ORÍ KẸJỌ
Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun
1-3. (a) Àtibo ni agbára ìdarí apanirun, tí ń wu ìdílé léwu ti ń wá? (b) Ìwàdéédéé wo ni àwọn òbí nílò ní dídáàbò bo ìdílé wọn?
ÓKÙ díẹ̀ kí o rán ọmọkùnrin rẹ kékeré jáde lọ sí ilé ẹ̀kọ́, nígbà tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ yàà. Báwo ni ìwọ yóò ṣe bójú tó ipò ọ̀ràn yìí? Ìwọ yóò ha jẹ́ kí ó bẹ́ jáde láìwọṣọ òjò kankan? Tàbí ìwọ yóò kó aṣọ sí i lọ́rùn débi tí kò ní ṣeé ṣe fún un láti rìn mọ́? Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe ọ̀kankan nínú méjèèjì. Ìwọ yóò fún un ní ìwọ̀nba ohun tí ó nílò kí òtútù má ba à mú un.
2 Ní ọ̀nà kan náà, àwọn òbí gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà wíwà déédéé láti dáàbò bo ìdílé wọn lọ́wọ́ agbára ìdarí apanirun, tí ń rọ̀ yàà lé wọn lórí láti ọ̀pọ̀ orísun—ilé iṣẹ́ eré ìnàjú, ilé iṣẹ́ ìròyìn, àwọn ojúgbà wọn, àti ní ilé ẹ̀kọ́ pàápàá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn òbí kan kì í ṣe ohunkóhun láti dáàbò bo ìdílé wọn. Àwọn mìíràn, ní wíwo gbogbo agbára ìdarí tí ń wá láti ìta gẹ́gẹ́ bí apanilára, ń káni lọ́wọ́ kò débi pé àwọn ọmọ nímọ̀lára pé a kò fún wọn ní àyè àtimí. Ó ha ṣeé ṣe láti wà déédéé bí?
3 Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe. Jíjẹ́ aláṣejù kì í gbéṣẹ́, ó sì lè fa ìjàm̀bá. (Oniwasu 7:16, 17) Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn Kristian òbí ṣe ń rí ìwàdéédéé yíyẹ nínú dídáàbò bo ìdílé wọn? Gbé àwọn apá mẹ́ta yẹ̀ wò: ẹ̀kọ́ ìwé, ìbákẹ́gbẹ́, àti eré ìnàjú.
TA NI YÓÒ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ?
4. Ojú wo ni ó yẹ kí àwọn Kristian òbí fi wo ẹ̀kọ́ ìwé?
4 Àwọn Kristian òbí ń fi ojú pàtàkì wo ẹ̀kọ́ ìwé. Wọ́n mọ̀ pé ilé ẹ̀kọ́ ń ran ọmọ lọ́wọ́ láti kàwé, kọ̀wé, báni sọ̀rọ̀, àti láti yanjú ìṣòro pẹ̀lú. Ó sì tún gbọ́dọ̀ kọ́ wọn ní bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́. Òye iṣẹ́ tí àwọn ọmọ ń jèrè ní ilé ẹ̀kọ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí láìka àwọn ìpèníjà inú ayé lónìí sí. Ní àfikún sí i, ẹ̀kọ́ ìwé gbígbámúṣé lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ gíga lọ́lá.—Owe 22:29.
5, 6. Bawo ni a ṣe lè ṣí àwọn ọmọ tí ń bẹ ní ilé ẹ̀kọ́ payá sí ìsọfúnni lílòdì lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo?
5 Bí ó ti wù kí ó rí, ilé ẹ̀kọ́ tún ń mú àwọn ọmọ ṣalábàápàdé àwọn ọmọ mìíràn—ọ̀pọ̀ nínú wọ́n sì ní ojú ìwòye òdì. Fún àpẹẹrẹ, gbé ojú ìwòye wọn nípa ìbálòpọ̀ takọtabo àti ìwà rere yẹ̀ wò. Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní Nàìjíríà, ọmọbìnrin oníṣekúṣe kan máa ń fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn lórí ìbálòpọ̀ takọtabo. Wọ́n máa ń fi ìháragàgà tẹ́tí sí i, bí àwọn èrò rẹ̀ tilẹ̀ kún fún ìsọkúsọ tí ó ti rí kọ́ láti inú àwọn ìwé arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè. Díẹ̀ lára àwọn ọmọbìnrin náà dán ìmọ̀ràn rẹ̀ wò. Ní àbárèbábọ̀, ọmọbìnrin kan gboyún, ó sì kú níbi tí ó ti ń gbìyànjú láti fúnra rẹ̀ ṣẹ́yún.
