fi àwọn òtítọ́ rírọrùn ti Bíbélì hàn. Fi bí ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣe ń mú kí kíkẹ́kọ̀ọ́ gbádùn mọ́ni hàn, kí o sì yọ̀ǹda láti fún un ní ìrànwọ́ ara ẹni.
5 Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí Ń Tẹ̀ Síwájú: Góńgó wa kì í wulẹ̀ ṣe kìkì láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́—a fẹ́ láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn tí yóò di alátìlẹ́yìn adúróṣinṣin fún ìjọsìn tòótọ́. A lè kárí ìwé pẹlẹbẹ yìí láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó sì yẹ kí ó ṣamọ̀nà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀. (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé ní ojú ìwé 31.) Láti ìbẹ̀rẹ̀ gan-an, ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti mọ ètò àjọ Jèhófà. (Wo ìwé Reasoning, ojú ìwé 283 àti 284.) Tẹnu mọ́ ìníyelórí àwọn ìpàdé ìjọ, kí o sì ṣàlàyé pé lílọ sí àwọn ìpàdé náà ń pèsè òye kíkún rẹ́rẹ́ nípa bí a óò ṣe máa ṣe ìjọsìn tòótọ́.—Héb. 10:24, 25.
6 Ìpín kíkún nínú àkànṣe iṣẹ́ yìí ní oṣù April àti May dájú pé yóò mú ayọ̀ tí ń wá láti inú ríran àwọn olótìítọ́ inú lọ́wọ́ láti “ní òye” tí ń ṣamọ̀nà sí ìyè, wá fún wa.—Òwe 4:5.