ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 2/1 ojú ìwé 22-30
  • “Ẹ̀rí Fún Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ̀rí Fún Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Náà Ṣe Rí ní Ọ̀rúndún Kìíní
  • Àwọn Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Tá À Ń Ṣe Lónìí
  • À Ń Sa Gbogbo Ipá Wa Láti Wàásù
  • Àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí Fún Ipò Ọba-aláṣẹ Àtọ̀runwá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • “Títí Dé Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Ìtọ́ni Jésù Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Jẹ́rìí Kúnnákúnná
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • “Ẹ Ó sì Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 2/1 ojú ìwé 22-30

“Ẹ̀rí Fún Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè”

“Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—ÌṢE 1:8.

1. Ìgbà wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn kọ́kọ́ gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Mátíù 24:14, ibo ni wọ́n sì ti gbọ́ ọ?

Ọ̀RỌ̀ Jésù tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú Mátíù 24:14 jẹ́ ohun tá a mọ̀ gan-an débi pé ọ̀pọ̀ lára wa mọ̀ ọ́n sórí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sì pabanbarì lóòótọ́! Fojú inú wo ohun tó máa wá sáwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn lọ́kàn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn! Ọdún 33 Sànmánì Kristẹni lọ̀rọ̀ yìí wáyé. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta làwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ti wà pẹ̀lú Jésù, wọ́n sì ti bá a wá sí Jerúsálẹ́mù báyìí. Wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, wọ́n sì ti fetí sáwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wọn dùn sí òtítọ́ ṣíṣeyebíye tí Jésù fi kọ́ wọn, síbẹ̀ wọ́n mọ̀ dájú pé inú gbogbo èèyàn kọ́ ló dùn sí i. Àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún láwùjọ ni ọ̀tá Jésù.

2. Kí làwọn ewu àti ìṣòro táwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn máa dojú kọ?

2 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́rin jókòó ti Jésù lórí Òkè Ólífì, wọ́n ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bó ṣe ń sọ nípa àwọn ewu tó ń bọ̀ àtàwọn ìṣòro tí wọ́n máa dojú kọ. Jésù ti sọ fún wọn ṣáájú àkókò yẹn pé àwọn èèyàn máa pa òun. (Mátíù 16:21) Ó wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ báyìí pé àwọn náà máa dojú kọ àtakò líle koko. Ó ní: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” Ìyẹn nìkan kọ́ o. Àwọn wòlíì èké yóò ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. Àwọn kan yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì da ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, wọn yóò sì kórìíra ara wọn pẹ̀lú. Kódà “ọ̀pọ̀ jù lọ” ló máa jẹ́ kí ìfẹ́ táwọn ní fún Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ di tútù.—Mátíù 24:9-12.

3. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 24:14 fi kàmàmà lóòótọ́?

3 Ẹ̀yìn ìgbà tí Jésù mẹ́nu kan àwọn nǹkan búburú tó máa ṣẹlẹ̀ yẹn ló wá sọ̀rọ̀ kan tó ní láti jẹ́ ìyàlẹ́nu fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Láìsí àní-àní, iṣẹ́ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ ní Ísírẹ́lì yẹn, tó ń “jẹ́rìí sí òtítọ́,” yóò máa bá a lọ, yóò sì dé ibi gbogbo láyé. (Jòhánù 18:37) Àsọtẹ́lẹ̀ kíkàmàmà gbáà lèyí jẹ́! Kò lè rọrùn rárá láti mú iṣẹ́ náà gbòòrò dé “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Àfi Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí iṣẹ́ náà ṣeé ṣe nítorí pé àwọn tó máa ṣe é yóò jẹ́ ẹni “ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Kì í ṣe ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti agbára rẹ̀ nìkan ni ṣíṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí láṣeyọrí máa gbé ga. Yóò tún fi bí ìfẹ́, àánú, àti sùúrù rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn. Yàtọ̀ síyẹn, yóò tún fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní láti fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ àwọn sì ń fọkàn sìn ín.

4. Àwọn wo ni Jésù sọ fún pé kó ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà, ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ló sì sọ fún wọn?

4 Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ ní kedere pé wọ́n ní iṣẹ́ pàtàkì kan láti ṣe. Kí Jésù tó gòkè lọ sí ọ̀run, ó fara hàn wọ́n, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Lóòótọ́, àwọn mìíràn máa dara pọ̀ mọ́ wọn láìpẹ́ sí àkókò yẹn. Síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà kéré níye. Ẹ wo bí ọkàn wọn ṣe máa balẹ̀ tó nígbà tí wọ́n wá mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó lágbára gan-an yóò fún àwọn lágbára láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn lọ́wọ́ yìí!

5. Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn ìjímìjí kò mọ̀ nípa iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà?

5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà mọ̀ pé àwọn ní láti wàásù ìhìn rere káwọn sì “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Àmọ́ wọn ò mọ bí àwọn ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà kúnnákúnná tó, wọn ò sì mọ ìgbà ti òpin máa dé. Èyí jẹ́ ohun kan táwa náà ò mọ̀. Jèhófà nìkan ló lè pinnu irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Mátíù 24:36) Nígbà tá a bá bá iṣẹ́ ìwàásù náà débi tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, yóò pa ètò nǹkan búburú yìí run. Ìgbà yẹn làwọn Kristẹni á tó mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà ti parí, pé àwọn sì tí ṣe é débi tí Jèhófà fẹ́ káwọn ṣe é dé. Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ìjímìjí yẹn ò lè mọ pé iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà máa gbòòrò tó báyìí lákòókò òpin yìí.

Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Náà Ṣe Rí ní Ọ̀rúndún Kìíní

6. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àti kété lẹ́yìn náà?

6 Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn yọrí sí rere gan-an ní ọ̀rúndún kìíní. Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nǹkan bí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn ló pé jọ sí yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dà sorí wọn, àpọ́sítélì Pétérù sì sọ àsọyé kan tó fakíki tó fi ṣàlàyé iṣẹ́ ìyanu náà, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún èèyàn ló di onígbàgbọ́ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Ìbẹ̀rẹ̀ ṣì nìyẹn o. Pẹ̀lú báwọn aṣáájú ìsìn ṣe pinnu láti dá ìṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà dúró tó, “Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn tí a ń gbà là dara pọ̀ mọ́ [àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà] lójoojúmọ́.” Láìpẹ́, “iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún.” Lẹ́yìn náà, “ṣe ni a ń fi àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa kún wọn ṣáá, ògìdìgbó lọ́kùnrin àti lóbìnrin.”—Ìṣe 2:1-4, 8, 14, 41, 47; 4:4; 5:14.

7. Kí nìdí tí ìyípadà Kọ̀nílíù fi jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun kan tó pabanbarì?

7 Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó jẹ́ mánigbàgbé tún wáyé lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Kọ̀nílíù, tó jẹ́ Kèfèrí yí padà tó sì ṣe ìrìbọmi. Bí Jèhófà ṣe darí àpọ́sítélì Pétérù sọ́dọ̀ ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run yìí fi hàn pé àṣẹ tí Jésù pa pé ká “sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn” kò mọ sọ́dọ̀ àwọn Júù tó wà ní onírúurú orílẹ̀-èdè nìkan. (Ìṣe 10:44, 45) Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù náà? Nígbà táwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jùdíà rí i pé ìhìn rere náà ti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù, wọ́n yin Ọlọ́run lógo. (Ìṣe 11:1, 18) Láàárín àkókò yẹn, iṣẹ́ ìwàásù náà tún ń méso jáde gan-an láàárín àwọn Júù pẹ̀lú. Lọ́dún bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ nǹkan bí ọdún 58 Sànmánì Kristẹni, “ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún [àwọn Júù ti di] onígbàgbọ́” yàtọ̀ sáwọn Kèfèrí tó jẹ́ onígbàgbọ́.—Ìṣe 21:20.

8. Báwo ni ìhìn rere náà ṣe ń nípa lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan?

8 Báwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe pọ̀ sí i wúni lórí gan-an, síbẹ̀ a ò ní gbàgbé pé àwọn èèyàn ló mú kí iye yẹn pọ̀ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ Bíbélì tí wọ́n gbọ́ lágbára gan-an. (Hébérù 4:12) Ó yí ìgbésí ayé àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á padà lọ́nà tó kàmàmà. Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó dára, wọ́n gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, wọ́n sì bá Ọlọ́run rẹ́. (Éfésù 4:22, 23) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí. Gbogbo àwọn tó ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà ló ní ìrètí àtiwà láàyè títí láé.—Jòhánù 3:16.