6 Ó bani nínú jẹ́ láti sọ pé, díẹ̀ lára àwọn ìsọfúnni tí kò tọ́ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo, tí a fi ń kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́, ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́, kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Ìdààmú máa ń bá ọ̀pọ̀ òbí nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ bá kọ́ àwọn ọmọ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo láìpèsè ìsọfúnni lórí ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere àti ìjíhìn. Ìyá ọmọdébìnrin ọlọ́dún 12 kan sọ pé: “Àdúgbò tí ìsìn ti jẹ àwọn ènìyàn lọ́kàn, tí wọ́n ti rọ̀ mọ́ àṣà ìbílẹ̀, ni a ń gbé, síbẹ̀, ní ilé ẹ̀kọ́ gíga àdúgbò, wọ́n ń há kọ́ńdọ̀ọ̀mù fún àwọn ọmọ!” Òun àti ọkọ rẹ̀ ṣàníyàn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn ọmọkùnrin ojúgbà ọmọbìnrin wọn ń fi ìbálòpọ̀ lọ̀ ọ́. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè dáàbò bo ìdílé wọn lọ́wọ́ irú agbára ìdarí lílòdì bẹ́ẹ̀?
7. Ọ̀nà dídára jù lọ wo ni a lè gbà yí ìsọfúnni tí kò tọ́ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo padà?
7 Ó ha dára jù lọ láti dáàbò bo àwọn ọmọ lọ́wọ́ mímẹ́nu kan ọ̀ràn ìbálòpọ̀ èyíkéyìí? Rárá. Ó dára jù láti fúnra rẹ kọ́ àwọn ọmọ rẹ nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo. (Owe 5:1) Lóòótọ́, ní àwọn apá ibì kan ní Europe àti Àríwá America, ọ̀pọ̀ òbí ń yẹra fún sísọ̀rọ̀ nípa kókó yìí. Bákan náà, ní àwọn ilẹ̀ kan ní Áfíríkà, agbára káká ni àwọn òbí fi ń bá àwọn ọmọ wọn jíròrò nípa ìbálòpọ̀ takọtabo. Bàbá kan ní Sierra Leone sọ pé: “Kì í ṣe àṣà wa ní Áfíríkà láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Àwọn òbí kan ń ronú pé, láti kọ́ àwọn ọmọ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo jẹ́ láti gbin èrò tí yóò sún wọn ṣèṣekúṣe sí wọn lọ́kàn! Ṣùgbọ́n, kí ni ojú ìwòye Ọlọrun?
OJÚ ÌWÒYE ỌLỌRUN NÍPA ÌBÁLÒPỌ̀
8, 9. Ìsọfúnni àtàtà wo nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ ni a rí nínú Bibeli?
8 Bibeli mú un ṣe kedere pé, kò sí ohun tí ń tini lójú nínú jíjíròrò ìbálòpọ̀ takọtabo lábẹ́ ipò yíyẹ. Ní Israeli, a sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọrun láti pé jọ pọ̀, títí kan “àwọn ọmọdé” wọn, láti fetí sí kíka Òfin Mose jáde ketekete. (Deuteronomi 31:10-12; Joṣua 8:35) Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, Òfin náà mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ ọ̀ràn nípa ìbálòpọ̀, títí kan nǹkan oṣù, ìtújáde àtọ̀, àgbèrè, panṣágà, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ìbábàátan-ẹni-lòpọ̀, àti ìbẹ́ranko-lòpọ̀. (Lefitiku 15:16, 19; 18:6, 22, 23; Deuteronomi 22:22) Lẹ́yìn gbígbọ́ kíka irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀, kò sí àníàní pé àwọn òbí yóò ní púpọ̀ láti ṣàlàyé fún àwọn ọmọ wọn, tí ń fẹ́ mọ̀ sí i.
