ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 10/1 ojú ìwé 28-31
  • Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Títẹ̀síwájú Nípasẹ̀ Ìdákẹ́kọ̀ọ́
  • Ó Yẹ Kí O Sún Mọ́ Ọlọ́run Tímọ́tímọ́
  • Wíwà Nípò Ìbátan Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà
  • Ìtẹ̀síwájú Tẹ̀mí Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Lẹ́yìn Tẹ́ Ẹ Ti Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Fi Ṣe Góńgó-Ìlépa Rẹ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun Títí Láé
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Jésù Gbọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 10/1 ojú ìwé 28-31

Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí!

Ọjọ́ tí ó yẹ ká máa fọkàn ṣìkẹ́, ká sì máa rántí ni ọjọ́ tí a ṣe batisí. ṣebí òun ni ọjọ́ tí a fi hàn fún àwọn ènìyàn pé a ti ya ara wa sí mímọ́ láti sin Ọlọ́run.

Ó GBA ìsapá gidigidi fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti dé ìpele yìí—yíyọwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tó ti di bárakú, yíyọ ara ẹni nínú ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ gbogbo, yíyí àwọn ọ̀nà ìrònú àti ìhùwà tó ti wọni lẹ́wù padà.

Síbẹ̀ náà, nígbà tí ìbatisí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ tó gbàfiyèsí nínú ìgbésí ayé Kristẹni kan, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó ti ṣe batisí ní Jùdíà pé: “Nísinsìnyí tí a ti fi àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 6:1) Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí gbogbo Kristẹni ‘dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, kí wọ́n di géńdé ọkùnrin, kí wọ́n dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.’ (Éfésù 4:13) Títẹ̀síwájú dé ipò ìdàgbàdénú nìkan ni ọ̀nà tí a lè gbà “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.”—Kólósè 2:7.

Láàárín ọdún mélòó kan tó kọjá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún olùsìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wọn sí mímọ́ ló ti wọnú ìjọ Kristẹni. Bóyá o wà lára wọn. Gẹ́gẹ́ bí ti àwọn arákùnrin rẹ ní ọ̀rúndún kìíní, o kò ní fẹ́ wà nípò ọmọ ọwọ́ nípa tẹ̀mí. O fẹ́ dàgbà, o fẹ́ tẹ̀ síwájú! Àmọ́ lọ́nà wo? Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo lo lè gbà tẹ̀ síwájú bẹ́ẹ̀?

Títẹ̀síwájú Nípasẹ̀ Ìdákẹ́kọ̀ọ́

Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ní ìlú Fílípì pé: “Èyí sì ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” (Fílípì 1:9) Níní “ìmọ̀ pípéye” sí i ṣe pàtàkì fún ọ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. ‘Gbígba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi sínú’ jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ń bá a lọ, kì í ṣe ohun tí ń dáwọ́ dúró lẹ́yìn ìbatisí.—Jòhánù 17:3.

Kristẹni arábìnrin kan tí a ó pè ní Alexandra, wá mọ èyí lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí ó ti ṣe ìbatisí ní ọmọ ọdún 16. A tọ́ ọ dàgbà nínú òtítọ́, kì í pa ìpàdé Kristẹni jẹ, ó sì máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé. Ó kọ̀wé pé: “Ní oṣù díẹ̀ tó kọjá yìí, mo mọ̀ pé bí nǹkan ṣe ń lọ kò dára rárá. Mo pinnu láti yẹ ara mi wò fínnífínní láìṣàbòsí, kí n mọ èrò mi nípa òtítọ́, àti ìdí tí mo fi wà nínú òtítọ́.” Kí ni ó rí? Ó ń bá a nìṣó pé: “Mo rí i pé ìdí tí mo fi wà nínú òtítọ́ kò yé mi. Mo rántí pé bí mo ṣe ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni a ń tẹnu mọ́ lílọ sí ìpàdé àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ṣe ni ó dà bí pe dídákẹ́kọ̀ọ́ àti gbígbàdúrà yóò ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo ṣàyẹ̀wò ipò mi, mo wá rí i pé kò rí bẹ́ẹ̀.”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Dé àyè tí a ti tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn létòletò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.” (Fílípì 3:16) Ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan lè pinnu ọ̀nà ìtẹ̀síwájú. Kí o tó ṣe batisí, ó dájú pé olùkọ́ títóótun kan ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bí ìmọrírì rẹ ti ń pọ̀ sí i, ó fi mímúra ẹ̀kọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sílẹ̀ kún ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ yìí, tí o sì ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a yàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní báyìí tí o ti ṣe batisí, ǹjẹ́ o ti ń ‘rìn ní ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yẹn’?

Bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, ó yẹ kí o ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ohun àkọ́múṣe rẹ, ‘kí o máa wádìí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù dájú.’ (Fílípì 1:10) Nítorí bí ọwọ́ wa ṣe ń dí tó, ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ àwọn àǹfààní tí a ń rí níbẹ̀ mú kí ó yẹ ní ohun tí àá sapá lé lórí. Tún ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Alexandra. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ṣe ni mo kàn wà nínú òtítọ́ ṣáá fún 20 ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí mo ti wà níbẹ̀, nípa wíwulẹ̀ lọ sí ìpàdé àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.” Ṣùgbọ́n, ó ń bá a nìṣó pé, “Mo ti wá dé ìparí èrò pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe pàtàkì, àwọn nìkan kò lè mú mi dúró nígbà tí nǹkan bá bẹ̀rẹ̀ sí nira. Gbogbo èyí wá sí ojútáyé nítorí pé n kì í dákẹ́kọ̀ọ́ mọ́, àdúrà mi sì jẹ́ èyí tí kò lórí tí kò nídìí, àdúrà tí kò tọkàn wá. Mo wá mọ̀ nísinsìnyí pé mo gbọ́dọ̀ yí ìrònú mi padà, kí n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó nítumọ̀, kí n bàa lè mọ Jèhófà dáradára, kí n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí n sì mọrírì ohun tí Ọmọ rẹ̀ ti ṣe fún wa.”

Bí o bá nílò ìrànlọ́wọ́ nípa bí o ṣe lè máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ gbígbámúṣé, inú àwọn alàgbà àti àwọn Kristẹni adàgbàdénú mìíràn nínú ìjọ rẹ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Láfikún sí i, àwọn àpilẹ̀kọ inú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ May 1, 1995; August 15, 1993; àti May 15, 1986, ní àwọn àbá tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú.

Ó Yẹ Kí O Sún Mọ́ Ọlọ́run Tímọ́tímọ́

Àgbègbè mìíràn tí ó ti yẹ kí o tiraka láti tẹ̀ síwájú ni nínú ìbátan rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, o lè nílò eléyìí púpọ̀ jù. Ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn Anthony, tí ó ṣe ìbatisí nígbà tí ó wà ní kékeré. Ó sọ pé: “Èmi ni ọmọ àkọ́kọ́ tí ó ṣe ìbatisí nínú ìdílé wa. Lẹ́yìn ìbatisí mi, màmá mi dì mọ́ mi. N kò tí ì rí kí inú rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀ rí. Ayọ̀ náà pọ̀ púpọ̀, mo sì kún fún agbára.” Àmọ́ ṣá o, ohun mìíràn tún wà nínú ọ̀ràn náà. Anthony ń bá a nìṣó pé: “Fún àkókò kan, kò tí ì sí èwe kankan tí ó ṣe ìbatisí nínú ìjọ wa. Nítorí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí gbéra ga. Ìdáhùn àti àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé tí mo sọ ní àwọn ìpàdé bẹ̀rẹ̀ sì jẹ́ kí n wú fùkẹ̀. Rírí ìyìn àti ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wá ṣe pàtàkì lójú mi ju mímú ìyìn wá fún Jèhófà lọ. Lóòótọ́, n kò ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.”

Bí ti Anthony, àwọn kan lè ti ṣe ìyàsímímọ́ kí wọ́n lè tẹ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́rùn ju kí wọ́n lè tẹ́ Jèhófà lọ́rùn lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run retí pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mú ìlérí wọn láti sin òun ṣẹ. (Fi wé Oníwàásù 5:4.) Àmọ́, ó ń ṣòro fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí ìsopọ̀ ara ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run. Anthony rántí pé: “Ayọ̀ ńlá tí mo ní nígbà ìbatisí mi kò tọ́jọ́. Kò tó ọdún kan lẹ́yìn ìbatisí mi tí mo ṣubú sínú ìwà àìtọ́ bíburú jáì, àwọn alàgbà ìjọ sì ní láti bá mi wí. Híhùwà àìtọ́ léraléra yọrí sí dídi ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn tí mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, a fi àṣẹ ọba mú mi, a sì jù mí sẹ́wọ̀n nítorí ìpànìyàn.”

