Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 8
Orin 109
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò United by Divine Teaching láti múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ October 22. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣàṣefihàn méjì tó ṣe ṣókí nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni, kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ October 15, kí ìkejì sì lo Jí! November 8.
17 min: “Nítorí Kí Ni?”a Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ìwúlò lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Fi àṣefihàn kan tí a múra sílẹ̀ dáadáa kún un nípa bí a ṣe lè ṣe èyí nípa lílo orí 17, ìpínrọ̀ 6 sí 8, nínú ìwé Ìmọ̀.
18 min: “Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí.”b Alàgbà ni kí ó sọ ọ́.
Orin 54 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 15
Orin 113
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: O Ha Ní “Ọkàn-Àyà Ìgbọràn” Bí? (1 Ọba 3:9) Alàgbà ni kí ó sọ àsọyé yìí tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 15, 1998, ojú ìwé 25 sí 27. Ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tí a lè gbà fi ìgbọràn hàn nínú bíbá ìjọ ṣiṣẹ́.
20 min: Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn àti ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa ohun tó ń mú wọn ṣàníyàn nípa ìpínkiri ìwé ìròyìn ní ìpínlẹ̀ ìjọ wọn. Wọ́n mẹ́nu kan iye ìwé ìròyìn tí ìjọ wọn ń gbà lóṣù ní ìfiwéra pẹ̀lú iye tí ìjọ ròyìn pé àwọn fi sóde. Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ ẹ̀dà ìwé ìròyìn wọ̀nyí la ń kó pa mọ́ tàbí tá a ń kó dà nù. Báwo ni àwọn akéde ṣe lè máa lo àwọn ìwé ìròyìn wa lọ́nà tó gbéṣẹ́? Àwọn arákùnrin náà jíròrò àwọn kókó méje tó wà nínú apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ October 11, 1999 tí a pè ní “Jẹ́ Kí Fífi Ìwé Ìròyìn Sóde Jẹ Ọ́ Lógún!” Wọ́n ṣàtúnyẹ̀wò ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ February 15, 1998, ojú ìwé 28 àti 29, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a lè gbà fi àwọn àbá náà sílò nínú ìjọ yẹ̀ wò. Wọ́n rọ olúkúlùkù láti gbìyànjú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a ń gbé jáde lóṣooṣù nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
Orin 156 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 22
Orin 120
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àwọn àbá tó wà lójú ìwé 8, ṣàṣefihàn méjì tó ṣe ṣókí nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni, kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ November 1, kí ìkejì sì lo Jí! November 8.
10 min: Báwo Lo Ṣe Máa Fèsì? Ní ṣókí, tọ́ka sí ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 2, nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, níbi tí a ti dáhùn ìbéèrè tó sọ pé, “Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́ pé ẹ̀sìn tiwọn nìkan ṣoṣo ló tọ̀nà.” Jẹ́ kí á ṣe àṣefihàn tí a ti múra sílẹ̀ dáadáa nípa bí a ṣe lè dáhùn ìbéèrè yìí nígbà ìpadàbẹ̀wò, kí á sì fi ọ̀yàyà ké sí ẹni náà láti máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ.
25 min: “Rírí Ìṣọ̀kan Ará Tòótọ́ Nínú Fídíò, United by Divine Teaching.” Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Lo ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ àti èyí tó kẹ́yìn láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ àti láti parí rẹ̀. Láti mú kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nípa fídíò ọ̀hún tani jí, béèrè ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè tí a pèsè. Bí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ bá ti lọ sí àpéjọpọ̀ ní orílẹ̀-èdè mìíràn, jẹ́ kí wọ́n sọ bí rírí tí wọ́n fojú rí bí ètò àjọ wa ṣe kárí ayé, tó sì ṣọ̀kan ṣe rí lára wọn. Tàbí kẹ̀, sọ àwọn ìrírí tí ń wọni lọ́kàn látinú ìwé 1994 Yearbook, ojú ìwé 7 sí 9, àti 1995 Yearbook, ojú ìwé 8 sí 11 (Gẹ̀ẹ́sì). Ní oṣù December, a ó ṣàyẹ̀wò fídíò To the Ends of the Earth. Ní àfidípò, sọ̀rọ̀ lórí “Àwọn Àpéjọpọ̀ Tí Ń Rùmọ̀lárasókè Gbé Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ga.” Alàgbà ni kí ó sọ àsọyé yìí tí a gbé ka Ilé-Ìṣọ́nà January 15, 1994, ojú ìwé 24 sí 30.
Orin 47 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 29
Orin 164
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù October sílẹ̀. Ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ ni a ó fi lọni ní oṣù November. Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí yìí: “Lákòókò ti ipò ọrọ̀ ajé kò rọgbọ yìí, ọ̀pọ̀ ló ṣòro fún láti gbọ́ bùkátà ara wọn. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ìjọba ènìyàn yóò lè yanjú ìṣòro yìí lọ́nà tí kò ní mú ojúsàájú lọ́wọ́ bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Mo rí i pé ìlérí tó wà nínú Bíbélì yìí ń fúnni níṣìírí gidigidi.” Ka Sáàmù 72:12-14. Lẹ́yìn náà, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọ̀ ọ́, kí o sì fi àlàyé tó bá a mu látinú ìtẹ̀jáde náà kún un.
15 min: “Mímọrírì Ohun Tá A Ní.” Kí alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tí ó tóótun bá ìjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀.
18 min: “Ǹjẹ́ O Máa Ń Jẹ Oúnjẹ Tẹ̀mí Dáadáa?”c Sọ pé kí àwùjọ ṣe àfikún àlàyé látinú Ilé Ìṣọ́ April 15, 1997, ojú ìwé 28 sí 31, láti sọ ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ lo ara wa tokuntokun láti lè máa bá jíjẹun kánú nípa tẹ̀mí nìṣó àti bí a ṣe lè ṣe é.
Orin 181 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 5
Orin 167
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
18 min: Ìmúrasílẹ̀ Ìdílé fún Ìpàdé. Bàbá bá ìdílé rẹ̀ jíròrò nípa bí gbogbo wọn ṣe lè múra sílẹ̀ láti kópa dáadáa ní àwọn ìpàdé. Wọ́n lo ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 1999, ojú ìwé 19 àti 20, ìpínrọ̀ 9, láti fi múra ohun tí wọn yóò sọ nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́sẹ̀ yìí sílẹ̀. (1) Olúkúlùkù nínú ìdílé yan ìbéèrè kan tàbí méjì tó máa dáhùn. (2) Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò àwọn ìpínrọ̀ kan ní pàtàkì, wọ́n múra àwọn ìdáhùn wọn sílẹ̀ ní ọ̀rọ̀ ara wọn. (3) Wọ́n yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì tí a tọ́ka sí, wọ́n jíròrò bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe jẹ mọ́ kókó ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì múra ohun tí wọn yóò sọ láti fi bí wọ́n ṣe tan mọ́ ẹ̀kọ́ náà hàn. Gbogbo wọn ló ń hára gàgà láti kópa nínú ìpàdé náà.
17 min: “Máa Fi Ìdí Tí A Fi Ń Wàásù Sọ́kàn”d Alàgbà ni kí ó sọ ọ́.
Orin 151 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.