Ríran Àwọn Ìdílé Lọ́wọ́ Láti Ní Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí
1 Olùṣekòkáárí owó okòwò kan sọ fún àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ń gboyè jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga pé: “Ìwọra kò burú,” ó sì fi kún un pé: “Ìwọ lè jẹ́ oníwọra síbẹ̀ kí ara sì tù ọ́.” Ìyẹn jẹ́ àpẹẹrẹ bí ayé ṣe ń gbé ọkàn ìfẹ́ ara ẹni lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti mú kí ọjọ́ ọ̀la ẹni dáni lójú. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, Jésù kọ́ni pé Kristẹni kan gbọ́dọ̀ “sẹ́ níní ara rẹ̀ . . . nítorí àǹfààní wo ni yóò jẹ́ fún ènìyàn kan bí ó bá jèrè gbogbo ayé ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ọkàn rẹ̀?” (Mát. 16:24-26) Láti ní ọjọ́ ọ̀la wíwà pẹ́ títí, ẹnì kan gbọ́dọ̀ gbé gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ka ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run—góńgó ṣíṣe pàtàkì jù lọ fún àwọn ìdílé lónìí. (Orin Dá. 143:10; 1 Tím. 4:8) A sọ ìhìn iṣẹ́ yẹn nínú orí tí ó parí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ìtẹ̀jáde tuntun yìí ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ó ṣe pàtàkì ní ti gidi nínú ìgbésí ayé àti bí wọ́n ṣe lè bá ìdílé wọn lò lọ́nà tí ó ń ṣàǹfààní. Bí a ti ń bá a nìṣó láti wàásù ìhìn rere níbi gbogbo, kí ni a lè sọ tí yóò fún àwọn tí a bá bá pàdé níṣìírí láti ka ìwé Ayọ̀ Ìdílé? Àwọn àbá mélòó kan nìyí:
2 Lẹ́nu ọ̀nà àti ní ojú pópó, o lè gbìyànjú lílo ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “Gbadun Igbesi-Aye Idile” láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. O lè béèrè pé:
◼ “Pẹ̀lú gbogbo hílàhílo tí ìgbésí ayé òde òní ń kó bá wa, o ha ronú pé ó ṣeé ṣe láti ní ìgbésí ayé ìdílé tí ó láyọ̀ ní tòótọ́ bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé àṣàrò kúkúrú yìí mú un dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti kà á bí?” Bí ó bá gbà á, o lè máa bá a nìṣó nípa sísọ pé: “Níwọ̀n bí o ti ní ọkàn ìfẹ́ nínú kókó ẹ̀kọ́ yìí, o tún lè gbádùn ìwé yìí tí ó pèsè ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè rí ayọ̀ nínú agbo ìdílé.” Fi kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé Ayọ̀ Ìdílé hàn án. Tọ́ka sí àwọn àkòrí orí ìwé mélòó kan tí ń fani lọ́kàn mọ́ra. Ṣí i sí ojú ìwé 10, kí o sì kà á láti gbólóhùn tí ó kẹ́yìn ìpínrọ̀ 17 dé òpin ìpínrọ̀ 18. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́, kí o sì sọ iye ọrẹ tí a ń ṣe fún un. Ṣàlàyé pé ohun tí o fẹ́ ṣàjọpín ṣì kù, kí o sì béèrè ìgbà tí o tún lè pa dà wá.
3 O lè pa dà ṣiṣẹ́ lórí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rẹ àkọ́kọ́ nípa ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ nípa sísọ pé:
◼ “Èmi yóò fẹ́ láti tọ́ka sí ohun kan tí mo rò pé ìwọ yóò mọrírì nínú ìwé tí o rà. Orí tí ó kẹ́yìn kó àfiyèsí jọ sórí àṣírí tòótọ́ fún ayọ̀ ìdílé. [Ka ìpínrọ̀ 2 ní ojú ìwé 183.] Ṣàkíyèsí pé ṣíṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni kọ́kọ́rọ́ náà. A dámọ̀ràn pé kí àwọn ìdílé kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ láti mọ ohun tí ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́ àti bí wọn óò ṣe lò ó nínú agbo ilé. A ń pèsè ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí ó ń gba kìkì oṣù díẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Bí ìwọ yóò bá fún mi láyè, èmi yóò fi bí a ṣe ń darí rẹ̀ hàn ọ́.” Pa dà lọ pẹ̀lú ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí ìwé Ìmọ̀, èyíkéyìí tí yóò bá bá a mu jù lọ.