9 Àwọn ẹsẹ kan nínú Owe orí ìkarùn-ún, ìkẹfà, àti ìkeje, sọ nípa ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ òbí lórí ewu tí ń bẹ nínú ìwà pálapàla. Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí fi hàn pé ìwà pálapàla lè dẹni wò nígbà míràn. (Owe 5:3; 6:24, 25; 7:14-21) Ṣùgbọ́n, wọ́n kọ́ni pé ó lòdì, pé àbájáde rẹ̀ kò sì sunwọ̀n, wọ́n sì pèsè ìtọ́sọ́nà láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún ìwà pálapàla. (Owe 5:1-14, 21-23; 6:27-35; 7:22-27) Síwájú sí i, a fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ìwà pálapàla àti ìtẹ́lọ́rùn ìgbádùn ìbálòpọ̀ takọtabo ní àyíká tí ó ti yẹ, nínú ìgbéyàwó. (Owe 5:15-20) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àtàtà fún ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí èyí jẹ́ fún àwọn òbí láti tẹ̀ lé!
10. Èé ṣe tí fífún àwọn ọmọ ní ìmọ̀ Ọlọrun nípa ìbálòpọ̀ takọtabo kì yóò fi ṣamọ̀nà wọn sí híwùwà pálapàla?
10 Àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ha ń sún àwọn ọmọ sínú ìwà pálapàla bí? Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá, Bibeli kọ́ni pé: “Ìmọ̀ ni a óò fi gba àwọn olódodo sílẹ̀.” (Owe 11:9) Ìwọ kò ha fẹ́ láti gba àwọn ọmọ rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ agbára ìdarí ayé yìí bí? Bàbá kan sọ pé: “Láti ìgbà tí àwọn ọmọ ti wà ní kékeré ni a kò ti fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún wọn ní ti ìbálòpọ̀ takọtabo. Ní ọ̀nà yẹn, nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí àwọn ọmọ mìíràn ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, wọn kì í ní ìfẹ́ ìtọpinpin. Kò sí àdììtú kankan.”
11. Báwo ni a ṣe lè kọ́ àwọn ọmọdé ní àwọn ọ̀ràn má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ inú ìgbésí ayé, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé?
11 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àwọn orí tí ó ṣáájú, a ní láti bẹ̀rẹ̀ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo ní kùtùkùtù. Nígbà tí o bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ kékeré láti dárúkọ àwọn ẹ̀yà ara, má ṣe fo dídárúkọ àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ ara wọn, bíi pé àwọn wọ̀nyí ń tini lójú. Kọ́ wọn ní orúkọ gidi tí a ń pè wọ́n. Bí àkókò ti ń lọ, ó ṣe kókó láti kọ́ wọn nípa níní ibi ìkọ̀kọ̀ àti ààlà. Ó dára jù bí àwọn òbí méjèèjì bá kọ́ àwọn ọmọ pé àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí jẹ́ àkànṣe, ní gbogbogbòò, tí a kò gbọdọ̀ fi han ẹnikẹ́ni, tàbí jẹ́ kí ẹlòmíràn fọwọ́ kàn án, a kò sì gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ nípa wọn ní ọ̀nà burúkú. Bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà sí i, a gbọ́dọ̀ sọ fún wọn nípa bí ọkùnrin àti obìnrin ti ń wà pọ̀ láti bí ọmọ. Kí wọ́n tó bàlágà, ó yẹ kí wọ́n ti mọ̀ nípa àwọn ìyípadà tí yóò wáyé. Gẹ́gẹ́ bí a ti jíròrò ní Orí 5, irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tún lè ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ lọ́wọ́ dídi ẹni tí a bá ṣèṣekúṣe.—Owe 2:10-14.
IṢẸ́ ILÉ TÍ ÀWỌN ÒBÍ NÍ
12. Irú ojú ìwòye òdì wo ni a sábà máa ń fi kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́?
12 Àwọn òbí ní láti gbara dì láti yí àwọn èrò òdì tí a lè máa fi kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ padà—àwọn ẹ̀kọ́ èrò orí ayé bí ẹfolúṣọ̀n, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, tàbí èrò náà pé kò sí òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro. (1 Korinti 3:19; fi wé Genesisi 1:27; Lefitiku 26:1; Johannu 4:24; 17:17.) Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ olótìítọ́ inú so ìjẹ́pàtàkì tí kò yẹ mọ́ kíkàwé sí i. Nígbà tí ọ̀ràn kíkàwé sí i jẹ́ yíyàn ẹnì kọ̀ọ̀kan, àwọn olùkọ́ kan gbà pé òun nìkan ṣoṣo ni ọ̀nà tí ó lọ sí àṣeyọrí ara ẹni èyíkéyìí.a—Orin Dafidi 146:3-6.
