Ǹjẹ́ o Dà Bí Igi Ṣẹkẹṣẹkẹ?
NÍ ABÚLÉ kan tó wà nítòsí ìlú Port Moresby, lórílẹ̀-èdè Papua New Guinea, àwọn oníwàásù méjì kan ń padà bọ̀ wá sílé látẹnu iṣẹ́ ìwàásù wọn. Bí wọ́n ti ń bọ̀ lọ́nà, wọ́n rí igi kan tó lẹ́wà gan-an. Èyí tó dàgbà jù láàárín àwọn ọkùnrin náà sọ pé: “Áà, igi ṣẹkẹṣẹkẹ ni!” Ó wá yíjú sí ẹnì kejì rẹ̀ ó sì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Igi tó ń rú lọ́dọọdún ni. Kò dà bí ọ̀pọ̀ igi mìíràn nílẹ̀ olóoru, ọdọọdún ló máa ń wọ́wé tí yóò sì dà bíi pé ó ti kú. Àmọ́, nígbà tójò bá rọ̀, á sọjí, á sì yọ òdòdó, yóò sì tún fi ẹwà rẹ̀ hàn padà.”
A lè rí ẹ̀kọ́ kan kọ́ lára igi ṣẹkẹṣẹkẹ. Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn onímọ̀ nípa igi sọ, igi yìí wà lára àwọn igi olódòdó márùn-ún tó lẹ́wà jù lọ láyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ewé àti òdòdó rẹ̀ máa ń rẹ̀ dà nù nígbà ẹ̀rùn, igi yìí máa ń tọ́jú omi pa mọ́ sára. Gbòǹgbò igi náà lágbára gan-an, ó sì lè ta yí àwọn àpáta tó wà lábẹ́ ilẹ̀ ká. Nítorí bẹ́ẹ̀, mìmì kan ò lè mì í nígbà tí afẹ́fẹ́ líle bá ń fẹ́. Ní ṣókí, igi yìí rọ́kú nítorí pé kò sí inú ipò tí ò ti lè dàgbà.
A lè bá ara wa nínú ipò tó máa dán bí ìgbàgbọ́ wa ti lágbára tó wò. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ipò náà? Bíi ti igi ṣẹkẹṣẹkẹ, a óò máa mu omi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìyè, a ó sì máa tọ́jú omi náà pa mọ́ sọ́kàn wa. A tún gbọ́dọ̀ fìdí múlẹ̀ dáadáa nínú ‘àpáta wa,’ ìyẹn Jèhófà àti ètò rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 22:3) Ká sòótọ́, igi ṣẹkẹṣẹkẹ jẹ́ igi kan tó ń ránni létí pé nínú ipò tó le koko pàápàá, a lè jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí ká sì máa ṣe ohun tó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu tá a bá ń lo àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò “jogún àwọn ìlérí” tó ṣe fún wa, títí kan ìlérí iyè àìnípẹ̀kun.—Hébérù 6:12; Ìṣípayá 21:4.