Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe É?
1 A sọ tẹ́lẹ̀ nípa Kristi pé ‘ìtara ilé Ọlọ́run yóò jẹ ẹ́ tán.’ (Orin Dá. 69:9) Ìtara tí Jésù ní fún ìjọsìn tòótọ́ Jèhófà sún un láti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà sí ipò kíní. (Lúùk. 4:43; Jòh. 18:37) Ìtara kan náà yí láti jẹ́rìí sí òtítọ́ ń fara hàn lónìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ó kọjá, ìpíndọ́gba 645,509 kárí ayé nípìn-ín nínú irú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà mélòó kan lóṣooṣù. Lójú ìwòye ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ronú tàdúràtàdúrà bóyá a lè ṣètò àyíká ipò wa láti lè ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé.—Orin Dá. 110:3; Oníw. 12:1; Róòm. 12:1.
2 Bí a ti ń gbé nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì lọ́nà ìmọtara-ẹni-nìkan, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ nínú ayé láti lóye ìdí tí ẹnì kan yóò fi máa ṣiṣẹ́ takuntakun nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ohun tí kò mú èrè owó àti ògo wá. Èé ṣe tí àwọn aṣáájú ọ̀nà fi ń ṣe é? Wọ́n mọ̀ pé àwọn ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí ń gbẹ̀mí là. Bí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ wọn fún Jèhófà àti fún ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn ti ń sún wọn ṣiṣẹ́, wọ́n ń nímọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe ti ara ẹni, tí ó lágbára, láti ṣèrànwọ́ láti gba ẹ̀mí là. (Róòm. 1:14-16; 1 Tím. 2:4; 4:16) Tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà kan ṣàkópọ̀ rẹ̀ lọ́nà títọ́ nípa sísọ pé: “Èé ṣe tí a fi ń ṣe aṣáájú ọ̀nà? A ha lè wí àwíjàre níwájú Jèhófà bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ bí?”
3 Arábìnrin mìíràn kọ èyí nípa ìpinnu rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà: “Èmi àti ọkọ mi wéwèé láti máa fi owó tí ẹnì kan ṣoṣo bá ń pa wọlé gbọ́ bùkátà, èyí tí ó túmọ̀ sí yíyááfì gbogbo ohun tí kò bá pọn dandan. Síbẹ̀, Jèhófà bù kún wa ní yanturu, kò fi wá fún òṣì ta, kò sì jẹ́ kí á ráágó. . . . Mo ti rí ìdí gidi fún wíwàláàyè—ìyẹn ti ríran àwọn aláìní lọ́wọ́ láti wá mọ̀ pé Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà, kò jìnnà sí àwọn tí ń wá a.” Ní mímọ ìjẹ́kánjúkánjú àkókò, àwọn aṣáájú ọ̀nà ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun tí ó pọn dandan nínú ìgbésí ayé, nígbà tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti ní àwọn ìṣúra tẹ̀mí, tí yóò wà títí láé.—1 Tím. 6:8, 18, 19.
4 Bí àyíká ipò rẹ bá gbà ọ́ láyè, èé ṣe tí o kò fi dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ kárí ayé tí wọ́n ń ṣe aṣáájú ọ̀nà? Lọ́nà yẹn, o lè nírìírí ayọ̀ kan náà tí wọ́n ń ní.