Fi Ìwé Ayọ̀ Ìdílé Lọ Tàgbàtèwe
1 Ọmọdékùnrin ọlọ́dún mọ́kànlá kan láti California fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ó kọ̀wé pé: “Mo kún fún ìmoore nítorí rẹ̀, mo sì ń fún àwọn ìdílé yòókù níṣìírí láti ka ìwé yìí nítorí ó tayọ lọ́lá. Ó . . . ń ran ìdílé mi lọ́wọ́ láti rí àlàáfíà àti ayọ̀ nínú ilé wa.” Ó yẹ kí ìrírí èwe yìí fún wa níṣìírí láti fi ìwé Ayọ̀ Ìdílé lọ tàgbàtèwe. Àwọn àbá kan nìyí tí ó ṣeé ṣe kí o fẹ́ láti gbìyànjú wò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní oṣù February.
2 Bí o bá bá ọ̀dọ́ kan pàdé, o lè sọ pé:
◼ “Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń ronú nípa ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bi wọ́n bóyá wọ́n ṣe tán láti ṣègbéyàwó tàbí wọn kò ṣe tán, ọ̀pọ̀ sọ pé kò dá àwọn lójú. Jẹ́ kí ń fi ohun tí ìwé àmúléwọ́ yìí sọ nípa kókó ẹ̀kọ́ yìí hàn ọ́.” Ṣí ìwé Ayọ̀ Ìdílé sí ojú ìwé 14, kí o sì ka ìpínrọ̀ 3. Lẹ́yìn náà, tọ́ka sí ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan nínú orí náà. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a máa ń fi í sóde, kí o sì ṣètò láti padà lọ.
3 Nígbà tí o bá ń bá òbí kan sọ̀rọ̀, o lè sọ pé:
◼ “A ń bá àwọn òbí ṣàjọpín àwọn ìlànà gbígbéṣẹ́ tí ó wúlò ní ti gidi nínú títọ́ àwọn ọmọ. A ti ṣàkójọ ìwọ̀nyí sínú ìwé àmúléwọ́ yìí, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.” Ṣí ìwé náà sí ojú ìwé 55. Ka ìpínrọ̀ 10, lẹ́yìn náà ka Diutarónómì 6:6, 7, tí ó wà ní ìpínrọ̀ 11. Lẹ́yìn náà, tọ́ka sí àwọn gbólóhùn tí a fi àwọn lẹ́tà wínníwínní kọ ní ìpínrọ̀ 12 sí 16. Máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ nípa sísọ pé: “Ìwé yìí ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí gidigidi gẹ́gẹ́ bí òbí. Bí o bá fẹ́ láti kà á, inú mi yóò dùn láti fi ẹ̀dà yìí sílẹ̀ fún ọ ní ọrẹ ₦55 (ẹlẹ́yìn rírọ̀, ₦50).”
4 Bí o bá ń bá àgbàlagbà sọ̀rọ̀, o lè sọ pé:
◼ “Nígbà tí mo bá ka àlàyé kúkúrú yìí tán, kí ẹ jọ̀wọ́ sọ èrò yín fún mi.” Ṣí ìwé Ayọ̀ Ìdílé sí ojú ìwé 169 kí o sì ka gbólóhùn méjì àkọ́kọ́ ní ìpínrọ̀ 17. Lẹ́yìn náà, sọ pé kí ó fèsì. Lójú ìwòye ohun tí ó bá jẹ́ èsì rẹ̀, o lè túbọ̀ ṣàyọkà láti inú ìwé náà kí o tó fi lọ̀ ọ́.
5 Nígbà tí o bá ń padà ṣiṣẹ́ lórí ìwé Ayọ̀ Ìdílé tí o fi sóde, fi í sọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó lè bẹ̀rẹ̀ ní Ẹ̀kọ́ 8 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí orí 15 nínú ìwé Ìmọ̀. Ní àkókò yìí, ẹ jẹ́ kí a sakun láti ran tàgbàtèwe lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé ìdílé Kristẹni tí ó láyọ̀.