ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/02 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 28
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 4
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 1/02 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 14

Orin 3

13 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

22 min: Jíjàǹfààní Látinú Àwọn Ìṣètò Onínúure. Alàgbà kan tí ó tóótun ni kó sọ ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà àsọyé. Kí ó ṣàlàyé nípa àwọn ìṣètò tá a ti gbé kalẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó jẹ mọ́ ìtọ́jú ìṣègùn. Àwọn ìṣètò ọ̀hún ni káàdì Advance Medical Directive/Release, Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ tí kò tíì ṣe batisí tí àwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ti ṣe batisí, àti àwọn àpilẹ̀kọ “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2000, àti October 15, 2000. Kí ìjọ ní káàdì Advance Medical Directive/Release àti Identity Card tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. A óò fún àwọn akéde tí wọ́n ti ṣe ìrìbọmi ní káàdì yìí bí ìpàdé tòní bá ti parí, ṣùgbọ́n kí ẹ MÁ ṢE buwọ́ lù ú lónìí. Lẹ́yìn ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ń bọ̀ ni a ó buwọ́ lu àwọn káàdì yìí, tí a óò jẹ́rìí sí wọn, tí a ó sì kọ déètì sí i, tí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yóò sì ṣèrànwọ́ bó bá pọn dandan. Kí àwọn tí ń buwọ́ lu káàdì náà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí jẹ́ kí ẹni tí ó ni káàdì náà buwọ́ lù ú níṣojú wọn. Àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lè ṣe káàdì tiwọn, tí àwọn àtàwọn ọmọ wọn yóò máa lò, nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú káàdì yìí kọ láti bá ipò wọn àti ìgbàgbọ́ wọn mu. Tẹnu mọ́ ọn pé ó bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn ará ti ṣe àwọn ìpinnu tó jẹ mọ́ ìtọ́jú ìṣègùn ṣáájú ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́.—Òwe 14:15; 27:12.

Ó ṣe pàtàkì pé ká ti jíròrò ṣáájú pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn, kí a ṣe àlàyé yékéyéké nípa irú ìtọ́jú ìṣègùn àti oògùn tí a óò fẹ́ láti tẹ́wọ́ gbà. Ó yẹ ká ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tá a fẹ̀sọ̀ ṣe ká ba lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ka àwọn ìpínrọ̀ tó ṣe wẹ́kú látinú àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tá a mẹ́nu kàn lókè. Àwọn alàgbà múra tán láti ṣèrànwọ́, àmọ́ ṣá o, tiwọn kọ́ ni láti ṣèpinnu fún àwọn mìíràn. Ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tá a lè gbà pèsè àkọsílẹ̀ tó péye nípa àwọn ìpinnu wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

10 min: “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn.” Kí a ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ January 15 àti Jí! January 8 lọni. Rọ gbogbo àwọn akéde láti ṣètìlẹyìn fún Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn.

Orin 55 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 21

Orin 104

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Jíròrò àpótí náà, “Ya Ohun Kan Sọ́tọ̀ Gedegbe.”

13 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́? Ìjíròrò láàárín ìdílé láti mú kí àǹfààní tí wọ́n á máa jẹ látinú ìjíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ wọn pọ̀ sí i. Wọ́n ṣàyẹ̀wò Ilé Ìṣọ́ December 15, 1996, ojú ewé 18, ìpínrọ̀ 13 àti 14. Ní ṣókí, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta tí a gbé yẹ̀ wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí, kí o sì ṣàlàyé bí ìsọfúnni náà ti ṣàǹfààní gidigidi. Tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí ṣíṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ jẹ́ apá kan ètò tí ìdílé ṣe fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, èyí tí ó wà fún mímú wọn wà lójúfò nípa tẹ̀mí.

22 min: “Fi Ìjọba Náà Sí Ipò Àkọ́kọ́.”a Fi àwọn ìbéèrè díẹ̀ kún un látinú àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 1998, ojú ewé 19 sí 21.

Orin 168 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 28

Orin 196

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù January sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ewé 8, ṣàṣefihàn ṣókí méjì nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni, kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ February 1, kí èkejì sì lo Jí! February 8. Mẹ́nu kan àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February, kí o sọ àwọn ìwé tí ìjọ ní lọ́wọ́.

20 min: “Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló.”b Fi àwọn àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ April 15, 1998, ojú ewé 32. Ké sí àwọn òbí láti sọ àwọn àbájáde rere tí wọ́n ti ní nítorí títètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí láti ìgbà ọmọdé jòjòló.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Ké sí àwọn akéde láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní nípa lílo ìwé Reasoning, fífi àwọn ìwé pẹlẹbẹ pàtó kan lọ àwọn èèyàn láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọn, tàbí fífún àwọn èèyàn ní ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́ nípasẹ̀ lílo ìwé pẹlẹbẹ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. O lè ṣe àṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn ìrírí náà.

Orin 202 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 4

Orin 212

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

17 min: “Báwo Ni Wọn Yóò Ṣe Gbọ́?”c Sọ pé kí àwùjọ sọ bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe gbéṣẹ́. Fi àwọn ìbéèrè tí ó wà fún ìpínrọ̀ 17 àti 18 ní ojú ewé 20 nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 1998, kún un.

20 min: “Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Àkìbọnú yìí ní àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá nínú tí wọ́n ti fara hàn nínú àwọn ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ti kọjá, àti àwọn kan tó jẹ́ tuntun. Àwọn ìlà òf ìfo tó wà nínú rẹ̀ ni a lè lò fún ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn àbá mìíràn tó lè fara hàn lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n lè gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìjọ. Ké sí àwùjọ láti sọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ àti ìdí tí wọ́n fi máa ń lò ó. Ṣàṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a lè lò pẹ̀lú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fẹ́ fi lọni ní oṣù February. Rọ gbogbo àwọn akéde láti tọ́jú àkìbọnú yìí, kí wọ́n sì máa gbé e yẹ̀ wò látìgbà dégbà bí wọ́n bá ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.

Orin 224 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́