Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní tí a tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1987. February: Ìṣípayá-Òtéńté Rẹ̀ Títóbilọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! tàbí ìwé olójú ewé 192 mìíràn tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ ju èyí tá a dárúkọ yìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o sì ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Kí gbogbo akéde tó ti ṣèrìbọmi tó bá wà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ January 14 gba káàdì Advance Medical Directive/Release, kí wọ́n sì gba Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ wọn.
◼ Society ń fẹ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ bí àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ (mechanical engineers), àwọn tó mọ̀ nípa ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà (computer programmers), àwọn ẹnjiníà tó mọ̀ nípa ohun abánáṣiṣẹ́ (electronic engineers), àwọn ayàwòrán ilé (architects), àwọn ẹnjiníà tó mọ̀ nípa ìgbékalẹ̀ ilé (civil and structural engineers), àwọn sọ̀fíọ̀ oníṣirò (quantity surveyors), àti àwọn ọ̀jáfáfá nínú iṣẹ́ ìkọ́lé (building technologists). Kí gbogbo àwọn wọ̀nyí ní ìwé-ẹ̀rí yunifásítì tàbí ìwé ẹ̀rí mìíràn tó bá ti yunifásítì dọ́gba. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mìíràn tá a tún ń fẹ́ ni àwọn awakọ̀, àwọn tó lè fi ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì tún un ṣe (machinists), àti àwọn tó lè lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé (press operators). Kí ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀ pé òun tóótun, tó sì fẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì kọ̀wé sí Society, kó béèrè fún fọ́ọ̀mù iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, àyàfi tó bá jẹ́ pé ó ti gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní àpéjọpọ̀ àgbègbè. Àwọn tí kò tí ì ṣègbéyàwó tàbí tọkọtaya tí kò sọ́mọ tí wọ́n ń tọ́jú ni kó kọ̀wé, kí wọ́n sì lè yọ̀ǹda ara wọn láti wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, tàbí ó pẹ́ tan láti March 3, àsọyé tuntun tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ fún gbogbo èèyàn yóò jẹ́, “Rírí Ààbò Nínú Ayé Eléwu.”
◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní ọjọ́ Thursday, March 28, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ lágbègbè yín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, èyí lè má ṣeé ṣe ní gbogbo ìgbà. Níbi tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ló jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè gba ilé mìíràn láti lò ní àṣálẹ́ yẹn. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, a dábàá pé ó kéré tán, kí àlàfo ogójì ìṣẹ́jú wà láàárín àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kí gbogbo ìjọ lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ayẹyẹ náà, kí àkókò lè wà láti kí àwọn àlejò, kí a sì lè fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi ìfẹ́ hàn níṣìírí. Ó yẹ kí a ronú nípa ọ̀ràn ọkọ̀ àti ibi tí a óò gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò àti gbígbé èrò. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ ní àdúgbò wọn.
◼ A ti fi ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2002 ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ. Kí àwọn ìjọ tí kò bá rí tiwọn gbà kí oṣù January tóó parí béèrè fún un. Kí wọ́n fi ìwé ìbéèrè wọn ránṣẹ́ sí: Shipping Office.
◼ Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyè si pé Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2003 yóò jẹ́ ní Wednesday, April 16, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. A tètè fi tó yín létí kí àwọn arákùnrin lè ṣètò tó bá yẹ láti wá gbọ̀ngàn tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí ó bá lọ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìjọ ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, tó sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́dọ̀ wá gbọ̀ngàn mìíràn. Kí àwọn alàgbà ṣàdéhùn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ gbọ̀ngàn náà láti rí i dájú pé kò ní sí àwọn mìíràn tí yóò ṣe nǹkan tí yóò ṣèdíwọ́ nínú gbọ̀ngàn náà kí ṣíṣe Ìṣe Ìrántí lè lọ wọ́ọ́rọ́wọ́ ní àlàáfíà àti létòlétò. Nítorí bí àṣeyẹ náà ti ṣe pàtàkì tó, bí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá fẹ́ yan ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ Ìṣe Ìrántí, kí wọ́n yan ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó tóótun jù lọ dípò kí wọ́n máa tò ó láàárín ara wọn tàbí dípò kí wọ́n máa lo arákùnrin kan náà ní gbogbo ọdún. Àyàfi bí ó bá jẹ́ pé alàgbà dídáńgájíá kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró wà tó lè sọ àsọyé náà.