ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fy orí 6 ojú ìwé 64-75
  • Ran Ọ̀dọ́langba Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Ọ̀dọ́langba Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí
  • Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀PỌ̀ OLÓTÌÍTỌ́ INÚ ÀTI ALÁÌLÁBÒSÍ
  • OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ JÙMỌ̀ SỌ̀RỌ̀ LÉ LÓRÍ
  • ÌBÁWÍ ÀTI Ọ̀WỌ̀
  • IṢẸ́ ÀTI ERÉ
  • LÁTI Ọ̀DỌ́LANGBA SÍ ÀGBÀLAGBÀ
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • A Ní Ọlọ̀tẹ̀ Nílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Bó O Ṣe Lè Máa Fi Òfin Lélẹ̀ fún Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà
    Jí!—2013
  • Tí Ọmọ Rẹ Bá N Tàpa sí Àṣẹ Rẹ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn Míì
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
fy orí 6 ojú ìwé 64-75

ORÍ KẸFÀ

Ran Ọ̀dọ́langba Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí

1, 2. Irú àwọn ìpèníjà wo àti irú ìdùnnú wo ni àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba lè mú wá?

NÍNÍ ọ̀dọ́langba nínú ilé yàtọ̀ pátápátá sí níní ọmọ ọlọ́dún márùn-ún tàbí ọmọ ọlọ́dún mẹ́wàá pàápàá. Àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba ń mú ìpèníjà àti ìṣòro tiwọn wá, ṣùgbọ́n, wọ́n tún lè mú ìdùnnú àti èrè wá pẹ̀lú. Àwọn àpẹẹrẹ bíi Josefu, Dafidi, Josiah, àti Timoteu fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ lè hùwà lọ́nà tí ó níláárí, kí wọ́n sì ní ipò ìbátan rere pẹ̀lú Jehofa. (Genesisi 37:​2-11; 1 Samueli 16:​11-13; 2 Ọba 22:​3-7; Ìṣe 16:​1, 2) Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́langba lónìí ń fi èyí hàn gẹ́gẹ́ bí òtítọ́. Ó ṣeé ṣe kí o mọ díẹ̀ lára wọn.

2 Síbẹ̀, fún àwọn kan, àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba kún fún wàhálà. Àwọn àgùnbánirọ̀ máa ń nírìírí ìmóríyá àti ìdàrú ọkàn. Àwọn ọ̀dọ́langba lọ́kùnrin lóbìnrin lè fẹ́ òmìnira díẹ̀ sí i, wọ́n sì lè máà nífẹ̀ẹ́ sí ìkálọ́wọ́kò tí àwọn òbí wọn fi lélẹ̀ fún wọn. Síbẹ̀, irú àwọn èwe bẹ́ẹ̀ ṣì jẹ́ aláìnírìírí, wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ onísùúrù, onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba lè jẹ́ alárinrin, ṣùgbọ́n, wọ́n tún lè lọ́jú pọ̀​—fún àwọn òbí àti fún àwọn ọ̀dọ́langba pẹ̀lú. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn èwe lọ́wọ́ ní àwọn ọdún wọ̀nyí?

3. Ọ̀nà wo ni àwọn òbí lè gbà fún àwọn ọmọ wọn àgùnbánirọ̀ ní àǹfààní dídára nínú ìgbésí ayé?

3 Àwọn òbí tí ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bibeli ń fún àwọn ọmọ wọn, àgùnbánirọ̀, ní àǹfààní dídára jù lọ, tí ó ṣeé ṣe, láti tẹ̀ síwájú la àwọn àdánwò yẹn kọjá bọ́ sí ìgbà àgbàlagbà, pẹ̀lú àṣeyọrí. Ní gbogbo ilẹ̀, àti ní gbogbo àsìkò, àwọn òbí àti àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n jọ lo àwọn ìlànà inú Bibeli ti ṣàṣeyọrí.​—Orin Dafidi 119:1.

ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀PỌ̀ OLÓTÌÍTỌ́ INÚ ÀTI ALÁÌLÁBÒSÍ

4. Èé ṣe tí sísọ̀rọ̀ láìlábòsí fi ṣe pàtàkì pàápàá jù lọ ní àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba?

4 Bibeli wí pé: “Ìjákulẹ̀ máa ń wà nínú ìwéwèé níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ àṣírí.” (Owe 15:22, NW) Bí ọ̀rọ̀ àṣírí bá pọn dandan nígbà tí àwọn ọmọ ṣì kéré, ó ṣe kókó ní àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba ní pàtàkì​—nígbà tí ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀dọ́ lo àkókò tí ó túbọ̀ kéré nílé, àti àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn nílé ẹ̀kọ́ tàbí pẹ̀lú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mìíràn. Bí kò bá sí ọ̀rọ̀ àṣírí​—kò ní sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ olótìítọ́ inú àti aláìlábòsí láàárín àwọn ọmọ àti òbí—​àwọn ọ̀dọ́langba lè di àjèjì nínú ilé. Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè mú kí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀?

5. Ojú wo ni a rọ àwọn ọ̀dọ́langba láti fi wo ọ̀ràn jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn?

5 Àwọn ọ̀dọ́langba àti àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwọn nínú ọ̀ràn yìí. Lóòótọ́, ó lè túbọ̀ nira fún àwọn àgùnbánirọ̀ láti bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ ju bí ó ti rí nígbà tí wọ́n wà ní kékeré lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, rántí pé, “níbi tí ìgbìmọ̀ kò sí, àwọn ènìyàn a ṣubú; ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìmọ̀ ni àìléwu.” (Owe 11:14) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kan gbogbo wa, àtèwe àtàgbà. Àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n mọ èyí yóò lóye pé àwọ́n ṣì nílò ìdarísọ́nà jíjáfáfá, níwọ̀n bí wọ́n ti ń dojú kọ àwọn ìṣòro tí ó túbọ̀ lọ́jú pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Wọ́n ní láti mọ̀ pé àwọn òbí wọn onígbàgbọ́ tóótun dáradára gẹ́gẹ́ bí olùgbani nímọ̀ràn nítorí pé wọ́n nírìírí ayé jù wọ́n lọ, wọ́n sì ti fẹ̀rí àníyàn onífẹ̀ẹ́ wọn hàn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nítorí náà, níbi tí wọ́n dàgbà dé yìí, àwọn ọ̀dọ́langba tí ó gbọ́n kì í kẹ̀yìn sí àwọn òbí wọn.

6. Ẹ̀mí ìrònú wo ni àwọn òbí tí ó gbọ́n, tí ó sì nífẹ̀ẹ́, yóò ní ní ti jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́langba wọn?

6 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ṣíṣísílẹ̀ túmọ̀ sí pé òbí yóò gbìyànjú kára láti wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà tí ọ̀dọ́langba náà bá fẹ́ láti sọ̀rọ̀. Bí ìwọ́ bá jẹ́ òbí kan, rí i dájú pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ṣí sílẹ̀, ó kéré tán, níhà ọ̀dọ̀ tìrẹ. Èyí lè má rọrùn. Bibeli sọ pé, “ìgbà dídákẹ́, àti ìgbà fífọhùn” wà. (Oniwasu 3:7) Nígbà tí ọ̀dọ́langba rẹ bá nímọ̀lára pé ó ti tó àkókò láti fọhùn, ó lè jẹ́ àkókò tí ìwọ́ fẹ́ láti dákẹ́. Bóyá o ti yan àkókò náà fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ìsinmi, tàbí fún ṣíṣiṣẹ́ láàárín ilé. Síbẹ̀, bí ọ̀dọ́langba rẹ bá fẹ́ láti bá ọ sọ̀rọ̀, gbìyànjú láti tún ètò rẹ ṣe, kí o sì fetí sílẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun lè má gbìyànjú mọ́. Rántí àpẹẹrẹ Jesu. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ó ti ṣètò àkókò rẹ̀ láti sinmi. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn ènìyàn ṣù bò ó láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó pa sísinmi tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. (Marku 6:​30-34) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́langba mọ̀ pé ọwọ́ àwọn òbí wọ́n máa ń há gádígádí, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ kí a mú un dá àwọn lójú pé àwọn òbí wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá nílò wọn. Nítorí náà, wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kí o sì fòye hàn.

