A Ń Fi Ògìdìgbó Kún Un
1 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òótọ́ ní ọ̀rúndún kìíní, ìdàgbàsókè tí ìjọ Kristẹni ń ní lónìí jọni lójú. (Ìṣe 2:41; 4:4) Ní ọdún tí ó kọjá, a batisí 366,579 àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun, ìpíndọ́gba tí ó ju 1,000 lọ lóòjọ́! A batisí èyí tí ó ju mílíọ̀nù kan lọ ní ọdún mẹ́ta tí ó kọjá. Ní tòótọ́, Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa fi ògìdìgbó àwọn onígbàgbọ́ kún un.—Ìṣe 5:14.
2 Ọ̀pọ̀ ẹni tuntun tí kò nírìírí nípa ọ̀nà ìgbé ayé Kristẹni nílò ìrànwọ́ àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n lágbára nínú ìgbàgbọ́. (Róòm. 15:1) Àwọn kan ń bẹ láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí tí ó jẹ́ pé, fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìbatisí wọn pàápàá, wọ́n kùnà láti “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Héb. 5:12; 6:1) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù, nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Hébérù, fi tẹnu mọ́ àwọn àgbègbè tí àwọn Kristẹni ti ní láti dàgbà nípa tẹ̀mí. Kí ni àwọn àgbègbè wọ̀nyí, báwo sì ni a ṣe lè fúnni ní ìrànwọ́ tí a nílò?
3 Níní Àṣà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí Ó Dára: Ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni Pọ́ọ̀lù, jíjẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ rere ní nínú, kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́, ṣíṣàtúnyẹ̀wò, àti lílo “oúnjẹ líle” tí ètò àjọ Jèhófà ń pèsè. (Héb. 5:13, 14; wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1993, ojú ìwé 12 sí 17.) Nípa mímú àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ wọnú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tẹ̀mí àti bíbá wọn ṣàjọpín ohun ṣíṣeyebíye ti òtítọ́ tí ìwọ ti kọ́ nípasẹ̀ ìwádìí fúnra ẹni, o lè ta wọ́n jí láti ní àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára. Bóyá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè ké sí ẹni tuntun kan láti dara pọ̀ mọ́ ọ nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ tàbí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ.
4 Lílọ sí Ìpàdé Déédéé: Àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ onífẹ̀ẹ́ tí ń fúnni níṣìírí yóò ran àwọn mẹ́ńbà tuntun nínú ìjọ lọ́wọ́ láti yẹra fún àgbègbè míràn tí ó yẹ fún àníyàn tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn—“àṣà náà” tí àwọn kan ní ní ti pípa ìpàdé Kristẹni jẹ. (Héb. 10:24, 25) Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ dáradára pé àwọn ìpàdé ni ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ní ìsopọ̀ tẹ̀mí pẹ̀lú ìjọ. Lo àtinúdá láti mú kí wọ́n nímọ̀lára pé a tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹgbẹ́ ará.
5 Fífi Ìgbọkànlé Tọ Jèhófà Lọ: Láti borí àwọn àìlera ti ara àti àléébù ara ẹni, a gbọ́dọ̀ tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà, ní sísọ àwọn èrò wa jíjinlẹ̀ jù lọ àti àwọn àníyàn wa ṣíṣe pàtàkì jù lọ fún un. Àwọn ẹni tuntun gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pé nípa bíbẹ Jèhófà fún ìrànwọ́, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti rọni, kò sí ìdí fún wọn láti kọsẹ̀. (Héb. 4:15, 16; 10:22) Sísọ àwọn ìrírí tìrẹ lórí èyí yóò fún ìgbọkànlé ẹni tuntun kan pé Jèhófà ń gbọ́ àwọn àdúrà àtọkànwá lókun.
6 Ṣíṣètò Àkókò fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Pọ́ọ̀lù tún fi hàn pé nígbà tí a bá ń “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo,” ó máa ń fúnni lókun nípa tẹ̀mí. (Héb. 13:15) O ha lè ké sí akéde tuntun kan láti dara pọ̀ mọ́ ọ nínú ìṣètò rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá bí? Bóyá ẹ̀yin méjèèjì lè múra àwọn ìgbékalẹ̀ tìrẹ sílẹ̀ tàbí kí ẹ ṣàgbéyẹ̀wò apá fífani mọ́ra kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ẹni tuntun náà kò tí ì dán wò.
7 Ògìdìgbó tí a ń fi kún un jẹ́ ìdí kan fún ìdùnnú ńláǹlà. Lílo ara wa láti dá àwọn mẹ́ńbà tuntun nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ àti láti gbà wọ́n níyànjú yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́ lílágbára tí wọ́n nílò láti ‘pa ọkàn wọn mọ́ láàyè’ dàgbà.—Héb. 3:12, 13; 10:39.