Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ Jósẹ́fù tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lo ife fàdákà tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan láti fi woṣẹ́, bó ṣe jọ pé Jẹ́nẹ́sísì 44:5 sọ?
Kò sídìí kankan tó fi yẹ ká gbà pé Jósẹ́fù lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wíwò èyíkéyìí.
Bíbélì jẹ́ ká mọ bí òye Jósẹ́fù ṣe jinlẹ̀ tó nípa bí kò ṣe dára kéèyàn máa lo agbára òkùnkùn láti mọ ọjọ́ ọ̀la. Nígbà tí wọ́n sọ pé kí Jósẹ́fù túmọ̀ àlá Fáráò lákòókò kan, léraléra ló tẹnu mọ́ ọn pé kìkì Ọlọ́run nìkan ló lè “kéde” ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn ló mú Fáráò alára wá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run tí Jósẹ́fù ń jọ́sìn ni Ọlọ́run tòótọ́ tó mú kí Jósẹ́fù mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, kì í ṣe agbára òkùnkùn. (Jẹ́nẹ́sísì 41:16, 25, 28, 32, 39) Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ pidán tàbí woṣẹ́, ìyẹn sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.—Diutarónómì 18:10-12.
Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé òun ń lo ife fàdákà láti fi ‘mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́nà jíjáfáfá’?a (Jẹ́nẹ́sísì 44:5) Ó yẹ ká gbé ohun tó fà á tó fi sọ bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.
Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù rìnrìn àjò lọ sí Íjíbítì láti ra oúnjẹ nítorí ìyàn tó mú gan-an. Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yìí kan náà tà á sí oko ẹrú. Àmọ́ báyìí, wọn ò mọ̀ pé ọwọ́ àbúrò àwọn, tó ti di alábòójútó oúnjẹ nílẹ̀ Íjíbítì làwọn ti ń wá ìrànlọ́wọ́. Jósẹ́fù kò sọ ẹni tóun jẹ́ fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pinnu pé òun á dán wọn wò. Láìsí àní-àní, Jósẹ́fù fẹ́ mọ̀ bóyá wọ́n ti ronú pìwà dà lóòótọ́. Ó tún fẹ́ mọ̀ bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ Bẹ́ńjámínì àbúrò wọn àti Jékọ́bù bàbá wọn tó fẹ́ràn Bẹ́ńjámínì gan-an. Ìdí nìyẹn tí Jósẹ́fù fi lo ọgbọ́n arúmọjẹ kan.—Jẹ́nẹ́sísì 41:55–44:3.
Jósẹ́fù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí ó kó oúnjẹ kún inú àpò àwọn arákùnrin òun, kó sì dá owó wọn padà sẹ́nu àpò olúkálukú wọn, ó tún sọ pé kó fi ife fàdákà òun sẹ́nu àpò Bẹ́ńjámínì. Nígbà tí Jósẹ́fù ń ṣe gbogbo èyí, ńṣe ló kàn ń ṣe bí alábòójútó ilẹ̀ abọ̀rìṣà kan. Ó yí ìṣe àti èdè ẹnu rẹ̀ padà kó bàa lè jọ ti alábòójútó ilẹ̀ abọ̀rìṣà, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí lójú àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọn ò fura.
Nígbà tí Jósẹ́fù ko àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú, ó ń lo ọgbọ́n arúmọjẹ rẹ̀ nìṣó, ìyẹn ló mú kó bi wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé irú ènìyàn bí èmi lè mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́nà jíjáfáfá?” (Jẹ́nẹ́sísì 44:15) Nípa bẹ́ẹ̀, ó hàn kedere pé arúmọjẹ lásán ló fi ife yẹn ṣe. Bó ṣe jẹ́ pé Bẹ́ńjámínì kò jí ife náà ló ṣe jẹ́ pé Jósẹ́fù kò lo ife náà láti fi woṣẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí wọ́n pè ní The Holy Bible, With an Explanatory and Critical Commentary, tí F. C. Cook ṣàtúnṣe rẹ̀, ṣàlàyé bí wọ́n ṣe máa ń fi ife woṣẹ́ láyé ìgbàanì, ó sọ pé: “Wọ́n máa ń ṣe é yálà nípa jíju wúrà, fàdákà tàbí òkúta iyebíye sínú omi, lẹ́yìn náà, wọ́n á yẹ irú àwọ̀ tó mú jáde wò; tàbí kí wọ́n kàn wo inú omi náà bí ẹni wo jígí.” Ọ̀gbẹ́ni Christopher Wordsworth tó máa ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Nígbà mìíràn, wọ́n á da omi sínú ife náà, wọ́n á sì rí ìdáhùn nínú àwòrán tí oòrùn tó tàn sórí omi inú ife náà bá mú jáde.”