Àwọn Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run

9. Kí làwọn Kristẹni ìjímìjí gbà pé ó jẹ́ àǹfààní àwọn àti ojúṣe àwọn?

9 Àwọn Kristẹni ìjímìjí kò yin ara wọn pé àwọn làwọn ṣe àṣeyọrí wọ̀nyẹn. Wọ́n gbà pé “agbára ẹ̀mí mímọ́” làwọn fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù táwọn ń ṣe. (Róòmù 15:13, 19) Jèhófà ló mú kí iye àwọn èèyàn tó tẹ́wọ́ gba Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pọ̀ sí i. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn mọ̀ pé àǹfààní ló jẹ́ fáwọn, ojúṣe àwọn sì tún ni láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 3:6-9) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Jésù sọ, wọ́n sapá gidigidi láti ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́.—Lúùkù 13:24.

10. Ipa wo làwọn Kristẹni ìjímìjí kan sà láti wàásù fún gbogbo orílẹ̀-èdè?

10 Gẹ́gẹ́ bí “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lórí ilẹ̀ àti lójú òkun. Ó dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀ láwọn àgbègbè tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso ní Éṣíà àti ní ilẹ̀ Gíríìsì. (Róòmù 11:13) Ó tún rìnrìn àjò lọ sí Róòmù, ó sì ṣeé ṣe kó dé ilẹ̀ Sípéènì pàápàá. Láàárín àkókò yẹn, àpọ́sítélì Pétérù tá a “fi ìhìn rere . . . ti àwọn tí ó dádọ̀dọ́ sí ìkáwọ́” rẹ̀ náà forí lé apá ibòmíràn, ó lọ wàásù ní Bábílónì níbi táwọn Júù pọ̀ sí gan-an lákòókò yẹn. (Gálátíà 2:7-9; 1 Pétérù 5:13) Àwọn obìnrin bíi Tírífénà àti Tírífósà wà lára ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tó ṣe gudugudu méje nínú iṣẹ́ Olúwa. Obìnrin mìíràn, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pésísì, ni Bíbélì sọ pé “ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò nínú Olúwa.”—Róòmù 16:12.

11. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún ìsapá àwọn ọmọ ẹ̀yìn?

11 Jèhófà bù kún ìsapá àwọn òjíṣẹ́ wọ̀nyẹn gan-an, ó sì tún bù kún ìsapá àwọn òjíṣẹ́ mìíràn tó jẹ́ onítara. Kò tíì pé ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ẹ̀rí yóò wà fún gbogbo orílẹ̀-èdè nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé “ìhìn rere” ni a ti “wàásù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Ǹjẹ́ òpin dé nígbà yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dé lọ́nà kan. Ó dé sórí ètò nǹkan àwọn Júù lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ run. Síbẹ̀, Jèhófà ti pinnu pé a ó ṣì jẹ́ ẹ̀rí tó pọ̀ gan-an jùyẹn lọ kóun tó mú gbogbo ayé búburú ti Sátánì yìí wá sópin.

Iṣẹ́ Ìwàásù Tá À Ń Ṣe Lónìí

12. Báwo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìgbà yẹn ṣe lóye àṣẹ náà pé ká wàásù?

12 Láàrín ọdún 1850 sí ọdún 1900, ìyẹn àkókò gígùn gan-an lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti pẹ̀yìn dà kúrò nínú ìsìn tòótọ́, ìjọsìn mímọ́ tún fìdí múlẹ̀ padà. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tá a mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lóye àṣẹ tó sọ pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn ní gbogbo ayé. (Mátíù 28:19, 20) Ní ọdún 1914, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn ó lé ọgọ́rùn-ún [5,100] èèyàn ló ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, ìhìn rere náà sì ti dé orílẹ̀-èdè méjìdínláàádọ́rin [68]. Àmọ́, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ò lóye ohun tí Mátíù 24:14 túmọ̀ sí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Nígbà tó kù díẹ̀ kí ọdún 1900 wọlé dé, àwọn ẹgbẹ́ tó ń ṣe Bíbélì jáde ti túmọ̀ Bíbélì tí ìhìn rere náà wà nínú rẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èdè, wọ́n sì ti pín in káàkiri ayé. Nítorí ìdí yìí, nǹkan bí ẹ̀wádún mélòó kan làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà fi gbà pé ẹ̀rí náà ti tipa bẹ́ẹ̀ kárí gbogbo orílẹ̀-èdè nìyẹn.

