Tọ́jú Rẹ̀
Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá
Bí a Ṣe lè Lo Àkìbọnú Yìí
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí ti fara hàn nínú àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ti kọjá. Gbìyànjú láti lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn nígbà tó o bá ń jẹ́rìí, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ àbájáde tó dára lo máa rí. Tọ́jú àkìbọnú yìí, kó o sì máa gbé e yẹ̀ wò bó o bá ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.
O lè ru ìfẹ́ tí ẹnì kan ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sókè bó o bá sọ ohun tó o ní í sọ ní ṣókí. Béèrè ìbéèrè kan ní pàtó, kó o sì ka ìdáhùn rẹ̀ jáde ní ṣókí látinú Ìwé Mímọ́. O lè gbìyànjú àwọn àbá wọ̀nyí:
“Bó o ti ń ronú nípa ọjọ́ iwájú, ṣé tayọ̀tayọ̀ lo fi ń retí rẹ̀ àbí ó ń kọ ọ́ lóminú? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń dani lọ́kàn rú tá à ń rí lónìí àti ohun tó máa kẹ́yìn wọn.”—2 Tím. 3:1, 2, 5; Òwe 2:21, 22.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń ṣàníyàn nípa ọ̀ràn ìlera. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò yanjú gbogbo ìṣòro ìlera pátápátá?”—Aísá. 33:24; Ìṣí. 21:3, 4.
“Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìjọba kan ṣoṣo ló máa ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé níkẹyìn?”—Dán. 2:44; Mát. 6:9, 10.
“Báwo lo ṣe rò pé ipò nǹkan ṣe máa rí bó bá jẹ́ pé Jésù Kristi ló ń ṣàkóso ayé?”—Sm. 72:7, 8.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni wọ́n ń hùwà ẹ̀tanú sí nítorí ẹ̀yà wọn, bóyá torí pé wọ́n jẹ́ ọkùnrin tàbí pé wọ́n jẹ́ obìnrin, ó sì lè jẹ́ nítorí ìsìn wọn tàbí nítorí àwọ̀ wọn. Ojú wo lo rò pé Ọlọ́run fi ń wo irú ìwà ẹ̀tanú bẹ́ẹ̀?”—Ìṣe 10:34, 35.
“A mọ̀ pé Jésù Kristi ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu lọ́jọ́ tiẹ̀. Ká ní o lè sọ fún un pé kó ṣiṣẹ́ ìyanu kan sí i, èwo ni wàá ní kó ṣe?”—Sm. 72:12-14, 16.
“Àwọn ìṣòro tá à ń gbọ́ lọ́tùn-ún lósì ti sú ọ̀pọ̀ èèyàn. Ojútùú ló kù tí wọ́n ń fẹ́ gbọ́ báyìí. Àmọ́, ibo la ti lè rí ojútùú gidi sí àwọn ìṣòro wa?”—2 Tím. 3:16, 17.
“Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ Ìjọba náà tó ò ń gbàdúrà fún nínú Àdúrà Olúwa (tàbí, Baba Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run)?”—Ìṣí. 11:15.
Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀
Àwọn ìbéèrè tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sísàlẹ̀ yìí ni a fà yọ látinú àwọn àkòrí tó wà nínú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, a sì fi ojú ìwé tí a ti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan hàn:
Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? (hw 2)
Èé ṣe tí ìwà ibi fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? (hw 2)
Ǹjẹ́ a ní àwọn ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti gba Ọlọ́run gbọ́? (hw 3)
Ǹjẹ́ ìpìlẹ̀ ha wà fún níní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run? (hw 3)
Báwo la ṣe lè túbọ̀ kojú àwọn ìṣòro tó wà nínú agbo ìdílé? (hw 3)
Báwo la ṣe lè mú kí ìdílé wa wà pa pọ̀ digbí? (hw 3)
Bíbélì ha jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́ bí? (hw 3)
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀? (hw 4)
Kí ni ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá èèyàn wà fún? (hw 4)
Irú ìgbésí ayé wo lo rò pé àwọn ọmọ wa máa dojú kọ bí wọ́n bá dàgbà? (hw 4)
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe? (hw 4-5)
Ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run tẹ́ wa lọ́rùn ju ìjọba èèyàn lọ? (hw 5)
Ṣé o gbà pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí? (hw 5)
O ha rò pé a óò rí àlàáfíà tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé yìí bí? (hw 6)
Ṣé ikú lòpin gbogbo nǹkan, àbí ohunkóhun ṣì wà lẹ́yìn téèyàn bá kú? (hw 6)
Ipò wo ni àwọn òkú wà? (hw 6)
Èé ṣe tá a fi ń dàgbà di arúgbó tá a sì ń kú? (hw 6)
Ayé tí kò ní í sí ìwà ọ̀daràn yóò ha wà bí? (hw 6)
Èé ṣe tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń bẹ àwọn èèyàn wò lemọ́lemọ́? (hw 7)
Àwọn Àbá fún Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Lọni
“Láìsí àní-àní, wàá gbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn gba Ọlọ́run gbọ́. Gbogbo ẹni tó gba Ọlọ́run gbọ́ ló gbà pé ó ń béèrè ohun kan lọ́wọ́ wa. Ohun tí àwọn èèyàn kò lè fẹnu kò lé lórí ni, Kí ni Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa?” Lẹ́yìn náà, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ̀ ọ́, ṣí i sí ẹ̀kọ́ 1, kí o sì jíròrò rẹ̀.