13. Báwo ni a ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ tí ń re ilé ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ àwọn èrò tí kò tọ́?
13 Bí àwọn òbí yóò bá yí àwọn ẹ̀kọ́ èké tàbí àwọn ẹ̀kọ́ òdì padà, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ irú ìtọ́ni tí a ń fún àwọn ọmọ wọn. Nítorí náà, ẹ̀yin òbí, ẹ rántí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ní iṣẹ́ ilé! Fi ojúlówó ìfẹ́ hàn nínú ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Bá wọn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá dé láti ilé ẹ̀kọ́. Béèrè ohun tí wọ́n ń kọ́, ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ, ohun tí ó ṣòro fún wọn jù lọ. Wo iṣẹ́ àmúrelé tí a gbé fún wọn, ìwé àkọsílẹ̀ wọn, àti èsì ìdánwò wọn. Gbìyànjú láti mọ àwọn olùkọ́ wọn. Jẹ́ kí àwọn olùkọ́ mọ̀ pé o mọrírì iṣẹ́ wọn, o sì fẹ́ẹ́ ṣèrànlọ́wọ́ ní ọ̀nà tí ó bá ṣeé ṣe.
ÀWỌN Ọ̀RẸ́ ỌMỌ RẸ
14. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ oníwà-bí-Ọlọ́run yan àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà?
14 “Níbo ni o ti kọ́ ìyẹn?” Òbí mélòó ni ó ti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, bí ẹnú ti yà wọ́n nípa ohun tí ọmọ wọ́n sọ tàbí ṣe, tí kò sì bójú mu rárá? Ìgbà mélòó sì ni ìdáhùn náà ń ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tuntun kan ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí ní àdúgbò? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wa máa ń nípa lórí wa gidigidi, bóyá a jẹ́ àgbà tàbí èwe. Aposteli Paulu kìlọ̀ pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà. Awọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba awọn àṣà-ìhùwà wíwúlò jẹ́.” (1 Korinti 15:33; Owe 13:20) Àwọn èwe ní pàtàkì máa ń tètè ṣubú sọ́wọ́ ìkìmọ́lẹ̀ ojúgbà. Wọn kì í sábà dá ara wọn lójú, ìfẹ́ láti tẹ́ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn lọ́rùn àti láti wú wọn lórí sì lè bò wọ́n mọ́lẹ̀ pátápátá nígbà míràn. Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó, nígbà náà, pé kí wọ́n yan ọ̀rẹ́ àtàtà!
15. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà nínú yíyan ọ̀rẹ́?
15 Gẹ́gẹ́ bí gbogbo òbí ti mọ̀, àwọn ọmọ kì yóò fìgbà gbogbo ṣe yíyàn tí ó dára; wọ́n nílò ìtọ́sọ́nà. Kì í ṣe ọ̀ran bíbá wọn yan ọ̀rẹ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ti ń dàgbà, fi ìfòyemọ̀ kọ́ wọn, sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ irú ànímọ́ tí ó yẹ kí wọ́n kà sí pàtàkì lára ọ̀rẹ́. Ànímọ́ pàtàkì jù lọ jẹ́ ìfẹ́ fún Jehofa àti fún ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú rẹ̀. (Marku 12:28-30) Kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún àwọn tí wọ́n ní ìwà àìlábòsí, inú rere, ọ̀làwọ́, aápọn. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti mọ irú ànímọ́ bẹ́ẹ̀ lára àwọn ènìyàn inú Bibeli, kí wọ́n sì wá àwọn ànímọ́ kan náà lára àwọn tí ó wà nínú ìjọ. Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa lílo ìdíwọ̀n kan náà nínú yíyan àwọn ọ̀rẹ tìrẹ.
16. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè bójú tó irú ọ̀rẹ́ tí àwọn ọmọ wọn ń yàn?
16 O ha mọ àwọn ọ̀rẹ́ ọmọ rẹ bí? Èé ṣe tí o kò sọ fún àwọn ọmọ rẹ láti mú wọn wálé, kí o baà lè mọ̀ wọ́n? O tún lè béèrè ohun tí àwọn ọmọ mìíràn rò nípa àwọn ọ̀rẹ́ wọ̀nyí, lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ. A ha mọ̀ wọ́n sí ẹni tí ń pa ìwà títọ́ mọ́ tàbí ẹni tí ń gbé ìgbésí ayé méjì? Bí wọ́n bá ń gbé ìgbésí ayé méjì, ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ronú lórí ìdí tí irú ìbákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ fi lè pa wọ́n lára. (Orin Dafidi 26:4, 5, 9-12) Bí o bá kíyè sí ìyípadà tí kò sunwọ̀n nínú ìwà, ìmúra, ìṣarasíhùwà, tàbí ìsọ̀rọ̀ ọmọ rẹ, o lè ní láti bá a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọmọ rẹ lè máa lo àkókò pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan tí ń ní agbára ìdarí búburú lórí rẹ̀.—Fi wé Genesisi 34:1, 2.
