MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Kí Kálukú Yín Ya Ohun Kan Sọ́tọ̀”
Kò yẹ ká dúró di ìgbà tá a bá ní nǹkan rẹpẹtẹ ká tó fowó ṣe ìtìlẹyìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé látìgbàdégbà “kí kálukú yín ya ohun kan sọ́tọ̀.” (1Kọ 16:2) Tá a bá ń ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí, á jẹ́ ká láyọ̀ bá a ṣe ń ti iṣẹ́ Jèhófà lẹ́yìn. Jèhófà mọyì ohunkóhun tá a bá fi ti iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn, kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé ohun tá a fi ṣe ìtìlẹyìn kò tó nǹkan.—Owe 3:9.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ ṢEUN TẸ́ Ẹ YA OHUN KAN SỌ́TỌ̀, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ TẸ̀ LÉ E YÌÍ:
Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ya iye kan sọ́tọ̀ láti fi ṣètìlẹyìn?
Kí ni àwọn kan ṣe kí wọ́n lè “ya ohun kan sọ́tọ̀”?