‘Báwo Ni Wọn Yóò Ṣe Gbọ́?’
1 Jésù sọ gbangba pé: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Láìfi ìsapá wa aláápọn pè, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ṣì wà tí a kò tíì wàásù fún. Àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan fòfin de iṣẹ́ wa. Àwọn olùgbé sì ń yára pọ̀ sí i ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Nítorí náà, ‘báwo ni wọn yóò ṣe gbọ́?’—Róòmù 10:14.
2 Ní Ìgbọ́kànlé Nínú Jèhófà: A ní láti rántí pé Jèhófà mọ bí ọkàn gbogbo èèyàn ṣe rí. Irú ipò yòówù kí ẹnì kan wà, bí ó bá fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ nípa Ọlọ́run, yóò rí i.—1 Kíró. 28:9.
3 Ábúráhámù ṣàníyàn nípa àwọn olùgbé Sódómù àti Gòmórà. Àmọ́, Ọlọ́run mú un dá a lójú pé òun kò ní pa Sódómù run kódà bí ó bá jẹ́ èèyàn olódodo mẹ́wàá ni òun rí níbẹ̀. (Jẹ́n. 18:20, 23, 25, 32) Jèhófà kò pa àwọn olódodo run pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni ibi rí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i tó pèsè ààbò fún Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀.—2 Pét. 2:6-9.
4 Èlíjà ronú nígbà kan rí pé òun nìkan ṣoṣo gíro ni òun ń sin Ọlọ́run tòótọ́ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà mú kó dá a lójú pé kì í ṣe òun nìkan ṣoṣo ló ṣẹ́ kù àti pé iṣẹ́ tó dáwọ́ lé yóò parí. (1 Ọba 19:14-18) Báwo lọ̀ràn ti rí lọ́jọ́ wa?
5 Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run: A ò mọ bí iṣẹ́ ìjẹ́rìí tá a ṣì máa ṣe á ṣe gbòòrò tó. Jèhófà ló ni iṣẹ́ yìí ó sì ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti bójú tó o. (Ìṣí. 14:6, 7) Òun ni ẹni tí yóò pinnu bí iṣẹ́ ìjẹ́rìí tá a máa ṣe fún gbogbo orílẹ̀-èdè yóò ṣe tó. Bí ó bá wu Jèhófà, ó lè mú kí a sọ ìhìn Ìjọba náà fáwọn èèyàn láwọn ọ̀nà tí a kò tiẹ̀ lè ronú kàn báyìí, kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lè “gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìn rere, kí wọ́n sì gbà gbọ́.” (Ìṣe 15:7) Ohun tí Jèhófà bá ṣe yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú irú ẹni tí ó jẹ́—Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, ọlọ́gbọ́n àti olódodo.
6 Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti máa ṣiṣẹ́ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu, ní ṣíṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti mú kí gbogbo èèyàn gbọ́ ìhìn rere náà.—1 Kọ́r. 9:16.