7. Kí ni àwọn òbí ní láti yẹra fún?

7 Gbìyànjú láti rántí bí nǹkan ti rí nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́langba, má sì ṣe pàdánù ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani rẹ! Àwọn òbí ní láti gbádùn wíwà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Nígbà tí àkókò gbẹ̀fẹ́ bá ṣí sílẹ̀, báwo ni àwọn òbí ṣe ń lò ó? Bí wọ́n bá ń fìgbà gbogbo fẹ́ láti lo àkókò gbẹ̀fẹ́ wọn láti ṣe àwọn ohun tí kò kan ìdílé wọn, àwọn ọ̀dọ́langba wọn yóò tètè fura. Bí àwọn àgùnbánirọ̀ bá dórí ìpinnu náà pé, àwọn ọ̀rẹ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ mọyì wọn ju àwọn òbí wọn lọ, ìjọ̀ngbọ̀n yóò ṣẹlẹ̀.

OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ JÙMỌ̀ SỌ̀RỌ̀ LÉ LÓRÍ

8. Báwo ni a ṣe lè gbin ìmọrírì fún ìwà àìlábòsí, iṣẹ́ àṣekára, àti ìwà bíbójú mu, sọ́kàn àwọn ọmọdé?

8 Bí àwọn òbí kò bá tí ì gbin ìmọrírì fún ìwà àìlábòsí àti iṣẹ́ àṣekára sí ọkàn àwọn ọmọ wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba. (1 Tessalonika 4:11; 2 Tessalonika 3:10) Ó tún ṣe kókó fún wọn láti rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn fi tinútinú gbà gbọ́ nínú ìjẹ́pàtàkì gbígbé ìgbésí ayé oníwà rere àti mímọ́. (Owe 20:11) Òbí kan ń ṣe èyí lọ́nà tí ó dára jù lọ nípa àpẹẹrẹ. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti lè “jèrè [àwọn ọkọ aláìgbàgbọ́] láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà awọn aya wọn,” bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọ̀dọ́langba lè kọ́ àwọn ìlànà títọ́ nípasẹ̀ ìwà àwọn òbí wọn. (1 Peteru 3:1) Síbẹ̀, àpẹẹrẹ nìkan kò tó, níwọ̀n bí a ti ṣí àwọn ọmọ payá sí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ burúkú àti sí ọ̀pọ̀ jaburata ìgbékèéyíde tí ń réni lọ lẹ́yìn òde ilé. Nítorí náà, àwọn òbí tí ó bìkítà ní láti mọ ojú ìwòye àwọn ọ̀dọ́langba wọn lórí ohun tí wọ́n ń rí tí wọ́n sì ń gbọ́, èyí sì ń béèrè fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán.​—Owe 20:5.

9, 10. Èé ṣe tí àwọn òbí fi gbọ́dọ̀ rí i pé wọ́n fi ọ̀ràn ìbálòpọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn, báwo sì ni wọ́n ṣe lè ṣe èyí?

9 Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo. Ẹ̀yin òbí, ẹ ha máa ń tijú láti jíròrò nípa ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú àwọn ọmọ yín bí? Bí ojú bá tilẹ̀ ń tì yín, ẹ sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé, dájúdájú, àwọn ọmọ yín yóò kọ́ nípa rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan. Bí wọn kò bá kọ́ ọ láti ọ̀dọ̀ yín, ta ní mọ irú ìsọfúnni tí kò jóòótọ́ tí wọn yóò rí gbà? Nínú Bibeli, Jehofa kò yẹra fún àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ ti ìbálòpọ̀ takọtabo, kò sì yẹ kí àwọn òbí ṣe bẹ́ẹ̀.​—Owe 4:​1-4; 5:​1-21.

