ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 November ojú ìwé 3
  • “Ẹ Sọ Ọ́ Di Àṣà Láti Máa Fúnni”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Sọ Ọ́ Di Àṣà Láti Máa Fúnni”
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Torí Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ̀ Ń Fi Hàn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • “Kí Kálukú Yín Ya Ohun Kan Sọ́tọ̀”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • ‘Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 November ojú ìwé 3
Arábìnrin àgbàlagbà kan ń fi fóònù rẹ̀ ṣètọrẹ lórí ìkànnì. Àwòrán: Onírúurú ọ̀nà tá à ń gbà lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ. 1. Iṣẹ́ ìtẹ̀wé ní Bẹ́tẹ́lì. 2. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. 3. Àtẹ tá a fi ń wàásù níbi térò pọ̀ sí. 4. Iṣẹ́ ìkọ́lé.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Ẹ Sọ Ọ́ Di Àṣà Láti Máa Fúnni”

Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí ọ̀làwọ́ máa ń ranni. (Lk 6:38) Tó o bá jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa fúnni, ìyẹn máa mú káwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin náà máa fúnni.

Apá kan lára ìjọsìn wa ni pé ká máa fúnni látọkàn. Jèhófà máa ń kíyè sí àwọn tó lawọ́, tó sì máa ń ran àwọn ará tó ṣaláìní lọ́wọ́. Ó ṣèlérí pé òun máa san wọ́n lẹ́san.​—Owe 19:17.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ A MỌRÍRÌ Ẹ̀MÍ Ọ̀LÀWỌ́ YÍN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo la ṣe ń lo owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ láti ran àwọn rán wa lọ́wọ́?

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dáwọ́ àtimáa fúnni dúró yálà ohun tá a ní pọ̀ tàbí kéré?​—Tún wo àpilẹ̀kọ náà, “Ohun Tó Ṣẹ́ Kù Níbì Kan Ń Dí Àìtó Àwọn Míì” lórí Ìkànnì jw.org.

MỌ PÚPỌ̀ SÍ I LÓRÍ ÌKÀNNÌ

Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé? Tẹ ìlujá “Donations” tó wà nísàlẹ̀ ibi tó o máa kọ́kọ́ rí tó o bá ṣí JW Library®. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wàá rí ìlujá kan tá a pè ní Ìbéèrè Tó Wọ́pọ̀. Tó o bá tẹ̀ ẹ́, á gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tá a pè ní Donations to Jehovah’s Witnesses​—Frequently Asked Questions.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́