-
‘Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló Ni Ìwọ Ti Mọ̀’Ilé Ìṣọ́—1998 | April 15
-
-
‘Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló Ni Ìwọ Ti Mọ̀’
GẸ́GẸ́ bí ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ti sọ, bíbá àwọn ọmọdé jòjòló sọ̀rọ̀ ń nípa jíjinlẹ̀ lórí ìdàgbàsókè ọpọlọ wọn, ó ń fìdí agbára ìrònú wọn, òye wọn, àti agbára wọn láti yanjú ìṣòro múlẹ̀. Èyí ń rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì ní ọdún àkọ́kọ́ ìgbésí ayé ìkókó kan. Ìwé ìròyìn International Herald Tribune sọ pé àwọn olùwádìí kan ti gbà nísinsìnyí pé “iye ọ̀rọ̀ tí ọmọdé jòjòló kan ń gbọ́ lójúmọ́ ni ohun títayọ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ń pinnu òye, àṣeyọrí ní ilé ẹ̀kọ́ àti ìdáńgájíá ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ọmọ náà lẹ́yìnwá ọ̀la.”
Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀rọ̀ àsọjáde náà gbọ́dọ̀ ti ẹnu ẹnì kan wá. A kò lè fi tẹlifísọ̀n tàbí rédíò rọ́pò.
Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò iṣan ara ní Yunifásítì Washington ní Seattle, U.S.A., wí pé: “A ti wá mọ̀ pé ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ni a ti ń ṣètò àwọn ìsopọ̀ ètò iṣan ara àti pé ọpọlọ ọmọdé jòjòló ń dúró de ìrírí láti pinnu bí a óò ṣe ṣètò àwọn ìsopọ̀ ètò iṣan ara rẹ̀. Kò tí ì pẹ́ púpọ̀ nísinsìnyí tí a mọ bí ètò yìí ṣe tètè ń bẹ̀rẹ̀ tó. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọdé jòjòló ti kọ́ ìró ohùn èdè ìbílẹ̀ wọn ní ọmọ oṣù mẹ́fà.”
Ìwádìí tako èrò tí ó wọ́pọ̀ pé, àwọn ìkókó yóò dàgbà dáadáa ní ti òye bí a bá wulẹ̀ fi ọ̀pọ̀ ìfẹ́ hàn sí wọn. Ó tún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ipa àwọn òbí nínú ìdàgbàsókè ọmọ.
Èyí rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ lẹ́tà onímìísí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì pé: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìwé mímọ́, tí ìyá Tímótì àti ìyà rẹ̀ àgbà tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ kà fún un, kó ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ó tayọ lọ́lá.—2 Tímótì 1:5; 3:15.
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?Ilé Ìṣọ́—1998 | April 15
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?
Àní nínú ayé onídààmú yìí, ìwọ lè jèrè ayọ̀ láti inú ìmọ̀ pípéye Bíbélì nípa Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú sí i tàbí kí ẹnì kan kàn sí ọ nílé láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú nínú èyí tí a tò sí ojú ìwé 2.
-