10 A dúpẹ́ pé Bibeli ní àwọn ìtọ́sọ́nà ṣíṣe kedere lórí ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ ìwà ìbálòpọ̀ takọtabo, Watchtower Society sì ti tẹ ọ̀pọ̀ ìsọfúnni ṣíṣàǹfààní jáde, tí ń fi hàn pé ìtọ́sọ́nà yìí ṣì ṣeé mú lò ní òde òní. Èé ṣe tí o kò lo àrànṣe yìí? Fún àpẹẹrẹ, èé ṣe tí o kò ṣàtúnyẹ̀wò ìpín náà, “Ibalopọ Takọtabo àti Ìwàrere,” nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, pẹ̀lú ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ obìnrin? Àbájáde rẹ̀ lè yà ọ́ lẹ́nu.

11. Ọ̀nà wo ni ó gbéṣẹ́ jù lọ tí àwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn láti sin Jehofa?

11 Kí ni kókó pàtàkì jù lọ tí àwọn òbí àti àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ lé lórí? Aposteli Paulu mẹ́nu kàn án nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.” (Efesu 6:4) Àwọn ọmọ ní láti tẹpẹlẹ mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa. Ní pàtàkì, wọ́n ní láti kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì gbọdọ̀ fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ín. Níhìn-ín, pẹ̀lú, àpẹẹrẹ lè ṣe púpọ̀. Bí àwọn àgùnbánirọ̀ bá rí i pé àwọn òbí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ‘pẹlu gbogbo ọkàn-àyà wọn ati pẹlu gbogbo ọkàn wọn ati pẹlu gbogbo èrò-inú wọn,’ tí èyí sì mú èso dídára jáde nínú ìgbésí ayé àwọn òbí wọn, a lè sún wọn láti ṣe ohun kan náà. (Matteu 22:37) Lọ́nà kan náà, bí àwọn ọ̀dọ́ bá rí i pé àwọn òbí wọ́n fi ojú tí ó tọ́ wo àwọn ohun ti ara, ní fífi Ìjọba Ọlọrun sí ipò àkọ́kọ́, a óò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ẹ̀mí ìrònú kan náà dàgbà.​—Oniwasu 7:12; Matteu 6:31-33.

12, 13. Àwọn kókó wo ni ó yẹ kí a ní lọ́kàn bí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yóò bá yọrí sí rere?

12 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ àrànṣe ńlá kan nínú ṣíṣàjọpín àwọn ìjẹ́pàtàkì tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́. (Orin Dafidi 119:​33, 34; Owe 4:​20-23) Ṣíṣe irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ déédéé ṣe kókó. (Orin Dafidi 1:​1-3) Àwọn òbí àti àwọn ọmọ wọn ní láti mọ̀ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gba ipò iwájú lọ́wọ́ àwọn ìgbòkègbodò yòókù, kì í ṣe àwọn ìgbòkègbodò yòókù ṣáájú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Síwájú sí i, ó ṣe pàtàkì pé kí a ní ìṣarasíhùwà tí ó tọ́, tí a bá fẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà gbéṣẹ́. Bàbá kan sọ pé: “Àṣírí ibẹ̀ ni fún ẹni tí ń darí rẹ̀ láti jẹ́ kí ara tu gbogbo àwọn tí ó pé jọ, síbẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé​—kí ó jẹ́ àìjẹ́-bí-àṣà, ṣùgbọ́n kí ó máà jẹ́ ṣeréṣeré. Ó lè má rọrùn ní gbogbo ìgbà láti wà déédéé, a sì ní láti tún ẹ̀mí ìrònú àwọn ọmọdé ṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Bí àwọn nǹkan kò bá lọ déédéé nígbà kan tàbí méjì, tẹpẹlẹ mọ́ ọn, kí o sì fojú sọ́nà fún ìgbà tí ó tẹ̀ lé e.” Bàbá yìí kan náà sọ pé, nínú àdúrà òun ṣáájú ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, òún máa ń bẹ̀bẹ̀ ní pàtàkì fún ìrànlọ́wọ́ Jehofa pé kí gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ ní ojú ìwòye títọ́.​—Orin Dafidi 119:66.