13, 14. Òye tó túbọ̀ ṣe kedere wo ni ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan lọ́dún 1928 fi hàn nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé?

13 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Jèhófà wá fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní òye tó túbọ̀ ṣe kedere nípa ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe àtohun tí òun náà fẹ́ ṣe fún aráyé. (Òwe 4:18) Ilé Ìṣọ́ December 1, 1928, lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ǹjẹ́ a lè sọ pé ìpínkiri Bíbélì ti mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìwàásù ìhìn rere ìjọba náà ṣẹ? Rárá o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ti wà káàkiri síbẹ̀ ó ṣì pọn dandan káwọn kéréje tó jẹ́ ẹlẹ́rìí Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó máa ṣàlàyé [ohun tí] Ọlọ́run [fẹ́ ṣe], kí wọ́n sì tún lọ sáwọn ilé táwọn Bíbélì wọ̀nyí wà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn èèyàn kò ní mọ̀ rárá pé Ìjọba Mèsáyà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lákòókò tiwa yìí.”

14 Ilé Ìṣọ́ yẹn kan náà tún sọ pé: “Ọdún 1920, . . . làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní òye tó tọ̀nà nípa àsọtẹ́lẹ̀ tí Olúwa sọ nínú Mátíù 24:14. Wọ́n wá mọ̀ pé ‘ìhìn rere yìí’ tá a ní láti wàásù rẹ̀ ní gbogbo ayé láti jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn Kèfèrí tàbí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, kì í ṣe ìhìn rere nípa ìjọba kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa dé àmọ́ ó jẹ́ ìhìn rere tó fi hàn pé Mèsáyà Ọba ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí ayé.”

15. Báwo ni iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà ṣe ń gbòòrò láti àwọn ọdún 1920?

15 Ńṣe làwọn “kéréje tó jẹ́ ẹlẹ́rìí” láwọn ọdún 1920 yẹn ń pọ̀ sí i látìgbà náà. Àwọn ẹ̀wádún tó tẹ̀ lé e làwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” wá fara hàn tá a sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó wọn jọ. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Lónìí, nǹkan bí 6,613,829 àwọn olùpòkìkí ìhìn rere ló wà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] orílẹ̀-èdè lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ ò rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ti ní ìmúṣẹ lọ́nà tó gadabú! Kò tíì sígbà kankan rí tá a wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” lọ́nà tó gbòòrò tó báyìí. Kò tíì sígbà táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà pọ̀ tó báyìí rí lórí ilẹ̀ ayé.

16. Kí làwọn ohun tá a gbé ṣe lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá? (Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 27 sí 30).

16 Gbogbo ogunlọ́gọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí yìí ló ṣe gudugudu méje láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2005. Wọ́n fi ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí wàásù ìhìn rere náà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] orílẹ̀-èdè. Wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìpadàbẹ̀wò, wọ́n sì kọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fínnúfíndọ̀ lo àkókò wọn àti ohun ìní wọn láti sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn ló ṣe iṣẹ́ tá à ń wí yìí. (Mátíù 10:8) Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára, kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Sekaráyà 4:6.

À Ń Sa Gbogbo Ipá Wa Láti Wàásù

17. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn Jèhófà gbà ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa wíwàásù ìhìn rere náà?

17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù sọ pé a ó wàásù ìhìn rere náà, síbẹ̀ ìtara táwọn èèyàn Ọlọ́run ní fún iṣẹ́ náà kò dín kù. A mọ̀ pé tá a bá ń fi ìfaradà ṣe ohun tó dára, ńṣe là ń fi hàn pé a ní àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní, bí ìfẹ́, àánú, àti sùúrù. Bíi ti Jèhófà, àwa náà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, ńṣe la fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n sì bá Jèhófà rẹ́. (2 Kọ́ríńtì 5:18-20; 2 Pétérù 3:9) Iná ẹ̀mí Ọlọ́run tó ń jó nínú wa ló mú kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fi ìtara kéde ìhìn rere náà títí dé òpin ilẹ̀ ayé. (Róòmù 12:11) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn níbi gbogbo ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́, wọ́n sì ń mú ìgbésí ayé wọn bá ìlànà onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà là sílẹ̀ mu. Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.

18, 19. Àwọn ìrírí wo lo lè sọ nípa àwọn kan tí wọ́n fi ọkàn tó dáa gba ìhìn rere náà?