Wíwà Nípò Ìbátan Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà

Ipò tó wù kí o wà, gbogbo Kristẹni lè dáhùn sí ìpè inú Bíbélì náà pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ó dájú pé o sún mọ́ Ọlọ́run dé ìwọ̀n kan nígbà tí o kọ́kọ́ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kì í ṣe òrìṣà àfinúrò tí wọ́n ń jọ́sìn nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù, ṣùgbọ́n ó ní orúkọ kan, Jèhófà. O tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó ní àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra, pé ó jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.”—Ẹ́kísódù 34:6.

Láti mú ìyàsímímọ́ rẹ láti sin Ọlọ́run ṣẹ ṣáá, o ní láti túbọ̀ sún mọ́ ọn! Lọ́nà wo? Onísáàmù gbàdúrà pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sáàmù 25:4) Dídákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìwé Society lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà sí i. Gbígbàdúrà àtọkànwá déédéé tún ṣe pàtàkì. Onísáàmù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀.” (Sáàmù 62:8) Bí àdúrà rẹ ṣe ń gbà, wàá nímọ̀lára pé Ọlọ́run ní ire rẹ lọ́kàn. Èyí yóò mú kí o nímọ̀lára pé o túbọ̀ sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.

Àwọn àdánwò àti ìṣòro tún ń fún ọ láǹfààní láti sún mọ́ Ọlọ́run. O lè kojú àwọn ìṣòro gbígbàfiyèsí àti ìdánwò ìgbàgbọ́, bí àìsàn, másùnmáwo nílé ìwé àti níbi iṣẹ́, tàbí ìṣòro ètò ọrọ̀ ajé. Ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run tí a ń ṣe déédéé, bí wíwàásù, lílọ sípàdé, tàbí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ ló ṣòro fún ọ. Má ṣe dá kojú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀! Ké pe Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́, kí o bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọ́ ọ sọ́nà, kí ó sì darí rẹ. (Òwe 3:5, 6) Bẹ̀ ẹ́ pé kí ó fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀! (Lúùkù 11:13) Bí o ti ń ní ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run, a óò túbọ̀ máa fà ọ́ sún mọ́ ọn. Bí onísáàmù náà, Dáfídì ṣe sọ ọ́, “ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere. Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.”—Sáàmù 34:8.

Anthony wá ńkọ́? Ó rántí pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rántí ìgbà tí mo ní ọ̀pọ̀ góńgó tẹ̀mí tí ó dá lórí ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ipò tí mo wà báyìí jẹ́ ẹ̀dùn-ọkàn fún mi. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dùn-ọkàn àti ìjákulẹ̀ yìí, mo ṣì rántí ìfẹ́ tí Jèhófà ní. Ó pẹ́ díẹ̀ kí n tó lè máa gbàdúrà sí Jèhófà, ṣùgbọ́n mo ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì tú ọkàn-àyà mi jáde fún un, mo tọrọ àforíjì. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì, ó sì yà mí lẹ́nu láti rí pé mo ti gbàgbé ọ̀pọ̀ nǹkan àti pé ohun tí mo mọ̀ nípa Jèhófà kò tó nǹkan mọ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Anthony kò tíì parí àkókò tí ó yẹ kó lò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìwà ọ̀daràn tí ó hù, ó ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà ládùúgbò, ó sì ti ń padà sípò nípa tẹ̀mí. Inú Anthony dùn jọjọ tí ó fi sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà nì sílẹ̀, mo sì n tiraka láti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ lójoojúmọ́. Nísinsìnyí, ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà ni ohun tí ó jẹ mí lógún jù lọ.”

Ìtẹ̀síwájú Tẹ̀mí Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ

Jésù Kristi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ oníwàásù “ìhìn rere ìjọba.” (Mátíù 24:14) Bí ó ti jẹ́ pé kò pẹ́ púpọ̀ tí o bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà, ìrírí rẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lè má pọ̀. Báwo ni o wá ṣe lè tẹ̀ síwájú láti “ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún”?—2 Tímótì 4:5.

Ọ̀nà kan ni pé kí o ní èrò yíyẹ. Kọ́ láti ka iṣẹ́ ìwàásù sí “ìṣúra,” àǹfààní kan. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ó fún wa láǹfààní láti fi ìfẹ́ wa, ìdúróṣinṣin wa, àti ìwàtítọ́ wa sí Jèhófà hàn. Ó tún ń jẹ́ kí a lè fi ìdàníyàn tí a ní fún àwọn aládùúgbò wa hàn. Lílo ara wa láìmọtara-ẹni-nìkan ní ọ̀nà yìí lè jẹ́ orísun ojúlówó ayọ̀.—Ìṣe 20:35.