13 Dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé jẹ́ ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí onígbàgbọ́. Lóòótọ́, àwọn òbí kan lè máà ní ẹ̀bùn kíkọ́ni, ó sì lè nira fún wọn láti wá ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lárinrin. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dọ́langba rẹ “ní ìṣe ati òtítọ́,” ìwọ yóò fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ọ̀nà onírẹ̀lẹ̀ àti aláìlábòsí láti ní ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí. (1 Johannu 3:18) Wọ́n lè ṣàròyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí wọ́n nímọ̀lára ìfẹ́ ọkàn tí o ní nínú ire wọn.

14. Báwo ni a ṣe lè lo Deuteronomi 11:​18, 19 nígbà tí a bá ń ṣàjọpín ohun tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́langba?

14 Kì í ṣe ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ni àkókò kan ṣoṣo láti ṣàjọpín àwọn ọ̀ràn ṣíṣe kókó nípa tẹ̀mí. O ha rántí àṣẹ Jehofa fún àwọn òbí bí? Ó sọ pé: “Ẹ fi ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà yín àti sí ọkàn yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ ọwọ́ yín fún àmì, kí wọn kí ó sì máa ṣe ọ̀já ìgbàjú níwájú yín. Kí ẹ̀yin kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, kí ẹ̀yin máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ìwọ́ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ́ bá ń rìn ní ọ̀nà, nígbà tí ìwọ́ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ́ bá dìde.” (Deuteronomi 11:​18, 19; tún wo Deuteronomi 6:​6, 7.) Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa wàásù fún àwọn ọmọ wọn ṣáá. Ṣùgbọ́n olórí ìdílé onífẹ̀ẹ́ ní láti wà lójú fò nígbà gbogbo láti lo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti gbé ojú ìwòye tẹ̀mí ìdílé rẹ̀ ró.

ÌBÁWÍ ÀTI Ọ̀WỌ̀

15, 16. (a) Kí ni ìbáwí? (b) Ta ni ó ni ẹrù iṣẹ́ fífúnni ní ìbáwí, ta sì ni ẹrù iṣẹ́ fífetí sí i já lé lórí?

15 Ìbáwí jẹ́ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ń tọ́ni sọ́nà, ó sì ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nínú. Ìbáwí ní èrò láti tọ́ni sọ́nà ju láti jẹni níyà lọ​—bí ìjẹniníyà tilẹ̀ lè wọ̀ ọ́. Àwọn ọmọ rẹ nílò ìbáwí nígbà tí wọ́n wà ní kékeré, nísinsìnyí tí wọ́n ti di ọ̀dọ́langba, wọ́n ṣì nílò rẹ̀ ní ọ̀nà kan, bóyá ju ìgbà tí wọ́n wà ní kékeré lọ pàápàá. Àwọn ọ̀dọ́langba tí ó gbọ́n mọ̀ pé èyí jẹ́ òtítọ́.

16 Bibeli sọ pé: “Aṣiwèrè gan ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fetí sí ìbáwí ni ó mòye.” (Owe 15:5) A rí ohun púpọ̀ kọ́ nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí. Ó fi hàn pé a óò fúnni ní ìbáwí. Ọ̀dọ́langba kan kò lè “fetí sí ìbáwí” bí a kò bá fún un. Jehofa gbé ẹrù iṣẹ́ bíbáni wí lé àwọn òbí lọ́wọ́, pàápàá jù lọ bàbá. Àmọ́ ṣáá o, ẹrù iṣẹ́ fífetí sí ìbáwí náà já lé ọ̀dọ́langba náà lórí. Òun yóò kẹ́kọ̀ọ́ sí i, àṣìṣe rẹ̀ yóò sì dín kù, bí òún bá fetí sí ìbáwí ọlọgbọ́n ti bàbá àti ìyá rẹ̀. (Owe 1:8) Bibeli sọ pé: “Òṣì àti ìtìjú ni fún ẹni tí ó kọ ẹ̀kọ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fetí sí ìbáwí ni a óò bu ọlá fún.”​—Owe 13:18.