18 Àgbẹ̀ ni Charles ní ìwọ̀ oòrùn Kẹ́ńyà. Lọ́dún 1998, ó ta ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] kìlógíráàmù tábà, wọ́n sì fún un ní ìwé ẹ̀rí tó fi hàn pé òun ni Àgbẹ̀ Tó Mọ Tábà Gbìn Jù Lọ. Àkókò yẹn ló bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tó fi wá mọ̀ pé ńṣe lẹni tó bá ń gbin tábà ń ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ Jésù pé ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa. (Mátíù 22:39) Nígbà tí Charles wá rí i pé ‘àgbẹ̀ tó mọ tábà gbìn jù lọ ló ń pa àwọn èèyàn jù lọ,’ kíá ló fín oògùn tó ń pa èpò sí gbogbo tábà rẹ̀ tí wọ́n sì kú. Ó tẹ̀ síwájú dórí yíya ara rẹ̀ sí mímọ́, ó sì ṣe ìrìbọmi, ó ti di aṣáájú-ọ̀nà báyìí, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ni pẹ̀lú.

19 Kò sí àní-àní pé Jèhófà ń mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jákèjádò ayé, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra, ìyẹn àwọn èèyàn sì ń wọlé wá. (Hágáì 2:7) Pedro, tó ń gbé nílẹ̀ Potogí wọ ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé kóun di àlùfáà, kóun sì máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ nígbà tó ṣe díẹ̀, ó fi ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ nítorí pé wọn kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ wọn. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó tún lọ ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìrònú àti ìhùwà ẹ̀dá ní yunifásítì kan nílùú Lisbon. Ọ̀dọ̀ obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ àbúrò ìyá rẹ̀ ló ń gbé nígbà yẹn, ìyẹn sì máa ń gbà á níyànjú pé kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lákòókò yẹn, kò dá Pedro lójú pé Ọlọ́run wà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mọ̀ bóyá kóun kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kóun má kọ́ ọ. Ó wá lọ bi ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ nípa ìrònú àti ìhùwà ẹ̀dá pé kó sọ fóun ìdí táwọn èèyàn kan kì í fi í lè ṣèpinnu. Ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ fún un pé ohun tí ìmọ̀ nípa ìrònú àti ìhùwà ẹ̀dá fi kọ́ni ni pé àwọn tí kò lè ṣèpinnu làwọn tó gbà pé àwọn ò wúlò fún nǹkan kan. Bí Pedro ṣe pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Ẹnu àìpẹ́ yìí ló ṣèrìbọmi, òun náà ti ń kọ àwọn kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí.

20. Kí nìdí tó fi yẹ kínú wa máa dùn pé ìṣẹ́ ìjẹ́rìí náà ti dé àwọn orílẹ̀-èdè tó pọ̀ gan-an?

20 A ò tíì mọ bí ẹ̀rí tá a máa jẹ́ fáwọn orílẹ̀-èdè ṣe máa pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà la ò mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin yóò dé. Ohun tá a kàn mọ̀ ni pé yóò dé láìpẹ́. Inú wa dùn pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe káàkiri ayé jẹ́ ọkàn lára ọ̀pọ̀ àmì tó fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní pẹ́ dé láti wá rọ́pò ìjọba èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44) Bọ́dún ti ń gorí ọdún ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ń láǹfààní láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, èyí sì ń fi ògo fún Jèhófà, Ọlọ́run wa. Á dára ká pinnu láti máa jẹ́ olóòótọ́ títí lọ, ká sì jẹ́ kí ọwọ́ wa dí bí àwa àtàwọn ará wa jákèjádò ayé ṣe ń bá iṣẹ́ jíjẹ́rìí fún gbogbo orílẹ̀-èdè náà lọ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò gba ara wa àtàwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ wa là.—1 Tímótì 4:16.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí Mátíù 24:14 fi jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó pabanbarì?

• Ipa wo làwọn Kristẹni ìjímìjí sà nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

• Báwo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe wá lóye pé ó yẹ ká jẹ́rìí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè?

• Nígbà tó o wo ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Jèhófà ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, kí ló wú ọ lórí níbẹ̀?

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 27-30]

ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 2005 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ

(Wo àdìpọ̀)

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lórí ilẹ̀ àti lórí òkun láti wàásù ìhìn rere náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Jèhófà darí Pétérù láti jẹ́rìí fún Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́