ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/97 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 7
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 28
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 4/97 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 7

Orin 100

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Jíròrò “Àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbáyé ní 1998.” Mẹ́nu kan àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn ti lọ́ọ́lọ́ọ́.

15 min: “A Ń Fi Ògìdìgbó Kún Un.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá pàtàkì tí a kárí nínú Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1993, ojú ìwé 12 sí 17.

18 min: “Ran Àwọn Aláìnírìírí Lọ́wọ́ Láti Lóye.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn apá fífani mọ́ra ti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè: ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ rírọrùn, àwọn ìbéèrè tí ó ṣe wẹ́kú, àwọn àwòrán tí ń fani mọ́ra, àwọn ìtọ́kasí Ìwé Mímọ́ púpọ̀ yanturu. Tẹnu mọ́ góńgó bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń ṣamọ̀nà sínú ìwé Ìmọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Jẹ́ kí akéde dídáńgájíá kan ṣàṣefihàn bí a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní lílo ìyọsíni tí a ṣàlàyé ní ìpínrọ̀ 4. Fún gbogbo òbí nínú ìjọ níṣìírí láti bá àwọn ọmọ wọn kékeré kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ náà.

Orin 130 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 14

Orin 107

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè, kí o sì jẹ́ kí ìjọ mọ̀ bí a bá nílò àwọn ìwé kan pàtó láti fi kún ibi àkójọ ìwé kíkà ti Gbọ̀ngàn Ìjọba.

15 min: “Dídarí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ sí Ètò Àjọ Náà Tí Ó Wà Lẹ́yìn Orúkọ Wa.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 6) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 5 àti 6 àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Sọ àwọn ìrírí àdúgbò nípa bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe hùwà pa dà nígbà tí wọ́n wo fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name.

20 min: “Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Ní Ohun Tí Ọlọ́run Ń Béèrè.” Ìjíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 4 pẹ̀lú àwùjọ. Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó wà ní ìpínrọ̀ 5, ní lílo ọ̀nà ìgbékalẹ̀ mẹ́rin yíyàtọ̀—lójú pópó, nínú ilé, ní ibi iṣẹ́ ajé, àti ní ibùdókọ̀. Rán gbogbo àwùjọ létí láti gba àwọn ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìròyìn fún iṣẹ́ ìsìn pápá kí wọ́n tó fi Gbọ̀ngàn Ìjọba sílẹ̀ lónìí.

Orin 126 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 21

Orin 113

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàlàyé pé kò tí ì pẹ́ jù láti fi ìwé ìbéèrè fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù May sílẹ̀. Ìròyìn ìnáwó. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, ní ṣókí, sọ ìrírí tí a ní nínú pápá ládùúgbò nípa fífi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sóde, tàbí nípa lílò ó láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

15 min: “Dídarí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ sí Ètò Àjọ Náà Tí Ó Wà Lẹ́yìn Orúkọ Wa.” (Ìpínrọ̀ 7 sí 14) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí olùkọ́ dídáńgájíá kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè bá akẹ́kọ̀ọ́ ní ìjíròrò onínúure láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa àìní náà láti máa lọ sí àwọn ìpàdé.

15 min: Lílo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa Lẹ́kùn-ún Rẹ́rẹ́. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1996, ojú ìwé 3 sí 5.) Ìròyìn fi hàn pé àwọn ìjọ sábà máa ń béèrè fún ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn ju ohun tí wọ́n ń pín kiri lóṣooṣù ní ti gidi. Ó tó ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún tí a kì í ròyìn pé a fi sóde. (Sọ ohun tí àkọsílẹ̀ oníṣirò fi hàn ní ti ìjọ àdúgbò.) Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí? Ọ̀pọ̀ ni a ń kó sínú àpótí ìwé tàbí tí a ń kó dànù. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún èyí? Akéde kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ díwọ̀n àìní rẹ̀, kí ó sì béèrè kìkì ohun tí ó lè fi sóde. Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ dàṣà láti máa fi ìwé ìròyìn lọ gbogbo ẹni tí a bá bá pàdé. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀dà ògbólógbòó ṣòfò. Ẹ máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwé ìròyìn déédéé.

Orin 128 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 28

Orin 121

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo àwùjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù April sílẹ̀. Kéde orúkọ àwọn tí yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù May. Sọ àfikún ìṣètò tí ìjọ ti ṣe fún àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn. Nínú oṣù May, a gbọ́dọ̀ ṣe ìsapá àkànṣe láti pa dà ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí a bá fi sóde pẹ̀lú góńgó bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́. Ní ṣókí, dábàá àwọn ọ̀nà tí a lè gbà dọ́gbọ́n béèrè orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn ènìyàn tí a bá jẹ́rìí fún láìjẹ́ bí àṣà. O lè kọ́kọ́ sọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ, kí o sì béèrè bí wọ́n bá ní nọ́ńbà fóònù tí o fi lè kàn sí wọn. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn àbá tí ó ti gbéṣẹ́ fún wọn.

15 min: “Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe É?” Alàgbà kan bá àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé méjì tàbí mẹ́ta jíròrò àpilẹ̀kọ náà. (Bí kò bá sí àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé, lo àwọn tí ó sábà máa ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.) Fi àwọn kókó pàtàkì láti inú àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Fìbùkún Jíǹkí Ẹni Wọ́n Sì Ń Rí I Gbà,” kún un láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1994. Jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣàlàyé ìdí tí ó fi tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Sọ pé kí wọ́n sọ ìrírí tí ń fi bí a ti ṣe bù kún wọn fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀ hàn.

15 min: Àwọn àìní àdúgbò. Àwọn alàgbà lè lo àkókò yí láti ṣàgbékalẹ̀ ìsọfúnni lórí àwọn àìní àdúgbò pàtó.

Orin 129 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́