17. Ìwàdéédéé wo ni àwọn òbí ní láti fojú sùn nígbà tí wọ́n bá ń báni wí?

17 Nígbà tí àwọn òbí bá ń bá àwọn ọ̀dọ́langba wí, wọ́n ní láti wa déédéé. Wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fún líle koko jù, débi tí wọn yóò fi mú àwọn ọmọ wọn bínú, bóyá kí wọ́n tilẹ̀ pa ìdánilójú tí àwọn ọmọ wọ́n ní nínú ara wọn lára. (Kolosse 3:21) Síbẹ̀, àwọn òbí kò fẹ́ gbọ̀jẹ̀gẹ́ débi pé àwọn ọmọ wọn yóò pàdánù ẹ̀kọ́ tí ó ṣe kókó. Irú ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ bẹ́ẹ̀ lè léwu. Owe 29:17 sọ pé: “Tọ́ ọmọ rẹ, yóò sì fún ọ ní ìsinmi; yóò sì fi inú dídùn sí ọ ní ọkàn.” Bí ó ti wù kí ó rí, Owe 29 ẹsẹ 21 (NW) sọ pé: “Bí ẹnì kan bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ bàjẹ́ láti ìgbà èwe wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀ yóò di aláìlọ́pẹ́ pàápàá.” Bí ẹsẹ yìí tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa ìránṣẹ́, ó kan ọmọ èyíkéyìí nínú ilé, ní ọ̀nà kan náà.

18. Ìbáwí jẹ́ ẹ̀rí kí ni, kí sì ni àwọn òbí ń yẹra fún nígbà tí wọ́n bá ń báni wí lọ́nà tí ó wà déédéé?

18 Ní tòótọ́, ìbáwí yíyẹ jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ tí òbí kan ní sí ọmọ rẹ̀. (Heberu 12:​6, 11) Bí ìwọ bá jẹ́ òbí, ìwọ́ mọ̀ pé ó ṣòro láti rọ̀ mọ́ ìbáwí wíwà déédéé. Kí àlàáfíà lè wà, ó lè jọ bíi pé ó rọrùn láti yọ̀ǹda fún ọ̀dọ́langba kan, tí ó ranrí, láti ṣe ohun tí ó fẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àbárèbábọ̀, òbí tí ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí, yóò jìyà rẹ̀ nipa níní agbo ilé tí kò ṣeé ṣàkóso.​—Owe 29:15; Galatia 6:9.

IṢẸ́ ÀTI ERÉ

19, 20. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè fi ọgbọ́n bójú tó ọ̀ràn eré ìnàjú fún àwọn ọ̀dọ́langba wọn?

19 Ní ìgbà láéláé, a retí kí àwọn ọmọ ṣèrànwọ́ nínú ilé tàbí lóko. Lónìí, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́langba ń ní ọ̀pọ̀ àkókò tí a kò bójú tó. Láti wáhun ṣe, ìṣòwò ayé ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu eré ìnàjú láti lo àkókò gbẹ̀fẹ́ fún. Fi òtítọ́ náà pé ayé kò fi ojú tí ó níláárí wo àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli nípa ìwà rere kún un, ìwọ yóò sì rí okùnfà àgbákò ńlá.

