ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwhf àpilẹ̀kọ 11
  • Tí Ọmọ Rẹ Bá N Tàpa sí Àṣẹ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tí Ọmọ Rẹ Bá N Tàpa sí Àṣẹ Rẹ
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ mi?
  • Tó bá jẹ́ pé ṣe ni ọmọ mi ń tàn mí ńkọ́?
  • Ta ló lẹ̀bi?
  • Báwo ni mo ṣe lè mú kí ọmọ mi máa pa àṣẹ mi mọ́?
  • Bó O Ṣe Lè Máa Fi Òfin Lélẹ̀ fún Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà
    Jí!—2013
  • Bí O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Láìsí Àríyànjiyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Bó O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀
    Jí!—2013
  • Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Wí
    Jí!—2013
Àwọn Míì
Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
ijwhf àpilẹ̀kọ 11
Bàbá àti ìyá kan tí ọmọ wọn ọkùnrin ṣe ohun tó dùn wọ́n.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Tí Ọmọ Rẹ Bá N Tàpa sí Àṣẹ Rẹ

Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń pẹ́ níta ju àkókò tí òbí wọn dá fún wọn lọ. Àwọn míì máa ń tan àwọn òbí wọn jẹ, bóyá kí wọ́n purọ́ fún wọn tàbí kí wọ́n yọ́ jáde kúrò nílé lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Kí lo lè ṣe tí ọmọ rẹ bá ń tàpá sí àṣẹ rẹ?

  • Ṣé ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ mi?

  • Tó bá jẹ́ pé ṣe ni ọmọ mi ń tàn mí ńkọ́?

  • Ta ló lẹ̀bi?

  • Báwo ni mo ṣe lè mú kí ọmọ mi máa pa àṣẹ mi mọ́?

  • Ohun táwọn òbí sọ

Ṣé ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ mi?

Rárá. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn ọmọdé ni ìwà òmùgọ̀ dì sí,” àwọn ọ̀dọ́ sì máa ń hùwà tó fi hàn pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. (Òwe 22:​15, àlàyé ìsàlẹ̀) Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Laurence Steinberg sọ pé: “Àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa ń ṣe ìpinnu wàdùwàdù tí kò sì mọ́gbọ́n dání. Torí náà, gbà pé wọ́n máa ṣe àwọn àṣìṣe kan.”a

Tó bá jẹ́ pé ṣe ni ọmọ mi ń tàn mí ńkọ́?

Má ṣe rò pé ṣe ló kàn wu ọmọ rẹ pé kó máa tàpá sí àṣẹ rẹ. Ìwádìí fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ káwọn òbí wọn ní èrò tó dáa nípa wọn tí ìwà àwọn ọmọ náà ò bá tiẹ̀ fi hàn bẹ́ẹ̀. Tí ọmọ ẹ bá ṣe ohun tó dùn ẹ́, inú tiẹ̀ gan-an ò ní dùn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má sọ fún ẹ.b

Iṣẹ́ ọnà: 1. Fọ́tò egungun ẹsẹ̀ tó kán. 2. Ẹsẹ̀ tí wọ́n mọ nǹkan sí kó lè sàn. 3. Ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ tó ti sàn rìn.

Tí egungun tó kán bá ti jinná, á pa dà lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀. Tí ọmọ rẹ bá tiẹ̀ já ẹ kulẹ̀ nígbà kan rí, ó lè pa dà di ẹni tó ṣeé gbára lé

Ta ló lẹ̀bi?

  • Ṣé àwọn tó ń bá rìn ni? Bíbélì sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àwọn ọ̀rẹ́ máa ń nípa lórí àwọn ọ̀dọ́ gan-an. Àwọn nǹkan míì bí ìkànnì àjọlò àti ìpolówó ọjà náà sì máa ń nípa lórí wọn. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pé àwọn ọ̀dọ́ ò ní ìrírí, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n ṣe ìpinnu tí kò tọ́. Síbẹ̀, tí wọ́n bá fẹ́ di ọmọlúwàbí èèyàn lọ́jọ́ iwájú, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ láti fara mọ́ ohun tó bá tìdí ìpinnu tí wọ́n ṣe jáde, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀.

  • Kí ni mo ṣe? O lè máa ronú pé o ti le koko jù mọ́ ọmọ rẹ, ìyẹn ló sì mú kó hùwà tí kò tọ́. O sì lè máa ronú nígbà míì pé bóyá o ti fàyè gbà á jù. Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá lórí bó o ṣe dá kún ìṣòro náà, ronú lórí ohun tó o lè ṣe báyìí láti yanjú ẹ̀.

Báwo ni mo ṣe lè mú kí ọmọ mi máa pa àṣẹ mi mọ́?