17, 18. Yàtọ̀ sí kíkìlọ̀ lòdì sí ẹgbẹ́ búburú, ìrànwọ́ gbígbéṣẹ́ wo ni àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn?
17 Síbẹ̀, kò tó láti wulẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti yẹra fún ẹgbẹ́ búburú. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Bàbá kan sọ pé: “A máa ń gbìyànjú nígbà gbogbo láti wá àfidípò. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ń fẹ́ kí ọmọkùnrin wa wà lára ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ní ilé ẹ̀kọ́, èmi àti ìyàwó mi pè é jókòó, a sì jíròrò ìdí tí ìyẹn kì í fi í ṣe àbá dáradára—nítorí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tuntun tí yóò ní. Ṣùgbọ́n, a dábàá pé kí a ṣa àwọn ọmọ jọ nínú ìjọ, kí a sì kó gbogbo wọn lọ gbá bọ́ọ̀lù nínú ọgbà ìtura. Ìyẹn sì yanjú ìṣòro náà.”
18 Àwọn ọlọgbọ́n òbí ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti wá ọ̀rẹ́ àtàtà, kí wọ́n sì gbádùn eré ìnàjú tí ó gbámúṣé pẹ̀lú wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, fún ọ̀pọ̀ òbí, ọ̀ran eré ìnàjú ń mú ìpènijà tirẹ̀ wá.
IRÚ ERÉ ÌNÀJÚ WO?
19. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bibeli wo ni ó fi hàn pé kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fún ìdílé láti gbádùn ara wọn?
19 Bibeli ha dẹ́bi fún gbígbádùn ara ẹni bí? Dájúdájú kò ṣe bẹ́ẹ̀! Bibeli sọ pé, “ìgba rírẹ́rìn-ín . . . àti ìgba fífò kiri” ń bẹ.b (Oniwasu 3:4, NW) Àwọn ènìyàn Ọlọrun ní Israeli ìgbàanì, gbádùn orin àti ijó, àwọn eré àṣedárayá, àti àlọ́ pípa. Jesu Kristi re ibi àsè ìgbéyàwó ńlá àti ibi “àsè ìṣenilálejò gbígbórín,” tí Matteu Lefi ṣe fún un. (Luku 5:29; Johannu 2:1, 2) Dájúdájú, Jesu kì í ṣe abaniláyọ̀jẹ́. Ǹjẹ́ kí a má ṣe ka ẹ̀rín àti ìgbádùn ara ẹni sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú agbo ilé rẹ!
20. Kí ni ó yẹ kí àwọn òbí ní lọ́kàn ní pípèsè eré ìnàjú fún ìdílé wọn?
20 Jehofa jẹ́ “Ọlọrun aláyọ̀.” (1 Timoteu 1:11) Nítorí náà, ìjọsìn Jehofa yẹ kí ó jẹ́ orísun ìdùnnú, kì í ṣe orísun àìláyọ̀ nínú ìgbésí aye ènìyàn. (Fi wé Deuteronomi 16:15.) Àwọn ọmọdé sábà máa ń kún fún ayọ̀ àìníjàánu àti agbára, tí wọ́n lè tú jáde nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré tàbí tí wọ́n bá ń najú. Eré ìnàjú tí a fi ìṣọ́ra yàn máa ń ṣe ju mímúni lórí yá lọ. Ó jẹ́ ọ̀nà kan fún ọmọ láti kẹ́kọ̀ọ́ àti láti dàgbà dénú. Ó jẹ́ ẹrù iṣẹ́ olórí ìdílé láti pèsè fún gbogbo àìní agbo ilé rẹ̀, títí kan eré ìnàjú. Bí ó ti wù kí ó rí, a ní láti wà déédéé.
21. Àwọn ọ̀fìn wo ní ń bẹ nínú eré ìnàjú lónìí?