20 Nítorí náà, ọlọgbọ́n òbí yóò tẹpẹlẹ mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ṣe ìpinnu tí ó kẹ́yìn nípa eré ìnàjú. Àmọ́ ṣáá o, má ṣe gbàgbé pé ọ̀dọ́langba náà ń gòkè àgbà. Lọ́dọọdún, ó ṣeé ṣe kí ó máa retí pé kí a túbọ̀ bá òun lò gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà. Nípa báyìí, ó bọ́gbọ́n mu fún òbí láti yọ̀ǹda òmìnira díẹ̀ nínú yíyan eré ìnàjú bí ọ̀dọ́langba náà ti ń dàgbà sí i​—níwọ̀n bí àwọn yíyàn náà bá ti ń fi ìtẹ̀síwájú síhà ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí hàn. Ní àwọn ìgbà míràn, ọ̀dọ́langba náà lè ṣe àwọn yíyàn tí kò lọ́gbọ́n nínú, nínú orin, alábàákẹ́gbẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ ní láti jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́langba náà, kí ó lè ṣe àwọn yíyàn dídára lọ́jọ́ iwájú.

21. Báwo ni ìwàdéédéé nínú iye àkókò tí ọ̀dọ́langba kan ń lò nínú eré ìnàjú yóò ṣe dáàbò bò ó?

21 Báwo ni ó ṣe yẹ kí àkókò tí a yà sọ́tọ̀ fún eré ìnàjú pọ̀ tó? Ní àwọn ilẹ̀ kan, a ti sún àwọn ọ̀dọ́langba láti gbà gbọ́ pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí eré ìnàjú tí ń bá a lọ títí. Nítorí náà, àgùnbánirọ̀ kan lè wéwèé ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ kí ó lè lọ láti orí “ìgbádùn” kan sí òmíràn. Ó kù sí àwọn òbí lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n mọ̀ pé wọ́n ní láti lo àkókò wọn lórí àwọn nǹkan mìíràn pẹ̀lú, irú bí ìdílé, ìdákẹ́kọ̀ọ́, kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, àwọn ìpàdé Kristian, àti àwọn iṣẹ́ ilé. Èyí yóò ṣèdíwọ́ fún “adùn ìgbésí-ayé yii” láti fún Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pa nínú ọkàn wọn.​—Luku 8:​11-15.

22. Pẹ̀lú kí ni eré ìnàjú ní láti ṣe déédéé nínú ìgbésí ayé ọ̀dọ́langba kan?

22 Ọba Solomoni sọ pé: “Èmí mọ̀ pé kò sí rere nínú wọn, bí kò ṣe kí ènìyàn kí ó máa yọ̀, kí ó sì máa ṣe rere ní àyà rẹ̀. Àti pẹ̀lú kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu, kí ó sì máa jadùn gbogbo làálàá rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọrun ni.” (Oniwasu 3:​12, 13) Bẹ́ẹ̀ ni, yíyọ̀ jẹ́ apá kan ìgbésí ayé wíwà déédéé. Ṣùgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ àṣekára pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́langba lónìí ni kò mọ ìtẹ́lọ́rùn tí ń bẹ nínú iṣẹ́ àṣekára tàbí ìmọ̀lára ọ̀wọ̀ ara ẹni tí ń bẹ́ nínú kíkojú ìṣòro àti yíyanjú rẹ̀. A kò fún àwọn kan ní àǹfààní láti mú òye iṣẹ́ tàbí iṣẹ́ ọnà tí wọ́n lè fi ti ara wọn lẹ́yìn ní ọjọ́ iwájú dàgbà. Ìpèníjà ńlá kan nìyí fún òbí. Ìwọ yóò ha rí i dájú pé ọmọ rẹ ní irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ bí? Bí o bá lè ṣàṣeyọrí nínú kíkọ́ ọ̀dọ́langba rẹ láti mọyì iṣẹ́ àṣekára, kí ó sì gbádùn rẹ̀, òun yóò mú ojú ìwòye tí ó sunwọ̀n tí yóò mú àwọn àǹfààní ayérayé wá dàgbà.

LÁTI Ọ̀DỌ́LANGBA SÍ ÀGBÀLAGBÀ

23. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè fún àwọn ọ̀dọ́langba wọn níṣìírí?

