Máa Fi Ìdí Tí A Fi Ń Wàásù Sọ́kàn
1 Bí a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó di dandan pé ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:37-39) Wíwàásù ìhìn rere náà jẹ́ ọ̀nà kan tí a lè gbà fi ìfẹ́ yìí hàn. A gbóríyìn fún yín fún ìsapá yín tí ń bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn náà.
2 Ìdí Tí A Fi Ń Wàásù: Bí a bá ń fi ìdí tí a fi ń wàásù sọ́kàn kò ní jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa di èyí tí a kàn ń fara ṣe láìfọkàn ṣe é. Ìdí kan tí a fi ń wàásù jẹ́ nítorí kí a lè kọ́ àwọn èèyàn kí a sì sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Ìdùnnú ńláǹlà mà ni o láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà ní àfarawé Jésù Kristi!
3 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń fi ìmọrírì hàn. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ìyẹn pa ìtara tá a ní fún ṣíṣe ohun tó dára kú. (Gál. 6:9) Ní àfikún sí sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ìdí mìíràn tí a fi ń wàásù ni láti jẹ́ ẹ̀rí. (Mát. 24:14) Nítorí náà, bóyá àwọn èèyàn fetí sílẹ̀ tàbí wọn kò fetí sílẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe pàtàkì. Àwọn tí a bá wàásù fún kò ní ní àwíjàre kankan fún kíkọ̀ láti sin Jèhófà. (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 2:3-5; 3:19.) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé iṣẹ́ ìwàásù wa ń fògo fún Jèhófà.—Sm. 50:23.
4 Ròyìn Iṣẹ́ Tó O Ṣe: Òótọ́ ni pé Jèhófà mọ ohun tí olúkúlùkù wa ń ṣe, ó sì lè mọ̀ bóyá tọkàntọkàn la fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wa tàbí pé ńṣe la kàn ń fọwọ́ hẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn ìdí pàtàkì wà tí a fi ní láti máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa. (Ìsík. 9:11; Máàkù 6:30) Ìròyìn máa ń jẹ́ ká mọ ohun tí a ti ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù jákèjádò ayé, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí olúkúlùkù wa lè mọ bí a ti ń ṣe dáadáa sí.
5 Nítorí wíwúlò tí ìròyìn wúlò yìí, ó yẹ ká máa rántí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù. Ní ìdajì oṣù àti ní ìparí rẹ̀. Bí a bá ń fi àwọn ìdí tá a fi ń wàásù sọ́kàn, kì í ṣe kíka wákàtí nìkan la óò máa gbájú mọ́ ṣùgbọ́n a óò tún máa wá bí a óò ṣe lo àkókò náà lọ́nà tó wúlò. Kò bọ́gbọ́n mu pé ká máa fi àkókò ṣòfò nípa bíbá àwọn èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ bọ̀wọ̀ fún ìhìn Ìjọba náà tàbí tí wọn kò tiẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un rárá jiyàn. Síwájú sí i, máa fi sọ́kàn pé “akoko iṣẹ-isin [pápá] rẹ gbọdọ bẹrẹ nigba tí o bẹrẹ iṣẹ ijẹrii ki ó sì pari nigba tí o bá pari ikesini rẹ tí ó kẹhin patapata laarin akoko ijẹrii kọọkan.”—om-YR 104.
6 Bí a bá ń fi ìdí tí a fi ń wàásù sọ́kàn, tí a sì ń gbára lé Jèhófà pátápátá, inú wa yóò máa dùn pé a ń mú inú rẹ̀ dùn nísinsìnyí, a óò sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 27:11; 1 Tím. 4:16.