“Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìbẹ̀rù”
1 Bí wọ́n bá fún ẹ láǹfààní nílé ẹ̀kọ́ tàbí níbi iṣẹ́ pé kó o sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́, ṣé o máa ń lọ́ tìkọ̀ nígbà míì? Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà fáwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn aládùúgbò rẹ tàbí fáwọn tó ò tiẹ̀ mọ̀ rí? Kí ló lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti máa lo àwọn àǹfààní tá a bá ní láti “sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù” nígbàkigbà tí àyè ẹ̀ bá yọ?—Fílí. 1:14.
2 Má Ṣe Lọ́ Tìkọ̀: Bí wọ́n bá fẹ̀sùn èké kan ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan, ṣé wàá lọ́ra láti lọ gbà á sílẹ̀? Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá ni wọ́n ti purọ́ tó burú jáì mọ́ Jèhófà, ẹni tó jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. A sì ní àǹfààní tá a fi lè sọ ohun tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run wa gíga! (Aís. 43:10-12) Bí ìfẹ́ Jèhófà bá jinlẹ̀ lọ́kàn wa, a ò ní jẹ́ káwọn tó ń wò wá kó wa láyà jẹ tàbí kí wọ́n mú wa dẹni tó ń bẹ̀rù àtisọ̀rọ̀, dípò ìyẹn, ńṣe ló máa mú ká lè sọ ohun tá a gbà gbọ́, a ò sì ní máa lọ́ tìkọ̀ láti fi ìgboyà wàásù òtítọ́.—Ìṣe 4:26, 29, 31.
3 Rántí pé ìhìn rere la fẹ́ wàásù. Ayọ̀ tí kò lópin ló sì máa jẹ́ tàwọn tó bá tẹ́tí sí i. Ó máa rọrùn fún wa láti máa wàásù láìṣojo bá a bá ń ronú nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ṣe pàtàkì tó dípò ká máa ronú nípa irú ẹni tá a jẹ́ tàbí nípa ohun táwọn alátakò ń rò tàbí sọ nípa wa.
4 Àpẹẹrẹ Àwọn Ẹlòmíì: Àpẹẹrẹ àwọn olùṣòtítọ́ míì tí wọ́n sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù lè fún wa lágbára láti ṣe bíi tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, Énọ́kù fìgboyà wàásù pé ìdájọ́ Jèhófà ń bọ̀ wá sórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. (Júdà 14, 15) Nóà fi ìṣòtítọ́ wàásù fáwọn èèyàn tí wọn ò fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀. (Mát. 24:37-39) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, tí wọn ‘ò mọ̀wé tí wọ́n sì jẹ́ gbáàtúù’ ń bá a nìṣó láti máa wàásù lójú àtakò tó gbóná janjan. (Ìṣe 4:13, 18-20) Lóòrèkóòrè làwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! máa ń gbé ìtàn ìgbésí ayé àwọn Kristẹni òde òní tí wọ́n ti fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà jáde nípa bí ìbẹ̀rù èèyàn kì í ṣeé pa wọ́n lẹ́nu mọ́, èyí tó mú kí wọ́n dẹni tó ń fìtara wàásù.
5 Ẹ̀rù ò ní máa bà wá bá a bá ń ronú lórí báwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ayé ìgbà yẹn ṣe gbé ìgbé ayé wọn láìfi onírúurú ipò tó le koko tí wọ́n bá pàdé pè. (1 Ọba 19:2, 3; Máàkù 14:66-71) Wọ́n “máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa,” wọ́n sì sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀!—1 Tẹs. 2:2.