ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/01 ojú ìwé 8
  • Ṣé Ohun Ìdènà Ló Jẹ́ fún Iṣẹ́ Ìwàásù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ohun Ìdènà Ló Jẹ́ fún Iṣẹ́ Ìwàásù?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìwọ Ha Nífẹ̀ẹ́ Mi Ju Ìwọ̀nyí Lọ Bí?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • ‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́’
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • O Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ọwọ́ Rẹ Ha Dí Jù Bí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 9/01 ojú ìwé 8

Ṣé Ohun Ìdènà Ló Jẹ́ fún Iṣẹ́ Ìwàásù?

1 Ọwọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń dí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tí ọwọ́ wọn máa ń dí jù lọ nítorí a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a máa ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, a sì máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ní àfikún sí i, a máa ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, iṣẹ́ ilé tàbí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, àti ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ mìíràn tí gbogbo wọn sì ní àkókò tí wọ́n ń gbà. Èyí tiẹ̀ túbọ̀ ṣòro fún àwọn olórí ìdílé.

2 Nítorí ipò ọrọ̀ ajé tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure lónírúurú ibi, ó ṣeé ṣe kí ó pọndandan fún àwọn olórí ìdílé kan láti ṣiṣẹ́ àṣekára fún ọ̀pọ̀ wákàtí láti lè gbọ́ bùkátà ìdílé. Nígbà tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn bá gba ọ̀pọ̀ jù lọ lára àkókò àti okun wọn, ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló máa ń ṣẹ́ kù fún iṣẹ́ ìwàásù. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ojúṣe wọn láti pèsè nípa ti ara fún ìdílé wọn, àwọn kan lè ronú pé ìwọ̀n díẹ̀ làwọn lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Tím. 5:8) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ wàhálà ló wà nídìí rírí àwọn ohun ìgbọ́bùkátà ìgbésí ayé lóde òní. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ẹni wá di ohun ìdènà fún iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà. (Máàkù 13:10) Nítorí náà, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ipò wa gan-an.

3 Nítorí pé ìrísí nǹkan nínú ayé yìí ń yí padà ṣáá ni, ó ṣeé ṣe kí olórí ìdílé kan fẹ́ máa lo àkókò tó pọ̀ kọjá àlà níbi iṣẹ́, kí ó máa ronú pé òun fẹ́ kó owó jọ nítorí bí wàhálà àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. (1 Kọ́r. 7:31) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dà bíi pé títúbọ̀ lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ máa ń jẹ́ kí èèyàn túbọ̀ ní àwọn ohun ti ara tàbí pé ó ń pèsè àfikún àǹfààní eré ìtura àti eré ìnàjú, ṣé ìyẹn yóò mú kí ìdílé túbọ̀ láyọ̀ kí wọ́n sì túbọ̀ ní ìtẹ́lọ́rùn bí ó bá jẹ́ pé àkókò tó yẹ kí wọ́n fi ṣe nǹkan tẹ̀mí tàbí kí wọ́n fi máa lọ sí ìpàdé déédéé ni wọ́n ń lò fún un? Ó dájú pé a ní láti yẹra fún ohunkóhun tí ó lè fi ipò tẹ̀mí wa sínú ewu. Kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn Jésù pé ká ‘to ìṣúra jọ pa mọ́ ní ọ̀run’ kí á sì “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” ni ọ̀nà ọgbọ́n.—Mát. 6:19-21; Lúùkù 12:15-21.

4 Máa Wá Ire Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́: Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fi àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí ṣáájú gbogbo ohun mìíràn. Ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣàlàyé pé: “Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” Bí ìyẹn bá dá wa lójú, kò ní sí ohun ìdènà tí kò ní jẹ́ ká ṣe ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn náà pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan [ti ara tó pọndandan] wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” Ọlọ́run yóò rí i dájú pé a ní nǹkan tó pọndandan wọ̀nyẹn! (Mát. 6:31-33) Àkókò kọ́ nìyí fún wa láti jẹ́ kí àníyàn tí kò yẹ lórí bí a ṣe máa gbọ́ bùkátà pín ọkàn wa níyà tàbí láti jẹ́ kí ìfẹ́ mímú kí ipò nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún wa nínú ètò àwọn nǹkan tó máa tó kọjá lọ yìí pín ọkàn wa níyà.—1 Pét. 5:7; 1 Jòh. 2:15-17.

5 Ìdí pàtàkì tí èèyàn ṣe ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ni láti pèsè àwọn ohun tí a nílò nípa tara. Ṣùgbọ́n báwo lohun táa nílò ti pọ̀ tó? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” Ṣé ńṣe la ń gbìyànjú láti ní jù bẹ́ẹ̀ lọ ni? Bí a bá lọ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe ká rí àbájáde tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” (1 Tím. 6:8, 9; Mát. 6:24; Lúùkù 14:33) Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá nínífẹ̀ẹ́ sí ohun tó pọ̀ jù ti ń ṣèdíwọ́ fún wa?

6 Bó bá jẹ́ pé nítorí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ táa ń ṣe, a kì í fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí tí a kò rí ìdí tó fi yẹ ká yááfì àwọn ohun kan nítorí ìhìn rere náà, a jẹ́ pé ó yẹ ká ṣàtúntò àwọn ohun àkọ́múṣe wa. (Héb. 13:15, 16) Ọ̀nà ìgbésí ayé tó túbọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì yóò ṣèrànwọ́ gidigidi láti mú ohun ìdènà fún iṣẹ́ ìwàásù wa yìí kúrò. Ire Ìjọba náà ló gbọ́dọ̀ máa gba ipò iwájú nígbà gbogbo bó bá dọ̀rọ̀ bí a ṣe máa lo àkókò àti agbára wa.

7 Òpò Tí Kì Í Ṣe Asán: Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò [wa] kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ni àkọ́kọ́ nínú “iṣẹ́ Olúwa.” (Mát. 24:14; 28:19, 20) Láti lè kópa nínú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ó yẹ kí á ṣètò àkókò fún iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí á sì sapá láti má ṣe lo àkókò yẹn fún ohun mìíràn. (Éfé. 5:15-17) Nígbà náà, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí ohunkóhun mìíràn kò ní di ohun ìdènà fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

8 Nígbà tí a bá yọ̀ǹda ara wa láti lọ sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn, a máa ń ní ojúlówó ayọ̀ tó máa ń wá látinú fífúnni. (Ìṣe 20:35) Nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, a lè ní ìgbọ́kànlé bí a ti ń wo ọjọ́ iwájú “nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ [wa] àti ìfẹ́ tí [a] fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Héb. 6:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́