23 Àní nígbà tí o bá níṣòro pẹ̀lú ọ̀dọ́langba rẹ pàápàá, ẹsẹ ìwé mímọ́ náà ṣì jẹ́ òótọ́ pé: “Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Korinti 13:8) Má ṣe kùnà láé láti fi ìfẹ́ tí o mọ̀ lára láìsí àníàní hàn. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Èmi ha máa ń gbóríyìn fún ọmọ kọ̀ọ̀kan lórí àṣeyọrí rẹ̀ nínú bíbójú tó ìṣòro tàbí ṣíṣẹ́pá àwọn ìdènà bí? Mo ha máa ń lo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti fi ìfẹ́ àti ìmọrírì mi hàn fún àwọn ọmọ mi, kí àǹfààní náà tó kọjá bí?’ Bí èdèkòyédè tilẹ̀ lè wà ní àwọn ìgbà kan, bí àwọn ọ̀dọ́langba bá ní ìdánilójú ìfẹ́ rẹ fún wọn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí ọ padà.

24. Ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ni ó jẹ́ òtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà gbogbogbòò kan nínú títọ́ àwọn ọmọ dàgbà, ṣùgbọ́n kí ni ó yẹ kí a rántí?

24 Dájúdájú, bí àwọn ọmọdé ti ń di àgbàlagbà, wọn yóò ṣe àwọn ìpinnu wíwúwo rinlẹ̀ fún ara wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn òbí lè máà nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìpinnu náà. Bí ọmọ wọ́n bá pinnu pé òun kò sin Jehofa Ọlọrun mọ́ ńkọ́? Èyí lè ṣẹlẹ̀. Àní díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀mí Jehofa fúnra rẹ̀ kọ ìmọ̀ràn rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì di ọlọ̀tẹ̀. (Genesisi 6:2; Juda 6) Àwọn ọmọ kì í ṣe ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà, tí a lè ṣe láti ṣe ohun tí a ń fẹ́. Wọ́n jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní agbára láti ṣe yíyàn, tí wọn yóò jíhìn fún Jehofa fún ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Síbẹ̀, Owe 22:6 ṣì jẹ́ òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí ìlànà gbogbogbòò kan: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kí yóò kúrò nínú rẹ̀.”

25. Ọ̀nà dídára jù lọ wo ni àwọn òbí lè gbà fi ìmọrírì wọn hàn fún Jehofa fún àǹfààní jíjẹ́ òbí?

25 Nítorí náà, fi ìfẹ́ púpọ̀ yanturu hàn sí àwọn ọmọ rẹ. Ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti tẹ̀ lé ìlànà Bibeli nínú títọ́ wọn dàgbà. Fi àpẹẹrẹ rere ti ìṣe oníwà-bí-Ọlọ́run lélẹ̀. Nípa báyìí, ìwọ yóò fún àwọn ọmọ rẹ ní àǹfààní dídára jù lọ láti dàgbà di àgbàlagbà tí ó níláárí, tí ó bẹ̀rù Ọlọrun. Èyí ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ fún àwọn òbí láti fi ìmọrírì hàn fún Jehofa fún àǹfààní jíjẹ́ òbí.

BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ SÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÀWỌN ÒBÍ LÁTI TỌ́ ÀWỌN Ọ̀DỌ́LANGBA WỌN?

A nílò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.​—Owe 15:22.

A ní láti máa gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yẹ̀ wò déédéé.​—Orin Dafidi 1:​1, 2.

Ọlọgbọ́n ènìyàn ń fetí sí ìbáwí.​—Owe 15:5.

Iṣẹ́ àti eré ní àyè tiwọn.​—Oniwasu 3:​12, 13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 67]

wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà tí ọ̀dọ́langba rẹ bá ń fẹ́ láti bá ọ sọ̀rọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 69]

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé ṣe kókó fún ìdílé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 70]

Fi ìfẹ́ àti ìmọrírì hàn fún àwọn ọmọ rẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́