Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Ò Yọ Ẹnikẹ́ni Nínú Ìjọ Sílẹ̀
1 Ẹnì kan ṣoṣo kọ́ ló máa ń sọ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Jèhófà lè lo gbogbo àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀ láti ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ́wọ́ kó bàa lè di ẹni tó máa túbọ̀ sún mọ́ òun. (1 Kọ́r. 3:6-9) Yàtọ̀ sí ìdáhùn wa nípàdé ìjọ, ìwà rere wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, èyí tó jẹ́ ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń bá wa gbé, tún máa ń ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́. (Jòh. 13:35; Gál. 5:22, 23; Éfé. 4:22, 23) Nǹkan míì wo la tún lè ṣe láti ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́?
2 Ohun Tí Ìjọ Lápapọ̀ Lè Ṣe: Gbogbo wa la lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé nípa lílo ìdánúṣe láti fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí wọn àti nípa fífi ọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Ọkùnrin kan níran ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó lọ sípàdé, ó sọ pé: “Látọjọ́ tí mo ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n bí mi sí, mi ò tíì rí àwọn èèyàn tó ní ojúlówó ìfẹ́ bí àwọn tí mo bá pàdé lọ́jọ́ kan ṣoṣo yìí rí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn ò mọ̀ mí rí. Mi ò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti máa dààmú mọ́, ó dájú pé mo ti rí òtítọ́.” Oṣù keje lẹ́yìn tó kọ́kọ́ lọ sípàdé ló ṣèrìbọmi.
3 Máa yin akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà bí òye òtítọ́ bá ṣe ń yé e sí i. Ǹjẹ́ kò ní inúnibíni tó ń fara dà lọ́wọ́lọ́wọ́? Ṣó máa ń wá sípàdé déédéé? Ǹjẹ́ ó máa ń gbìyànjú láti dáhùn nípàdé? Ṣó ti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ṣó sì ti ń jáde òde ẹ̀rí? Máa yìn ín bó bá ṣe ń tẹ̀ síwájú sí. Èyí á mára tù ú, á sì tún fún un lókun.—Òwe 25:11.
4 Ohun Tí Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Lè Ṣe: Àwọn akéde kan ti ran ẹni tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti dojúlùmọ̀ àwọn ará ìjọ nípa bí wọ́n ṣe máa ń mú àwọn akéde míì dání bí wọ́n bá fẹ́ lọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Máà jẹ́ kó pẹ́ rárá ti wàá fi fi ìpàdé lọ akẹ́kọ̀ọ́ náà. Bó bá sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, fi í mọ àwọn ẹlòmíràn. Ṣé ẹni tó ń sapá láti fi àṣà búburú bíi sìgá mímu sílẹ̀ ni? Àbí àwọn aráalé rẹ̀ kan ò fẹ́ kó tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀? Ó lè ṣe é láǹfààní bó o bá fojú ẹ̀ mọ akéde tó ti kojú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí tó sì ti borí.—1 Pét. 5:9.
5 Ó pọn dandan kí ìjọ ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà. Gbogbo wa la lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú bá a bá ń ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ wá lógún.