  • Má le koko jù. Ọmọ rẹ lè máa retí pé wàá bínú. O ò ṣe ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn? Fara balẹ̀ bá ọmọ rẹ jíròrò ohun tó fa ìṣòro náà. Ṣé ojúmìító ló ṣe? Ṣé nǹkan ti sú u ni? Ṣé ó máa ń dá wà ni? Ṣé ó wù ú kó lọ́rẹ̀ẹ́ ni? Kò yẹ kó tìtorí èyíkéyìí nínú ohun tá a béèrè yìí ṣe ohun tí kò tọ́, ṣe ló máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ibi tí ọ̀rọ̀ ti wọ́ wá.

    Ìlànà Bíbélì: ‘Yára láti gbọ́rọ̀, lọ́ra láti sọ̀rọ̀, má sì tètè máa bínú.’​—Jémíìsì 1:19.

  • Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀. Bi í láwọn ìbéèrè bíi, Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Tírú nǹkan báyìí bá tún ṣẹlẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ máa ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè mọ béèyàn ṣe ń ronú lọ́nà táá fi lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.

    Ìlànà Bíbélì: “Máa báni wí, máa fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, máa gbani níyànjú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ sùúrù àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.”​—2 Tímótì 4:2.

  • Jẹ́ kó mọ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Èyí máa ṣiṣẹ́ gan-an tí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ò bá ju ohun tó ṣe lọ. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ bá lo mọ́tò rẹ láìgbàṣẹ, o lè má jẹ́ kó wakọ̀ fún àwọn àkókò kan.

    Ìlànà Bíbélì: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”​—Gálátíà 6:7.

  • Mú kó rọrùn fún ọmọ rẹ láti máa pa àṣẹ rẹ mọ́. Òótọ́ ni pé ọmọ rẹ ò ní ṣàdédé máa pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́. Síbẹ̀, ọmọ rẹ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, nǹkan ṣì lè pa dà bọ̀ sípò. Jẹ́ kó rí i pé o kì í ṣe ẹni téèyàn ò lè tẹ́ lọ́rùn. Tí ọmọ rẹ bá rí i pé òun ò lè tẹ́ ọ lọ́rùn láé, ó lè má gbìyànjú mọ́.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọ́n má bàa soríkodò.”​—Kólósè 3:21.

Gílóòbù.

Ìmọ̀ràn: Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa títọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ rẹ nígbà tó o bá ṣe àṣìṣe tàbí tó o ṣe ìpinnu tí kò tọ́.

Ohun táwọn òbí sọ

Joseph àti Lisa.

“Àwọn òbí lè máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbọràn, ṣùgbọ́n tí àwọn fúnra wọn kì í bá ṣe ohun tí wọ́n sọ, wọn ò ní ṣeé gbára lé. Lọ́wọ́ kejì, táwọn ọmọ bá rí i pé àwọn òbí wọn fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣe ohun tí wọ́n sọ, àwọn ọmọ wọn á fẹ́ fìwà jọ wọ́n. Kódà, inú àwọn ọmọ náà á dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀.”​—⁠Joseph àti ìyàwó rẹ̀ Lisa.

Karyn àti Daniel.

“Tí òbí bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ọmọ nígbà tí wọ́n ṣì kéré, ìyẹn máa mú kí nǹkan rọrùn táwọn ọmọ náà bá di ọ̀dọ́. Ó tún yẹ káwọn òbí máa fún àwọn ọmọ wọn ní òmìnira díẹ̀díẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ ohun tí àwọn fẹ́ àtohun táwọn ò fẹ́. Táwọn ọmọ bá rí i pé àwọn òbí àwọn ń gbìyànjú láti mọ àwọn àti pé wọ́n ń fún àwọn lómìnira tó yẹ, àwọn ọmọ ò ní máa fi bẹ́ẹ̀ tàpá sí àṣẹ àwọn òbí wọn.”​—Karyn àti ọkọ rẹ̀ Daniel.

Àtúnyẹ̀wò: Tí Ọmọ Rẹ Bá N Tàpa sí Àṣẹ Rẹ

  • Má le koko jù. Fara balẹ̀ bá ọmọ rẹ jíròrò ohun tó fa ìṣòro náà.

  • Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀. Bi í láwọn ìbéèrè bíi, Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Kí lo máa ṣe tírú ẹ̀ bá tún ṣẹlẹ̀?

  • Jẹ́ kó mọ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Èyí máa ń ṣiṣẹ́ gan-an tí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ò bá ju ohun tó ṣe lọ.

  • Mú kó rọrùn fún ọmọ rẹ láti máa pa àṣẹ rẹ mọ́. Tí ọmọ rẹ bá rí i pé òun ò lè tẹ́ ọ lọ́rùn láé, ó lè má gbìyànjú mọ́.

a Látinú ìwé You and Your Adolescent.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọkùnrin là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí, tọkùnrin tobìnrin ni ìsọfúnni tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí wà fún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́