ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 5/13 ojú ìwé 15-16
  • Bó O Ṣe Lè Máa Fi Òfin Lélẹ̀ fún Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Máa Fi Òfin Lélẹ̀ fún Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà
  • Jí!—2013
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Wí
    Jí!—2013
  • Bí O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Láìsí Àríyànjiyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Tí Ọmọ Rẹ Bá N Tàpa sí Àṣẹ Rẹ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ran Ọ̀dọ́langba Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—2013
g 5/13 ojú ìwé 15-16

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Máa Fi Òfin Lélẹ̀ fún Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọmọ rẹ máa ń sọ pé àwọn òfin rẹ ti le jù. Àmọ́ lójú tìẹ, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Torí pé, tí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún un, ó lè kó sí wàhálà!

Kò burú to o bá fi àwọn òfin lélẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ìdí tí ọmọ rẹ fi ń ráhùn pé àwọn òfin yẹn ti le jù.

OHUN TÓ FÀ Á

Èrò èké: Gbogbo ọmọ ni kì í fẹ́ tẹ̀ lé òfin àwọn òbí, bó ṣe máa ń rí nìyẹn tọ́mọ bá ti ń bàlágà.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Tí òbí bá fi òfin lélẹ̀ fún ọmọ tó ti ń bàlágà, tí òun àti ọmọ náà sì jọ jíròrò rẹ̀ dáadáa, kò dájú pé ọmọ yẹn á tàpá sí òfin náà.

Àwọn nǹkan kan lè mú kí ọmọ kọ̀ láti tẹ̀ lé òfin àwọn òbí rẹ̀, bóyá torí pé òbí yẹn ti le jù tàbí kò fẹ́ gbà pé ọmọ náà ti ń dàgbà. Jẹ́ ká gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò:

  • Tó o bá le jù. Tí òbí bá kàn gbé òfin kalẹ̀ tí kò sì bá ọmọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ọmọ lè máa rò pé òfin yẹn ń ká òun lọ́wọ́ kò dípò kó dáàbò bo òun. Torí náà, ó lè máa dọ́gbọ́n ṣe ohun tí òbí rẹ̀ sọ pé kò gbọ́dọ̀ ṣe.

  • Tí ọmọ rẹ bá ti ń bàlágà. Àwọn ọmọ tó ti ń bàlágà máa ń nílò àlàyé ju àwọn ọmọdé lọ, wọ́n fẹ́ mọ ìdí tó o fi ní kí wọ́n má ṣe ohun kan. Torí tó bá yá, ọmọ tó ti bàlágà ṣì máa kúrò lákàtà òbí, á sì máa dá ìpinnu ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi dáa kó mọ béèyàn ṣe lè ronú jinlẹ̀ kó tó ṣe ìpinnu, kó tó lọ máa dá gbé.

Kí lo lè ṣe tó bá dà bíi pé àwọn òfin tó o fi lélẹ̀ ti le jù fún ọmọ rẹ?

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Lákọ̀ọ́kọ́, mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ tó ti ń bàlágà ń fẹ́ ìtọ́sọ́nà, wọ́n sì nílò rẹ̀. Torí náà, fún wọn lófin, àmọ́ rí i pé o ṣàlàyé ohun tó o fẹ́ kí wọ́n ṣe fún wọn dáadáa. Ìwé kan tó ń jẹ́ Letting Go With Love and Confidence sọ pé: “Táwọn òbí bá fún àwọn ọmọ wọn lófin tí kò le jù, tó sì yé wọn dáadáa, wọn kò ní tàpá sí òfin náà. Torí wọ́n á ti gbà pé òbí àwọn kò ní máa tojú bọ gbogbo ohun táwọn bá ń ṣe.” Ṣùgbọ́n, àwọn òbí tí kò bá fi òfin lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn kò fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ náà jẹ àwọn lógún. Ìyẹn sì lè mú kí àwọn ọmọ náà ya pòkíì.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 29:15.

Kí lo lè ṣe tí ìṣòro yìí kò fi ní wáyé? Jẹ́ kí ọmọ rẹ sọ ohun tó rò nípa àwọn òfin tó o fi lélẹ̀ nínú ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, tó bá sọ pé aago tó o ní kí òun máa wọlé ti yá jù, fara balẹ̀ gbọ́ àlàyé tó fẹ́ ṣe. Tó bá rí i pé o gba tòun rò, kódà tí o kò bá tiẹ̀ yí òfin náà pa dà, kò ní torí ìyẹn kọ̀rọ̀ sí ẹ lẹ́nu.—Ìlànà Bíbélì: Jákọ́bù 1:19.

Kó o tó ṣe ìpinnu, máa rántí pé àwọn ọmọ tó ti ń bàlágà sábà máa ń ráhùn pé àwọn òbí kì í fún àwọn láyè tó báwọn ṣe fẹ́, àwọn òbí sì lè má fi bẹ́ẹ̀ fún wọn láyè tó bó ṣe yẹ. Torí náà, ronú dáadáa lórí ohun tí ọmọ rẹ sọ pé òun ń fẹ́. Ṣé ọmọ náà kò ní ṣi àǹfààní tó o bá fún un lò? Ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣe ohun tó fẹ́? O lè ṣe ohun tó fẹ́, tó o bá rí i pé kò burú.—Ìlànà Bíbélì: Jẹ́nẹ́sísì 19:17-22.

Yàtọ̀ sí pé kó o gba ọmọ láyè láti sọ tẹnu rẹ̀, jẹ́ kó mọ àwọn ohun tó wà lọ́kàn tìẹ náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń kọ́ ọ láti máa gba tàwọn ẹlòmíì rò.—Ìlànà Bíbélì: 1 Kọ́ríńtì 10:24.

Lẹ́yìn náà, pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe, kó o sì ṣàlàyé ìdí tó o fi fẹ́ ṣe é. Tí ọmọ rẹ ò bá tiẹ̀ fara mọ́ ìpinnu rẹ, inú rẹ̀ á ṣì dùn pé òun ní àwọn òbí tó gba ti òun rò. Rántí pé ọmọ rẹ ti ń dàgbà. Torí náà, máa gba tiwọn rò kó o tó gbé òfin kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jọ máa jíròrò rẹ̀. Wàá lè ràn án lọ́wọ́ kó lè di ọmọlúwàbí.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 22:6.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.”—Fílípì 4:5.

  • “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”—Kólósè 3:21.

ÌMỌ̀RÀN FÚN ÀWỌN Ọ̀DỌ́

“Ká sọ pé ọkùnrin kan jẹ báńkì lówó. Bó bá ń san gbèsè rẹ̀ pa dà bó ṣe yẹ, ó dájú pé báńkì yẹn máa fọkàn tán an, wọ́n á sì lè yá a lówó nígbà míì. Bọ́ràn ṣe rí pẹ̀lú àwọn òbí nìyẹn. Ìwọ náà jẹ àwọn òbí rẹ ní gbèsè ìgbọràn. Bó o bá jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ lórí nǹkan kékeré pàápàá, ó dájú pé wọ́n á fọkàn tán ẹ lọ́jọ́ iwájú. Bí o kò bá gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé wọ́n lè dín òmìnira tó o ní tẹ́lẹ̀ kù tàbí kí wọ́n tiẹ̀ má fún ẹ láyè kankan mọ́ pàápàá.’”—Látinú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́