“Bí ọ̀pọ̀ ìṣòro ṣe ń dojú kọ ìgbésí ayé ìdílé lónìí, ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ohun tó lè mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé?” Lẹ́yìn tí o bá ti gbọ́ ìdáhùn, ṣàlàyé pé nínú Bíbélì, Ọlọ́run sọ ohun náà gan-an tó lè mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé. Ka Aísáyà 48:17. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 8, kí o sì tọ́ka sí àwọn kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí tí ó pèsè ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé fún mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé. Ka àwọn ìbéèrè tí a tò lẹ́sẹẹsẹ ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà. Béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bóyá yóò fẹ́ láti mọ àwọn ìdáhùn wọn.
“Ìwé pẹlẹbẹ yìí ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tó kún rẹ́rẹ́, èyí tó kárí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ Bíbélì. Lójú ewé kọ̀ọ̀kan, wàá rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ti ń da àwọn èèyàn láàmú fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Fún àpẹẹrẹ, Kí ni ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé?” Ṣí i sí ẹ̀kọ́ 5, kí o sì ka àwọn ìbéèrè tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà. Béèrè èyí tó wu onílé jù lọ, lẹ́yìn náà kí o ka àwọn ìpínrọ̀ tó bá a mu rẹ́gí àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu. Ṣàlàyé pé kò ṣòro rárá láti rí ìdáhùn tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè yòókù bẹ́ ẹ ṣe rí ìdáhùn sí èyí tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé yẹ̀ wò yìí. Sọ fún un pé wàá padà wá láti wá jíròrò ìbéèrè mìíràn.
“Kí lo rò pé ó fa gbogbo ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́? Ṣé torí pé àwọn ọmọ kò lẹ́kọ̀ọ́ ilé ni? Àbí ohun mìíràn ló ń fà á, bóyá ká tiẹ̀ ní Èṣù ló ń darí wọn?” Jẹ́ kí ó fèsì. Bí ẹni náà bá ní Èṣù tó ń darí wọn ló fà á, ka Ìṣípayá 12:9, 12. Ṣàlàyé ipa tí Èṣù ń kó nínú mímú kí pákáǹleke túbọ̀ máa pọ̀ sí i nínú ayé. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 4, kí o sì béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bó bá ti ṣe kàyéfì rí nípa ibi tí Èṣù ti wá. Ka ìpínrọ̀ méjì àkọ́kọ́ kí o sì jíròrò wọn. Bí ó bá jẹ́ ‘àìlẹ́kọ̀ọ́ ilé’ ni ẹni náà sọ pé ó ń fa ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ nílé ẹ̀kọ́, ka 2 Tímótì 3:1-3 kí o sì tọ́ka sí àwọn ìwà tó hàn gbangba pé ó ń dá kún ìṣòro yìí. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 8, ka ìpínrọ̀ 5, kí o sì máa bá ìjíròrò náà nìṣó.
“Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu láti retí pé Ẹlẹ́dàá yóò fún wa ní ìmọ̀ tá a nílò kí ìgbésí ayé ìdílé wa lè kẹ́sẹ járí?” Lẹ́yìn tí o bá ti gbọ́ ìdáhùn, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè hàn án. Ṣí i sí ẹ̀kọ́ 8, kí o sì ṣàlàyé pé àwọn ìlànà Bíbélì wà nínú rẹ̀ fún gbogbo mẹ́ńbà ìdílé. Sọ pé wà á fẹ́ láti fi hàn án bí a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà pa pọ̀ mọ́ Bíbélì láti lè jàǹfààní tó pọ̀ gan-an.
“Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìṣòro tí a ń dojú kọ nínú ìgbésí ayé lóde òní, ṣé o rò pé àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ ní ti gidi? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọ̀pọ̀ sọ pé gbígbàdúrà máa ń fún àwọn lókun inú. [Ka Fílípì 4:6, 7.] Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan lè ronú pé àwọn àdúrà òun kò gbà. [Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 7.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣàlàyé bí àdúrà ṣe lè ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ gan-an.”
“A ti ń bá àwọn aládùúgbò wa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ọ̀pọ̀ ìsìn lóríṣiríṣi fi wà nínú ayé. Síbẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo ni Bíbélì. Lójú tìrẹ, kí ló dé tí ìdàrúdàpọ̀ nípa ìsìn fi wà? [Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 13, kí o sì ka àwọn ìbéèrè tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀.] Wàá rí àwọn ìdáhùn tó máa tẹ́ ọ lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nípa kíka ẹ̀kọ́ yìí.”
Lẹ́yìn tí o bá ti fún ẹnì kan ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, béèrè bóyá kí o ka ìpínrọ̀ kúkúrú kan fún un. Bí ó bá ní kí o kà á, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 5. Tọ́ka sí àwọn ìbéèrè tí a tò sí ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà, kí o sì ní kí ó fetí sílẹ̀ láti gbọ́ ìdáhùn sí ìbéèrè àkọ́kọ́ bí o ti ń ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́. Lẹ́yìn tí o bá ti ka ìpínrọ̀ náà, béèrè ìbéèrè kí o sì gbọ́ ìdáhùn rẹ̀. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́. Bí ó bá gbà á, ṣètò pé wàá padà wá láti wá gbọ́ ìdáhùn rẹ̀ sí àwọn ìbéèrè méjì tí ó tẹ̀ lé e ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà.
Àwọn Àbá fún Fífi Ìwé Ìmọ̀ Lọni
Pẹ̀lú Bíbélì rẹ lọ́wọ́, bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ pé: “A ń ṣàjọpín ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pẹ̀lú gbogbo ẹni tó wà ní òpópónà yín yìí lónìí. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà kà pé . . . ” Ka Jòhánù 17:3, kí o sì béèrè pé: “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí ohun tí a ṣèlérí fún wa bí a bá ní ìmọ̀ tó tọ̀nà? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ibo ni ẹnì kan ti lè rí irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀?” Lẹ́yìn tí o bá ti gbọ́ ìdáhùn, fi ìwé Ìmọ̀ hàn án, kí o sì sọ pé: “Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ tí ó lè ṣamọ̀nà wa lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó ṣe èyí nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè tó wọ́pọ̀ jù lọ táwọn èèyàn máa ń béèrè nípa Bíbélì.” Fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé náà hàn án, kí o sì béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bó bá ti ṣe kàyéfì rí nípa èyíkéyìí nínú àwọn kókó wọ̀nyẹn.
“O ha ti ṣe kàyéfì rí bóyá Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà rárá nípa àìṣèdájọ́ òdodo àti ìjìyà tó gbòde kan tàbí èyí tí àwa fúnra wa pàápàá ń nírìírí rẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé yóò ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.” Ka díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Sáàmù 72:12-17. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 8, kí o sì ṣàlàyé pé ó pèsè ìdáhùn tí ń tuni nínú sí ìbéèrè kan tí àìmọye èèyàn ti ń béèrè, Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? Bó bá ṣeé ṣe, jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ní ìpínrọ̀ 3 sí 5, tàbí kí o ṣe èyí nígbà ìpadàbẹ̀wò.
“Ọ̀pọ̀ nínú wa ti pàdánù àwọn olólùfẹ́ wa nínú ikú. O ha ti ṣe kàyéfì rí bóyá a óò tún rí wọn mọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jésù fẹ̀rí hàn pé ó ṣeé ṣe láti mú kí àwọn olólùfẹ́ wa tó ti kú padà bọ̀. [Ka Jòhánù 11:11, 25, 44.] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ó jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí láti ṣe fún wa.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí àwòrán tó wà ní ojú ìwé 85, kí o sì ka àkọlé orí àwòrán náà. Lẹ́yìn náà, fi àwòrán tó wà ní ojú ewé 86 hàn án, kí o sì ṣàlàyé rẹ̀. Ṣètò ìpadàbẹ̀wò tí yóò tẹ̀ lé e sílẹ̀ nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé wàá fẹ́ láti mọ ìdí tí àwa ẹ̀dá èèyàn fi ń dàgbà di arúgbó tí a sì ń kú?” Padà lọ láti jíròrò orí 6.