4 Nígbà tí o bá ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí àwọn ọ̀dọ́ ní ìpínlẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀, o lè rí ìdáhùnpadà sí ìbéèrè yí:
◼ “Báwo ni ó ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ wọn láti máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ṣàkíyèsí ohun tí ìwé tí ó dá lórí ìgbésí ayé ìdílé yìí sọ nípa kókó ẹ̀kọ́ náà, ‘Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Olótìítọ́ Inú àti Aláìlábòsí.’ [Ka ìpínrọ̀ 4 pátápátá àti gbólóhùn àkọ́kọ́ ní ìpínrọ̀ 5 ní ojú ìwé 65 nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé.] Àwọn ìpínrọ̀ tí ó tẹ̀ lé e pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ lórí bí a ṣe lè mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nínú ìdílé sunwọ̀n sí i. A pe àkọlé ìwé yìí ni Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Èmi yóò fi ẹ̀dà yí sílẹ̀ fún ọ fún ọrẹ ₦80.” Ṣàlàyé pé ìwọ yóò pa dà wá láti gbọ́ ohun tí yóò sọ lórí ohun tí ó bá kà.
5 O lè mú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rẹ àkọ́kọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ kan nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ òbí òun ọmọ tẹ̀ síwájú nípa sísọ báyìí:
◼ “Mo mọrírì ọkàn ìfẹ́ tí o fi hàn nínú ìjẹ́pàtàkì níní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rere láàárín ìdílé rẹ. Kí ni o lè sọ pé ó jẹ́ kókó pàtàkì jù lọ tí ó yẹ kí àwọn òbí àti ọmọ jíròrò?” Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé Ayọ̀ Ìdílé sí ojú ìwé 68, kí o sì ka ìdáhùn tí ó wà ní apá ìdajì àkọ́kọ́ ní ìpínrọ̀ 11. “Ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ ọ̀nà dídára jù lọ láti ní ìmọ̀ Ọlọ́run.” Fi ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? lọ̀ ọ́. Ṣàlàyé pé ẹ̀kọ́ 16 tí ó ní pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ pàtàkì nípa ìhìn iṣẹ́ Bíbélì. Ka ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ojú ìwé 2, kí ẹ sì jíròrò ẹ̀kọ́ kìíní pa pọ̀ lẹ́yìn náà.
6 Bí o bá pàdé òbí kan nínú iṣẹ́ ilé dé ilé, tàbí bóyá níbi ọgbà ìtura tàbí ibi ìṣeré, o lè ru ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ sókè nípa sísọ pé:
◼ “Ó dá mi lójú pé ìwọ yóò gbà pé ìṣòro gidigidi ni ọmọ títọ́ jẹ́ lónìí. Kí ni o rò pé ó lè dáàbò bo ìdílé rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn agbára ìdarí tí ń sọni dìbàjẹ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn ìmọ̀ràn yíyè kooro mélòó kan tí mo mọrírì rèé.” Sọ àkàwé tí ó wà ní ìpínrọ̀ 1, kí o sì ka ìpínrọ̀ 2 ní ojú ìwé 90 nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé. Ṣàlàyé bí ó ṣe ń fúnni ni ìdarí wíwà déédéé tí ó gbéṣẹ́ ní ti gidi láti dáàbò bo àwọn ìdílé kúrò lọ́wọ́ àwọn agbára ìdarí tí ń pani run. Yọ̀ǹda láti fi ẹ̀dà kan sílẹ̀ fún ọrẹ ₦80, kí o sì mú ara rẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tí ó bá dìde.
7 Nígbà ìbẹ̀wò rẹ ẹlẹ́ẹ̀kejì sọ́dọ̀ òbí kan tí ó gba ìwé “Ayọ̀ Ìdílé,” o lè máa bá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nìṣó lọ́nà yí:
◼ “Nígbà tí a kọ́kọ́ pàdé, mo rí i pé o bìkítà ní ti gidi nípa àwọn ọmọ rẹ, o sì fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí tí kò tọ́. Bóyá o kò tí ì kà á, ṣùgbọ́n àkíyèsí pàtàkì gidi kan wà tí a ṣe nínú ìwé tí mo fi sílẹ̀ fún ọ tí ó yẹ kí o rí. [Ka ìpínrọ̀ 19 ní ojú ìwé 59.] Mímú ipò ìbátan kan dàgbà pẹ̀lú Ọlọ́run ń béèrè pé kí a mọ̀ ọ́n nípasẹ̀ àwọn ojú ìwé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, Bíbélì. Ìwọ yóò ha fẹ́ kí n fi bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan hàn ọ́ bí?”
8 Àwọn olùgbani-nímọ̀ràn ayé kò lè fi ọ̀nà ayọ̀ han àwọn ìdílé, ṣùgbọ́n ó dájú pé wọn óò já wọn kulẹ̀ ni. Ẹ jẹ́ kí a fún ìwé Ayọ̀ Ìdílé ní ìpínkiri tí ó pọ̀ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run baà lè ran àwọn ènìyàn níbi gbogbo lọ́wọ́ láti ní ọjọ́ ọ̀la wíwà pẹ́ títí.—1 Tím. 6:19.