ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/02 ojú ìwé 1
  • Fi Ìjọba Náà Sí Ipò Àkọ́kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìjọba Náà Sí Ipò Àkọ́kọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́’
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ń Ṣe Ìjọ Láǹfààní
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ṣé Ohun Ìdènà Ló Jẹ́ fún Iṣẹ́ Ìwàásù?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • “Kí Ìjọba Rẹ Dé”—Àdúrà Tí Àìmọye Èèyàn Ń Gbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 1/02 ojú ìwé 1

Fi Ìjọba Náà Sí Ipò Àkọ́kọ́

1 Fífi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ kí á sì máa bá a nìṣó kì í rọrùn bá a bá dojú kọ ìṣòro ìṣúnná owó tàbí àwọn ìṣòro mìíràn. Báwo la ṣe lè fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ nígbà tí àwọn ìṣòro bá yọjú? Ká ní wọ́n fi iṣẹ́ kan lọ̀ wá ńkọ́ èyí tó máa béèrè pé ká máa pa ìpàdé jẹ tàbí tá á máa forí gbárí pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn pápá wa? Ṣé ó yẹ kí Ìjọba náà wá bọ́ sí ipò kejì nínú ìgbésí ayé wa nígbà yẹn?

2 Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Pọn Dandan: Bí irú àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀ bá ń dán ìgbàgbọ́ wa wò, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìlérí tí Jèhófà ṣe àti ìdánilójú tí Jésù fún wa pé a óò ní ìtìlẹyìn àtọ̀runwá bí a bá wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. (Sm. 37:25; Mát. 6:31-34) Àwọn ìwà tí ń sọni dìbàjẹ́ àti ìṣòro ìgbésí ayé lè bò wá lójú kí wọ́n sì ṣèdíwọ́ fún wa láti má ṣe ka Ìjọba náà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Àwọn kan ti jẹ́ kí ìfẹ́ láti yọrí ọlá níbi iṣẹ́ tàbí láti di olówó rẹpẹtẹ di ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn. Àmọ́ ṣá o, bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó yẹ ká ṣe ìdíwọ̀n kíkún nípa ohun náà gan-an tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé.—Fílí. 3:7, 8.

3 Ṣé Ó Yẹ Ká Ṣe Àwọn Àtúnṣe Kan?: Akéde kan sọ pé: “Ìdí òwò mi ni ọkàn mi wà—òun ni ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ. Mo rò pé mo ṣì lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí bí mo tilẹ̀ ń ya èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àkókò mi sọ́tọ̀ fún òwò mi.” Àmọ́ èrò náà pé òun ṣì lè ṣe púpọ̀ sí i láti sin Jèhófà máa ń wá sí i lọ́kàn léraléra. Bí àkókò ṣe ń lọ, ó fi òwò rẹ̀ sílẹ̀, èyí tó ti jẹ́ ìdènà kan fún ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Gbàrà tó ti fara rẹ̀ jìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà, ó wá lè sọ pé: “Mo . . . nímọ̀lára nísinsìnyí pé ìgbésí ayé mi kẹ́sẹ járí lójú Jèhófà, èyí tí ó jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ.”

4 Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ ti yááfì iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó lè sọ wọ́n dolówó rẹpẹtẹ, wọ́n ti mú ìgbésí ayé wọn rọrùn, wọ́n sì ti wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ohun tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà tó jẹ́ ọ̀dọ́ àti àpọ́n tí wọ́n ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ṣe nìyí, wọ́n sì ń gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Ní fífarawé àpẹẹrẹ àtàtà ti Pọ́ọ̀lù, wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìgbẹ́mìíró tó ṣe kókó.—1 Kọ́r. 11:1; 1 Tím. 6:6-8; Héb. 13:5.

5 Bí àwọn èèyàn ayé bá tiẹ̀ ń kẹ́gàn wa nítorí ojú tí a fi ń wo ìgbésí ayé, a ní ìbùkún Jèhófà. (1 Kọ́r. 1:26-31) Ǹjẹ́ kì í fún wa níṣìírí láti mọ̀ pé òun yóò lò wá bó bá ti lè ṣeé ṣe tó tí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ rẹ̀? Àǹfààní tí a ní báyìí láti pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run tí ó ti fìdí múlẹ̀ ni a kì yóò tún ní mọ́ láé. Nítorí náà, ìsinsìnyí ni àkókò láti fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́