Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 9
Orin 201
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú láti wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú àwo DVD tó ní àkọlé náà, Young People Ask—What Will I Do With My Life? láti múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tó máa dá lé e lórí ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀. Tọ́ka sí “Main Menu,” ìyẹn àwọn ohun tó wà nínú àwo DVD náà, kó o sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè rí ohun tí wọ́n bá fẹ́ wò níbẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ April 15 àti Jí! April–June. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! April–June.) Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, ní kí akéde béèrè ìbéèrè kan tó máa fẹ́ láti dáhùn nígbà ìpadàbẹ̀wò.
15 min: “Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Ò Yọ Ẹnikẹ́ni Nínú Ìjọ Sílẹ̀.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí àwùjọ sọ ọ̀nà táwọn ará gbà jẹ́ ìṣírí fún wọn kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. O lè ti sọ fún ẹnì kan tàbí ẹni méjì pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀ kó tó dọjọ́ náà.
20 min: Màá Sọ Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́! Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Àwọn ọ̀dọ́ kan kì í fẹ́ káwọn ojúgbà wọn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn, torí kí wọ́n má bàa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó o jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó o jẹ́. Báwọn olùkọ́ rẹ bá mọ ohun tó o gbà gbọ́, á túbọ̀ rọrùn fún wọn láti fọ̀wọ̀ ìgbàgbọ́ ẹ wọ̀ ẹ́, wọn ò sì ní takú pé dandan àfi bó o bá ṣe ohun tí ò bójú mu. Ara ò ní máa yá àwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ tí wọn ò níwà ọmọlúwàbí láti ní kó o báwọn lọ́wọ́ sí ìwàkiwà. Àwọn ẹlòmíì á sì máa tètè lóye ìdí tí o kì í fi í bá wọn káṣà bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ jáde, ìdí tí o kì í fi í kópa nínú eré ìdárayá nílé ẹ̀kọ́ àtàwọn nǹkan míì tó yàtọ̀ sí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́. Ẹ̀rù ò sì ní máa fi bẹ́ẹ̀ bà ẹ́ láti wàásù nílé ẹ̀kọ́ tàbí nígbà tó o bá bá ẹni tẹ́ ẹ jọ wà ní kíláàsì pàdé lóde ẹ̀rí. (g02-YR 4/8 ojú ìwé 28) Ní káwọn akéde sọ àǹfààní tí wọ́n ti rí nínú jíjẹ́ káwọn tí wọ́n jọ wà nílé ìwé mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. O lè ti sọ fún ẹnì kan tàbí méjì ṣáájú ọjọ́ tí wàá ṣiṣẹ́ yìí pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti dáhùn.
Orin 43 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 16
Orin 161
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wọn ti ìlàjì oṣù April sílẹ̀. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìbẹ̀rù.”b Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ ṣàlàyé lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ.
20 min: “Báwo Lo Ṣe Máa Lo Ìgbésí Ayé Ẹ?”—Apá Kìíníc Ṣe àlàyé ṣókí lórí ìpínrọ̀ 1 àti 2, kó o wá lọ tààràtà sórí ìjíròrò ìbéèrè ìpínrọ̀ 3 àti 4. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìbéèrè 4 ní ìpínrọ̀ 3, ka ẹsẹ Bíbélì méjèèjì tó wà níbẹ̀. Níparí, ṣàgbéyẹ̀wò “Main Menu,” ìyẹn àwọn ohun tó wà nínú àwo náà. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wo ìsọ̀rí “Interviews” (Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò) àti “Supplementary Material” (Àlàyé Síwájú Sí I) láti lè múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tó máa wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àfirọ́pò, ẹ jíròrò ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “Youths—What Will You Do With Your Life?”
Orin 207 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 23
Orin 215
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! April–June. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 8 fún Jí! April–June.)
10 min: Wò Ó! Àgbàyanu Ni Ìmọ́lẹ̀ Náà! Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ March 15, 2007, ojú ìwé 12 sí 14.
25 min: “Báwo Lo Ṣe Máa Lo Ìgbésí Ayé Ẹ?”—Apá Kejìd Lọ tààràtà sórí ìjíròrò àwọn ìbéèrè ìpínrọ̀ 5 sí 7. Kó o wá fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà ní ìpínrọ̀ 8 kádìí rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àfirọ́pò, ẹ lè jíròrò àpilẹ̀kọ “Ilé Ẹ̀kọ́ Kan Táwọn Tó Jáde Níbẹ̀ Ń Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní Jákèjádò Ayé.” Èyí tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2006, ojú ìwé 10.
Orin 172 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 30
Orin 186
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù April sílẹ̀. Jíròrò Àpótí Ìbéèrè.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
25 min: “Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ọdún 2007.”e Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Kó o tó jíròrò àkìbọnú, ka lẹ́tà tá a kọ ní April 1, 2007, èyí tá a fi sọ déètì àpéjọ tá a yan ìjọ yín sí. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 8 nínú àkìbọnú, ka gbogbo kókó tó wà nínú àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Béèrè Ilé Tó O Máa Dé Sí.” Gba gbogbo gbòò níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò tó bá yẹ ní kánmọ́ bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó.
Orin 44 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 7
Orin 164
10 min: Ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 11.
20 min: “Kí Ni Ṣíṣe Bá Ò Bá Bá Àwọn Kan Nílé?”f Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí.
Orin 178 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.