Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí
1 Àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé kò sí ohun téèyàn lè dáwọ́ lé tó níláárí ju pé kéèyàn jẹ́ ẹni tẹ̀mí kí ó sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Bí a kò bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, a ò lè sọ pé a ń sin Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 2:14-16) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Báwo la ṣe lè di ẹni tẹ̀mí, kí sì ni èrè rẹ̀?
2 Ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Àṣàrò: Ìkẹ́kọ̀ọ́ ju pé kéèyàn ṣáà ti ka Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tá a gbé karí Bíbélì lọ. Ó kan pé kéèyàn dìídì pọkàn pọ̀ láti fiyè sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ànímọ́ àwọn kan ni láti máa kẹ́kọ̀ọ́, àwọn kan kò ní in. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní láti kọ́ láti fẹ́ràn kíkẹ́kọ̀ọ́ ni.—Sm. 34:8; 1 Pét. 2:2.
3 Ṣíṣe àṣàrò kan wíwá àyè láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀ràn kan. A lè ronú nípa ìràpadà, àwọn ànímọ́ Jèhófà tí ìṣẹ̀dá fi hàn, bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe tan mọ́ra wọn àti bí a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò fúnra ẹni. Sísapá láti wá àkókò sígbà tí nǹkan pa rọ́rọ́, tí àwọn ohun tó lè pín ọkàn níyà kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí nígbà téèyàn bá ń ṣàṣàrò yóò jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀.—Jẹ́n. 24:63; Lúùkù 4:42.
4 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe fọwọ́ kékeré mú ìdàgbàsókè wa nípa tẹ̀mí. Obìnrin kan tó ti ń wá sí àwọn ìpàdé tó sì ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ látìgbà ọmọdé rí i pé a gbọ́dọ̀ ṣe ju pé ká kàn máa kópa nínú ìgbòkègbodò Kristẹni, nítorí pé nígbà tó yá, ó lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla. Lẹ́yìn tó ṣàtúnṣe, ó sọ pé: “Mo ronú pé mo jẹ́ ẹni tẹ̀mí, ṣùgbọ́n mo wá rí i pé ọwọ́ yẹpẹrẹ ni mo fi mú nǹkan tẹ̀mí. Lẹ́yìn tí mo ṣubú nípa tẹ̀mí, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í túbọ̀ dá kẹ́kọ̀ọ́, mo sì ń fi àwọn ohun tí mo ń kọ́ sílò. Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́. Àbájáde rẹ̀ ni pé, mo bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà nípa tẹ̀mí, tí mo sì wá ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́.”
5 Kò Sáyè fún Ìfẹ́ Ara: Jèhófà kò fẹ́ ká jìyà ká tóó gbọ́n. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.” (Gál. 5:16) Bí a bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí, a óò ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ níwájú Ọlọ́run nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 1:1-3.