21 Ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” oníwàhálà wọ̀nyí, àwùjọ ènìyàn kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun,” gan-an gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ tẹ́lẹ̀. (2 Timoteu 3:1-5) Fún ọ̀pọ̀, eré ìnàjú ni ohun pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Ọ̀pọ̀ jaburata eré ìnàjú ni ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, débi pé ó lè tètè gba àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù kúrò lọ́kàn. Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ eré ìnàjú òde òní ń gbé ìwà pálapàla takọtabo, ìwà ipá, ìjoògùnyó, àti àwọn ìwà pípani lára gidi mìíràn, jáde. (Owe 3:31) Kí ni a lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ eré ìnàjú apanilára?
22. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ṣe ìpinnu ọlọgbọ́n ní ti eré ìnàjú?
22 Àwọn òbí ní láti fi ààlà àti ìkálọ́wọ́kò lélẹ̀. Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn bí a ti ń mọ irú eré ìnàjú tí ń pani lára, àti bí a ti ń mọ̀ nígbà tí ó bá pọ̀ jù. Irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ń gba àkókò àti ìsapá. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Bàbá àwọn ọmọkùnrin méjì kan kíyè sí i pé ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà ń fetí sí ilé iṣẹ́ rédíò kan lemọ́lemọ́. Nítorí náà, nígbà tí ó ń wa ọkọ̀ rẹ̀ lọ́ sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ kan, bàbá náà yí rédíò rẹ̀ sí ilé iṣẹ́ kan náà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń dúró láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ orin kan báyìí sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó pe àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ jókòó láti jíròrò ohun tí ó gbọ́ pẹ̀lú wọn. Ó béèrè àwọn ìbéèrè olójú ìwòye, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “Ẹ ti rò ó sí?” ó sì fetí sílẹ̀ kínníkínní sí ìdáhùn wọn. Lẹ́yìn ríronú pọ̀ pẹ̀lú wọn lórí ọ̀ràn náà, ní lílo Bibeli, àwọn ọmọkùnrin náà gbà pé àwọn kò ní fetí sí ilé iṣẹ́ náà mọ́.
23. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ eré ìnàjú tí kò gbámúṣé?
23 Àwọn Kristian òbí tí ó gbọ́n máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn orin, ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, téèpù fídíò, àwọn ìwé aláwòrán àwòrẹ́rìn-ín, àwọn eré àṣedárayá orí fídíò, àti àwọn sinimá, tí àwọn ọmọ wọ́n lọ́kàn ìfẹ́ sí. Wọ́n ń wo àwòrán ara páálí, ọ̀rọ̀ orin, àti ìwé tí ń bá wọn wá, wọ́n ń ka ohun tí ìwé ìròyìn kọ nípa wọn, wọ́n sì ń wo apá díẹ̀ tí a ń fi polówó wọn. Díẹ̀ lára “eré ìnàjú” tí a pète fún àwọn ọmọdé lónìí ń mú ọ̀pọ̀ gbọ̀n rìrì. Àwọn tí ń fẹ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ agbára ìdarí àìmọ́ ń pe ìdílé wọn jókòó láti jíròrò àwọn ewu tí ń bẹ níbẹ̀, ní lílo Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bibeli, irú bí ìwe Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!c Nígbà tí àwọn òbí bá fi ìtọ́sọ́nà dídúró ṣánṣán lélẹ̀, tí wọ́n ṣe déédéé, tí wọ́n sì fòye báni lò, wọ́n sábà máa ń rí àbájáde rere.—Matteu 5:37; Filippi 4:5.
24, 25. Kí ni díẹ̀ lára àwọn eré ìnàjú gbígbámúṣé tí àwọn ìdílé lè jọ gbádùn pọ̀?
