“Ya Ohun Kan Sọ́tọ̀ Gedegbe”
Nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí, àwọn àìní nípa ti ara wà tí wọ́n ní láti fún ní àfiyèsí. Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti láásìkí sí ni a ṣe rọ̀ wọ́n láti “ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe” gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá láti fi bójú tó àwọn ohun tí wọ́n nílò wọ̀nyẹn. (1 Kọ́r. 16:1-3) Ìwà ọ̀làwọ́ wọn ló mú kí inú gbogbo wọn dùn, wọ́n sì fi “ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run.”—2 Kọ́r. 9:11, 12.
Lónìí, iṣẹ́ tí àwa èèyàn Jèhófà ń ṣe kárí ayé ń gbòòrò sí i, èyí sì ń béèrè fún ìtìlẹ́yìn owó tó túbọ̀ ń ga sí i. Ohun tó dára ni pé kí àwa pẹ̀lú máa “ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe” láti máa fi ṣètìlẹ́yìn déédéé. (2 Kọ́r. 8:3, 4) Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà fi àwọn ohun ìní wa ṣètọrẹ. (Wo Ilé Ìṣọ́ November 1, 2001, ojú ìwé 28 àti 29.) Lọ́nà tó tọ́, a ń wo èyí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní pàtàkì kan èyí tó ń fúnni láyọ̀ tòótọ́.—Ìṣe 20:35.