“Ṣé o ti fìgbà kan rí ronú nípa ìdí tí àwa ẹ̀dá èèyàn fi máa ń yán hànhàn fún ẹ̀mí gígùn?” Lẹ́yìn tí o bá ti gbọ́ ìdáhùn, ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 6, kí o sì ka ìpínrọ̀ 3. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Nípa títọ́ka sí àwọn ìbéèrè méjì tí a tọ́ka sí ní ìparí ìpínrọ̀ náà, béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bí òun yóò bá fẹ́ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà fúnra rẹ̀. Bí ó bá dáhùn dáadáa, jíròrò àwọn ìpínrọ̀ díẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Nípa títọ́ka sí àwọn ìbéèrè méjì tí a tọ́ka sí ní ìparí ìpínrọ̀ náà, béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bí òun yóò bá fẹ́ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà fúnra rẹ̀. Bí ó bá dáhùn dáadáa, jíròrò àwọn ìpínrọ̀ díẹ̀ tó tẹ̀ lé e.
“A ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bí wọ́n bá gba ọ̀rọ̀ yìí gbọ́ . . . ” Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:1, kí o sì béèrè pé: “Ṣé o gbà pé òótọ́ ni gbólóhùn yìí?” Bí ẹni náà bá gbà bẹ́ẹ̀, sọ pé: “Èmi náà gbà á gbọ́ pẹ̀lú. Àmọ́ ṣá o, ṣé o rò pé bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, òun náà ló fa gbogbo ìwà ibi?” Lẹ́yìn tí o bá gbọ́ bí ẹni náà ṣe fèsì, ka Oníwàásù 7:29. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 8, kí o sì ka ìpínrọ̀ 2. Bó bá ní òun kò gba Jẹ́nẹ́sísì 1:1 gbọ́, rọ̀ ọ́ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ.—Wo ìwé Reasoning, ojú ìwé 84 sí 89.
“O ha gbà pé bí ìlànà ìwà rere ṣe ń yí padà lọ́nà tó yára kánkán lónìí, a nílò amọ̀nà tó ṣeé gbára lé nínú ìgbésí ayé? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ni ìwé tó lọ́jọ́ lórí jù lọ, ó pèsè ìmọ̀ràn tó wúlò fún ìgbé ayé òde òní àti bí ìdílé ṣe lè jẹ́ aláyọ̀.” Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 2, ka ìpínrọ̀ 10 àti ìlà àkọ́kọ́ ní ìpínrọ̀ 11, kí o sì ka 2 Tímótì 3:16, 17.
“Ṣé wàá fẹ́ láti mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wa àti sí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì lo ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo láti ṣàkópọ̀ ọjọ́ ọ̀la wa. Ọ̀rọ̀ náà ni Párádísè! Ibẹ̀ ni Ọlọ́run fi tọkọtaya ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ sí lẹ́yìn tí ó dá wọn. Kíyè sí àpèjúwe yìí nípa bí ó ti ṣeé ṣe kí Párádísè náà rí nígbà yẹn.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ewé 8, kí o sì ka ìpínrọ̀ 9 lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Ìwàláàyè nínú Párádísè.” Lẹ́yìn náà, jíròrò àwọn kókó tí ó wà ní ìpínrọ̀ 10, kí o sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, ìyẹn Aísáyà 55:10, 11. Sọ pé wàá padà wá láti máa bá ìjíròrò náà nìṣó nípa bí ìgbésí ayé nínú Párádísè tí a óò mú bọ̀ sípò ṣe máa rí, nínú ìpínrọ̀ 11 sí 16.
Nígbà tí o bá padà lọ bẹ àwọn tí o fún ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! wò, o lè sọ pé:
“Nígbà tí mo wá síbí kẹ́yìn, mo láyọ̀ láti fún ọ ní ẹ̀dà kan ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Bóyá o ti ṣàkíyèsí pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọlé ìwé àtìgbàdégbà yìí ni Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. Lónìí, màá fẹ́ láti ṣàlàyé ohun tí Ìjọba yìí jẹ́ àti ohun tí ó lè ṣe fún ìwọ àti ìdílé rẹ.” Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 6, kà á kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ẹni náà bí ó bá ti lè fàyè sílẹ̀ tó.