24 Dájúdájú, kíka àwọn eré ìnàjú apanilára léèwọ̀ wulẹ̀ jẹ́ ara ìjà náà ni. A ní láti fi rere rọ́pò búburú, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ọmọ lè tọ ipa ọ̀nà tí kò tọ́. Ọ̀pọ̀ ìdílé Kristian ń rántí àìmọye eré ìnàjú tí wọ́n ti jọ gbádùn pọ̀—gbígbádùn lọ, rírìnrìn-in gbẹ̀fẹ́, pípàgọ́ láti gbé fún ìgbà díẹ̀, títayò àti ṣíṣeré ìdárayá, rírìnrìn àjò láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìbátan tàbí ọ̀rẹ́. Àwọn kan ti rí i pé jíjọ kàwé sókè ketekete láti fi dára yá ń mú ìgbádùn àti ìtura ńlá wá. Àwọn mìíràn ń gbádùn pípìtàn apanilẹ́rìn-ín tàbí alárinrin. Síbẹ̀ àwọn mìíràn ti jọ mú ìgbòkègbodò àfipawọ́ jáde, fún àpẹẹrẹ, fífigi ṣe àwọn ohun mèremère àti àwọn iṣẹ́ ọnà míràn, títí kan lílo àwọn ohun èlò orin pa pọ̀, kíkun àwòrán, tàbí kíkẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọrun. A ń dáàbò bo àwọn ọmọ, tí ń kọ́ láti gbádùn irú nǹkan oríṣiríṣi bẹ́ẹ̀, lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ eré ìnàjú tí kò mọ́, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ pé, kì í ṣe jíjókòó tẹtẹrẹ, kí a sì dáni lára yá nìkan ni eré ìnàjú. Kíkópa nínú rẹ̀ máa ń gbádùn mọ́ni ju jíjẹ́ olùwòran lọ.
25 Ìkórajọpọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà pẹ̀lú lè jẹ́ eré ìnàjú kan tí ń mérè wá. Nígbà tí a bá bójú tó wọn dáradára, tí kò sì jẹ́ onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn, ajẹni-lákòókò, ohun tí wọ́n lè fún àwọn ọmọ rẹ lè ju ìgbádùn lọ. Wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti mú ìdè ìfẹ́ tí ń bẹ nínú ìjọ lágbára sí i.—Fi wé Luku 14:13, 14; Juda 12.
ÌDÍLÉ RẸ LÈ ṢẸ́GUN AYÉ
26. Nígbà tí ó bá kan dídáàbò bo ìdílé lọ́wọ́ agbára ìdarí tí kò sunwọ̀n, ànímọ́ wo ni ó ṣe pàtàkì jù lọ?
26 Láìsí àníàní, dídáàbò bo ìdílé rẹ lọ́wọ́ agbára ìdarí apanirun ayé yìí ń béèrè iṣẹ́ àṣekára gidigidi. Ṣùgbọ́n ohun kan wà tí yóò mú kí àṣeyọrí ṣeé ṣe, ju ohunkóhun mìíràn lọ. Ìfẹ́ ni! Ìdè ìdílé pẹ́kípẹ́kí, onífẹ̀ẹ́ yóò mú kí ilé rẹ jẹ́ ibi tí ń fọkàn ẹni balẹ̀, yóò sì gbé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ lárugẹ, èyí tí ó jẹ́ ààbò ńlá lọ́wọ́ agbára ìdarí búburú. Síwájú sí i, mímú oríṣi ìfẹ́ mìíràn dàgbà túbọ̀ ṣe pàtàkì—ìfẹ́ fún Jehofa. Nígbà tí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá wà nínú ìdílé, ó ṣeé ṣe gan-an pé àwọn ọmọ yóò dàgbà di ẹni tí ń kórìíra èrò ṣíṣẹ̀ sí Ọlọrun nípa jíjuwọ́ sílẹ̀ fún agbára ìdarí ayé. Àwọn òbí tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jehofa láti inú ọkàn àyà wọn wá yóò wá ọ̀nà láti fara wé ìwà onífẹ̀ẹ́, lílọ́gbọ́n nínú, wíwà déédéé rẹ̀. (Efesu 5:1; Jakọbu 3:17) Bí àwọn òbí bá ṣe ìyẹn, kò ní sí ìdí fún àwọn ọmọ wọn láti wo ìjọsìn Jehofa gẹ́gẹ́ bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun tí wọn kò gbọdọ̀ ṣe, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbésí ayé tí kò ní ìgbádùn tàbí tí ń múni fajú ro, tí wọ́n sì ń fẹ́ láti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó bá ti lè tètè ṣeé ṣe tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọn yóò rí i pé jíjọ́sìn Ọlọrun ni ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó láyọ̀, tí ó sì nítumọ̀ jù lọ tí ó ṣeé ṣe.