Jésù fúnra rẹ̀ ní èrò yíyẹ nípa iṣẹ́ ìwàásù. Bíbá àwọn ẹlòmíràn ṣàjọpín òtítọ́ Bíbélì dà bí “oúnjẹ” fún un. (Jòhánù 4:34) A lè fi ohun tí òun fúnra rẹ̀ sọ ṣàkópọ̀ ohun tí ń mú kí ó ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” (Mátíù 8:3) Jésù ń yọ́nú sí àwọn ènìyàn, pàápàá àwọn tí ayé Sátánì ‘bó láwọ, tí ó sì fọ́n wọn ká.’ (Mátíù 9:35, 36) Ǹjẹ́ ìwọ pẹ̀lú “fẹ́” láti ran àwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí, tí wọ́n sì nílò ìlàlóye láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, o ní láti rí i bí àìgbọ́dọ̀máṣe láti dáhùn sí àṣẹ Jésù pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19) Ní gidi, a óò sún ọ láti kópa kíkún nínú iṣẹ́ yìí bí ìlera rẹ àti ipò tí o wà bá ṣe yọ̀ǹda fún ọ tó.

Kókó pàtàkì mìíràn fún ìtẹ̀síwájú ni kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́—lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, bí ó bá ṣeé ṣe. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè dín ojora àti ìbẹ̀rù tó lè dí ẹnì kan tí ń wàásù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ kù. Kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá yóò ṣe ọ́ láǹfààní ní àwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú. Yóò mú kí ìmọrírì tí o ní fún òtítọ́ pọ̀ sí i, yóò gbé ìfẹ́ rẹ fún Jèhófà àti aládùúgbò ró, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ìrètí Ìjọba náà.

Àmọ́, bí ipò rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ kò bá jẹ́ kí ohun tí o lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù tó nǹkan ńkọ́? Bí kò bá ṣeé ṣe láti wulẹ̀ ṣe ìyípadà, kúkú ní ìtùnú ní mímọ̀ pé inú Ọlọ́run dùn sí ohun tí o bá lè ṣe, níwọ̀n bí o bá ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ tọkàntọkàn. (Mátíù 13:23) Ó ṣeé ṣe kí o tún lè tẹ̀ síwájú ní àwọn ọ̀nà mìíràn, bí mímú ìjáfáfá rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù sunwọ̀n sí i. Nínú ìjọ, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ń fúnni ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ àtàtà ní ọ̀nà yìí. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, bí a bá ṣe jáfáfá tó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ni a ó ṣe gbádùn rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí rere tó.

Nígbà náà, ó ṣe kedere pé ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí kò gbọ́dọ̀ dúró sí ọjọ́ tí a ṣe batisí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ìrètí tí ó ní láti jèrè ìyè àìleèkú nínú ọ̀run pé: “Ẹ̀yin ará, èmi kò tíì ka ara mi sí ẹni tí ó ti gbá a mú nísinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun kan wà nípa rẹ̀: Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí iye àwa tí a ti dàgbà dénú ní ẹ̀mí ìrònú yìí; bí ẹ bá sì ní èrò orí tí ó tẹ̀ sí ibòmíràn lọ́nà èyíkéyìí, Ọlọ́run yóò ṣí ẹ̀mí ìrònú tí ó wà lókè yìí payá fún yín.”—Fílípì 3:13-15.

Ní tòótọ́, gbogbo Kristẹni, yálà wọ́n nírètí àìleèkú nínú ọ̀run tàbí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, gbọ́dọ̀ ‘nàgà’—kí wọ́n nà tàntàn lọ́nà àpèjúwe, kí ọwọ́ wọn lè tẹ góńgó ìyè! Ìbatisí rẹ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ rere, àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni. Máa làkàkà nìṣó láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. “Dàgbà di géńdé nínú agbára òye” nípasẹ̀ àwọn ìpàdé àti ìdákẹ́kọ̀ọ́. (1 Kọ́ríńtì 14:20) “Lè fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ jẹ́. (Éfésù 3:18) Láfikún sí pé ìtẹ̀síwájú rẹ kò ní jẹ́ kí ìdùnnú àti ayọ̀ rẹ ìsinsìnyí dín kù, yóò tún jẹ́ kí o ní àyè tí ó dájú nínú ayé tuntun Ọlọ́run, níbi tí yóò ti ṣeé ṣe fún ọ láti máa tẹ̀ síwájú títí ayérayé, lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ ọ̀run!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ó gba ìkóra-ẹni -níjàánu láti ní àkókò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Níní èrò yíyẹ lè mú kí a láyọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́