“Mo bẹ̀ ọ́ wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo sì fún ọ ní àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àwọn ìwé ìròyìn yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Bíbélì àti ìtọ́sọ́nà tó ń fúnni nípa ìwà rere. Mo padà wá láti fi ohun kan hàn ọ́ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí mo rò pé ó ṣe pàtàkì fún olúkúlùkù wa láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ hàn án, kí o sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́.
Nígbà tí o bá ń fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 tó ti pẹ́ lọni, o lè lo ìgbékalẹ̀ yìí:
“A mọ̀ pé àwọn èèyàn máa ń fojú tó ṣe pàtàkì wo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ojúlówó. Lójú tìrẹ, irú ẹ̀kọ́ wo lo rò pé ẹnì kan lè máa lépa tí yóò fún un láyọ̀ tó ga jù lọ, tí yóò sì lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun ti ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Òwe 9:10, 11.] Bíbélì la gbé ìwé yìí kà [dárúkọ ìwé tó o fẹ́ fi lọ̀ ọ́]. Ó sọ orísun ìmọ̀ kan ṣoṣo tó lè sìn wá lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.” Fi àpẹẹrẹ kan ní pàtó han ẹni náà nínú ìwé yìí, kí o sì fún un níṣìírí láti kà á.
Àwọn Ìtẹ̀jáde Mìíràn
Wo inú àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ti kọjá láti rí àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá fún àwọn ìwé àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ mìíràn ní àfikún sí ìwọ̀nyí.
Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni Ní Tààràtà
Láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbìyànjú lílo ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà ìyọsíni tààràtà wọ̀nyí:
“Ǹjẹ́ o mọ̀ pé láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ péré, o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì kan nínú Bíbélì? Fún àpẹẹrẹ, . . . ” Lẹ́yìn náà, béèrè ìbéèrè kan tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, èyí tó o rò pé ẹni náà á nífẹ̀ẹ́ sí.
“Mo yà síbí láti fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ bí a ṣe ń bá àwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ hàn ọ́. Mi ò ní lò ju ìṣẹ́jú márùn-ún láti fi í hàn ọ́. Ṣé o lè yọ̀ǹda ìṣẹ́jú márùn-ún fún mi?” Bó bá ní àyè wà, lo ẹ̀kọ́ Kìíní nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè láti fi bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti rí hàn án, kí o ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì péré tí o yàn. Lẹ́yìn náà, béèrè pé: “Ìgbà wo lo tún máa lè yọ̀ǹda nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ká lè parí ẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé èyí?”
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní Bíbélì, ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ̀ pé ó dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì tí gbogbo wá ń béèrè nípa ọjọ́ iwájú wa. Nípa lílo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí [ìyẹn ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀] fún nǹkan bíi wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, o lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ Bíbélì láàárín oṣù díẹ̀ péré. Inú mi á dùn láti fi bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe máa ń rí hàn ọ́.”
“Mo wá sọ́dọ̀ rẹ láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí à ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́ lọ̀ ọ́. Bó o bá gbà mí láyè, màá fẹ́ láti lo ìṣẹ́jú díẹ̀ péré láti fi hàn ọ́ bí àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè tó ju igba [200] lọ ṣe ń jíròrò Bíbélì nínú ilé wọn gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ìdílé. A lè gbé ìjíròrò wa ka èyíkéyìí nínú àwọn àkòrí wọ̀nyí. [Fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé Ìmọ̀ hàn án.] Èwo lo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ?” Fún un láyè láti yan èyí tó wù ú. Ṣí ìwé náà sí orí tí onílé yàn, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́.
“Mo máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìgba kọ́bọ̀, mo sì máa ń rí àyè láti bá àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ sí i kẹ́kọ̀ọ́. Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ni a máa ń lò. [Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án.] Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kì í gbà ju oṣù díẹ̀ péré lọ, ó sì máa dáhùn irú àwọn ìbéèrè bí: Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? Èé ṣe tí a fi ń darúgbó tí a sì ń kú? Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú? Àti, báwo la ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run? Ṣé kí a jíròrò ẹ̀kọ́ kan péré láti fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà hàn ọ́?”
Bí o bá ti ní ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tó gbéṣẹ́, tó sì ń yọrí sí rere, tó ń ru ìfẹ́ àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sókè, gbìyànjú láti máa lò ó nìṣó! Kó o kàn wá mú kí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà bá ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi ń lọni ní oṣù lọ́ọ́lọ́ọ́ mu.