27. Báwo ni ìdílé kan ṣe lè ṣẹ́gun ayé?
27 Àwọn ìdílé tí ó wà pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀, wíwà déédéé ti Ọlọrun, tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn tiraka láti wà ní “àìléèérí ati ní àìlábààwọ́n” lọ́wọ́ agbára ìdarí asọnidìbàjẹ́ ayé yìí, jẹ́ orísun ìdùnnú fún Jehofa. (2 Peteru 3:14; Owe 27:11) Irú ìdílé bẹ́ẹ̀ ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jesu Kristi, tí ó gbéjà ko gbogbo ìsapá ayé Satani láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Ní òpin ìgbésí ayé Jesu gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, ó ṣeé ṣe fún un láti sọ pé: “Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Johannu 16:33) Ǹjẹ́ kí ìdílé rẹ náà pẹ̀lú lè ṣẹ́gun ayé, kí ẹ sì gbádùn ìwàláàyè títí láé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò nípa kíkàwé sí i, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú ìwé 4 sí 7.
b Ọ̀rọ̀ Heberu tí a tú sí “rírẹ́rìn-ín” níhìn-ín, ní ọ̀nà míràn, ni a lè tú sí “ṣíṣeré,” dídáni lára yá,” “ṣíṣàjọyọ̀,” tàbí “gbígbádùn ara ẹni” pàápàá.
c Tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ . . . LÁTI DÁÀBÒ BO ÌDÍLÉ RẸ?
Ìmọ̀ ń ṣamọ̀nà sí ọgbọ́n, tí ó lè gba ẹ̀mí ẹnì kan là.—Oniwasu 7:12.
“Ọgbọ́n ayé yii jẹ́ ìwà òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.”—1 Korinti 3:19.
A gbọ́dọ̀ yẹra fún ẹgbẹ́ búburú.—1 Korinti 15:33.
Bí eré ìnàjú tilẹ̀ ní àyè tirẹ̀, a ní láti ṣàkóso rẹ̀.—Oniwasu 3:4.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 97]
KÒ RONÚ PÉ A FI OHUNKÓHUN DU ÒUN
Àwọn Kristian òbí náà, Paul àti ìyàwó rẹ̀, Lu-Ann, máa ń ṣàpèjẹ nínú ilé wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Wọ́n máa ń rí sí i pé a bójú tó àpèjẹ náà dáradára, tí èrò kò sì pọ̀ jù. Wọ́n ní ìdí rere láti gbà gbọ́ pé àwọn ọmọ wọn ń jàǹfààní láti inú rẹ̀.
Lu-Ann ròyìn pé: “Ìyá ọmọ kíláàsì ọmọkùnrin mi ọlọ́dún mẹ́fà, Eric, tọ̀ mí wá láti sọ fún mi pé, àánú Eric ṣe òun, nítorí pé ó dá jókòó, kò sì dara pọ̀ nínú àpèjẹ ọjọ́ ìbí tí kíláàsì rẹ̀ ṣe. Mo sọ fún un pé: ‘Mo mọrírì pé o bìkítà nípa ọmọ mi lọ́nà yẹn. Ó fi irú ẹni tí o jẹ́ hàn. Mo sì mọ̀ pé kò sí ohun tí mo lè sọ tí yóò mú ọ gbà gbọ́ pé Eric kò ronú pé a fi ohunkóhun du òun.’ Obìnrin náà gbà pẹ̀lú mi. Nítorí náà, mo sọ pé: ‘Nígbà náà, fún ire rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o sì fúnra rẹ béèrè lọ́wọ́ Eric nípa bí ó ṣe nímọ̀lára.’ Nígbà tí n kò sí níbẹ̀, ó bi Eric pé, ‘O kò ha rò pé a ń fi ohun kan dù ọ́, nítorí tí o kì í dara pọ̀ nínú ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí?’ Ọmọ náà wò ó, tìyanutìyanu, ó sì sọ pé: ‘O ha rò pé ìṣẹ́jú mẹ́wàá, àwọn kéèkì kéékèèké, àti orin kan, ni a ń pè ní àpèjẹ bí? Ó yẹ kí o wá sí ilé wa láti wá wo bí àpèjẹ gidi ti ń rí!’” Ìtara aláìlábòsí ọmọ náà mú un ṣe kedere—kò ronú pé a ń fi ohunkóhun du òun tàbí pé òun ń pàdánù ohunkóhun!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 99]
Eré ìnàjú tí a fìṣọ́ra yàn, irú bíi pípàgọ́ láti gbé fún ìgbà díẹ̀, bíi ti ìdílé yìí, lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ àti láti dàgbà nípa tẹ̀mí